Àwọn Ìwé Mímọ́
3 Nífáì 5


Orí 5

Àwọn ará Nífáì ronúpìwàdà wọn sì kọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wọn sílẹ̀—Mọ́mọ́nì kọ ìtàn nípa àwọn ènìyàn rẹ̀ ó sì kéde ọ̀rọ̀ nã tí ó wà títí ayé fún wọn—A ó kó Ísráẹ́lì jọ kúrò nínú ipò ìfọ́nká rẹ̀ ọlọ́jọ́ pípẹ́. Ní ìwọ̀n ọdún 22 sí 26 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, kò sí ẹ̀mí alãyè kan lãrín àwọn ènìyàn Nífáì tí ó ní àìdánilójú bí ó ti kéré tó nípa àwọn ọ̀rọ̀ gbogbo àwọn wòlĩ mímọ́ tí ó ti sọ̀rọ̀; nítorítí wọ́n mọ̀ wípé ó di dandan pé kí wọn ó di mímúṣẹ.

2 Wọ́n sì mọ̀ pé ó tọ̀nà pé Krístì ti dé, nítorí àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì èyítí a ti fún wọn, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ àwọn wòlĩ; àti nítorí àwọn ohun nnì èyítí ó ti di mímúṣẹ wọ́n mọ̀ pé ó di dandan pé ohun gbogbo níláti di mímúṣẹ ní ìbámu pẹ̀lú èyítí àwọn wòlĩ ti sọ.

3 Nítorínã ni wọn kọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn sílẹ̀, àti àwọn ohun ìríra wọn, àti àwọn ìwà àgbèrè wọn, tí wọ́n sì nsin Ọlọ́run tọkàn tọkàn tọ̀sán-tòru.

4 Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí nwọ́n ti kó gbogbo àwọn ọlọ́ṣà nã lẹ́rú, tóbẹ̃ tí kò sí èyíkéyi tí ó sálọ tí a kò pa, wọn sì kó àwọn ẹrú wọn nã sínú túbú, wọ́n sì mú kí a wãsù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí wọn; gbogbo àwọn tí ó bá sì ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti tí wọ́n sì bá wọn dá májẹ̀mú pé àwọn kò ní pànìyàn mọ́ ni wọ́n tú sílẹ̀.

5 Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí wọn kò bá wọn dá májẹ̀mú, àti tí wọn sì tẹ̀síwájú lati ni ìwà ìpànìyàn ní ìkọ̀kọ̀ nínú ọkan wọn, bẹ̃ni, gbogbo àwọn tí wọ́n rí tí wọn nmí ẽmí ìdẹ́rùbani mọ́ àwọn arákùnrin wọn ni wọ́n dálẹ́bi tí wọ́n sì fìyàjẹ ní ìbámu pẹ̀lú òfin.

6 Bàyĩ ni wọn sì fi òpin sí gbogbo awọn ẹgbẹ́ ìkọ̀kọ̀, búburú, ati ìríra nnì, nínú èyí tí ìkà ṣíṣe púpọ̀ wa, àti tí wọn nṣe ìpànìyàn púpọ̀púpọ̀.

7 Báyĩ sì ni ọdún kejìlélógún ti kọjá lọ, àti ọdún kẹtàlélógún pẹ̀lú, àti ọdún kẹrìnlélógún, àti ìkárúndínlọ́gbọ̀n; àti báyĩ ni ọdún marúndínlọ́gbọ̀n ti kọjá lọ.

8 Àwọn ohun tí ó pọ̀ sì ti ṣẹlẹ̀ èyítí, ní ojú àwọn ènìyàn kan, ó jẹ́ ohun nlá àti ìyanilẹ́ni; bíótilẹ̀ríbẹ̃, a kò lè kọ gbogbo wọn sínú ìwé yĩ; bẹ̃ni, ìwé yĩ kò lè gba ìdá kan nínú ọgọ́rún àwọn ohun tí nwọ́n ṣe lãrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn nínú ìwọ̀n ọdún márúndínlọ́gbọ̀n.

9 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ àwọn àkọsílẹ̀ wà èyítí o ni àwọn ìṣe àwọn ènìyàn yĩ nínú; Nífáì sì kọ nípa ìṣe nã ní kúkúrú ṣùgbọ́n ní òtítọ́.

10 Nítorínã ni èmi fi kọ àkọsílẹ̀ mi nípa àwọn ohun yĩ ní ìbámu pẹ̀lú àkọsílẹ̀ Nífáì, èyítí a gbẹ́ sí orí àwọn àwo àkọsílẹ̀ tí a pè ní àwo Nífáì.

11 Ẹ sì kíyèsĩ, èmi kọ àkọsílẹ̀ nã lé orí àwọn àwo èyítí èmi fi ọwọ́ ara mi ṣe.

