Àwọn Ìwé Mímọ́
3 Nífáì 24


Orí 24

Oníṣẹ Olúwa yíò tún ọ̀nà ṣe fún Bíbọ̀ kejì—Krístì yíò joko ní ìdájọ́—A pàṣẹ fún Ísráẹ́lì lati san ìdámẹ̃wá àti ọrẹ—A kọ ìwé ìrántí—A fi orí ìwé yĩ wé Málákì 3. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe tí ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọn ó kọ àwọn ọ̀rọ̀ tí Bàbá ti fifún Málákì, èyítí òun yíò sọ fún wọn. Ó sì ṣe lẹ́hìn tí wọn ti kọọ́ tán ó sọ àsoyé lórí wọn. Èyí sì ni àwọn ọ̀rọ̀ nã tí ó sọ fún wọn, wípé: Báyĩ ni Bàbá wí fún Málákì—Kíyèsĩ, èmi yíò rán oníṣẹ́ mi, yíò sì tún ọ̀nà ṣe níwájú mi, Olúwa tí ẹ̀yin sì nwá yíò dé ní òjijì sí tẹ́mpìlì rẹ̀, àní oníṣẹ́ májẹ̀mú nã, ẹnití inú yín dùn sí; ẹ kíyèsĩ, oun yíò wá, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí.

2 Ṣùgbọ́n tani ó lè gbà ọjọ́ wíwá rẹ̀, tani yíò sì dúró nígbàtí ó bá fi ara hàn? Nítorítí ó dàbí iná ẹnití ndà fàdákà, àti bí ọṣẹ afọṣọ.

3 Òun yíò sì joko bí ẹnití nyó àti ẹnití ndà fàdákà; òun yíò sì ṣe àwọn àtẹ̀lé ọmọ Léfì ní mímọ́, yíò sì yọ wọn bí wúrà òun fàdákà, kí wọn kí ó lè rú ẹbọ òdodo sí Olúwa.

4 Nígbànã ni ọrẹ Júdà àti ti Jerúsálẹ́mù yíò wu Olúwa gẹ́gẹ́bí ọjọ́ ti ìgbà àtijọ́, àti gẹ́gẹ́bí ọdún ti àtijọ́.

5 Èmi ó sì súnmọ́ ọ láti ṣe ìdájọ́; èmi yíò sì ṣe ẹlẹri ní kánkán sí àwọn oṣó, àti sí àwọn panṣágà, àti sí àwọn abúra èké àti àwọn tí ó ni alágbàṣe lára nínú owó ọya rẹ̀, àti opó, àti aláìníbàbá, àti sí ẹnití ó kọ̀ láti ran àjèjì lọ́wọ́, tí wọn kò sì bẹ̀rù mi, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí.

6 Nítorí èmi ni Olúwa, èmi kò yípadà; nítorínã ni a kò ṣe run ẹ̀yin ọmọ Jákọ́bù.

7 Àní láti ọjọ́ àwọn bàbá yín wá ni ẹ̀yin ti yapa kúrò nínú ìlànà mi, tí ẹ kò sì pa wọ́n mọ́. Ẹ yípadà sí ọ̀dọ̀ mi, èmi o sì yípadà sí ọ̀dọ̀ yín, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wípé: Nípa báwo ni àwa ó yipadà?

8 Ènìyàn yíò ha ja Ọlọ́run ní olè bí? Síbẹ̀síbẹ̀ ẹ̀yin ti jà mií ní ólè. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wípé: Nípa báwo ni àwa fi jà ọ́ ní olè? Nípa ìdámẹ̃wá àti ọrẹ.

9 A ti fi yín bú, nítorí ẹ̀yin ti jà mí ní ólè, àní gbogbo orílè-èdè yĩ.

10 Ẹ mú gbogbo ìdámẹ́wá wá sí ilé ìṣura, kí oúnjẹ ó lè wà ní ilé mi; ẹ sì fi èyí dán mi wò nísisìyí, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí, bí èmi kì yíò bá ṣí fèrèsé ọ̀run fún yín, kí èmi ó sì tú ìbùkún jáde fún yín, tóbẹ̃ tí kì yíò sí àyè láti gbã.

11 Èmi ó sì bá ajẹnirun wí nítorí yín, òun kì ó sì run èso ilẹ̀ yín; bẹ̃ni àjàrà yín kì yìó rẹ̀ dànù ní àìpé ọjọ́ nínú oko, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí.

12 Gbogbo orílẹ̀-èdè ni yíò sì pè yín ní alábùkún fún, nítorípé ẹ̀yin ó jẹ́ ilẹ̀ tí ó wunni, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí.

13 Àwọn ọ̀rọ̀ yín jẹ́ líle sí mi, ni Olúwa wí. Síbẹ̀síbẹ̀ ẹ̀yin wípé: Ọ̀rọ̀ kíni àwa sọ sí ọ?

14 Ẹ̀yin ti wípé: Asán ni láti sin Ọlọ́run, ànfàní kíni ó sì jẹ́, tí àwa ti pa àwọn ìlànà rẹ̀ mọ́, tí àwa ti rìn nínú ìrora-ọkàn níwájú Olúwa àwọn Ọmọ-ogun?

15 Àti nísisìyí àwa pe agbéraga ní onínúdídùn; bẹ̃ni, àwọn tí ó nṣe búburú npọ̀ síi; bẹ̃ní, àwọn tí ó dán Ọlọ́run wò sã ni a dá sí.

16 Nígbànã ni àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa nbá ara wọn sọ̀rọ̀ nígbàkũgbà, Olúwa sì fetísílẹ̀, ó sì gbọ́; a sì kọ ìwé-ìrántí kan níwájú rẹ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa, tí wọ́n sì nrántí, tí wọ́n sì bẹ̀rù orúkọ rẹ̀.

17 Wọn yíò sì jẹ́ tèmi, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí, ní ọjọ́ nã nígbàtí èmi ó kó àwọn ohun ọ̀ṣọ́ mi jọ; èmi ó sì dá wọn sí gẹ́gẹ́bí ènìyàn íti máa dá ọmọ rẹ̀ tí ó nsìn í sí.

18 Nígbànã ni ẹ̀yin ó padà, tí ẹ ó sì mọ́ ìyàtọ̀ lãrín olódodo àti ẹni-búburú, lãrín ẹnití nsin Ọlọ́run àti ẹnití kò sìn ín.