Àwọn Ìwé Mímọ́
3 Nífáì 4


Orí 4

Àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ará Nífáì ṣẹ́gun àwọn ọlọ́ṣà Gádíátónì—Wọ́n pa Gídíánhì, ẹnití ó rọ́pò rẹ̀, Sẹ́mnáríhà, ni wọn sì so rọ̀—Àwọn ará Nífáì yin Olúwa fún ìṣẹ́gun tí wọ́n ní. Ní ìwọ̀n ọdún 19 sí 22 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe ní ìparí ọdún kejìdínlógún tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ọlọ́ṣà nnì ti múrasílẹ̀ fún ogun, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí sọ̀kalẹ̀ wá tí wọ́n sì tú jáde láti orí àwọn òkè nã, àti jáde láti inú àwọn òkè gíga, àti aginjù, àti àwọn ibi gíga wọn, àti àwọn ibi ìkọ̀kọ̀ wọn tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí mú àwọn ilẹ̀ nã ní ìní, àti àwọn tí ó wà ní ilẹ̀ apá gúsù àti àwọn tí ó wà ní ilẹ̀ apá àríwá, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí mú gbogbo àwọn ilẹ̀ tí àwọn ará Nífáì ti kọ̀ sílẹ̀ ní ìní, àti àwọn ìlú nlá tí wọ́n ti sọ di ahoro.

2 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, kò sí àwọn ẹranko búburú tàbí ẹran ọdẹ nínú àwọn ilẹ̀ nnì èyítí àwọn ará Nífáì ti kọ̀ sílẹ̀, kò sì sí ẹran ọdẹ fún àwọn ọlọ́ṣà nã àfi nínú aginjù.

3 Àwọn ọlọ́ṣà nã kò sì lè wà lãyè àfi nínú aginjù, nítorí àìsí oúnjẹ; nítorí tí àwọn ará Nífáì ti sọ ilẹ̀ wọn di ahoro, wọ́n sì ti kó àwọn ọ̀wọ ẹran wọn àti àwọn agbo ẹran wọn àti gbogbo ohun ìní wọn, wọ́n sì wà ní ìṣọ̀kán.

4 Nítorínã, kò sí ãyè fún àwọn ọlọ́ṣà nã láti ṣe ìkógun àti láti rí oúnjẹ, àfi bí wọ́n bá jáde wá láti dojúkọ àwọn ará Nífáì ní ìjà; àwọn ará Nífáì sì wà ní àkójọpọ̀ kanṣoṣo, nítorípé wọ́n pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, tí wọ́n sì ti fi àwọn ohun-ìpèsè pamọ́ fún ara wọn, àti ẹṣin àti ẹran ọ̀sin àti ọ̀wọ́ ẹran ní onírũrú, kí wọn ó lè jẹ́ fún ìwọ̀n ọdún méje, nínú àkokò èyítí wọ́n ní ìrètí pé àwọn yíò pa àwọn ọlọ́ṣà nã run kúrò lórí ilẹ̀ nã; bayĩ sì ni ọdún kejìdínlógún kọjá lọ.

5 Ó sì ṣe ní ọdún kọkàndínlógún tí Gídíánhì rí i pé ó yẹ fún òun láti jáde lọ láti gbé ogun ìjà ti àwọn ará Nífáì, nítorítí kò sí ọ̀nà tí wọ́n lè gbà jẹ àfi kí wọn ó kógun àti jalè àti kí wọn ó pànìyàn.

6 Wọn kò sì jẹ́ tàn ká orí ilẹ̀ nã láti gbin irúgbìn, ní ìbẹ̀rù pé àwọn ará Nífáì yíò kọlũ wọ́n tí wọn ó sì pa wọ́n; nítorínã ni Gídíánhì pàṣẹ fún àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ pé nínú ọdún yĩ ni kí wọn ó lọ láti gbé ogun ìjà ti àwọn ará Nífáì.

7 Ó sì ṣe ti wọ́n jáde lọ láti jà; ó sì jẹ́ nínú oṣù kẹfà; ẹ sì kíyèsĩ, ọjọ́ nla ti ó sì ní ẹ̀rù, ni ọjọ́ nã nínú èyítí wọn jáde lọ láti jà; wọ́n sì wọ ẹ̀wù gẹ́gẹ́bí àwọn ọlọ́ṣà; wọ́n sì lọ́ awọ-ọ̀dọ́-àgùtàn mọ́ ìbàdí, wọ́n sì rẹ ara wọn nínú ẹ̀jẹ̀, wọ́n sì fá orí wọn, wọ́n sì fi ìbòrí-ogun bò orí wọ́n; àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Gídíánhì nã sì pọ̀ wọn sì ní ẹ̀rù, nítorí ìhámọ́ra wọn àti nítorítí wọn ti rẹ ara wọn nínú ẹ̀jẹ̀.

8 Ó sì ṣe ti àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Nífáì, nígbàtí wọ́n rí i bí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Gídíánhì ti rí, wọ́n wó lulẹ̀, wọ́n sì kígbe pe Olúwa Ọlọ́run wọn, pé kí ó dá wọn sí kí ó sì gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn.

