Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 19


Orí 19

Lámónì rí ìmọ́lẹ̀ ìyè títí ayé gbà, ó sì rí Olùràpadà nã—Agbo ilé rẹ wọ inú ìran lọ, ọ̀pọ̀ sì rí àwọn ángẹ́lì—Olúwa pa Ámọ́nì mọ́ ní ọ̀nà ìyanu—“Ó ṣe rìbọmi fún ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó sì dá ìjọ-onígbàgbọ́ sílẹ̀ lãrín nwọn. Ní ìwọ̀n ọdún 90 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe, lẹ́hìn ọjọ́ méjì àti òru méjì, tí nwọn nmúra láti gbée lọ tẹ́ sínú ibojì, èyítí nwọn ti ṣe fún sísin òkú nwọn.

2 Nísisìyí, nítorítí ayaba ti gbọ́ nípa òkìkí Ámọ́nì, nítorínã ó ránṣẹ́ ó sì fẹ́ kí ó tọ òun wá.

3 Ó sì ṣe, tí Ámọ́nì ṣe gẹ́gẹ́bí a ti paláṣẹ fún un; tí ó sì tọ ayaba lọ, tí ó sì bẽrè ohun tí ó fẹ́ kí òun ṣe.

4 Ó sì wí fún un: Àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ ọkọ mi ti sọọ́ di mímọ̀ fún mi pé wòlĩ Ọlọ́run mímọ́ ni ìwọ íṣe, àti pé ìwọ ní agbára láti ṣe iṣẹ́ títóbi tí ó pọ̀ ní orúkọ rẹ̀;

5 Nítorínã, tí ó bá rí báyĩ, èmi fẹ́ kí ìwọ kí ó wọlé lọ wo ọkọ mi, nítorĩ a ti tẹ́ẹ lé orí ibùsùn rẹ̀ fún ìwọ̀n ọjọ́ méjì àti òru méjì; tí àwọn kan sọ wípé kòì kú, ṣùgbọ́n àwọn míràn wípé ó ti kú, ó sì ti nrùn, pé kí nwọ́n gbée lọ sínú ibojì; ṣùgbọ́n ní tèmi, kò rùn sí mi.

6 Nísisìyí, ohun tí Ámọ́nì fẹ́ ni èyí, nítorí tí ó mọ̀ pé ọba Lámónì nbẹ lábẹ́ agbára Ọlọ́run; ó mọ̀ pé ìbòjú dúdú àìgbàgbọ́ ti nká kúrò lọ́kàn rẹ̀, ìmọ́lẹ̀ tí ó sì tàn sí ọkàn rẹ, èyítí ó jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ògo Ọlọ́run, èyítí í ṣe ìmọ́lẹ̀ ìyànu dídára rẹ̀—bẹ̃ni, ìmọ́lẹ̀ yí ti fi ọ̀pọ̀ ayọ̀ sínú ọkàn rẹ̀, lẹ́hìn tí ìkũkù òkùnkùn ti ká kúrò, tí ìmọ́lẹ̀ ìyè títí ayé ti tànmọ́lẹ̀ sí ọkàn rẹ, bẹ̃ni, òun mọ̀ pé èyí ti ṣíji bò ara rẹ̀, tí a sì gbée lọ nínú Ọlọ́run—

7 Nítorínã, ohun tí ayaba fẹ́ kí ó ṣe ni ìfẹ́ ọkàn rẹ. Nítorínã, ó wọlé lọ rí ọba gẹ́gẹ́bí ayaba ti fẹ́ kí ó ṣe; ó sì rí ọba nã, ó sì mọ̀ wípé kò kú.

8 Ó sì wí fún ayaba pé: Kò kú, ṣùgbọ́n ó nsùn nínú Ọlọ́run ni, ní ọ̀la òun yíò sì dìde; nítorínã ẹ máṣe sin ín.

9 Ámọ́nì tún wí fún un pé: Njẹ́ ìwọ gba èyí gbọ́? Òun sì wí fún un pé: Èmi kò ní ẹ̀rí míràn àyàfi ọ̀rọ̀ rẹ, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ wa; bíótilẹ̀ríbẹ̃ èmi gbàgbọ́ wípé yíò rí gẹ́gẹ́bí ìwọ ti sọ.

