Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 22


Orí 22

Áárọ́nì kọ́ bàbá Lámónì nípa dídá ayé; ìṣubú Ádámù, àti ìlànà ìràpadà nípasẹ̀ Krístì—Ọba nã àti gbogbo agbo ilé rẹ̀ ni a yí l’ọ́kàn padà—A ṣe àlàyé lórí bí a ṣe pín ilẹ̀ nã lãrín àwọn ará Nífáì àti àwọn ará Lámánì. Ní ìwọ̀n ọdún 90 sí 77 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Nísisìyí, bí Ámọ́nì ṣe tẹ̀síwájú nípa kíkọ́ àwọn ará Lámónì, a ó padà sí àkọsílẹ̀ Áárọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀; nítorípé lẹ́hìn tí ó fi ilẹ̀ Mídónì sílẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ darí rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Nífáì, àní lọ sí ilé ọba tí ó wà lórí gbogbo ilẹ̀ nã, àfi ilẹ̀ Íṣmáẹ́lì; òun sì ni bàbá Lámónì.

2 Ó sì ṣe tí ó tọ̃ lọ, sínú ãfin ọba, pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀; ó sì tũbá níwájú ọba, ó sì wí fún un pé: Kíyèsĩ, A! ọba, arákùnrin Ámọ́nì ni àwa í ṣe, ẹnití ìwọ ti tú sílẹ̀ nínú tũbú.

3 Àti nísisìyí, A! ọba, tí ìwọ yíò bá dá ẹ̀mí wa sí àwa yíò ṣe ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ. Ọba sì wí fún nwọn pé: Ẹ dìde, nítorítí èmi yíò dá ẹ̀mí nyin sí, èmi kò sì ní gbà kí ẹ jẹ́ ọmọ-ọ̀dọ̀ fún mi; ṣùgbọ́n èmi yíò fi dandan lée pé kí ẹ̀yin dúró níwájú mi; nítorítí ọkàn mi kò balẹ̀ nípa inú-rere àti títóbi ọ̀rọ̀ Ámọ́nì arákùnrin nyín; èmi sì fẹ́ mọ́ ìdí tí kò fi jáde wá láti Mídónì pẹ̀lú nyín.

4 Áárọ́nì sì wí fún ọba nã pé: Kíyèsĩ, Ẹ̀mí Olúwa ti darí rẹ̀ sí ibòmíràn; ó ti lọ sí ilẹ̀ Íṣmáẹ́lì, láti kọ́ àwọn ará Lámónì ní ẹ̀kọ́.

5 Nísisìyí, ọba nã wí fún nwọn pé: Kíni èyí yĩ tí ìwọ ti wí nípa Ẹ̀mí Olúwa? Kíyèsĩ, èyí yĩ ni ohun tí ó nrú mi lójú.

6 Àti pẹ̀lú, kíni èyí yĩ tí Ámọ́nì wí—Bí ìwọ yíò bá ronúpìwàdà a ó gbà ọ́ là, àti pé bí ìwọ kì yíò bá ronúpìwàdà, a ó ta ọ́ nù ní ọjọ́ ìkẹhìn?

7 Áárọ́nì sì dá a lóhùn ó sì wí fún un pé: Njẹ́ ìwọ gbàgbọ́ pé Ọlọ́run kan nbẹ? Ọba nã sì wípé: Èmi mọ̀ pé àwọn ará Ámálẹ́kì sọ wípé Ọlọ́run kan nbẹ, èmi sì ti gbà nwọ́n lãyè kí nwọ́n kọ́ àwọn ibi-mímọ́, kí nwọ́n lè péjọ láti lè sìn ín. Nísisìyí, bí ìwọ bá sì sọ wípé Ọlọ́run kan nbẹ, kíyèsĩ èmi yíò gbàgbọ́.

8 Àti nísisìyí nígbàtí Áárọ́nì gbọ́ èyí, ọkàn rẹ bẹ̀rẹ̀sí yọ̀, ó sì wípé: Kíyèsĩ, dájúdájú bí ìwọ ti wà lãyè, Á! ọba, Ọlọ́run kan nbẹ.

9 Ọba nã sì wí pé: Njẹ́ Ọlọ́run ha ni Òrìṣà Nlá nnì ẹnití ó mú àwọn bàbá wa jáde kúrò ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù?

10 Áárọ́nì sì wí fún un pé: Bẹ̃ni òun ni Òrìṣà Nlá nã, òun ni ó sì dá ohun gbogbo ní ọ̀run àti ní ayé. Njẹ́ ìwọ gba èyí gbọ́ bí?