9 Ó sì ṣe nígbàtí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Gídíánhì rí èyí wọ́n bẹ̀rẹ̀sí kígbe pẹ̀lú ohùn rara, nítorí ayọ̀ wọn, nítorítí wọ́n rò pé àwọn ará Nífáì nã ti ṣubú fún ẹ̀rù nítorí ẹ̀rù àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn.

10 Ṣùgbọ́n nínú èyí ni ìrètí wọn ṣákì, nítorítí àwọn ará Nífáì kò bẹ̀rù wọn; ṣùgbọ́n wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run wọn tí nwọn sì nbẹ̃ fún ãbò rẹ̀; nítorínã, nígbàtí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Gídíánhì sáré síwájú láti pàdé wọn; bẹ̃ni, nínú agbára Olúwa ni wọ́n pàdé wọn.

11 Ìjà nã sì bẹ̀rẹ̀ nínú oṣù kẹfà, ìjà nã sì pọ̀ ó sì ní ẹ̀rù, bẹ̃ni, ìpànìyàn rẹ̀ sì pọ̀ ó sì ní ẹ̀rù, tóbẹ̃ tí kò sí irú ìpànìyàn tí ó pọ̀ báyĩ rí lãrín àwọn ènìyàn Léhì láti ìgbàtí ó ti jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù.

12 Àti l’áìṣírò àwọn ìhàlẹ̀mọ́ àti ìbúra ti Gídíánhì ti ṣe, ẹ kíyèsĩ, àwọn ará Nífáì lù wọ́n, tóbẹ̃ tí wọ́n fi sá padà kúrò níwájú wọn.

13 Ó sì ṣe tí Gídgídónì pàṣẹ pé kí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ ó sá tẹlé wọn títí dé òpin ilẹ̀ aginjù nã, àti pé kí wọn ó má dá ẹnikẹ́ni tí ó bá bọ́ sí ọwọ́ wọ́n bí wọ́n ti nlọ sí; báyĩ ni wọn sì sá tele wọn àti tí wọ́n sì pa wọ́n, títí dé ibi òpin ilẹ̀ aginjù, àní títí wọ́n fi pa àṣẹ Gídgídónì mọ́ tán.

14 Ó sì ṣe tí nwọ́n sá tẹ̀lé Gídíánhì, ẹnití ó ti dúró tí ó sì jà pẹ̀lú ìgboyà, bí ó ti nsálọ; àti nítorípé ó ti rẹ̃ nítorí ìjà púpọ̀ tí ó ti jà wọ́n bã wọ́n sì pã. Báyĩ sì ni ìgbésí ayé Gídíánhì ọlọ́ṣà nnì dópin.

15 Ó sì ṣe tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Nífáì sì padà sí ibi àbò wọn. Ó sì ṣe tí ọdún kọkàndínlógún yí kọjá lọ, àwọn ọlọ́ṣà nã kò sì tún padà wá bá wọn jà; bẹ̃ sì ni wọn kò tún padà wá ní àkokò ogún ọdún.

16 Àti ní ọdún kọkànlélógún wọn kò wá láti bá wọn jà, ṣùgbọ́n wọn gba ọ̀nà púpọ̀ yọ sí wọn láti ká àwọn ènìyàn Nífáì nã mọ́; nítorítí wọ́n rò wípé bí àwọn bá dínà mọ́ àwọn ènìyàn Nífáì nã kúrò lórí ilẹ̀ wọn, tí wọ́n sì ká wọn mọ́ ní gbogbo ọ̀nà, àti pé bí wọ́n bá dínà mọ́ wọn mọ́ gbogbo àwọn ohun tí nlọ ní àyíká wọn pé wọn ó mú kí wọ́n jọ̀wọ́ ara wọn lé wọn lọ́wọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ inú wọn.

17 Nísisìyí wọ́n ti yan olórí míràn lé ara wọn lórí, ẹnití orúkọ rẹ̀ íṣe Sẹ́mnáríhà; nítorínã ni ó fi jẹ́ wípé Sẹ́mnáríhà ni ẹnití ó mú kí ìdótì yĩ ó wá.

18 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, èyí jẹ́ ohun ànfãní fún àwọn ará Nífáì; nítorítí ó jẹ́ ohun tí kò ṣeéṣe fún àwọn ọlọ́ṣà nã láti ká àwọn ará Nífáì nã mọ́ pẹ́ títí láti lè pa wọ́n lára, nítorí ìpèsè púpọ̀ tí wọ́n ti kó pamọ́.

19 Àti nítorí ìpèsè tí kò tó lãrín àwọn ọlọ́ṣà nã; nítorí ẹ kíyèsĩ, wọn kò ní ohunkóhun bíkòṣe ẹran fún jíjẹ, ẹran èyítí wọn nrí mú nínú aginjù.

