Àwọn Ìwé Mímọ́
3 Nífáì 19


Orí 19

Àwọn ọmọ-ẹ̀hìn méjìlá nã nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn nã wọ́n sì gbàdúrà fún gbígba Ẹ̀mí Mímọ́–A ṣe ìrìbomi fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn nã wọ́n sì gba Ẹ̀mí Mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ángẹ́lì—Jésù gbàdúrà ó sì lo èdè tí ẹnìkẹ́ni kò lè kọ sílẹ̀—Ó jẹ̃rí sí ìgbàgbọ́ nlá tí ó tayọ ti àwọn ará Nífáì ní. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti gòkè re ọ̀run, àwọn ọ̀pọ̀-ènìyàn nã bá ọ̀nà ara wọn lọ, olúkúlukù sì mú ìyàwó àti ọmọ rẹ̀ wọ́n sì padà sí ilé wọn.

2 A sì kókìkí ìròyìn nã lãrín àwọn ènìyàn nã lójúkannã, kí ilẹ̀ ó tó ṣú, pé àwọn ọ̀pọ̀-ènìyàn nã ti rí Jésù, àti pé ó ti jíṣẹ́ ìránṣẹ́ fún wọn, àti pé òun yíò tún fi ara rẹ̀ hàn ní ọjọ́ kejì sí àwọn ọ̀pọ̀-ènìyàn nã.

3 Bẹ̃ni, àti pẹ̀lú ní gbogbo òru ọjọ́ nã ni wọ́n kókìkí nípa ọ̀rọ̀ Jésù; wọn sì tan ọ̀rọ̀ nã ká tóbẹ̃ tí wọ́n pọ̀ tí ó tàn án ká, bẹ̃ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn, ni ó ṣiṣẹ́ takun-takun ní òru ọjọ́ nã, kí wọn ó lè wà níbití Jésù yíò gbé fi ara rẹ̀ hàn sí àwọn ọ̀pọ̀-ènìyàn ní ọjọ́ kejì.

4 Ó sì ṣe ní ọjọ́ kejì, nígbàtí àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn ti péjọ pọ̀, ẹ kíyèsĩ, Nífáì àti arákùnrin rẹ̀ èyítí ó ti jí dìde kúrò nínú ipò-òkú, ẹnití orúkọ rẹ̀ íṣe Tímótéù, àti ọmọkùnrin rẹ̀, ẹnití orúkọ rẹ̀ íṣe Jónà, àti Mátónì pẹ̀lú, àti Mátóníhà, arákùnrin rẹ̀, àti Kúménì, àti Kúménónhì, àti Jeremíàh, àti Ṣẹ́mnónì, àti Jónà, àti Sẹdẹkíàh, àti Isaiah—nísisìyí èyí ni orúkọ àwọn ọmọ-ẹ̀hin èyítí Jésù ti yàn—ó sì ṣe tí wọ́n jáde lọ tí wọ́n sì dúró lãrín àwọn ọ̀pọ̀-ènìyàn nã.

5 Ẹ sì kíyèsĩ, àwọn ọ̀pọ̀-ènìyàn nã pọ̀ tó bẹ̃ tí wọ́n fi pín wọn sí ọ̀nà méjìlá.

6 Àwọn méjìlá nnì sì kọ́ àwọn ọ̀pọ̀-ènìyàn nã ní ẹ̀kọ́; ẹ sì kíyèsĩ, wọ́n sì mú kí àwọn ènìyàn nã ó kúnlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé kí wọn ó sì gbàdúrà sí Bàbá ní orúkọ Jésù.

7 Àwọn ọmọ-ẹ̀hìn nã sì gbàdúrà sí Bàbá pẹ̀lú ní orúkọ Jésù. Ó sì ṣe tí wọ́n dìde tí wọ́n sì jíṣẹ́ ìránṣẹ́ lãrín àwọn ènìyàn nã.

8 Nígbàtí wọ́n sì ti jíṣẹ́ ìránṣẹ́ níti àwọn ọ̀rọ̀ kannã tí Jésù ti sọ—láìṣe àyípadà sí àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù ti sọ—ẹ kíyèsĩ, wọ́n tún kúnlẹ̀ wọ́n sì gbàdúrà sí Bàbá ní orúkọ Jésù.

