Àwọn Ìwé Mímọ́
3 Nífáì 23


Orí 23

Jésù fi inúdídùn rẹ̀ hàn sí àwọn ọ̀rọ̀ Isaiah—Ó pàṣẹ kí àwọn ènìyàn nã ó ṣe ìwãdí ọ̀rọ̀ àwọn wòlĩ—Àwọn ọ̀rọ̀ Sámúẹ́lì ará Lámánì nípa Àjĩnde Jésù ni à fikún àwọn àkọsílẹ̀ wọn. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí, ẹ kíyèsĩ, mo wí fún yín, pé kí ẹ̀yin ó ṣe ìwãdí àwọn ohun wọ̀nyí. Bẹ̃ni, mo pãláṣẹ fún yín pé kí ẹ̀yin ó wãdí àwọn ohun wọ̀nyí tọkàn-tara; nítorí títóbi ni àwọn ọ̀rọ̀ Isaiah.

2 Nítorí dájúdájú ni ó sọ nípa ohun gbogbo nípa àwọn ènìyàn mi tí íṣe ti ìdílé Ísráẹ́lì; nítorínã ó di dandan pé kí ó bá àwọn Kèfèrí nã sọ̀rọ̀.

3 Ohun gbogbo tí ó sì ti sọ ni ó ti rí bẹ̃, wọn yíò sì rí bẹ̃, àní ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ nã ti ó sọ.

4 Nítorínã ẹ ṣe ìgbọràn sí àwọn ọ̀rọ̀ mi; ẹ kọ àwọn ohun tí mo ti wí fún yín sílẹ̀; wọn yíò sì tọ àwọn Kèfèrí lọ ní ìbámu pẹ̀lú àkokò àti ìfẹ́ Bàbá.

5 Ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì fetísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ mi tí ó sì ronúpìwàdà tí a sì ṣe iribọmi fun, òun nã ni a ó gbàlà. Ẹ máa ṣe ìwãdí àwọn wòlĩ, nítorípé wọ́n pọ̀ tí ó ṣe ìjẹ́rísí àwọn ohun wọ̀nyí.

6 Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wonyĩ tán ó tún wí fún wọn, lẹ́hìn tí ó ti sọ àsọyé fún wọn lórí àwọn ọ̀rọ̀ ìwé-mímọ́ tí wọ́n ti gbà, ó wí fún wọn pé: Ẹ kíyèsĩ, èmi fẹ́ kí ẹ̀yin ó kọ àwọn ìwé-mímọ́ míràn sílẹ̀, èyítí ẹ̀yin kò ì kọ.

7 Ó sì ṣe tí ó wí fún Nífáì pé: Mú àwọn àkọsílẹ̀ tí ẹ ti kọ wá.

8 Nígbàtí Nífáì sì ti mú àwọn àkọsílẹ̀ nã wá, tí ó sì gbé wọn kalẹ̀ níwájú rẹ̀, ó wò wọn ó sì wípé:

9 Lóotọ́ ni mo wí fún yín, mo pàṣẹ fún ìránṣẹ́ mi Sámúẹ́lì, ará Lámánì, pé kí ó ṣe ìjẹ́rĩ sí fún àwọn ènìyàn yìi, pé ní ọjọ́ nã tí Bàbá yíò ṣe orúkọ rẹ̀ lógo nínú mi, pé àwọn ènìyàn mímọ́ púpọ̀ ni yíò jí dìde kúrò nínú ipò-òkú, tí wọn yíò sì farahàn sí àwọn ènìyàn púpọ̀, tí wọn yíò sì ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ lãrín wọn. Ó sì wí fún wọn pé: Njẹ́ kò ha rí bẹ̃ bí?

10 Àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ sì dáa lóhùn wọ́n sì wípé: Bẹ̃ni, Olúwa, Sámúẹ́lì ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ rẹ, gbogbo wọn ni ó sì ti ṣẹ.

11 Jésù sì wí fún wọn pé: Báwo ni ẹ̀yin kò ṣe tĩ kọ eleyĩ, pé àwọn ènìyàn mímọ́ púpọ̀ ni ó jí dìde kúrò nínú ipò-òkú tí wọ́n sì farahàn sí àwọn ènìyàn púpọ̀ ti wọ́n sì ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ lãrín wọn?

12 Ó sì ṣe tí Nífáì rántí pé wọn kò ì kọ eleyĩ.

13 Ó sì ṣe tí Jésù pàṣẹ pé kí wọn ó kọọ́; nítorínã ni wọ́n kọọ́ gẹ́gẹ́bí ó ti pãláṣẹ.

14 Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti sọ àsọyé fún wọn lórí àwọn ìwé-mímọ́ nã lápapọ̀, èyítí wọ́n ti kọ, ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọn ó máa kọ́ni ní ẹ̀kọ́ nípa àwọn ohun tí òun ti sọ àsọyé lórí wọn.