Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 10


Orí 10

Léhì jẹ́ ìran Mánássè—Ámúlẹ́kì tún sọ̀rọ̀ nípa àṣẹ tí ángẹ́lì fún un pé kí ó tọ́jú Álmà—Àdúrà àwọn olódodo-ènìyàn ngba àwọn ènìyàn là—Àwọn aláìṣõtọ́ amòfin àti adájọ́ ṣe ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìparun àwọn ènìyàn. Ní ìwọ̀n ọdún 82 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Nísisìyí àwọn wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ tí Ámúlẹ́kì wãsù sí àwọn ènìyàn tí nwọ́n wà ní ilẹ̀ Amonáíhà, wípé:

2 Èmi ni Ámúlẹ́kì; ọmọ Gídónà ni èmi íṣe, ẹnití íṣe ọmọ Íṣmáẹ́lì, tĩ sì íṣe àtẹ̀lé Ámínádì; Ámínádì kannã sì ni ó túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tí a kọ sí ára ògiri tẹ́mpìlì, èyítí a kọ nípa ìka Ọlọ́run.

3 Ámínádì sì jẹ́ ìran Nífáì, ẹnití íṣe ọmọ Léhì, èyítí ó jáde kúrò láti inú ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, ẹnití íṣe ìran Mánássè, ẹnití íṣe ọmọ Jósẹ́fù, ẹnití a tà sí ilẹ̀ Égíptì láti ọwọ́ àwọn arákùnrin rẹ̀.

4 Ẹ kíyèsĩ, èmi jẹ́ ẹni tí o ní orúkọ rere pẹ̀lú lãrín àwọn tí ó mọ̀ mí; bẹ̃ni, ẹ sì kíyèsĩ, èmi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbátan àti ọ̀rẹ́, èmi sì ti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ nípa iṣẹ́ õgùn ojú mi.

5 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, lẹ́hìn gbogbo èyí, èmi kò mọ́ púpọ̀ nínú àwọn ọ̀nà Olúwa, àti ohun ìjìnlẹ̀ rẹ̀, àti agbára nlá rẹ̀. Mo wípé èmi kò mọ́ púpọ̀ nínú àwọn ohun wọ̀nyí tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀; ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ èmi kùnà, nítorítí mo ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìjìnlẹ̀ rẹ̀ àti agbára nlá rẹ̀; bẹ̃ni, àní nínú ìpamọ́ ìgbésí ayé àwọn ènìyàn yĩ.

6 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, mo se àyà mi le, nítorí tí a pè mí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, èmi sì ṣe àìgbọ́; nítorínã èmi mọ̀ nípa àwọn ohun wọ̀nyí, síbẹ̀ èmi sì ṣe àìmọ̀; nítorínã èmi tẹ̀ síwájú nínú ìṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run nínú ìwà búburú ọkàn mi, àní títí di ọjọ́ kẹ́rin nínú oṣù kéje yĩ, èyítí ó wà nínú ọdún kẹẹ̀wá ti ìjọba àwọn onídàjọ́.

7 Bí èmi sì ṣe nrin ìrìnàjò lọ sí ọ̀dọ̀ ìbátan tí ó súnmọ́ mi kan, kíyèsĩ, ángẹ́lì Olúwa farahàn mí ó sì wípé: Ámúlẹ́kì, padà sí ilé rẹ, nítorítí ìwọ yíò bọ́ wòlĩ Olúwa; bẹ̃ni, ẹni mímọ́ kan, ènítí íṣe ẹnití Ọlọ́run yàn; nítorítí ó ti gba ãwẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn yí, ebi sì npa á, ìwọ yíò sì gbã sínú ilé rẹ, ìwọ yíò bọ́ọ, òun yíò sì bùkún fún ọ pẹ̀lú ilé rẹ; ìbùkún Olúwa yíò sì wà lórí rẹ àti ilẽ rẹ.

8 Ó sì ṣe tí èmi gbọ́ran sí ohùn ángẹ́lì nã, èmi sì padà lọ sí ilé mi. Bí èmi sì ṣe nlọ sí ibẹ̀, èmi rí ọkùnrin nã èyítí ángẹ́lì sọ fún mi pé: Ìwọ yio gbà sínú ilé rẹ—sì kíyèsĩ ọkùnrin yìi kan nã ní ó ti nbá a yín sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun Ọlọ́run.

9 Ángẹ́lì nã sì wí fún mi pé ẹni-mímọ́ ni íṣe; nítorí-eyi èmi mọ̀ pé ẹni-mímọ́ ni íṣe nítorípé ángẹ́lì Ọlọ́run ti wí bẹ̃.

10 Àti pẹ̀lú, èmi mọ̀ pé àwọn ohun tí ó ti jẹri sì jẹ́ òtítọ́; nítorí kíyèsĩ èmi wí fún yín, pé bí Olúwa ti wà lãyè, bẹ̃ nã ni ó ṣe rán ángẹ́lì rẹ̀ láti fi àwọn ohun wọ̀nyí hàn mí; ó sì ti ṣe èyí ní àkokò tí Álmà yĩ gbé inú ilé mi.

11 Nítorí ẹ kíyèsĩ, òun ti bùkún fún ilé mi, ó ti bùkún fún mi, àti àwọn obìnrin mi, àti àwọn ọmọ mi, àti bàbá mi, àti àwọn ìbátan mi; bẹ̃ni, àní gbogbo tẹbítará mi ni ó bùkún fún, tí ìbùkún Olúwa sì ti wà lórí gbogbo wa gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ tí ó ti sọ.

