Àwọn Ìwé Mímọ́
3 Nífáì 18


Orí 18

Jésù fi ìlànà àmì májẹ̀mu lélẹ̀ lãrín àwọn ará Nífáì—Ó pàṣẹ fún wọn láti máa gbàdúrà ní orúkọ òun ní gbogbo ìgbà—Àwọn tí ó jẹ nínú ara rẹ̀ àti tí ó mu nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ní àìpé ni a ó dá lẹ́bi—Ó fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn nã ní agbára láti lè fúnni ní Ẹ̀mí Mímọ́. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe tí Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ pé kí wọn ó mú àkàrà àti wáìnì wá sí ọ̀dọ̀ òun.

2 Nígbàtí wọn sì ti lọ láti mú àkàrà àti wáìnì nã wá, ó pàṣẹ fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã pé kí wọn ó joko lé orí ilẹ̀.

3 Nígbàtí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn nã ti mú àkàrà àti wáinì nã dé, ó mú lára àkàrà nã ó bũ sí wẹ́wẹ́ ó sì súre síi; ó sì fií fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ ó sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọn ó jẹẹ́.

4 Nígbàtí wọ́n sì ti jẹ́ tí wọ́n sì ti yó, ó pàṣẹ pé kí wọn ó fi fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã.

5 Nígbàtí àwọn ọ̀pọ̀-ènìyàn nã sì ti jẹ tí wọn yó, ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn nã pé: Ẹ kíyèsĩ, ẹnìkan wà ní ãrin yín tí èmi yíò yàn, òun ni èmi yíò sì fún ni agbára láti lè bù àkàrà kí ó sì súré sĩ, kí ó sì fií fún àwọn ènìyàn ìjọ mi, fún gbogbo àwọn tí yíò gbàgbọ́ tí a ó sì rìbọmi ní orúkọ mi.

6 Èyí ni ẹ̀yin yíò sì ṣe àkíyèsí láti ṣe, àní gẹ́gẹ́bí èmi ti ṣe, àní gẹ́gẹ́bí èmi ti bù àkàrà tí emí sì súre sĩ, tí èmi sì fií fún yín.

7 Èyí ni ẹ̀yin yíò ṣe ní ìrántí ara mi, èyítí èmi ti fi hàn yín. Yíò sì jẹ́ ẹ̀rí níwájú Bàbá pé ẹ̀yin ṣe ìrántí mi nígbà-gbogbo. Bí ẹ̀yin bá sì ṣe ìrántí mi nígbà-gbogbo, nígbànã ni Ẹ̀mí mi yíò wà pẹ̀lú yín.

8 Ó sì ṣe nígbàtí ó sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ pé kí wọn ó mu nínú wáìnì tí ó wà nínú ago kí wọn ó sì mu lára rẹ̀, àti pé kí wọn ó fi fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã kí wọn ó lè mu nínú rẹ̀.

9 Ó sì ṣe tí wọn ṣe bẹ̃, wọ́n sì mu nínú rẹ̀ wọ́n sì yó, wọn sì fi fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã, wọ́n sì mu, wọ́n sì yó.

10 Nígbàtí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn nã si ti ṣe eleyĩ, Jésù wí fún wọn pé: Alábùkún-fún ni ẹ̀yin íṣe nítorí ohun yĩ èyítí ẹ̀yin ti ṣe, nítorítí èyĩ ni ìmúṣẹ àwọn òfin mi, èyí sì ṣe ìjẹ̃rí sí fún Bàbá pé ẹ̀yin ní ìfẹ́ láti ṣe èyítí mo ti pa láṣẹ fún yín.

11 Èyí sì ni kí ẹ̀yin ó ṣe ní ìgbà gbogbo fún àwọn tí ó ti ronúpìwàdà àti tí a sì rìbọmi ní orúkọ mi; ẹ̀yin ó sì ṣeé ní ìrántí ẹ̀jẹ̀ mi, èyítí èmi ti ta sílẹ̀ fún yín, pé kí ẹ̀yin ó lè ṣe ìjẹ̃rí sí fún Bàbá pé ẹ̀yin nrántí mi ní ìgbà gbogbo. Bí ẹ̀yin bá sì nrántí mi Ẹ̀mí mi yíò wà pẹ̀lú yín.

12 Èmi sì fún yín ní òfin kan pé kí ẹ̀yin ó ṣe àwọn ohun wọ̀nyí. Bí ẹ̀yin yíò bá sì ṣe wọ́n ní ìgbà gbogbo alábùkún-fún ni ẹ̀yin íṣe, nítorítí a ti kọ́ọ yín lé orí àpáta mi.