10 Ámọ́nì sì wí fún un pé: Ìbùkún ni fún ọ nítorí ìgbàgbọ́ rẹ tí ó tayọ; mo wí fún ọ, ìwọ obìnrin, a kòĩ tì rí ìgbàgbọ́ nlá irú èyí rí lãrín gbogbo àwọn ará Nífáì.

11 Ó sì ṣe tí ó nṣọ́ ibùsùn ọkọ rẹ̀, láti ìgbà nã lọ títí di àkokò nã ní ọjọ́ kejì tí Ámọ́nì sọ wípé yíò dìde.

12 Ó sì ṣe tí ó sì dìde, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Ámọ́nì; bí ó si ṣe ndìde, ó na ọwọ́ rẹ sí obìnrin nã, ó sì wípé: Ìbùkún ni fún orúkọ Ọlọ́run, ìbùkún sì ni fún ìwọ nã.

13 Nítorítí bí ó ṣe dájú pé ìwọ wà lãyè, kíyèsĩ, èmi ti rí Olùràpadà mi; òun yíò sì wa, tí a ó bĩ nípasẹ̀ obìnrin, òun yíò sì ra gbogbo ènìyàn padà tí nwọ́n gba orúkọ rẹ̀ gbọ́. Nísisìyí, nígbàtí ó ti sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ọkàn rẹ̀ wúwo nínú rẹ̀. ó sì tún ṣubú lulẹ̀ lẹ́ẹkan síi pẹ̀lú ayọ̀; ayaba nã sì ṣubú lulẹ̀ pẹ̀lú, nítorítí Ẹ̀mí Mímọ́ ṣíji bõ.

14 Nísisìyí, nígbàtí Ámọ́nì ríi pé Ẹ̀mí Olúwa sọ̀ kalẹ̀ gẹ́gẹ́bí àdúrà rẹ̀ sí órí àwọn ará Lámánì, àwọn arákùnrin rẹ̀, tí nwọ́n ti fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀fọ̀ ṣíṣe lãrín àwọn ará Nífáì, tàbí gbogbo àwọn ènìyàn Ọlọ́run nitori àìṣedẽdé nwọn àti àṣà nwọn, ó wólẹ̀ lórí eékún rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀sí gbàdúrà tọkàn-tọkàn pẹ̀lú ọpẹ́ sí Ọlọ́run fún ohun tí ó ti ṣe fún àwọn arákùnrin rẹ̀; òun nã sì kún fún ayọ̀ púpọ̀púpọ̀; báyĩ sì ni àwọn mẹ́tẹ̃ta wólẹ̀.

15 Nísisìyí, nígbàtí àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ ọba ríi pé nwọ́n ti ṣubú, àwọn nã sì bẹ̀rẹ̀sí kígbe pé Ọlọ́run, nítorípé ìbẹ̀rù Olúwa ti bá àwọn nã, nítorípé àwọn ni nwọ́n dúró níwájú ọba tí nwọn jẹ́rĩ nípa agbára nlá Ámọ́nì.

16 Ó sì ṣe tí nwọ́n kígbe pe orúkọ Olúwa pẹ̀lú gbogbo agbára nwọn, àní títí nwọ́n fi ṣubú lulẹ̀ àfi ọ̀kan nínú àwọn obìnrin Lámání, tí orúkọ rẹ̀ íṣe Ábíṣì, nítorítí a ti yíi lọ́kàn padà sí Olúwa ní ọdún pípẹ́ sẹ́hìn, nípasẹ̀ ìran ìyanu bàbá rẹ̀ kan—

17 Bí ó sì ti jẹ́ wípé ó ti yípadà sọ́dọ̀ Olúwa, tí kò sì jẹ́ kí ẹnìkẹ́ni kí ó mọ̀, nítorínã, nígbàtí ó ríi pé gbogbo àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ Lámónì ti ṣubú lulẹ̀, àti pẹ̀lú pé “ọ̀gá” rẹ, ayaba, àti ọba, àti Ámọ́nì nà gbalaja lé ilẹ̀, ó mọ̀ wípé agbára Ọlọ́run ni; nígbàtí ó sì rõ pé tí òun bá jẹ́ kí àwọn ènìyàn nã mọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí nwọn, pé nípa rírí ohun yìi, yíò jẹ́ kí nwọ́n gbàgbọ́ nínú agbára Ọlọ́run, nítorínã ó sáré jáde láti ilé kan dé ìkejì, ó sì nfi tó àwọn ènìyàn létí.

