Àwọn Ìwé Mímọ́
3 Nífáì 1


Nífáì Kẹ́ta

Ìwé ti Nífáì
Ọmọ Nífáì, Tí Íṣe Ọmọ Hẹ́lámánì

Hẹ́lámánì sì ni ọmọ Hẹ́lámánì, tí íṣe ọmọ Álmà, tí íṣe ọmọ Álmà, ẹnití íṣe ìran Nífáì tí íṣe ọmọ Léhì, ẹnití ó jáde wá láti inú Jerúsálẹ́mù nínú ọdún èkínnì nínú ìjọba Sẹdẹkíàh, ọba Júdà.

Orí 1

Nífáì, ọmọ Hẹ́lámánì, jáde kúrò nínú ilẹ̀ nã, ọmọ rẹ̀ Nífáì sì nkọ àwọn àkọsílẹ̀ nã pamọ́—Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé àwọn àmì àti ohun ìyanu pọ̀ púpọ̀, àwọn ènìyàn búburú pa ète láti pa àwọn olódodo—Alẹ́ ọjọ́ bíbí Krístì dé—A fún nwọn ní àmì nã, ìràwọ̀ titun sì yọ—Irọ́pípa àti ẹ̀tàn pọ̀ síi, àwọn ọlọ́ṣà Gádíátónì sì pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn. Ní ìwọ̀n ọdún 1–4 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Nísisìyí ó sì ṣe tí ọdún kọkànlélãdọ́rún ti kọjá tí ó sì di ẹgbẹ̀ta ọdún láti ìgbà tí Léhì fi Jerúsálẹ́mù sílẹ̀; o sì tún jẹ́ ọdún tí Lákónéúsì jẹ́ adájọ́ àgbà àti bãlẹ̀ lórí ilẹ̀ nã.

2 Àti Nífáì, ọmọ Hẹ́lámánì, sì ti jáde kúrò nínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, tí ó sì ti fún ọmọ rẹ Nífáì ní ojuṣe, ẹnití íṣe ọmọ rẹ̀ àkọ́bí ọkùnrin, nípa àwọn àwo idẹ̀, àti gbogbo àwọn àkọsílẹ̀ tí nwọ́n ti kọ ṣíwájú, àti gbogbo àwọn ohun tí nwọ́n ti pamọ́ ní mímọ́ láti ìgbà tí Léhì ti jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù.

3 Nígbànã ni ó jáde kúrò ní ilẹ̀ nã, ibití ó sì lọ, ẹnìkan kò mọ̀; ọmọ rẹ̀ Nífáì sì kọ àwọn àkọsílẹ̀ nã pamọ́ dípò rẹ̀, bẹ̃ni, àkọsílẹ̀ nípa àwọn ènìyàn yĩ.

4 Ó sì ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kejìlélãdọ́rún, ẹ kíyèsĩ, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ti àwọn wòlĩ bẹ̀rẹ̀sí di mìmúṣẹ síi ní kíkún; nítorítí àwọn ohun àmì tí ó tóbí síi àti ohun ìyanu tí ó tóbi síi ni ó ndi ṣíṣe lãrín àwọn ènìyàn nã.

5 Ṣùgbọ́n àwọn díẹ̀ wà tí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí sọ wípé àkokò nã ti kọjá fún àwọn ọ̀rọ̀ nã láti di mìmúṣẹ, èyítí Sámúẹ́lì, ará Lámánì ti sọ.

6 Nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí yọ̀ lórí àwọn arákùnrin nwọn, tí nwọ́n ńsọ wípé: Ẹ kíyèsĩ àkokò nã ti kọjá, àwọn ọ̀rọ̀ Sámúẹ́lì kò sì ṣẹ; nítorínã, ayọ̀ nyín àti ìgbàgbọ́ nyín nípa ohun yĩ ti jẹ́ lásán.

7 Ó sì ṣe tí nwọn npariwo nlá jákè-jádò ilẹ̀ nã; àwọn ènìyàn tí ó sì gbàgbọ́ sì bẹ̀rẹ̀sí kún fún ìbànújẹ́ pupọ̀, ní ìbẹ̀rù pé ni ọ̀nàkọnà àwọn ohun tí a ti sọ nnì lè ṣàì di mímúṣẹ.

8 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, nwọ́n nṣọ́nà ní ìdúró sinsin fún ọjọ́ nã àti òru nã àti ọjọ́ nã tí yíò rí bí ọjọ́ kan bí èyítí kò ní òru, kí nwọn ó lè mọ̀ pé ìgbàgbọ́ nwọn kò wà lásán.

9 Nísisìyí ó sì ṣe tí ọjọ́ kan wà tí àwọn aláìgbàgbọ́ ènìyàn yà sọ́tọ, pé kí gbogbo àwọn ẹnití ó gbàgbọ́ nínú àwọn àṣà nnì ni kí nwọn ó pa, àfi bí àmì nã bá wa si ìmúṣẹ, èyítí wòlĩ Sámúẹ́lì ti fún nwọn.