13 Ṣùgbọ́n ẹnìkẹ́ni nínú yín tí ó bá ṣe ju èyí tàbí kí ó dín in kù, òun nã ni a kò kọ́ lé orí àpáta mi, ṣùgbọ́n a kọ́ọ lé orí ìpìlẹ̀ yanrìn; nígbàtí òjò sì rọ̀, tí ìkún omi sì dé, tí afẹ́fẹ́ sì fẹ́, tí wọn sì bìlù wọn, wọn yíò ṣubú, àwọn ẹnu-ọ̀nà ipò-òkú sì ti ṣí sílẹ̀ láti gbà wọ́n wọlé.

14 Nítorínã alábùkún-fún ni ẹ̀yin íṣe bí ẹ̀yin bá pa òfin mi mọ́, èyítí Bàbá pàṣẹ pé kí èmi ó fi fún yín.

15 Lóotọ́, lóotọ́, mo wí fún yín, ẹ níláti máa ṣọ́nà kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà-gbogbo, kí èṣù ó má bã dán yín wò, kí ó sì mú yín ní ìgbèkùn.

16 Gẹ́gẹ́bí èmi sì ti gbàdúrà lãrín yín bẹ̃ nã ni kí ẹ̀yin ó gbàdúrà nínú ìjọ mi, lãrín àwọn ènìyàn mi tí ó bá ronúpìwàdà àti tí a rìbọmi ní orúkọ mi. Ẹ kíyèsĩ èmi ni ìmọ́lẹ̀; èmi ti fi àpẹrẹ lélẹ̀ fún yín.

17 Ó sì ṣe nígbàtí Jésù sì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọnyĩ fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀, ó tún yíjú padà sí àwọn ọ̀pọ̀-ènìyàn nã ó sì wí fún wọn pé:

18 Ẹ kíyèsĩ, lóotọ́, lóotọ́, ni mo wí fún yín, ẹ níláti máa ṣọ́nà kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà-gbogbo kí ẹ̀yin ó má bã bọ́ sínú ìdẹ́wò; nítorí Sátánì fẹ́ láti níi yín, kí ó lè kù yín bí àlìkámà.

19 Nítorínã ẹ níláti máa gbàdúrà nígbà-gbogbo sí Bàbá ní orúkọ mi;

20 Ohunkóhun tí ẹ̀yin yíò sì bẽrè lọ́wọ́ Bàbá ní orúkọ mi, èyítí ó yẹ, tí ẹ sì gbàgbọ́ pé ẹ ó rí gbà, ẹ kíyèsĩ a ó fí i fún yín.

21 Ẹ máa gbàdúrà nínú ẹbí yín sí Bàbá, ní orúkọ mi nígbà-gbogbo, kí àwọn aya yín àti àwọn ọmọ yín ó lè jẹ́ alábùkún-fún.

22 Àti kí ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin yíò máa bá ara yín péjọ pọ̀ nígbà-kũgbà; ẹ̀yin kò sì ní dá ẹnìkẹ́ni lẹ́kun láti wá sí ọ̀dọ̀ yín nígbàtí ẹ̀yin bá nbá ara yín péjọ pọ̀, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí wọn ó wá sí ọ̀dọ̀ yín ẹ má sì ṣe dá wọn lẹ́kun;

23 Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin ó gbàdúrà fún wọn, kí ẹ má sì ṣe lé wọn jáde; bí ó bá sì rí bẹ̃ tí wọn wá sí ọ̀dọ̀ yín nígbà-kũgbà ẹ̀yin ó máa gbàdúrà fún wọn sí Bàbá, ní orúkọ mi.

24 Nítorínã, ẹ gbé ìmọ́lẹ̀ yín sókè kí ó lè tàn sí aráyé. Ẹ kíyèsĩ, èmi ni ìmọ́lẹ̀ tí ẹ̀yin ó máa gbé sókè—èyítí ẹ̀yin ti rí tí èmi ṣe. Ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin ríi tí èmi ti gbàdúrà sí Bàbá, ẹ̀yin sì ti jẹ̃rí síi.

25 Ẹ̀yin sì ríi pé èmi ti pàṣẹ pé kí ẹnìkẹ́ni nínú yín máṣe lọ, dípò èyí èmi pàṣẹ pé kí ẹ wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí ẹ̀yin ó fi ọwọ́ bá ojú ọgbẹ́ ara mi àti kí ẹ fi ojú ara yín rí mi; bẹ̃ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀yin ó ṣe fún aráyé; ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì dá òfin yĩ kọjá ngba ara rẹ̀ lãyè fún fífà sínú ìdẹ́wò.