20 Ó sì ṣe tí àwọn ẹranko ìgbẹ́ nã sì ṣọ̀wọ́n nínú aginjù tóbẹ̃ tí àwọn ọlọ́ṣà nã fẹ́rẹ̀ parun fún ebi.

21 Àwọn ará Nífáì sì njáde lọ ní ọ̀sán àti ní òru, tí wọ́n sì nkọlù àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn, tí wọ́n sì npa wọn ní ẹgbẹ̃gbẹ̀rún àti ní ẹgbẹ̃gbẹ̀rún mẹ́wã-mẹ́wã.

22 Báyĩ ni ó sì jẹ́ ìfẹ́ inú àwọn ènìyàn Sẹ́mnáríhà láti fà sẹ́hìn nínú ète wọn, nítorí ìparun nlá tí ó ti kọlũ wọ́n ní òru àti ní ọ̀sán.

23 Ó sì ṣe tí Sẹ́mnáríhà sì pàṣẹ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pé kí wọn ó fà sẹ́hìn nínú ìdótì nã, kí wọn ó sì kọjá lọ sí ibití ó jìnà réré nínú ilẹ̀ nã ní apá àríwá.

24 Àti nísisìyí, nítorítí Gídgídónì ti ní ìfura sí ète wọn, tí ó sì mọ̀ nípa àìlera tí wọn ní nítorí àìsí oúnjẹ fún wọn, àti ìpakúpa tí wọ́n ti pa wọ́n, nítorínã ni ó ṣe rán àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ jáde ní òru, tí ó sì sé ọ̀nà mọ́ wọn láti má lè sá padà, tí ó sì fi àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ dínà mọ́ wọn lati má lè sá padà.

25 Èyí ni wọ́n sì ṣe ní òru, tí wọ́n sì kọjá àwọn ọlọ́ṣà nã, tí ó fi jẹ́ wípé ní ọjọ́ kejì, nígbàtí àwọn ọlọ́ṣà nã bẹ̀rẹ̀ ìrìn wọn, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Nífáì bá wọn pàdé ní iwájú àti ní ẹ̀hìn.

26 Wọ́n sì sé ọ̀nà mọ́ àwọn ọlọ́ṣà tí ó wà ní apá gúsù pẹ̀lú láti má lè sá padà. Gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí ni wọ́n sì ṣe nípasẹ̀ àṣẹ Gídgídónì.

27 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹgbẹ̃gbẹ̀rún wọn ni ó sì jọ̀wọ́ ara wọn sílẹ̀ ní ẹrú fún àwọn ará Nífáì, àwọn tí ó kù ni a sì pa.

28 Olórí wọn, Sẹ́mnáríhà, ni wọn mú tí wọ́n sì soó rọ̀ kọ́ igi, bẹ̃ni, àní kọ́ orí rẹ̀ títí ó fi kú. Nígbàtí wọ́n sì ti so ó rọ̀ títí ó fi kú nwọn gé igi nã lulẹ̀ wọ́n sì kígbe ní ohùn rara, wípé:

29 Kí Olúwa kí ó pa àwọn ènìyàn rẹ̀ mọ́ nínú òdodo àti nínú ọkàn mímọ́, kí wọn ó lè mú kí a ké lulẹ̀ gbogbo àwọn tí yíò lépa láti pa wọ́n nítorí agbára àti ẹgbẹ́ òkùnkùn, àní gẹ́gẹ́bí a ti ké ọkùnrin yì í lulẹ̀.

30 Nwọ́n sì yọ̀ wọn sì tún kígbe pẹ̀lú ohùn kanṣoṣo, wípé: Kí Ọlọ́run Ábráhámù, àti Ọlọ́run Ísãkì, àti Ọlọ́run Jákọ́bù, ó dãbò bò àwọn ènìyàn yĩ nínú òdodo, níwọ̀n ìgbà tí wọn yíò bá ké pe orúkọ Ọlọ́run wọn fún ìdãbò bò.

31 Ó sì ṣe tí wọ́n gbé ohùn sókè ní ọkanṣoṣo, ní orin kíkọ, àti ní fífi ìyìn fún Ọlọ́run wọn fún ohun nlá èyítí ó ti ṣe fún wọn, ní pípa wọ́n mọ́ kúrò nínú ìṣubú sí ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn.

32 Bẹ̃ni, wọ́n sì kígbe wípé: Hòsánnà sí Ọlọ́run Ẹnití-Ó-Gá-Jùlọ. Nwọ́n sì tún kígbe wípé: Ìbùkún ni fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè, Ọlọ́run Ẹnití-Ó-Gá-Jùlọ.

33 Ọkan wọn sì kún fún ayọ̀, títí omije púpọ̀ fi jáde lójú wọn, nítorí dídára ńlá Ọlọ́run ní gbígbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn; wọ́n sì mọ̀ pé nítorí ìrònúpìwàdà wọn àti ìwà-ìrẹ̀lẹ̀ wọn ni Olúwa ṣe gbà wọ́n kúrò nínú ìparun àìlópin.