10 Nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Nífáì, ọmọ Nífáì, rí ìwà búburú àwọn ènìyàn rẹ̀ yĩ, ọkàn rẹ̀ kún fún ìbànújẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀.

11 Ó sì ṣe tí ó jáde lọ tí ó sì wólẹ̀ lórí ilẹ̀, tí ó sì kígbe kíkan-kíkan pè Ọlọ́run rẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀, bẹ̃ni, àwọn tí nwọ́n ti fẹ́rẹ̀ di píparun nítorí ìgbàgbọ́ wọn nínú àṣà àwọn bàbá wọn.

12 Ó sì ṣe tí ó kígbe kíkan-kíkan pe Olúwa ni gbogbo ọjọ́ nã; ẹ sì kíyèsĩ, ohùn Olúwa sì tọ̀ ọ́ wá ti o nsọ wípé:

13 Gbé orí rẹ sókè kí ó sì tújúká; nítorí kíyèsĩ, àkokò nã ti dé tán, ní òru òní ni a o fún nyín ní àmì nã, àti ní ọ̀la ni èmi yíò wá sínú ayé, láti fi hàn fún ayé pé èmi yíò ṣe ìmúṣẹ gbogbo àwọn ohun tí èmi ti mú kí a sọ láti ẹnu àwọn wòlĩ mímọ́ mi.

14 Kíyèsĩ, èmi tọ àwọn tí íṣe tèmi wá, láti ṣe ìmúṣẹ gbogbo àwọn ohun tí èmi ti sọ di mímọ̀ fún àwọn ọmọ ènìyàn láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, àti láti ṣe ìfẹ́ ti Bàbá àti ti Ọmọ—ti Bàbá nítorí mi, àti ti Ọmọ nítorí ẹran ara mi. Sì kíyèsĩ, àkokò nã ti dé tán, lóru òní ni a ó sì fún nyín ní àmì nã.

15 Ó sì ṣe tí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó tọ Nífáì wá di mìmúṣẹ, gẹ́gẹ́bí a ti sọ wọ́n; nítorí ẹ kíyèsĩ, nígbàtí ó di àṣálẹ́ kò sí òkùnkùn; ẹnu sì bẹ̀rẹ̀ sí yà àwọn ènìyàn nã nítorípé kò sí òkùnkùn nígbàtí alẹ́ lẹ́.

16 Àwọn tí kò sì gba ọ̀rọ̀ àwọn wòlĩ gbọ́ sì pọ̀, tí nwọ́n wó lulẹ̀ tí nwọ́n sì dàbí ẹ̀nítí ó ti kú, nítorítí nwọ́n mọ̀ pé ète ìparun nlá èyítí nwọ́n ti tẹ́ sílẹ̀ fún àwọn tí ó gbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ àwọn wòlĩ ti di asán; nítorítí àmì nã èyítí a ti fún nwọn ti dé.

17 Nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí mọ̀ wípé Ọmọ Ọlọ́run yíò farahàn láìpẹ́ dandan; bẹ̃ni, ní kúkúrú, gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé gbogbo láti ìwọ oòrùn dé ìlà oòrùn, àti ní ilẹ̀ apá àríwá àti ní ilẹ̀ apá gúsù, ni ẹnu yà nwọ́n lọ́pọ̀lọpọ̀ tí nwọ́n sì wó lulẹ̀.

18 Nítorí nwọ́n mọ̀ pé àwọn wòlĩ ti jẹ́risí àwọn ohun wọ̀nyí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, àti pé àmì nã èyítí a ti fi fun nwọn ti dé; nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí bẹ̀rù nítorí àìṣedẽdé nwọn àti àìgbàgbọ́ nwọn.

19 Ó sì ṣe tí òkùnkùn kò sí ní gbogbo òru nã, ṣùgbọ́n tí ó mọ́lẹ̀ bí èyítí íṣe ọ̀sán gangan. Ó sì ṣe tí oòrùn sì tún yọ ní òwúrọ̀, gẹ́gẹ́bí ó ti yẹ kí ó rí; nwọ́n sì mọ̀ wípé ọjọ́ nã ni a bí Olúwa, nítorí àmì nã èyítí a ti fún ni.

20 Ó sì ṣe, bẹ̃ni, ohun gbogbo, títí dé èyítí ó kéré jùlọ, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ àwọn wòlĩ.

21 Ó sì ṣe pẹ̀lú tí ìràwọ̀ titun kan yọ, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ nã.

