Àwọn Ìwé Mímọ́
3 Nífáì 22


Orí 22

Ní ọjọ́-ìkẹhìn, a ó fi ìdí Síónì àti àwọn ẽkàn rẹ múlẹ̀, a ó sì kó Ísráẹ́lì jọ nínú ãnú àti ìkẹ́—Wọn yíò borí—A fi órí ìwé yĩ wé Isaiah 54. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọ Olúwa wa.

1 Nígbànã sì ni èyítí a kọ sílẹ̀ yíò ṣẹ: Kọrin, A! ìwọ àgàn, ìwọ tí kò bí rí; bú sí orin, sì ké rara, ìwọ tí kò rọbí rí; nítorí àwọn ọmọ ẹni-ahoro pọ̀ ju àwọn ọmọ ẹnití a gbé ní ìyàwó, ni Olúwa wí.

2 Sọ ibi àgọ́ rẹ di gbígbõrò, sì jẹ́ kí wọn na aṣọ ìbòjú inú àgọ́ ibùgbé rẹ; máṣe dá-sí, sọ okùn rẹ di gígùn, kí ó sì mú ẽkàn rẹ le;

3 Nítorítí ìwọ ó yà sí apá ọ̀tún àti sí apá òsì, irú-ọmọ rẹ yíò sì jogún àwọn Kèfèrí tí wọn ó sì mú kí àwọn ìlú ahoro wọnnì di ibi gbígbé.

4 Máṣe bẹ̀rù, nítorí ojú kì yíò tì ọ́; bẹ̃ni kí o máṣe dãmú, nítorí a kì yíò dójú tì ọ́; nítorí ìwọ ó gbàgbé ìtìjú ìgbà èwe rẹ, ìwọ kì yíò sì rántí ẹ̀gàn ìgbà èwe rẹ, ìwọ kò sì ní rántí ẹ̀gàn ìgbà-opó rẹ mọ́.

5 Nítorí ẹlẹ́da rẹ, ọkọ rẹ, Olúwa àwọn Ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀, àti Olùràpadà rẹ, Ẹní Mímọ́ Ísráẹ́lì—Ọlọ́run àgbáyé ni a ó máa pẽ.

6 Nítorí Olúwa ti pè ọ́ bí obìnrin tí a kọ̀ sílẹ̀, tí a sì bà nínú jẹ́, àti bí aya ìgbà èwe, nígbàtí a ti kọ̃ ni Ọlọ́run rẹ wí.

7 Ní ìṣẹ́jú díẹ̀ ni mo ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n nínú ãnú nlá ni èmi ó kó ọ jọ.

8 Nínú ìbínú díẹ̀ ni èmi pa ojú mi mọ́ kúrò lára rẹ ní ìṣẹ́jú díẹ̀, ṣùgbọ́n pẹ̀lú inú-rere tí ó wà títí ayé ni èmi ó fi ṣãnú fún ọ, ni Olúwa Olùràpadà rẹ wí.

9 Nítorí bí omi Nóà ni èyí rí sí mi, nítorí gẹ́gẹ́bí mo ti búra pé omi Nóà kì yíò bò ayé mọ́, bákannã ni mo ti bura pe èmi kì yíò bínú sí ọ.

10 Nítorí àwọn òkè-gíga yíò ṣí kúrò, a ó sì ṣí àwọn òkè kékèké ní ìdí, ṣùgbọ́n inú rere mi kì yíò fi ọ́ sílẹ̀, bẹ̃ni èmi kì yíò ṣí májẹ̀mú àlãfíà mi ní ipò, ni Olúwa ẹnití ó ṣãnú fún ọ wí.

11 A! ìwọ ẹnití à npọ́n lójú, tí a sì nfi agbara bí ìjì nlá gbá kiri, tí a kò sì tù nínú! Kíyèsĩ, èmi ó fi òkúta aláwọ̀ aláràbarà lélẹ̀ fun ọ, èmi ó sì fi òkúta sàfírà ṣe ìpìlẹ̀ rẹ.

12 Èmi yíò si fi agate ṣe fèrèsé rẹ, èmi ó sì fi òkúta iyebíye dídán ṣe ilẹ̀kùn rẹ, èmi ó sì fi òkúta àṣàyàn ṣe agbègbè rẹ.

13 Olúwa yíò sì kọ́ gbogbo àwọn ọmọ rẹ; àlãfíà àwọn ọmọ rẹ yíò sì pọ̀.

14 Nínú òdodo ni a ó fi ìdí rẹ múlẹ̀; ìwọ jìnà sí ìnira nítorítí ìwọ kì yíò bẹ̀rù, àti pẹ̀lú ìwọ ó jìnà sí ìfòyà nítorí kì yíò súnmọ́ ọ.

15 Kíyèsĩ, ní kíkójọ wọn ó kó ara wọn jọ dojúkọ ọ́, kĩ ṣe nípasẹ̀ mi; ẹnìkẹ́ni tí ó bá kó ara wọn jọ dojúkọ ọ́ yíò ṣubú nítorí rẹ.

16 Kíyèsĩ, èmi ni ẹnití ó dá alágbẹ̀dẹ tí nfẹ́ ẹyin-iná, tí ó sì ńrọ irin-iṣẹ́ fún iṣẹ́ ara rẹ̀; èmi sì ni ẹnití ó dá apanirun láti panirun.

17 Kò sí ohun ìjà tí a ṣe sí ọ tí yíò lè ṣe rere; àti gbogbo ahọ́n tí yíò pẹ̀gàn rẹ ní ìdájọ́ ni ìwọ ó dá ní ẹ̀bi. Èyí ni ogún àwọn ìránṣẹ́ Olúwa, láti ọ̀dọ̀ mi ni òdodo wọn ti wá, ni Olúwa wí.