26 Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tán, ó tún yíjú rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ àwọn tí ó ti yàn, ó sì wí fún wọn pé:

27 Ẹ kíyèsĩ lóotọ́, lóotọ́, ni èmi wí fún yín, èmi fi òfin míràn fún yín, nígbànã ni èmi ó tọ Bàbá mi lọ kí èmi kí ó lè mú àwọn òfin míràn tí ó ti fún mi ṣẹ.

28 Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, èyí ni òfin èyítí èmi fi fún yín, pé ẹ̀yin kì yíò jẹ́ kí ẹnìkẹ́ni kí ó bá yín pín nínú ara àti ẹ̀jẹ̀ mi ní àìpé, nígbàtí ẹ̀yin bá npín in fúnni;

29 Nítorítí ẹnìkẹ́nì tí ó bá jẹ tí ó sì mu nínú ara àti ẹ̀jẹ̀ mi ní àìpé ni ó jẹ tí ó sì mu ìdálẹ́bi sí ẹ̀mí ara rẹ̀; nítorínã bí ẹ̀yin bá mọ̀ pé ẹnìkan wà ní àìpé láti jẹ àti láti mu nínú ara àti ẹ̀jẹ̀ mi kí ẹ̀yin kí ó dáa lẹ́kun.

30 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, ẹ̀yin kì yíò leè kúrò lãrín yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yíò jíṣẹ́ ìránṣẹ́ fún un ẹ̀yin yíò sì gbàdúrà fún un sí Bàbá, ní orúkọ mi; bí òun bá sì ronúpìwàdà tí a sì rĩbọmi ní orúkọ mi, nígbànã ni ẹ̀yin yíò gbã sí ãrin yín, tí ẹ̀yin yíò sì fún un nínú ara àti ẹ̀jẹ̀ mi.

31 Ṣùgbọ́n bí òun kò bá ronúpìwàdà, a kò ní kã mọ́ àwọn ènìyàn mi, kí ó má bã pa àwọn ènìyàn mi run, nítorí ẹ kíyèsĩ mo mọ́ àwọn àgùtàn mi, a sì ti ka iye wọn.

32 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, ẹ̀yin kì yíò lé wọn kúrò nínú àwọn sínágọ́gù yín, tàbí àwọn ibi ìjọsìn yín, nítorítí irú àwọn bẹ̃ ni ẹ̀yin yíò tẹramọ́ láti jíṣẹ́ ìránṣẹ́ fún; nítorí ẹ̀yin kò mọ̀ bóyá wọn yíò padà tí wọn yíò sì ronúpìwàdà, tí wọn yíò sì wá sí ọ̀dọ̀ mi tọkàn-tọkàn, tí èmi yìo sì wò wọ́n sàn; ẹ̀yin yíò sì jẹ́ ipa èyítí a fi mú ìgbàlà bá wọn.

33 Nítorínã, kí ẹ̀yin kí ó pa àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí èmi ti pa láṣẹ fún yín mọ́ kí ẹ̀yin ó máṣe gba ìdálẹ́bi; nítorí ègbé ni fún ẹnití Bàbá bá dálẹ́bi.

34 Èmi sì fún yín ní àwọn òfin wọ̀nyí nítorí àwọn àríyànjiyàn tí ó ti wà lãrín yín. Ìbùkún si ni fún yín bí kò bá sí àríyànjiyàn lãrín yín.

35 Àti nísisìyí èmi nlọ sí ọ̀dọ̀ Bàbá, nítorítí ó tọ̀nà pé kí èmi ó lọ sí ọ̀dọ̀ Bàbá nítorí yín.

36 Ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní sísọ, ó fi ọwọ́ rẹ kan àwọn ọmọ-ẹ̀hìn tí ó ti yàn ní ọ̀kọ̃kan, àní títí ó fi fi ọwọ́ kan gbogbo wọn, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀ bí ó ti nfi ọwọ́ kàn wọ́n.

37 Àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã kò sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó nsọ, nítorínã wọn kò ní àkọsílẹ̀ nípa wọn; ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀hìn nã ní àkọsílẹ̀ pé ó fún wọn ní agbára láti fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún ni. Èmi yíò sì fi hàn yín tí ó bá yá pé òtítọ́ ni àkọsílẹ̀ yí jẹ́.

38 Ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti fi ọwọ́ kan gbogbo wọn tán, ikũku kan yọ tí ó sì ṣíjibo àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã tí wọn kò lè rí Jésù.

39 Bí a sì ti síjibò wọ́n, ó kúrò lãrín wọn, ó sì gòkè re ọ̀run. Àwọn ọmọ-ẹ̀hìn nã sì ríi wọ́n sì jẹ̃rí síi pé ó tún gòkè re ọ̀run.