Àwọn Ìwé Mímọ́
3 Nífáì 6


Orí 6

Àwọn ará Nífáì ní ìlọsíwájú—Ìgbéraga, ọrọ̀, àti ẹlẹ́yà-mẹ̀yà ẹgbẹ́ yọ jáde—Ìjọ pínyà pẹ̀lú ìyapa—Sátánì darí àwọn ènìyàn nã sí ìṣọ̀tẹ̀ gbangba—Àwọn wòlĩ púpọ̀ wãsù ìrònúpìwàdà a sì pa wọ́n—Àwọn tí ó pa wọn dìtẹ̀ láti gba ìjọba. Ní ìwọ̀n ọdún 26–30 nínú ọjọ́ Olúwa.

1 Àti nísisìyí ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn ará Nífáì gbogbo sì padà lọ sí órí ilẹ̀ wọn nínú ọdún kẹrìndínlọ́gbọ̀n, olúkúlukù, pẹ̀lú ìdílé rẹ̀, ọ̀wọ́ ẹran rẹ̀ àti agbo ẹran rẹ̀, àwọn ẹṣin rẹ̀ àti àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀, àti ohun gbogbo tí íṣe tiwọn.

2 Ó sì ṣe tí wọn kò tĩ jẹ gbogbo àwọn ohun ìpèsè wọn tán; nítorínã ni wọ́n fi kó gbogbo ohun tí wọn kò tĩ jẹ pẹ̀lú wọn, gbogbo àwọn ọkà wọn lónírurú, àti wúrà wọn, àti fàdákà wọn, àti àwọn nkan ojúlówó wọn, wọ́n sì padà sí órí ilẹ̀ wọn àti sí àwọn ohun ìní wọn, àti ní àríwá àti ní gúsù, àti ní ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá àti ní ilẹ̀ tí ó wà ní apá gúsù.

3 Wọ́n sì fi ilẹ̀ fún àwọn ọlọ́ṣà nnì tí wọ́n ti bá wọn dá májẹ̀mú láti wà ní álãfíà lórí ilẹ̀ nã, tí wọ́n ní ìfẹ́ láti wà bí àwọn ará Lámánì, àwọn ilẹ̀, gẹ́gẹ́bí wọn ti pọ̀ tó, kí wọn ó lè ní ohun tí wọn yíò fi gbé ilé ayé nípa iṣẹ́ ṣíṣe wọn; báyĩ sì ni wọ́n fi àlãfíà lélẹ̀ lórí ilẹ̀ nã.

4 Wọ́n sì tún bẹ̀rẹ̀sí ní ìlọsíwájú àti láti pọ̀ síi ní agbara; ọdún kẹrìndínlọ́gbọ̀n àti ìkẹtàdínlọ́gbọ̀n sì kọjá, ètò nlá sì wà lórí ilẹ̀ nã; wọn sì ṣe àwọn òfin wọn ní ọ̀nà ìṣòtítọ́ àti àìṣègbè.

5 Àti nísisìyí kò sí ohunkóhun nínú gbogbo ilẹ̀ nã tí yíò ṣe ìdíwọ́ fún àwọn ènìyàn nã láti ní ìlọsíwájú títí, àfi bí wọ́n bá ṣubú sínú ìwà ìrékọja.

6 Àti nísisìyí Gídgídónì, àti Lákónéúsì, onidajọ, àti àwọn wọnnì tí a ti yàn gẹ́gẹ́bí olórí ni wọ́n fi àlãfíà nlá yĩ lélẹ̀ ní ilẹ̀ nã.

7 Ó sì ṣe tí àwọn ìlú nlá púpọ̀ di títúnkọ́, tí àwọn ìlú àtijọ́ sì di títúnṣe.

8 Àwọn ọ̀nà òpópó púpọ̀ sì di kíkọ́, àti àwọn ọ̀nà púpọ̀ ni a là, èyítí ó lọ láti ìlú-nlá dé ìlú-nlá, àti láti ilẹ̀ dé ilẹ̀, àti láti ibìkan dé ibìkan.