18 Nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí kó ara nwọn jọ sínú ilé ọba. Ọ̀gọ̃rọ̀ ènìyàn sì wá, sí ìyàlẹ́nu nwọn ẹ̀wẹ̀, nwọ́n rí ọba, pẹ̀lú ayaba àti àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ nwọn tí nwọ́n ti nà gbalaja lélẹ̀, tí nwọ́n sì wà níbẹ̀ bí ẹnipé nwọ́n ti kú; nwọ́n sì rí Ámọ́nì pẹ̀lú, sì wõ, ara Nífáì ni òun íṣe.

19 Àti nísisìyí, àwọn ènìyàn nã bẹ̀rẹ̀sí ráhùn lãrín ara nwọn; àwọn kan nsọ wípé ìṣẹ̀lẹ̀ búburú kan ni ó ti dé bá nwọn, tàbí bá ọba àti ilé rẹ, nítorítí ó ti jẹ́ kí ará Nífáì nã dúró ní ilẹ̀ náà.

20 Ṣùgbọ́n àwọn míràn bá nwọn wí, wípé: Ọba ni ó mú ibi wá sí ilé rẹ nítorípé ó pa àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí nwọn ti tú agbo-ẹran nwọn ká ní ibi omi Sébúsì.

21 Àwọn ọkùnrin tí nwọ́n dúró ní ibi omi Sébúsì tí nwọ́n sì tú agbo-ẹran tĩ ṣe ti ọba ká nã bá nwọn wi nítorípé nwọ́n bínú sí Ámọ́nì nítorí iye àwọn tí ó ti pa nínú àwọn arákùnrin nwọn ní ibi odò Sébúsì, nígbàtí ó ndãbò bò àwọn agbo-ẹran ọba.

22 Nísisìyí, ọ̀kan nínú nwọn, tí a ti fi idà Ámọ́nì pa arákùnrin rẹ̀, nítorítí ó bínú púpọ̀púpọ̀ pẹ̀lú Ámọ́nì, fa idà rẹ yọ, ó sì lọ kí òun lè kọlũ Ámọ́nì, láti pa; bí ó ṣe gbé idà sókè láti bẹ̃, kíyèsĩ, ó wó lulẹ̀ ó sì kú.

23 Nísisìyí, a ríi pé nwọn kò lè pa Ámọ́nì, nítorítí Olúwa ti sọọ́ fún Mòsíà bàbá rẹ̀ pé: Èmi yíò dáa sí, yió sì rí bẹ̃ gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ rẹ—nítorínã, Mòsíà gbẽ lé Olúwa lọ́wọ́.

24 Ó sì ṣe nígbàtí àwọn ọ̀gọ̃rọ̀ ènìyàn ríi pé ọkùnrin nã ti wó lulẹ̀ tí ó sì kú, ẹnití ó gbé idà sókè láti pa Ámọ́nì, ẹ̀rù bá gbogbo nwọn, nwọn kò sì jẹ́ na ọwọ́ nwọn jáde láti fi ọwọ́ kan an tàbí èyíkẽyí nínú àwọn tí ó ti ṣubú lulẹ̀; ẹnu sì tún bẹ̀rẹ̀sí ya nwọn lãrín ara nwọn pé kíni ó lè jẹ́ ìdí agbára nlá yĩ, tàbí kíni gbogbo nkan wọ̀nyí lè jẹ́.

25 Ó sì ṣe tí púpọ̀ wà nínú nwọn tí nwọ́n wípé Ámọ́nì ni Òrìṣà Nlá nnì, tí àwọn míràn wípé Òrìṣà Nlá ni ó rán an wa;

26 Ṣùgbọ́n àwọn míràn bá gbogbo nwọn wí, tí nwọ́n wípé ohun abàmì ni, èyítí a rán wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ará Nífáì láti dãmú nwọn.