9 Wọ́n sì gbàdúrà fún ohun èyítí wọ́n fẹ́ jùlọ; wọ́n sì fẹ́ kí a fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún wọn.

10 Nígbàtí wọ́n sì ti gbàdúrà ní ọ̀nà yĩ wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí etí omi nã, àwọn ọ̀pọ̀-ènìyàn nã sì tẹ̀lé wọn.

11 Ó sì ṣe ti Nífáì sọ̀kalẹ̀ lọ sínú omi nã tí a sì ṣe ìrìbọmi fũn.

12 Ó sì jáde kúrò nínú omi nã, ó sì bẹ̀rẹ̀sí íṣe ìrìbọmi. Ó sì ṣe ìrìbọmi fun gbogbo àwọn ti Jésù ti yàn.

13 Ó sì ṣe nígbàtí a ti ri gbogbo wọn bọmi tan ti wọ́n sì ti jáde kúrò nínú omi, Ẹ̀mí Mímọ́ sì bà lé wọn, wọ́n sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti pẹ̀lú iná.

14 Ẹ sì kíyèsĩ, ohun èyítí ó rí bí iná yí wọn ká; ó sì sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, àwọn ọ̀pọ̀-ènìyàn nã sì jẹ̃rí síi, wọ́n sì ṣe àkọsílẹ̀ nípa rẹ̀; àwọn ángẹ́lì sì sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá wọ́n sì ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ lãrín wọn.

15 Ó sì ṣe bí àwọn ángẹ́lì nã ti nṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ lãrín àwọn ọmọ-ẹ̀hìn nã, ẹ kíyèsĩ, Jésù wá ó sì dúró lãrín wọn o si ṣiṣé ìránṣẹ́ sí wọn.

16 Ó sì ṣe tí ó bá àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn sọ̀rọ̀, ó sì paṣẹ fún wọn pé kí wọn ó tún kúnlẹ̀ lórí ilẹ̀, àti pẹ̀lú kí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ ó kúnlẹ̀ lórí ilẹ̀.

17 Ó sì ṣe nígbàtí gbogbo wọn ti kúnlẹ̀ lórí ilẹ̀ tán, ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ pé kí wọn ó gbàdúrà.

18 Ẹ sì kíyèsĩ, wọ́n bẹ̀rẹ̀sí gbàdúrà; wọ́n sì gbàdúrà sí Jésù, tí wọ́n sì npẽ ní Olúwa àti Ọlọ́run wọn.

19 Ó sì ṣe tí Jésù jáde lọ kúrò lãrín wọn, ó sì rìn jìnà sí wọn díẹ̀ ó sì wolẹ̀ lé orí ilẹ̀, ó sì wípé:

20 Bàbá, èmi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ pé ìwọ ti fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún àwọn wọ̀nyí tí èmi ti yàn; nítorí ìgbàgbọ́ wọn nínú mi ni èmi sì ṣe yàn wọ́n kúrò nínú ayé.

21 Bàbá, èmi gbàdúrà sí ọ kí ó fún gbogbo àwọn tí yíò gba ọ̀rọ̀ wọn gbọ́ ní Ẹ̀mí Mímọ́.

22 Bàbá, ìwọ ti fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún wọn nítorípé wọ́n gbà mí gbọ́; ìwọ sì ríi pé wọ́n gbà mí gbọ́ nítorípé ó ngbọ́ wọn, wọ́n sì gbàdúrà sí mi; wọ́n sì gbàdúrà sí mi nítorípé mo wà lọ́dọ̀ wọn.

23 Àti nísisìyí Bàbá, èmi gbàdúrà sí ọ nítorí wọn, àti nítorí gbogbo àwọn tí yíò gba ọ̀rọ̀ wọn gbọ́, kí wọn ó lè gbà mí gbọ́, kí èmi ó lè wà nínú wọn gẹ́gẹ́bí ìwọ, Bàbá, ti wà nínú mi, kí àwa ó lè jẹ́ ọ̀kan.

24 Ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti gbàdúrà sí Bàbá báyĩ tán, ó tọ àwọn ọmọ-ẹ̀hin rẹ̀ wá, ẹ sì kíyèsĩ, wọ́n sì tẹramọ́ gbígba àdúrà síi, láìsinmi; wọn kò sì lo ọ̀rọ̀ púpọ̀, nítorítí a ti fún wọn ní ohun tí wọn yíò gbàdúrà nípa rẹ̀, wọ́n sì kún fún ìbẽrè.

