Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 42


Orí 42

Ipò ara ìdibàjẹ́ jẹ́ ìgbà ìdánwò tí ó fún ènìyàn ní ànfãní láti ronúpìwàdà àti láti sin Ọlọ́run—Ìṣubú nnì mú ikú ti ara àti ti ẹ̀mí wá sí órí ọmọ aráyé—Ìràpadà wá nípa ìrònúpìwàdà—Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni ó ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ ayé—ãnú jẹ́ tí àwọn tí ó ronúpìwàdà—Gbogbo àwọn tí ó kù wà lábẹ́ àìṣègbè Ọlọ́run—Àánú wá nítorí Ètùtù nã—Àwọn tí nwọn bá ronúpìwàdà nítõtọ́ nìkan ni a ó gbàlà. Ní ìwọ̀n ọdún 74 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí, ọmọ mi, mo wòye pé ohun kan tún kù tí ó nni ọkàn rẹ lára, èyítí kò yé ọ—èyítí íṣe nípa àìṣègbè Ọlọ́run ní ti ìfìyàjẹ ẹlẹ́ṣẹ̀; nítorí ìwọ tiraka láti ròo pé ìṣègbè ni kí a fi ẹlẹ́ṣẹ̀ sí ipò ìbànújẹ́.

2 Nísisìyí kíyèsĩ, ọmọ mi, èmi yíò la ohun yĩ yé ọ. Nítorí kíyèsĩ, lẹ́hìn tí Olúwa Ọlọ́run lé àwọn òbí wa àkọ́kọ́ jáde kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì, láti máa ro ilẹ̀, nínú èyítí a ti mú nwọn jáde wá—bẹ̃ni, ó mú ọkùnrin nã jáde, ó sì fi sí ìhà apá ìlà-oòrùn ọgbà Édẹ́nì nã, àwọn kérúbímù, àti idà iná èyítí njù kãkiri, láti máa ṣọ́ igi ìyè nã—

3 Nísisìyí, a ríi pé ènìyàn nã ti dàbí Ọlọ́run, tí ó sì mọ́ rere àti búburú; njẹ́ kí ó má bã na ọwọ́ rẹ̀, kí ó sì mú nínú èso igi ìyè nã pẹ̀lú, kí ó sì jẹ kí ó sì yè títí láé, Olúwa Ọlọ́run fi kérúbímù àti idà iná sí ibẹ̀, kí ó má lè jẹ nínú èso nã—

4 Bẹ̃ni àwa sì ríi pé a fún ènìyàn ní àkokò kan láti ronúpìwàdà, bẹ̃ni, àkokò ìdánwò, àkokò láti ronúpìwàdà àti láti sin Ọlọ́run.

5 Nítorí kíyèsĩ, bí Ádámù bá ti na ọwọ́ rẹ̀ jáde lẹ́sẹ̀kannã, tí ó sì ti jẹ nínú igi ìyè nã, kì bá wà ní ãyè títí láé, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, òun kò sì ní ní àkokò tí yíò ronúpìwàdà; bẹ̃ ni, àti pẹ̀lú pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kì bá sì di òfo, ìlànà ìgbàlà nlá nnì yíò sì di asán.

6 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, a ti yàn án fún ènìyàn láti kú—nítorínã, bí a ti ṣe pín nwọn níyà kúrò lára igi ìyè nã, a níláti pín nwọn níyà kúrò lórí ilẹ̀ ayé—ènìyàn sì sọnù títí láé, bẹ̃ni, nwọn di ẹni-ìṣubú.

7 Àti nísisìyí, ìwọ ríi nípasẹ̀ nkan yĩ pé a ké àwọn òbí wa àkọ́kọ́ kúrò ni ti ara àti ti ẹ̀mí níwájú Olúwa; àwa sì ríi bẹ̃ pé nwọ́n di ẹni ara nwọn láti ṣe gẹ́gẹ́bí èrò inú ọkàn nwọn.

8 Nísisìyí kíyèsĩ, kò jẹ́ ohun tí ó tọ́ kí a gba ènìyàn lọ́wọ́ ikú ti ara yĩ, nítorípé ṣíṣe èyí yìó pa ìlànà ayọ̀ nlá nnì run.

9 Nítorínã, nítorípé ẹ̀mí ènìyàn kò lè kú, tí ìṣubú nnì sì ti mú ikú ẹ̀mí àti ikú ara bá gbogbo ènìyàn pé a ti ké nwọn kúrò níwájú Olúwa, ó jẹ́ ohun tí ó tọ́ ní ṣíṣe pé kí a gba ènìyàn lọ́wọ́ ikú ẹ̀mí yĩ.

