Àwọn Ìwé Mímọ́
3 Nífáì 26


Orí 26

Jésù sọ àsọyé lórí ohun gbogbo láti ìbẹ̀rẹ̀ wá títí dé òpin—Àwọn ọmọ ọwọ́ àti àwọn ọmọdé sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó yani lẹ́nu tí a kò lè kọ—Àwọn tí ó wà nínú Ìjọ Krístì jùmọ̀ ní ohun gbogbo. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tán ó sọ àsọyé lórí wọn fún àwọn ọ̀pọ̀-ènìyàn nã; ó sì tún sọ àsọyé lórí ohun gbogbo fún wọn, lórí ohun tí ó tóbi àti kékeré.

2 Ó sì wí pé: Àwọn ìwé-mímọ́ wọ̀nyí, èyítí ẹ̀yin kò ní, Bàbá pàṣẹ pé kí èmi ó fifún yín; nítorítí ohun ọgbọ́n ni nínú rẹ̀ pé kí a fifún àwọn ìran tí nbọ̀ lẹ́hìn-ọ̀la.

3 Ó sì sọ àsọyé lórí ohun gbogbo, àní láti ìbẹ̀rẹ̀ wá títí dé àkokò tí yíò wá nínú ògo rẹ̀—bẹ̃ni, àní ohun gbogbo tí yíò ṣẹ ní orí ilẹ̀ ayé, àní títí àwọn iṣẹ́ inú rẹ̀ yíò di yíyọ́ nítorí àwọn õru tí ó gbóná, tí àwọn ọ̀run àti ayé yíò kọjá lọ;

4 Àti pãpã títí dé ọjọ́ nlá èyítí ó kẹ́hìn, nígbàtí ènìyàn gbogbo, àti gbogbo ìbátan, àti orílẹ̀-èdè gbogbo, àti gbogbo èdè, yíò dúró níwájú Ọlọ́run fún ìdájọ́ lórí iṣẹ́ wọn, bóyá rere ni wọ́n tàbí bóyá búburú ni wọn íṣe—

5 Bí wọ́n bá jẹ́ rere, sí àjínde ìyè àìlópin; bí wọ́n bá sì jẹ́ búburú, sí àjínde sí ìdálẹ́bi; nítorítí wọ́n wà ní ọ̀tọ̀, tí ọ̀kan wà ní apá kan, tí èkejì sì wà ní apá kejì, gẹ́gẹ́bí ãnú, àti àìṣègbè, àti ìwà mímọ́ èyítí ó wà nínú Krístì, ẹnití ó ti wà ṣãjú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé.

6 Àti nísisìyí èmi kò lè kọ ìdá kan nínú ọgọ́run sí inú ìwé yĩ nínú àwọn ohun tí Jésù kọ́ àwọn ènìyàn yĩ ní tõtọ́;

7 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, àwọn àwo Nífáì ni ó ní púpọ̀ nínú àwọn ohun tí ó kọ àwọn ènìyàn nã;

8 Àwọn ohun wọ̀nyí sì ni èmi sì ti kọ, tí ó jẹ́ díẹ̀ nínú àwọn ohun tí ó kọ́ àwọn ènìyàn nã; èmi sì kọ wọ́n kí a lè tún mú wọn wá fún àwọn ènìyàn yĩ, láti ọ̀dọ̀ àwọn Kèfèrí, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ti Jésù ti sọ.

9 Nígbàtí wọ́n bá sì ti rí èyí gbà tán, èyítí ó tọ̀nà, pé kí wọn ó kọ́kọ́ gbà, láti dán ìgbàgbọ́ wọn wò, bí ó bá sì rí bẹ̃ tí wọ́n sì gba ohun wọ̀nyí gbọ́, nígbànã ni a ó fi àwọn ohun púpọ̀ tí a ti kọ nã hàn sí wọn.

10 Bí ó bá sì rí bẹ̃ tí wọn kò bá gba àwọn ohun wọ̀nyí gbọ́, nígbànã ni a ó fi àwọn ohun púpọ̀ nã tí a ti kọ pamọ́ fún wọn, sí ìdálẹ́bi fún wọn.