9 Báyĩ sì ni ọdún kéjìdínlọ́gbọ̀n kọjá, àwọn ènìyàn nã sì ní àlãfíà títí.

10 Ṣùgbọ́n ó sì ṣe ní ọdún kọkàndínlọ́gbọ̀n tí àríyànjiyàn bẹ̀rẹ̀sí wà lãrín àwọn ènìyàn nã; tí àwọn kan gbé ara wọn sókè ní ìgbéraga àti lílérí nítorípé wọn ní ọrọ̀ púpọ̀, bẹ̃ni, àní, títí fi de ṣíṣe inúnibíni púpọ̀púpọ̀;

11 Nítorí àwọn oníṣòwò púpọ̀ wà lórí ilẹ̀ nã, àti àwọn amòfin púpọ̀púpọ̀ àti olórí púpọ̀púpọ̀.

12 Àwọn ènìyàn nã sì bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìyàtọ̀ sí ara wọn nípa ipò tí ènìyàn wà; gẹ́gẹ́bí ọrọ̀ wọ́n ti pọ̀ tó àti gẹ́gẹ́bí wọ́n ti ní ànfàní ẹ̀kọ́ kíkọ́ tó; bẹ̃ni, àwọn kan wà ní ipò aláìmọ̀ nítorí àìní wọn, àwọn míràn sì gba ẹ̀kọ́ kíkọ́ púpọ̀púpọ̀ nítorí ọ̀pọ̀ ọrọ̀ wọn.

13 Àwọn kan gbé ọkàn wọn sókè ní ìgbéraga, àwọn míràn sì rẹ ara wọn sílẹ̀ púpọ̀púpọ̀; àwọn kan sì fi ẽbú san fún ẽbú, tí àwọn míràn yíò sì gba ẽbú àti inúnibíni àti onírurú ìpọ́njú, tí wọn kìyo sí yíjú padà láti dá ẽbú padà, ṣùgbọ́n wọn rẹ ara wọn sílẹ̀ wọ́n sì wà ní ipò ìrònúpìwàdà níwájú Ọlọ́run.

14 Báyĩ sì ni àidọ́gba nlá wà lórí gbogbo ilẹ̀ nã, tóbẹ̃ tí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run nã sì bẹ̀rẹ̀sí pín sí ọ̀nà púpọ̀; bẹ̃ni, tóbẹ̃ tí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run nã fi pín sí ọ̀nà púpọ̀ ni gbogbo ilẹ̀ nã nígbàtí odi ọgbọ̀n ọdún, àfi ní ãrín àwọn ará Lámánì díẹ̀ tí a ti yípadà sí ìgbàgbọ́ òtítọ́; tí wọn kò sì ní yísẹ̀padà kúrò nínú rẹ̀, nítorítí wọ́n dúróṣinṣin, wọ́n sì wà gbọin-gbọin, àti láìyísẹ̀padà, tí wọn sì ní ìfẹ́ tọkàntara láti pa òfin Olúwa mọ́.

15 Nísisìyí ohun tí ó mú àìṣedẽdé àwọn ènìyàn nã wá ni èyí—Sátánì ní agbára nla, láti fi rú àwọn ènìyàn sókè láti ṣe onírũrú àìṣedẽdé, àti láti mú wọn di agbéraga, tí ó ntàn wọ́n láti máa wá agbára, àti àṣẹ, àti ọrọ̀, àti àwọn ohun asán ayé yĩ.

16 Báyĩ sì ni Sátánì darí ọkàn àwọn ènìyàn nã láti ṣe onírurú àìṣedẽdé; nítorínã ni wọ́n ṣe rí àlãfíà fún ọdún díẹ̀.

17 Àti báyĩ, ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ̀n ọdún—lẹhin ti a ti fi àwọn ènìyàn nã sílẹ̀ fún ìwọ̀n ọjọ́ pípẹ́ fún àdánwò èṣù láti darí wọn lọ sí ibikíbi tí ó bá wũ, àti láti ṣe àìṣedẽdé èyíkéyi tí ó bá wũ kí wọn ṣe—àti báyĩ ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ̀n ọdún yĩ, wọn wà ní ipò ìwà búburú tí ó lẹ́rù.

18 Nísisìyí wọn kò dẹ́ṣẹ̀ láìmọ̀, nítorítí wọ́n mọ́ ìfẹ́ Ọlọ́run fún wọn, nítorítí a ti fi kọ́ wọn; nítorínã ni wọ́n ṣe mọ̃mọ̀ ṣe ìṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run.

19 Àti nísisìyí àkokò Lákónéúsì ní íṣe, ọmọkunrin Lákónéúsì, nítorítí Lákónéúsì ni ó wà lórí ìtẹ́-ìdájọ́ rọ́pò bàbá rẹ̀ ó sì ṣe ìjọba lórí àwọn ènìyàn nã ní ọdún nnì.