10 Nítorínã, nítorípé nwọ́n ti di ti ara, ti ayé àti ti èṣù ni ti ìdánidá nwọn, ipò ìdánwò yĩ sì jẹ́ ipò fún nwọn láti murasílẹ̀; ó sì jẹ́ ipò ìmúrasílẹ̀.

11 Àti nísisìyí rántí, ọmọ mi, bí kò bá jẹ́ fún ti ìlànà ìràpadà nnì, (tí a bá pa á tì) ní kété tí nwọn bá ti kú, ẹ̀mí nwọn yíò wà ní ipò ìbànújẹ́, nítorípé a ó ké nwọn kúrò níwájú Olúwa.

12 Àti nísisìyí, kò sí ọ̀nà tí a fi lè gba ènìyàn kúrò nínú ipò ìṣubú yĩ, èyítí ènìyàn tí mú wá sí órí ara rẹ̀ nítorí ìwà àìgbọràn ara rẹ̀;

13 Nítorínã, ní ìbámu pẹ̀lú àìṣègbè, ìlàna ìràpadà nnì kò lè wáyé, àfi nípasẹ̀ ìrònúpìwàdà ènìyàn ní ipò ìdánwò yĩ, bẹ̃ni, ipò ìmúrasílẹ̀ yí; nítorípé bíkòbáṣe fún ti àwọn ìlànà wọ̀nyí, ãnú kò lè já mọ́ nkankan, àfi kí ó pa iṣẹ́ àìṣègbè run. Báyĩ iṣẹ́ àìṣègbè kò ṣeé parun; bí ó bá sì rí bẹ̃, Ọlọ́run kò ní jẹ́ Ọlọ́run mọ́.

14 Báyĩ ni àwa sì ríi pé gbogbo ènìyàn ti ṣubú, tí nwọ́n sì wà lábẹ́ ìdarí àìṣègbè; bẹ̃ni, àìṣègbè Ọlọ́run, èyítí ó fi nwọ́n sí ipò ìkékúrò níwájú rẹ̀ títí láé.

15 Àti nísisìyí, ìlànà ãnú nnì kò lè wáyé àfi bí a bá ṣe ètùtù kan; nítorínã, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni ó ṣe ètùtù fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ayé láti mú ìlànà ãnú nnì wáyé, láti ṣe ìtánràn fún ẹ̀tọ́ àìṣègbè, kí Ọlọ́run lè jẹ́ Ọlọ́run pípé àti títọ́, àti Ọlọ́run alãnú pẹ̀lú.

16 Nísisìyí, ìrònúpìwàdà kò lè dé fún ènìyàn láìsí ìfìyàjẹni, èyítí ó sì jẹ́ tí ayérayé gẹ́gẹ́bí ẹ̀mí ènìyàn ṣe yẹ kí ó rí, tí a ti soó ní ìtakò mọ́ ìlànà ayọ̀ nnì, èyítí í ṣe ti ayérayé pẹ̀lú gẹ́gẹ́bí ẹ̀mí ènìyàn ṣe wà títí ayérayé.

17 Nísisìyí, báwo ni ènìyàn ó ṣe ronúpìwàdà bí kò bá ṣe pé ó ṣẹ̀? Báwo ni yíò ṣe ṣẹ̀ bí kò bá sí òfin? Báwo ni òfin ó ṣe wà bí kò bá sí ìfìyàjẹni?

18 Nísisìyí, a ti so ìfìyàjẹni mọ́ ẹ̀ṣẹ̀, a sì fún ni ní òfin títọ́, èyítí ó mú ẹ̀dùn ọkàn lórí ẹ̀ṣẹ̀ bá ènìyàn.

19 Nísisìyí, bí a kò bá fún ni ní òfin—bí ènìyàn bá pànìyàn ó níláti kú—njẹ́ yíò ha bẹ̀rù pé òun yíò ku bí òun bá pànìyàn?

20 Àti pẹ̀lú, bí kò bá sí òfin tí a fi fúnni tí ó tako ẹ̀ṣẹ̀, ènìyàn kò ní bẹ̀rù láti dẹ́ṣẹ̀.

21 Bí kò bá sì sí òfin tí a fún ni, bí ènìyàn bá dẹ́ṣẹ̀, kíni àìṣègbè lè ṣe, tàbí ãnú ẹ̀wẹ̀, nítorítí nwọn kò ní àṣẹ lórí ẹ̀dá nã?