27 Àwọn kan sì wà tí nwọ́n wípé Òrìṣà Nlá rán Ámọ́nì wá láti fi ìyà jẹ nwọ́n nítorí àìṣedẽdé nwọn; àti pé Òrìṣà Nlá nií ti máa nṣọ́ àwọn ará Nífáì, tĩ máa ngbà nwọ́n kúrò lọ́wọ́ nwọn; nwọn sì sọ pé Òrìṣà Nlá yìi ni ó ti pa púpọ̀ nínú àwọn arákùnrin nwọn, àwọn ará Lámánì run.

28 Báyĩ sì ni ìjà bẹ̀rẹ̀sí pọ̀ lãrín nwọn. Bí nwọ́n sì ṣe njà yí, ọmọ-ọ̀dọ̀ obìnrin nã, èyítí ó ṣeé tí àwọn ọ̀gọ̃rọ̀ ènìyàn nã fi kó jọ pọ̀ wa, nígbàtí ó sì rí ìjà èyítí ó wà lãrín àwọn ọ̀gọ̃rọ̀ ènìyàn nã, inú rẹ̀ bàjẹ́ tó bẹ̃ tí ó fi sọkún.

29 Ó sì ṣe tí ó lọ tí ó sì mú ayaba ní ọwọ́, pé bóyá òun lè gbée dìde sókè kúrò ní ilẹ̀; ní kété tí ó sì ti fọwọ́kàn ọwọ́ rẹ, ó dìde, ó sì wà lórí ẹsẹ̀ rẹ̀ ó sì kígbe lóhùn rara, wípé; A! Jésù Olùbùkúnfún, ẹnití ó ti gbà mí kúrò nínú ọ̀run àpãdì búburú! A! Ọlọ́run Olùbùkúnfún, ẹ ṣãnú fún àwọn ènìyàn yí!

30 Nígbàtí ó sì ti wí báyĩ, ó pàtẹ́wọ́ nítorítí ayọ̀ kún inú rẹ̀, ó sì sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí kò yé nwọn; nígbàtí ó sì ti ṣe eleyĩ tán, ó mú ọba, Lámónì lọ́wọ́, sì wõ, ó dìde ó sì dúró lórí ẹsẹ̀ ara rẹ̀.

31 Bí òun, ní ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ṣe rí ìjà tí ó wà lãrín àwọn ènìyàn nã, ó jáde lọ ó sì bẹ̀rẹ̀sí bá nwọn wí, ó sì nkọ́ nwọn ní ẹ̀kọ́ nípa àwọn ọ̀rọ̀ tí òun ti gbọ́ láti ẹnu Ámọ́nì; gbogbo àwọn tí nwọ́n sì gbọ́ ohùn rẹ ni nwọ́n gbàgbọ́, tí nwọ́n sì yí padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa.

32 Ṣùgbọ́n àwọn púpọ̀ wà lãrín nwọn tí nwọn kò fetísí ọ̀rọ̀ rẹ̀; nítorínã, nwọ́n bá ọ̀nà nwọn lọ.

33 Ó sì ṣe nígbàtí Ámọ́nì dìde, ó sì jíṣẹ́ fún nwọn, àti sí gbogbo àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ Lámónì; gbogbo nwọn sì kéde fún àwọn ènìyàn nã ohun kan nã—pé ọkàn nwọn ti yí padà; pé nwọn kò ní ìfẹ́ àti ṣe búburu mọ́.

34 Sì kíyèsĩ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó fi mọ̀ fún àwọn ènìyàn nã pé nwọ́n ti rí ángẹ́lì, tí nwọ́n sì ti bá nwọn sọ̀rọ̀; bákannã sì ni nwọ́n ṣe bá nwọn sọ àwọn ohun nípa Ọlọ́run, àti ti ìwà òdodo rẹ.

35 Ó sì ṣe tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ gba ọ̀rọ̀ nwọn gbọ́; tí gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́ ni a sì ṣe ìrìbọmi fún; tí nwọ́n sì di olódodo ènìyàn, nwọ́n sì dá ìjọ-onígbàgbọ́ sílẹ̀ lãrín nwọn.

36 Báyĩ sì ni iṣẹ́ Olúwa bẹ̀rẹ̀ lãrín àwọn ará Lámánì; bẹ̃ sì ni Olúwa bẹ̀rẹ̀sí da Ẹ̀mí rẹ̀ lé nwọn; a sì ríi pé ó na ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn ẹnití yíò bá ronúpìwàdà, tí nwọ́n sì gba orúkọ rẹ̀ gbọ́.