11 Ẹ kíyèsĩ, mo ti ṣetán láti kọ wọ́n, gbogbo àwọn ohun tí àwọn wòlĩ ti fín sí orí àwọn àwo Nífáì, ṣùgbọ́n Olúwa dá mi lẹ́kun, ó wípé: Èmi yíò dán ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn mi wò.

12 Nítorínã ni èmi, Mọ́mọ́nì, kọ àwọn ohun tí Olúwa ti pa láṣẹ fún mi. Àti nísisìyí èmi, Mọ́mọ́nì, mú ọ̀rọ̀ mi wá sí òpin, èmi sì tẹ̀síwájú láti kọ àwọn ohun tí Olúwa ti pa láṣẹ fún mi.

13 Nítorínã, èmi fẹ́ kí ẹ̀yin ó ríi pé Olúwa kọ́ àwọn ènìyàn yĩ ní tõtọ́, fún ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta; lẹ́hìnnã ó sì nfi ara rẹ̀ hàn sí wọn nígbà-kũgbà, ó sì nbu àkàrà nígbà-kũgbà, ó súre síi, ó sì nfifún wọn.

14 Ó sì ṣe tí ó nkọ́ àwọn ọmọ àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã lẹkọ, tí ó sì ṣiṣẹ́-ìránṣẹ́ lãrín wọn, àwọn tí a ti sọ̀rọ̀ nípa wọn, ó sì là wọ́n ní ohùn, wọ́n sì sọ àwọn ohun nlá tí ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún àwọn bàbá wọn, àní àwọn ohun tí ó tóbi ju èyítí ó ti fi han àwọn ènìyàn nã; ó sì là wọ́n ní ohùn kí wọn ó lè sọ̀rọ̀.

15 Ó sì ṣe lẹ́hìn tí ó ti gòkè re ọ̀run—ní ìgbàkejì ti ó ti fi ara rẹ̀ hàn wọ́n, àti tí ó sì ti lọ sí ọ̀dọ̀ Bàbá, lẹ́hìn tí ó ti wo àwọn aláìsàn wọn, àti àwọn arọ wọn, àti tí ó la ojú àwọn afọ́jú wọn àti tí ó la etí àwọn adití, àti pãpã tí ó ti ṣe onírurú ìwòsàn lãrín wọn, àti tí ó ti jí ẹnìkan dìde kúrò nínú ipò-òkú, àti tí ó ti fi agbára rẹ̀ hàn sí wọn, tí ó sì ti gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ Bàbá—

16 Ẹ kíyèsĩ, ó sì ṣe ní ọjọ́ kejì tí àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã kó ara wọn jọ, tí wọ́n sì rí àti tí wọn gbọ́ àwọn ọmọdé wọ̀nyí; bẹ̃ni, àní àwọn ọmọ ọwọ́ sì la ẹnu wọn tí wọ́n sì sọ àwọn ohun ìyàlẹ́nu; àwọn ohun tí wọ́n sì sọ ni Olúwa dá wọn lẹ́kun kí ẹnìkẹ́ni ó máṣe kọ wọ́n.

17 Ó sì ṣe tí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn tí Jésù ti yàn bẹ̀rẹ̀sí ńṣe ìrìbọmi láti ìgbà nã lọ àti láti kọ́ gbogbo àwọn tí ó bá tọ̀ wọ́n wá; àti gbogbo àwọn tí ó ṣe ìrìbọmi ní orúkọ Jésù ni ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́.

18 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni wọ́n sì rí àti tí ó gbọ́ àwọn ohun tí a kò lè sọ, èyítí a kò gbà wọ́n lãyè láti kọ.

19 Wọ́n sì kọ́ ni lẹ́kò, wọ́n sì ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ fún ara wọn; wọ́n sì jùmọ̀ ní ohun gbogbo lápapọ̀, olúkúlùkù sì nṣe èyítí ó tọ́ sí èkejì rẹ̀.

20 O sì ṣe tí wọn ṣe ohun gbogbo àní gẹ́gẹ́bí Jésù ti palaṣẹ fun wọn.

21 Àwọn tí a sì ṣe ìrìbọmi fun ní orúkọ Jésù ni a pè ní ìjọ Krístì.