22 Ṣùgbọ́n òfin wà tí a fúnni, àti ìfìyàjẹni tí ó rọ̀ mọ́ ọ, àti ìrònúpìwàdà tí a fi fún ni; èyítí ìrònúpìwàdà ati ãnu tẹ́wọ́gbà; láìjẹ́bẹ̃, àìṣègbè yíò de ẹ̀dá nã, yíò sì ṣe ìdájọ́ gẹ́gẹ́bí òfin, òfin yíò sì fìyàjẹni; bíkòbájẹ́ bẹ̃, iṣẹ́ àìṣègbè yíò parun, Ọlọ́run kò sì ní jẹ́ Ọlọ́run mọ́.

23 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò lè ṣàì jẹ́ Ọlọ́run, ãnú sì rọ̀gbà ká olùrònúpìwàdà, ãnú sì wà nítorí ètùtù nnì; ètùtù nã sì mú àjĩnde òkú wa; àjĩnde òkú sì mú àwọn ènìyàn padà bọ̀wá síwájú Ọlọ́run; bẹ̃ sì ni a mú ènìyàn padàbọ̀sípò níwájú rẹ̀, fún ìdájọ́ gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ nwọn, ní ìbámu pẹ̀lú òfin àti àìṣègbè.

24 Nítorí kíyèsĩ, àìṣègbè a máa ṣe ẹ̀tọ́ rẹ̀, ãnú nã pẹ̀lú a máa rọ̀gbàká gbogbo èyítí íṣe tirẹ̀; báyĩ, kò sí ẹni nã àfi èyítí ó bá ronúpìwàdà nítõtọ́ ni a ó gbàlà.

25 Kíni, ìwọ ha rò wípé ãnú lè ja àìṣègbè lólè bí? Mo wí fún ọ, Rárá; kò lè rí bẹ̃ bí ó ti wù kí ó kéré tó. Bí ó bá rí bẹ̃, Ọlọ́run yíò ṣe aláì jẹ́ Ọlọ́run mọ́.

26 Bẹ̃ sì ni Ọlọ́run ṣe mú ìlànà nlá rẹ̀ ayérayé wá, àwọn tí a ti pèsè sílẹ̀ láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé. Bẹ̃ sì ni ìgbàlà àti ìràpadà àwọn ènìyàn ṣe wáyé, àti ìparun òun ìbànújẹ́ nwọn pẹ̀lú.

27 Nítorínã, A! ọmọ mi, ẹnìkẹ́ni tí ó bá fẹ́ wá lè wá kí ó sì mu nínú omi ìyè nã ní ọ̀fẹ́; ẹnìkẹ́ni tí kò bá sì wá òun nã ni a kò fi dandan mú láti wa; ṣùgbọ́n ní ọjọ́ ìkẹhìn a ó ṣe ìmúpadàbọ̀sípò fún un gẹ́gẹ́bí ìṣe rẹ̀.

28 Bí òun bá ti ní ìfẹ́ láti ṣe búburú, tí òun kò sì ronúpìwàdà ní ọjọ́ ayé rẹ̀, kíyèsĩ, búburú ni a ó ṣe síi, ní ìbámu pẹ̀lú ìmúpadàbọ̀sípò Ọlọ́run.

29 Àti nísisìyí, ọmọ mi, mo fẹ́ kí o máṣe jẹ́ kí àwọn ohun wọ̀nyí da ọkàn rẹ lãmu mọ́, jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ nìkan da ọkàn rẹ̀ lãmu, pẹ̀lú ìdãmú nnì èyítí yíò mú ọ bọ́ sí ipò ìrònúpìwàdà.

30 A! ọmọ mi, mo fẹ́ kí o ṣíwọ́ sísẹ́ àìṣègbè Ọlọ́run. Máṣe gbìyànjú dídá ara rẹ̀ láre bí ó ti wù kí ó mọ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, nípa sísẹ́ àìṣègbè Ọlọ́run; ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ kí àìṣègbè Ọlọ́run, àti ãnú rẹ̀, àti ọ̀pọ̀ sũrù rẹ̀ yí ọkàn rẹ̀ padà; kí ó sì jẹ́ kí ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ nínú eruku ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn.

31 Àti nísisìyí, A! ọmọ mi, Ọlọ́run pè ọ́ láti wãsù ọ̀rọ̀ nã sí àwọn ènìyàn yĩ. Àti nísisìyí, ọmọ mi, má bá tirẹ lọ, kí ó sì kéde ọ̀rọ̀ nã pẹ̀lú òtítọ́ àti ní àìrékọjá, kí ìwọ kí ó lè mú àwọn ọkàn wá sí ìrònúpìwàdà, kí ìlànà ãnú nlá nnì lè gbà nwọ́n. Kí Ọlọ́run kí ó sì ṣeé fún ọ gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ mi. Àmín.