Àwọn Ìwé Mímọ́
3 Nífáì 8


Orí 8

Èfũfùlíle, ile riri, iná, ìjì, àti àwọn ìrúkèrúdò ayé jẹ́rĩ sí ìyà kíkàn mọ́ àgbélèbú Krístì—Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn ni ó parun—Òkùnkùn bò ilẹ̀ nã fùn ọjọ́ mẹ́tà—Àwọn tí ó wà lãyè npohùn réré ẹkún nítorí ìpín wọn. Ní ìwọ̀n ọdún 33–34 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí ó sì ṣe wípé gẹ́gẹ́bí àkọsílẹ̀ wa, àwá sì mọ̀ pè àkọsílẹ̀ wa jẹ́ òtítọ́, nítorítí ẹ kíyèsĩ, ẹnití o tọ́ ni ẹnití ó pa àkọsílẹ̀ nã mọ́—nítorítí ó se ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ìyanu ní orúkọ Jésù; kò sì sí ẹnìkẹ́ni tí ó lè se iṣẹ́ ìyanu kan ní orúkọ Jésù bí kò se pé a wẹ̃ mọ́ pátápátá kúrò nínú àìṣedẽdé rẹ̀—

2 Àti nísisìyí ó sì ṣe, bí kò bá sí àṣìṣe láti ọwọ́ ọkùnrin yĩ nípa ìṣírò ìgbà wa, ọgbọ̀n ọdún ó lé mẹ́ta ti kọjá lọ;

3 Àwọn ènìyàn nã sì bẹ̀rẹ̀sí fojúsọ́nà pẹ̀lú ìtara fún àmì nã èyítí wòlĩ Sámúẹ́lì, ará Lámánì nì ti kéde, bẹ̃ni, fún àkókò nã tí òkùnkùn yíò bò ojú ilẹ̀ nã ní ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta.

4 Iyè meji àti àríyànjiyàn nlá sì bẹ̀rẹ̀ sí wà lãrín àwọn ènìyàn nã, l’áìṣírò a ti fún wọn ní àwọn àmì tí ó pọ̀.

5 Ó sì ṣe ní ọdún kẹrinlélọ́gbọ̀n, ní osù kíni, ní ọjọ́ kẹ́rin osù nã, ìjì nlá kan rú sókè, irú èyítí a kò rí rí ní gbogbo ilẹ̀ nã.

6 Èfũfù nlá kan ti o dẹ́rùbani sì tún wà; àrá búburú sì sán, tóbẹ̃ tí ó mi gbogbo ayé bí èyítí yìó là sí méjì.

7 Àwọn mọ̀nàmọ́ná tí ó mọ́lẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ sì wà, irú èyítí a kò rí rí ní gbogbo ilẹ̀ nã.

8 Ìlú-nlá Sarahẹ́múlà sí jóná.

9 Ìlú-nlá Mórónì sì jìn sínú ibú omi, àwọn olùgbé inú rẹ̀ sì rì sínú omi.

10 Ilẹ̀ sì di gbígbé sókè ká orí ìlú-nlá Móróníhà, tí a fi ní òkè gíga nlá kan dípò ìlú-nlá nã.

11 Ìparun nlá èyítí ó burú sì wà ní ilẹ̀ tí ó wà ní apá gũsù.

12 Sùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, ìparun nla tí ó sì burú síi sì wà ní ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá; nítorí ẹ kíyèsĩ, gbogbo orí ilẹ̀ nã ni ó yípadà, nítorí ìjì àti àwọn ẹ̀fũfù líle nã, sísán àrá àti kíkọ mọ̀nàmọ́ná, àti mimì tìtì gbogbo ilẹ̀ nã;

13 Gbogbo àwọn ọ̀nà òpópó ni ó sì fọ́ sí wẹ́wẹ́, àwọn ọ̀nà tí ó tẹ́jú sì di bíbàjẹ́, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ibití ó tẹ́jú di págun-pàgun.

14 Àwọn ìlú nlá olókìkí rì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì jóná, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì mì tí àwọn ilé inú wọn fi wó lulẹ̀, tí àwọn tí ngbé inú wọn sì kú, tí gbogbo ibẹ̀ sì di ahoro.

15 Àwọn ìlú kan sì wà tí a dásí; ṣùgbọ́n tí àdánù inú wọn pọ̀ jùlọ, àti ọpọlọlopọ ni o wà nínú wọn ti wọn sì kú.