20 Àwọn ènìyàn sì bẹ̀rẹ̀sí gba ìmísí láti ọ̀run tí a sì rán wọ́n jáde, tí wọ́n sì dúró lãrín àwọn ènìyàn nã ní gbogbo ilẹ̀ nã, tí wọn nwãsù ti wọn si njẹ́rĩ pẹ̀lú igboya nipa àwọn ẹṣẹ àti àwọn àìṣedẽdé àwọn ènìyàn nã, tí wọ́n sì njẹ́rĩ fún wọn nípa ìràpadà nã èyítí Olúwa yíò ṣe fún àwọn ènìyàn rẹ̀, tàbí ní ọ̀nà míràn, àjĩnde Krístì; wọ́n sì jẹ́rĩ pẹ̀lú ìgboyà nípa ikú àti ìjìyà rẹ̀.

21 Nísisìyí àwọn púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn nã ni ó bínú gidigidi nítorí àwọn tí ó jẹ́rĩ nípa àwọn ohun wọ̀nyí; àwọn tí ó sì bínú jùlọ ni àwọn adájọ́ àgbà, àti àwọn tí wọn ti fi igbakan rí jẹ́ olórí àlùfã àti amòfin; bẹ̃ni, gbogbo àwọn tí íṣe amòfin ni ó bínú sí àwọn tí ó jẹ́rĩ nípa àwọn ohun wọ̀nyí.

22 Nísisìyí kò sí amòfin kankan tàbí adájọ́ tàbí olórí àlùfã tí ó ní agbára láti dájọ́ ikú fún ẹnìkẹ́ni láìjẹ́ wípé bãlẹ̀ ilẹ̀ nã fi ọwọ́ sí ìdájọ́ nã.

23 Nísisìyí àwọn púpọ̀ nínú àwọn tí ó jẹ́rĩ nípa àwọn ohun ti Krístì tí wọ́n jẹ́rĩ pẹ̀lú ìgboyà, ni àwọn adájọ́ mú tí wọn sì pa ní ìkọ̀kọ̀, tí pípa tí wọ́n pa wọ́n kò sì di mímọ̀ fún bãlẹ̀ ilẹ̀ nã títí di ẹ̀hìn tí wọ́n ti pa wọ́n.

24 Nísisìyí ẹ kíyèsĩ, èyí tako àwọn òfin ilẹ̀ nã, pé wọn yíò pa ẹnìkẹ́ni bíkòṣepé wọ́n ní àṣẹ láti ọwọ́ bãlẹ̀ ilẹ̀ nã—

25 Nítorínã ni ẹ̀sun fi wá sí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, sí ọ̀dọ̀ bãlẹ̀ ilẹ̀ nã, nípa àwọn adájọ́ yĩ tí wọ́n ti dájọ́ ikú fún àwọn wòlĩ Olúwa, ní ìtakò òfin.

26 Nísisìyí ó sì ṣe tí a mú wọn tí a sì mú wọ́n wá sí iwájú adajọ́, fún ìdájọ́ lórí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti ṣẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú òfin èyítí àwọn ènìyàn nã ti fi lélẹ̀.

27 Nísisìyí ó sì ṣe tí àwọn adájọ́ nnì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rẹ́ àti ìbátan; àti àwọn yókù, bẹ̃ni, àní tí ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ gbogbo àwọn amòfin àti àwọn olórí àlùfã, ni wọn sì kó ara wọn jọ, tí wọ́n sì darapọ̀ mọ́ àwọn ìbátan àwọn adájọ́ nnì tí a fẹ́ ṣe ìdájọ́ fún ní ìbámu pẹ̀lú òfin.

28 Nwọ́n sì bá ara wọn dá májẹ̀mú, bẹ̃ni, àní wọ inú májẹ̀mú èyítí àwọn ẹni ìgbà nnì fi lélẹ̀, májẹ̀mú èyítí ẹ̀ṣù fi lélẹ̀, tí ó sì nṣe ìpínfúnni rẹ̀, láti gbìmọ̀ lòdìsí gbogbo òdodo.

29 Nítorínã ni wọ́n ṣe gbìmọ̀ lòdìsí àwọn ènìyàn Olúwa, tí wọn sì dá májẹ̀mú láti pa wọ́n run, àti láti gbá àwọn tí wọ́n jẹ̀bi ìpànìyàn kúrò lọ́wọ́ àìṣègbè, èyítí nwọ́n ti ṣetán láti ṣe ìpínfúnni rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú òfin.

30 Nwọ́n sì ṣe ìpèníjà sí òfin àti ẹ̀tọ́ orílẹ̀-èdè wọn; wọ́n sì bá ara wọn dá majẹ̀mú láti pa bãlẹ̀ nã run, àti láti fi ọba sí orí ilẹ̀ nã, kí ilẹ̀ nã ó má lè wà ní ipò òmìnirà ṣùgbọ́n kí wọn ó wà lábẹ́ òfin àwọn ọba.