12 Ẹ sì kíyèsĩ, Mọ́mọ́nì ní orúkọ mi, nítorítí a fi orúkọ ilẹ̀ ti Mọ́mọ́nì pè mí, ilẹ̀ nínú èyítí Álmà dá ìjọ onígbàgbọ́ sílẹ̀ lãrín àwọn ènìyàn nã, bẹ̃ni, ìjọ onígbàgbọ́ èkínní tí a da sílẹ̀ lãrín wọn lẹ́hìn ìwà ìrékọjá wọn.

13 Ẹ kíyèsĩ, ọmọ ẹ̀hìn Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run ni èmi íṣe. Òun ni ó pè mí láti kéde ọ̀rọ̀ rẹ̀ lãrín àwọn ènìyàn rẹ̀, kí wọn ó lè ní ìyè títí ayé.

14 Ó sì ti di ohun tí ó tọ̀nà kí èmi, ní ìbámú pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run, pé kí àdúrà àwọn tí ó ti kọjá lọ, àwọn tí ó jẹ́ àwọn ẹni mímọ́, lè gbà gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ wọn, kí ó kọ àkọsílẹ̀ nípa àwọn ohun yĩ èyítí wọn ti ṣe—

15 Bẹ̃ni, àkọsílẹ̀ kékeré nípa èyítí ó ti ṣẹlẹ̀ láti àkokò tí Léhì ti fi Jerúsálẹ́mù sílẹ̀, àní títí dé àkokò yĩ.

16 Nítorínã ni èmi ṣe kọ àkọsílẹ̀ mi bẹ̀rẹ̀ láti àwọn ìṣe èyítí àwọn tí ó ṣãju mi ti kọ, títí di ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà tèmi;

17 Nígbànã ni èmi ṣe àkọsílẹ̀ nípa àwọn ohun tí èmi ti fi ojú ara mi rí.

18 Èmi sì mọ̀ pé àkọsílẹ̀ tí èmi ṣe jẹ́ àkọsílẹ̀ tí ó tọ́ tí ó sì jẹ́ òtítọ́; bíótilẹ̀ríbẹ̃ àwọn ohun púpọ̀ ni ó wà tí a kò lè kọ nítorí èdè wa.

19 Àti nísisìyí èmi mú ọ̀rọ̀ mi wá sí ópin, èyítí íṣe nípa ara mi, mo sì tẹ̀síwájú láti kọ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀ kí èmi ó tó dé ayé.

20 Mọ́mọ́nì ni èmi íṣe, mo sì jẹ́ àtẹ̀lé Léhì lódodo. Mo ní ìdí láti fi ìbùkún fún Ọlọ́run mi àti Olùgbàlà mi Jésù Krístì, pé ó mú àwọn bàbá wa jáde kúrò nínú ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, (kò sì sí ẹnikẹ́ni tí ó mọ̀ nípa rẹ̀ àfi òun tìkararẹ̀ àti àwọn tí ó mú jáde kúrò nínú ilẹ̀ nã) àti nítorítí ó ti fún èmi àti àwọn ènìyàn mi ní ìmọ̀ tí ó pọ̀ púpọ̀ sí ìgbàlà ọkàn wa.

21 Dájúdájú ó ti bùkún fún ìdílé Jákọ́bù, ó sì ti ṣãnú fún irú-ọmọ Jósẹ́fù.

22 Àti tóbẹ̃ bí àwọn àtẹ̀lé Léhì ti pa òfin rẹ̀ mọ́ ni ó ṣe bùkún fún wọn tí ó sì mú wọn ṣe rere gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

23 Bẹ̃ni, dájúdájú òun yíò sì tún mú ìyókù nínú irú-ọmọ Jósẹ́fù sínú ìmọ̀ nípa Olúwa Ọlọ́run wọn.

24 Àti bí ó ti dájú pé Olúwa wà lãyè, ni yíò kó wọn jọ láti igun mẹ́rẹ̀rin ayé gbogbo àwọn ìyókù nínú irú-ọmọ Jákọ́bù, tí ó ti fọ́nkákiri lórí gbogbo orí ilẹ̀ ayé.

25 Bí ó sì ti bá gbogbo ìdílé Jákọ́bù dá májẹ̀mú, bẹ̃ nã ni májẹ̀mú nã èyítí ó ti bá ìdílé Jákọ́bù dá yíò di mìmúṣẹ ní àkokò tirẹ, títí dé ìmúpadà bọ́ sípò gbogbo ìdílé Jákọ́bù sí ti ìmọ̀ nípa májẹ̀mú tí ó ti bá wọn dá.

26 Nígbànã ni wọn yíò sì mọ́ Olùràpadà wọn, ẹnití íṣe Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run; nígbànã ni a o sì kó wọn jọ láti igun mẹ́rẹ̀rin ayé sínú àwọn ilẹ̀ tiwọn, láti ibití wọn ti fọ́n wọn ká sí; bẹ̃ni, bí Olúwa ti wà lãyè, bẹ̃ni yíò rí. Àmín.