16 Àwọn kan ni èfùfulile sì gbé lọ; tí ẹnì kan kò sì mọ́ ibití wọ́n lọ, bíkòse pé wọ́n mọ̀ pé ó gbé wọn lọ.

17 Báyĩ sì ni orí ilẹ̀ ayé gbogbo wà ní àìbójúmu nítorí àwọn èfũfù nlá, àti sísán àrá, àti kíkọ mọ̀nàmọ́ná, àti mimì tìtì ilẹ̀ nã.

18 Sì kíyèsĩ, àwọn àpáta di lílà sí méjì; wọn sì di fífọ́ sí orí ilẹ̀ ayé gbogbo, tóbẹ̃ tí a sì rí wọn ní àkúfọ́, àti ní sísán, àti ní fífọ́ sí wẹ́wẹ́, lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.

19 Ò sì ṣe nígbàtí àwọn sísán àrá, àti kíkọ mọ̀nàmọ́ná, àti èfũfù líle, àti ìjì àti mimì tìtì ilẹ̀ nã dáwọ́dúró—nítorítí ẹ kíyèsĩ, wọ́n wà fún ìwọ̀n wákàtí mẹ́ta; àwọn ènìyàn kan sì sọ pé àkokò nã ju èyí; bíótilẹ̀ríbẹ̃, gbogbo àwọn ohun ìṣẹ̀lẹ̀ nlá búburú yĩ ni ó ṣẹ̀ ní ìwọ̀n wákàtí mẹ́ta—nígbànã ẹ sì kíyèsĩ, òkùnkùn bò ojú ilẹ̀ nã.

20 Ó sì ṣe tí òkùnkùn biribiri bò gbogbo ojú ilẹ̀ nã, tóbẹ̃ tí àwọn olùgbé inú ìlú nã tí kò ì kú sì mọ̀ ìkùukù òkùnkùn;

21 Kò sì lè sí ìmọ́lẹ̀, nítorí òkùnkùn nã, tàbí iná fìtílà, tàbí ètúfù iná; tàbí kí iná kankan ó lè tàn pẹ̀lú àwọn igi wọn dáradára tí ó gbẹ lọ́pọ̀lọpọ̀, tí ó fi jẹ́ wípé kò sí ìmọ́lẹ̀ kankan rárá;

22 Kò sì sí ìmọ́lẹ̀ kankan tí wọ́n rí, tàbí iná, tàbí ìmọ́lẹ̀ báìbáì, tàbí oòrùn, tàbí òṣùpá, tàbí àwọn ìràwọ̀, nítorítí àwọn ikúkuú tí ó wà lójú ilẹ̀ nã pọ̀ tóbẹ̃.

23 Ó sì ṣe tí ó wà fún ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta tí wọn kò rí ìmọ́lẹ̀; ìkẹ́dùn ọkàn nlá àti híhu àti ẹkún sísun sì wà lãrín àwọn ènìyàn nã títí; bẹ̃ni, títóbi sì ni ìkérora àwọn ènìyàn nã, nítorí òkùnkùn nã àti ìparun nlá èyítí ó ti dé bá wọn.

24 Ní ibìkan ni a sì tí gbọ́ tí wọn nkígbe, tí wọ́n nwípé: A! àwa ìbá sì ti ronúpìwàdà ṣãjú ọjọ́ nlá èyítí ó burú yĩ, nígbànã ni àwọn arákùnrin wa ìbá wà ní dídásí, tí iná kì bá ti jó wọn pa nínú ìlú nlá títóbi nnì, Sarahẹ́múlà.

25 Ní ibòmíràn a sì gbọ́ tí wọn nkígbe tí wọn nṣọ̀fọ̀, tí wọn nwípé: A! àwa ìbá sì ti ronúpìwàdà ṣãjú ọjọ́ nlá èyítí ó burú yĩ, tí àwa ìbá má ti pa àwọn wòlĩ, ti a sì sọ wọ́n lókuta, tí a sì lé wọn jáde; nígbànã ni àwọn ìyá wa àti àwọn ọmọbìnrin wa tí ó lẹ́wà, àti àwọn ọmọ wa ìbá ti wà ní dídásí, tí wọn kì bá ti di bíbòmọ́lẹ̀ nínú ìlú-nlá títóbi nnì, Móróníhà. Báyĩ sì ni híhu àwọn ènìyàn nã pọ̀ tí ó sì burú.