25 Ó sì ṣe tí Jésù súre fún wọn bí wọn ti ngbàdúrà síi; ìwò rẹ sì fi ojú ãnú wò wọ́n, ìmọ́lẹ̀ ìwò rẹ̀ sì tàn sí wọn, ẹ sì kíyèsĩ wọ́n funfun bí ìwò Jésù àti bí ẹ̀wù Jésù pẹ̀lú; ẹ sì kíyèsĩ fífunfun yĩ tayọ fífunfun èyíkéyĩ, bẹ̃ni, àní kò sí ohunkóhun lórí ayé tí ó funfun tó fífunfun yìi.

26 Jésù sì wí fún wọn pé: Ẹ tẹ̀síwájú nínú àdúrà gbígbà; bíótilẹ̀ríbẹ̃ wọn kò sì simi àdúrà gbígbà.

27 Ó sì yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn, ó sì kọjá lọ síwájú díẹ̀ ó sì wolẹ̀ sí órí ilẹ̀; ó sì tún gbàdúrà sí Bàbá, wípé:

28 Bàbá, èmi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ nítorítí ìwọ ti sọ àwọn tí èmi yàn di mímọ́, nítorí ìgbàgbọ́ wọn, èmi a sì máa gbàdúrà fún wọn, àti pẹ̀lú fún àwọn ti yíò gba ọ̀rọ̀ wọn gbọ́, kí a lè sọ wọ́n di mímọ́ nínú mi, nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ wọn, àní bí a ti sọ wọn di mímọ́ nínú mi.

29 Bàbá, èmi ngbàdúrà, kĩ ṣe fún aráyé, ṣùgbọ́n fún àwọn tí ìwọ ti fifún mi láti inú ayé wá, nítorí ìgbàgbọ́ wọn, kí wọn ó lè di mímọ́ nínú mi, kí èmi ó lè wà nínú wọn gẹ́gẹ́bí ìwọ, Bàbá, ti wà nínú mi, kí àwa ó lè jẹ́ ọ̀kan, kí a lè ṣe mí lógo nínú wọn.

30 Nígbàtí Jésù sì ti sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tán ó tún padà wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀; ẹ sì kíyèsĩ wọn ngbàdúrà ní ìtẹramọ́, láìsinmi, síi; ó sì tún fi ojú ãnú rẹ̀ wò wọ́n; ẹ sì kíyèsĩ wọ́n funfun, àní bí Jésù ṣe rí.

31 Ó sì ṣe tí ó tún lọ síwájú díẹ̀ síi ó sì gbàdúrà sí Bàbá;

32 Kò sì sí ahọ́n tí ó lè sọ àwọn ọ̀rọ̀ àdúrà tí ó gbà, bẹ̃ni ẹnìkẹ́ni kò lè kọ àwọn ọ̀rọ̀ àdúrà tí ó gbà.

33 Àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã sì gbọ́ wọn sì jẹ̃rí síi; ọkàn wọn sì ṣí sílẹ̀ wọ́n sì ní ìmọ̀ nínú ọkàn wọn àwọn ọ̀rọ̀ àdúrà tí ó gbà.

34 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, ọ̀rọ̀ àdúrà tí ó gbà nã jẹ́ nlá àti ìyanu tóbẹ̃ tí ẹnìkẹ́ni kò lè kọ wọ́n sílẹ̀, tàbí kí a sọ wọ́n.

35 Ó sì ṣe nígbàtí Jésù parí àdúrà tí ó gbà ó tún padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀hìn nã, ó sì wí fún wọn pé: Irú ìgbàgbọ́ tí ó tó èyí èmi kò ríi rí lãrín gbogbo àwọn Ju; nítorí-èyí ni èmi kò ṣe lè fi àwọn iṣẹ́ ìyanu nlá hàn wọ́n bí èmi ti fi hàn yín, nítorí àìgbàgbọ́ wọn.

36 Lóotọ́ ni mo wí fún yín, kò sí ẹnìkẹ́ni nínú wọn tí ó rí àwọn ohun nlá irú èyí tí ẹ̀yin ti rí; bẹ̃ni wọn kò gbọ́ àwọn ohun nlá irú èyí tí ẹ̀yin ti gbọ́.