11 Òun sì wípé: Bẹ̃ni, èmi gbàgbọ́ wípé Òrìṣà Nlá nã ni ó dá ohun gbogbo, èmi sì fẹ́ kí ìwọ kí ó sọ nípa àwọn ohun wọ̀nyí fún mi, èmi yíò sì gba àwọn ọ̀rọ̀ rẹ gbọ́.

12 Ó sì ṣe tí Áárọ́nì rí i pé ọba ṣetán láti gba àwọn ọ̀rọ̀ òun gbọ́, ó bẹ̀rẹ̀ láti dídá Ádámù, ó sì ka àwọn ìwé-mímọ́ sí Ọba—bí Ọlọ́run ṣe dá ènìyàn ní àwòrán ara rẹ̀, tí Ọlọ́run sì fún un ní àwọn òfin, àti pé nítorí ìwàìrékọjá, ènìyàn ti ṣubú.

13 Áárọ́nì sì la àwọn ìwé-mímọ́ yé e ní kíkún láti ìgbà dídá Ádámù, ó sì fi ìṣubú ènìyàn yé e pẹ̀lú ipò àìmọ́ inú èyí tí nwọ́n wà, àti pẹ̀lú ìlànà ìràpadà, èyítí a ti pèsè sílẹ̀ láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, nípasẹ̀ Krístì, fún gbogbo ẹnìkẹ́ni tí yíò bá gba orúkọ rẹ̀ gbọ́.

14 Níwọ̀n ìgbà tí ènìyàn sì ti ṣubú, òun tìkalára rẹ̀ kò lè rí ojú rere àti ìyọ́nú; ṣùgbọ́n ìjìyà àti ikú Krístì ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nípa ìgbàgbọ́ àti ìrònúpìwàdà, àti bẹ̃bẹ̃ lọ; àti pé òun ni ó já ìdè ikú, tí isà-òkú kò lè ní ìṣẹ́gun, tí oró ikú yíò di gbígbémì nínú ìrètí ògo; Áárọ́nì sì la gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí yé ọba ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.

15 Ó sì ṣe lẹ́hìn tí Áárọ́nì ti la àwọn ohun wọ̀nyí yée, ọba nã wípé: Kíni èmi yíò ṣe tí èmi yíò fi rí ìyè àìnípẹ̀kun èyítí ìwọ ti sọ nípa rẹ̀? Bẹ̃ni, kíni èmi yíò ṣe tí a ó fi bí mi nipa ti Ọlọ́run, tí a ó fi fa ẹ̀mí búburú yìi tú jáde kúrò ní àyà mi, tí èmi yíò sì gba ẹ̀mí rẹ̀, kí èmi lè kún fún ayọ̀, tí èmi kò sì ní di títa dànù ní ọjọ́ ìkẹhìn? Kíyèsĩ, èyí ni ó wí, èmi yíò fi ohun gbogbo tí mo ní sílẹ̀, bẹ̃ni, èmi yíò kọ ìjọba mi sílẹ̀, kí èmi lè gba ayọ̀ nlá yĩ.

16 Ṣùgbọ́n Áárọ́nì wí fún un pé: Bí ìwọ bá ní ìfẹ́ sí ohun wọ̀nyí, bí ìwọ bá lè rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run, bẹ̃ni, bí ìwọ bá lè ronúpìwàdà gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, tí ìwọ sì wólẹ̀ níwájú Ọlọ́run, tí ìwọ sì képe orúkọ rẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́, tí ìwọ sì gbàgbọ́ pé ìwọ yíò rí gbà, nígbànã ni ìwọ yíò rí ìrètí tí ìwọ nṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní ọkàn rẹ gbà.

17 Ó sì ṣe lẹ́hìn tí Áárọ́nì ti parí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ọba nã wólẹ̀ níwájú Ọlọ́run lórí ekún rẹ; bẹ̃ni, àní ó na ara rẹ̀ gbalaja lórí ilẹ̀, ó sì kígbe l’óhùn rara, pé:

18 A! Ọlọ́run, Áárọ́nì ti wí fún mi pé Ọlọ́run kan nbẹ; bí Ọlọ́run bá sì nbẹ, tí ìwọ bá sì í ṣe Ọlọ́run, njẹ́ kí ìwọ kí ó fi ara rẹ hàn mí, èmi yíò sì kọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi sílẹ̀ kí èmi kí ó lè mọ̀ ọ́ àti kí èmi lè jínde kúrò nínú ipò-òkú, àti kí a lè gbà mí là ní ọjọ́ ìkẹhìn. Àti nísisìyí, nígbàtí ọba nã ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, agbára Ọlọ́run kọ lù ú ó sì dà bí èyítí ó ti kú.