22 Ó sì ṣe pé láti ìgbà yĩ lọ ni irọ́ bẹ̀rẹ̀sí jáde wá láti ẹnu àwọn ènìyàn nã, láti ọwọ́ Sátánì, láti sé àyà nwọn le, pé kí nwọn ó má bã gbàgbọ́ nínú àwọn àmì àti ohun ìyanu èyítí nwọ́n ti rí; ṣùgbọ́n l’áìṣírò àwọn irọ́ àti ẹ̀tàn wọ̀nyí èyítí ó pọ̀ jù nínú àwọn ènìyàn nã ni ó gbàgbọ́, tí a sì yí nwọn lọ́kàn padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa.

23 Ó sì ṣe tí Nífáì kọjá lọ lãrín àwọn ènìyàn nã, àti àwọn míràn pẹ̀lú, tí nwọ́n nṣe ìrìbọmi sí ìrònúpìwàdà, nínú èyítí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ tí ó tóbi wà. Báyĩ sì ni àwọn ènìyàn nã tún bẹ̀rẹ̀ si ní àlãfíà lórí ilẹ̀ nã.

24 Kò sì sí asọ̀, bíkòṣe ní ti àwọn ènìyàn díẹ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀sí wãsù, tí nwọn nsa ipá láti lè làdí rẹ̀ nípa àwọn ìwé-mímọ́ pé kò tọ̀nà mọ́ láti pa òfin Mósè mọ́. Nísisìyí nínú ohun yĩ, nwọ́n ṣìnà, nítorítí àwọn ìwé-mímọ́ kò yé nwọn.

25 Ṣùgbọ́n ó sì ṣe tí ọ́kàn nwọ́n yí padà láìpẹ́, tí nwọ́n sì ní ìdánilójú nípa ti ìṣìnà nínú èyítí nwọ́n wà, nítorítí a jẹ́ kí o di mímọ̀ fún nwọ́n pé òfin nã kò tĩ di mímúṣẹ, àti pé ó níláti di mímúṣẹ títí dé èyítí ó kéré jùlọ; bẹ̃ni, ọ̀rọ̀ nã tọ̀ nwọ́n wá pé ó níláti di mímúṣẹ; bẹ̃ni, wípé ohun kíkiní tabi kékeré kan kì yíò kọjá lọ títí yíò fi di mímúṣẹ pátápátá; nítorínã nínú ọdún yĩ kannã ni a mú nwọ́n sínú ìmọ̀ ìṣìnà nwọn àti tí nwọ́n sì jẹ́wọ́ àṣìṣe nwọn.

26 Báyĩ sì ni ọdún kejìlélãdọ́rún kọjá, èyítí ó mú ìròhìn ayọ̀ bá àwọn ènìyàn nã nítorí àwọn àmì èyítí nwọ́n ti di mímúṣẹ, gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ gbogbo àwọn wòlĩ mímọ́.

27 Ó sì ṣe tí ọdún kẹtàlélãdọ́run nã sì kọjá ní àlãfíà, bíkòṣe fún àwọn ọlọ́ṣà Gádíátónì, tí nwọn ngbé lórí àwọn òkè gíga, tí nwọ́n sì nyọ ilẹ̀ nã lẹ́nu; nítorítí àwọn ibi gíga nwọn àti àwọn ibi ìkọ̀kọ̀ nwọn lágbára tóbẹ̃ tí àwọn ènìyàn nã kò lè borí nwọn; nítorínã nwọ́n sì ṣe ìpànìyàn púpọ̀púpọ̀, tí nwọ́n sì pa àwọn ènìyàn nã ní ìpakúpa.

28 Ó sì ṣe nínú ọdún kẹ́rinlélãdọ́rún tí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí pọ̀ síi, ní ìlọ́po ìwọ̀n, nítorípé àwọn olùyapakúrò lãrín àwọn ará Nífáì púpọ̀ ni ó sá lọ bá nwọn, èyítí ó mú kí ìrora-ọkàn púpọ̀ ó bá àwọn ará Nífáì tí ó kù lórí ilẹ̀ nã.

29 Ohun kan sì wà tí ó mú kí ìrora-ọkàn ó wà lãrín àwọn ará Lámánì; nítorí kíyèsĩ, nwọ́n ní àwọn ọmọ púpọ̀ tí nwọ́n dàgbà tí nwọ́n sì nlọ́jọ́ lórí, tí nwọ́n sì di ẹni ara nwọn, tí àwọn ènìyàn kan tí íṣe ará Sórámù sì ṣì nwọ́n lọ́nà, nípa irọ́ pípa nwọn àti àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn nwọn, láti darapọ̀ mọ́ àwọn ọlọ́ṣà Gádíátónì nnì.

30 Báyĩ sì ni àwọn ará Lámánì ṣe rí ìpọ́njú pẹ̀lú, tí nwọn sì bẹ̀rẹ̀sí fà sẹ́hìn nínú ìgbàgbọ́ àti ìwà òdodo nwọn, nítorí ìwà búburú ìran tí ó ndìde.