19 Ó sì ṣe tí àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ sáré lọ wí fún ayaba ohun gbogbo tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọba. Ó sì tọ ọba wá; nígbàtí ó sì ríi tí ó dùbúlẹ̀ bí èyítí ó ti kú, àti pẹ̀lú, Áárọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ bí ẹni wípé àwọn ni nwọn ṣeé tí ó fi ṣubú, ó bínú sí nwọn, ó sì pàṣẹ pé kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ, tàbí àwọn ìránṣẹ́ ọba, mú nwọn, kí nwọ sì pa nwọ́n.

20 Nísisìyí, àwọn ìránṣẹ́ yĩ ti rí ohun tí ó fã tí ọba fi ṣubú lulẹ̀, nítorínã nwọn kò lè fi ọwọ́ kan Áárọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀; nwọ́n sì ṣìpẹ̀ fún ayaba wípé: Kíni ìwọ ha ṣe pàṣẹ fún wa pé kí àwa kí ó pa àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, nígbàtí kíyèsĩ, ọ̀kan nínú nwọn lágbára jù wá lọ? Nítorínã àwa yíò ṣègbé níwájú nwọn.

21 Nísisìyí nígbàtí ayaba rí ìbẹ̀rù àwọn ìránṣẹ́ nã, òun pẹ̀lú bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù púpọ̀, nítorí kí ohun búburú kan máṣe ṣẹlẹ̀ síi. Ó sì pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí nwọ́n lọ pe àwọn ènìyàn gbogbo wá, kí nwọ́n lè pa Áárọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀.

22 Nísisìyí nígbàtí Áárọ́nì rí ìpinnu ayaba nã, tí òun pẹ̀lú sì mọ́ líle ọkàn àwọn ènìyàn nã, ẹ̀rù bã kí àwọn ọ̀gọ̃rọ̀ ènìyàn má ṣe kó ara nwọn jọ, kí àríyànjiyàn àti ìrúkèrúdò sì bẹ́ sílẹ̀ lãrín nwọn; nítorínã, ó na ọwọ́ rẹ̀ jáde, ó sì gbé ọba nã dìde kúrò nílẹ̀, ó sì wí fún un pé: Dìde dúró. Òun sì dìde dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì gba okun sára.

23 Nísisìyí a ṣe èyí níwájú ayaba àti púpọ̀ nínú àwọn ìránṣẹ́. Nígbàtí nwọ́n sì ríi, ẹnu yà nwọ́n púpọ̀, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí bẹ̀rù. Ọba nã sì dìde dúró, ó sì ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fun wọn tó bẹ̃ tí ayí gbogbo agbo ilé rẹ̀ padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa.

24 Nísisìyí ọ̀gọ̃rọ̀ àwọn ènìyàn péjọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ayaba ti pàṣẹ, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìkùnsínú lãrín ara nwọn nítorí Áárọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀.

25 Ṣùgbọ́n ọba dìde dúró lãrín nwọn ó sì njíṣẹ́ fún nwọn. A sì tù nwọn l’ọ́kàn sí Áárọ́nì pẹ̀lú àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀.

26 Ó sì ṣe nígbàtí ọba rí i pé a ti tù nwọ́n l’ọ́kàn, ó pàṣẹ pé kí Áárọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jáde wá sí ãrín àwọn ọ̀gọ̃rọ̀ ènìyàn nã, kí nwọ́n sì wãsù ọ̀rọ̀ nã sí nwọn.

27 Ó sì ṣe tí ọba ṣe ìkéde ní gbogbo ilẹ̀ nã, lãrín àwọn ènìyàn rẹ̀ tí nwọ́n wà ní gbogbo orílẹ̀-èdè, tí ó wà ní àyíká títí fi dé etí òkun, ní ìhà ìlà-oòrùn àti ìhà ìwọ̀-oòrùn, àwọn èyítí ó pa ãlà pẹ̀lú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà pẹ̀lú aginjù tẹ̃rẹ́ èyítí ó nà láti òkun tí ó wà ní ìhà ìlà-oòrùn àní sí èyí tí ó wà ní ìhà ìwọ̀-oòrùn àti yíká gbogbo ìhà etí òkun, àti ìhà aginjù tí ó wà ní apá àríwá ní ẹ̀bá ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, títí dé etí ilẹ̀ Mántì, nítòsí orísun odò Sídónì, èyítí ó ṣàn láti apá ìlà-oòrùn lọ sí apá ìwọ̀-oòrùn—báyĩ sì ni a ṣe pa ãlà àwọn ará Lámánì àti àwọn ará Nífáì.

28 Nísisìyí, àwọn ará Lámánì tí nwọ́n jẹ́ ọ̀lẹ ènìyàn nínú nwọn ngbé inú aginjù, nwọn a sì máa gbé nínú àgọ́; nwọ́n sì tàn ká kiri inú aginjù ní apá ìwọ̀-oòrùn, ní ilẹ̀ Nífáì; bẹ̃ni, àti ní apá ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, nítósí etí òkun, àti ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ní ilẹ̀ Nífáì, ní ibi ìní àkọ́kọ́ àwọn bàbá nwọn, tí nwọ́n sì fi ara pẹ́ etí-òkun.

29 Àti pẹ̀lú pé àwọn ará Lámánì púpọ̀ ni ó wà ní apá ìhà ìlà-oòrùn nítòsí etí òkun, níbití àwọn ará Nífáì ti lé nwọn sí. Báyĩ sì ni ó rí tí àwọn ará Lámánì fẹ́rẹ̀ yí àwọn ará Nífáì ká; bíótilẹ̀ríbẹ̃, àwọn ará Nífáì ti gba gbogbo apá gũsù ilẹ̀ tí ó kángun sí aginjù, ní ibi orísun odò Sídónì, láti apá ìlà-oòrùn títí dé apá ìwọ̀-oòrùn, yíká kiri apá ibi aginjù; ní apá àríwá, àní títí fi dé ilẹ̀ nã èyítí nwọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Ibi-Ọ̀pọ̀.

30 Ó sì pa ãlà pẹ̀lú ilẹ̀ tí a npè ọrúkọ rẹ̀ ní Ibi-Ahoro, nítorítí ó jìnà réré sí apá àríwá, tí ó fi dé ibi ilẹ̀ èyítí àwọn ènìyàn ngbé tẹ́lẹ̀rí ṣùgbọ́n tí nwọ́n ti parun, ní ti egungun àwọn tí a ti sọ nípa nwọn ṣãjú, ilẹ̀ èyítí ó jẹ́ pé àwọn ará Sarahẹ́múlà ni ó wá a rí, nítorípé òun ní ibi tí nwọ́n ti kọ́kọ́ gúnlẹ̀.

31 Nwọ́n sì ti ibẹ̀ wá lọ sí apá gũsù aginjù nã. Báyĩ ní ó rí tí a fi npe ilẹ̀ apá àríwá ní Ibi-Ahoro, àti ilẹ̀ ti o wà ní apá gũsù ni a pè ní Ibi-Ọ̀pọ̀, nítorípé aginjù nã kún fún onírurú ẹranko ìgbẹ́ ní oríṣiríṣi, nínú àwọn èyítí ó ti wá láti ilẹ̀ àríwá fún oúnjẹ.

32 Àti nísisìyí, ìrìnàjò ọjọ́ kan àti ãbọ̀ ni ó jẹ́ fún ará Nífáì láti ãlà lãrín Ibi-Ọ̀pọ̀ àti Ibi-Ahoro, láti òkun tí ó wà ní apá ìlà-oòrùn títí dé òkun èyítí ó wà ní apá ìwọ̀-oòrùn; báyĩ sì ni ó rí, tí omi fẹ́rẹ̀ yí ilẹ̀ Nífáì pẹ̀lú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà ká, tí ilẹ̀ tẹ́rẹ́ kan sì wà lãrín ilẹ̀ tí ó wà ní ìhà àríwá àti èyítí ó wà ní gũsù.

33 Ó sì ṣe tí àwọn ará Nífáì ti tẹ Ibi-Ọ̀pọ̀ dó, àní láti apá ìhà ìlà oòrùn títí fi dé òkun èyítí ó wà ní ìwọ oòrùn, báyĩ sì ni ó rí tí àwọn ara Nífáì, nínú ọgbọ́n nwọn, pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ àti ọmọ ogun nwọn, ti há àwọn ará Lámánì mọ́ ní apá gũsù, kí nwọn má bã lè ní ìní kankan mọ́ ní apá àríwá, kí nwọn má bã lè wọ inú ilẹ̀ tí ó wà ní ìhà apá àríwá.

34 Nítorínã, àwọn ará Lámánì kò ní ìní kankan mọ́, àfi ní ilẹ̀ Nífáì pẹ̀lú aginjù tí ó yíi ka. Nísisìyí eleyĩ jẹ́ ohun ọgbọ́n fún àwọn ará Nífáì—nítorípé àwọn ará Lámánì jẹ́ ọ̀tá fún nwọn, nwọ́n kọ̀ láti gba ìyà àwọn ará Lámánì ní gbogbo ibi, àti pé kí nwọn le ni orílẹ̀-èdè èyítí nwọ́n lè sálọ sí, bí nwọ́n bá ti fẹ́.

35 Àti nísisìyí èmi, lẹ́hìn tí mo ti sọ eleyĩ, padà sórí ọ̀rọ̀ nípa àkọsílẹ̀ Ámọ́nì àti Áárọ́nì, Òmnérì àti Hímnì, àti àwọn arákùnrin nwọn.