12 Àti nísisìyí, nígbàtí Ámúlẹ́kì ti sọ̀rọ̀ wọ̀nyí tán, ẹnu bẹ̀rẹ̀sí ya àwọn ènìyàn nã, ní rírí tí wọ́n ríi pé ojú ẹlẹ̃rí ẹyọ kan tí ó jẹ́rĩ sí ohun ti a fi sùn nwọ́n, àti pẹ̀lú nípa àwọn ohun èyítí nbọ̀wá gẹ́gẹ́bí ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀ tí ó wà nínú nwọn.

13 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, àwọn kan wà lãrín wọn tí wọ́n gbèrò láti ṣe ìwãdí ọ̀rọ̀ lẹ́nu wọn, pé nípa ọ̀nà àrékérekè wọn, wọn ò rí wọn mú nípa ọ̀rọ̀ tí wọn yíò sọ, pé wọn yíò rí ẹlẹ̃rí tí yíò ta kò wọ́n, tí wọn yíò sì fi wọ́n lé àwọn adájọ́ nwọn lọ́wọ́, tí nwọn yíò sì ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́bí òfin, tí wọn yíò sì pa wọ́n tàbí kí wọ́n jù wọ́n sínú túbú, gẹ́gẹ́bí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n yíò fi sùn wọ́n.

14 Nísisìyí àwọn ọkùnrin wọnnì ni wọ́n wá ọ̀nà láti pa nwọ́n run, tí nwọ́n jẹ́ agbẹjọ́rò, tí nwọ́n gbà, tàbí tí àwọn ènìyàn nã yàn láti gbé òfin ró ní ìgbà ìpèlẹ́jọ́ nwọn, tàbí ní àkokò ìpèlẹ́jọ́ ní iwájú adájọ́ fún ìwà arúfin tí àwọn ènìyàn bá hù.

15 Nísisìyí, àwọn agbẹjọ́rò wọ̀nyí ní ìmọ̀ ní gbogbo ọ̀nà ọgbọ́n àrekérekè àwọn ènìyàn nã; ìdí èyí sì ni kí nwọ́n lè já fáfá nínú iṣẹ́ nwọn.

16 Ó sì ṣe tí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí bí Ámúlẹ́kì lọ́rọ̀, ní ọ̀nà tí òun yíò fi tako ọ̀rọ̀ ara rẹ̀, tàbí kí ó lọ́ ẹjọ́ mọ́ ara rẹ̀ lẹ́sẹ̀ nípa ohun tí yíò sọ.

17 Nísisìyí nwọn kò mọ̀ pé Ámúlẹ́kì lè mọ̀ nípa ète nwọn. Ṣùgbọ́n ó sì ṣe nígbàtí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí bĩ lẹ́jọ́, ó mọ́ èrò ọkàn nwọn, ó sì sọ fún nwọn pé: Á!, ẹ̀yin ìran aláìgbàgbọ́ àti alárèkérekè ènìyàn yí, ẹ̀yin agbẹjọ́rò àti àgàbàgebè ènìyàn, nítorítí ẹ̀yin nfi ìdí èṣù mulẹ̀; nítorítí ẹ̀yin ndọdẹ sílẹ̀ àti ìkẹ́kùn láti mú àwọn ẹni mímọ́ Ọlọ́run.

18 Ẹ̀yin ngbèrò làti yí àwọn ọ̀nà òdodo padà, àtí láti mú ìbínú Ọlọ́run sọ̀ kalẹ̀ wá sí óríi yín, àní títí dé ìparun àwọn ènìyàn yí.

19 Bẹ̃ni, Mòsíà ti sọọ́ dáradára, ẹnití íṣe ọba wa tí ó kẹ́hìn, nígbàtí ó ṣetán láti gbé ìjọba sílẹ̀, tí kò sì sí ẹnití yíò gbée lé lọ́wọ́, èyítí ó sì jẹ́ kí ó sọ fún àwọn ènìyàn rẹ pé kí nwọ́n ṣe ìjọba nwọn nípa ohùn ara nwọn—bẹ̃ni, ó sì sọọ́ dáradára pé tí àkokò nã bá dé tí ohùn àwọn ènìyàn yí bá yan ìwà búburú, èyí ni pé, tí àkokò nã bá dé tí àwọn ènìyàn bá ṣubú sínú ìwàìrékọjá, nwọ́n ti ṣetán fún ìparun.

20 Àti nísisìyí, èmi wí fún un yín pé Olúwa nṣe ìdájọ́ àìṣedẽdé yín; ó nkígbe pe àwọn ènìyàn yí, nípa ohùn àwọn ángẹ́lì rẹ: Ẹ ronúpìwàdà, ronúpìwàdà, nítorítí ìjọba ọ̀run ti dé tán.

21 Bẹ̃ni, ó nkígbe, nípa ohùn àwọn ángẹ́lì rẹ pé: Èmi nsọ̀kalẹ̀ bọ̀wá sí ãrin àwọn ènìyàn mi, pẹ̀lú ìṣòtítọ́ àti àìṣègbè ní ọwọ́ mi.

22 Bẹ̃ni, èmi wí fún yín pé tí kò bá jẹ́ ti àdúrà àwọn olódodo tí nwọ́n wà nínú ilẹ̀ yí, pé à bá ti bẹ̀ yín wò pẹ̀lú ìparun nlá; síbẹ̀ kò ní ṣe nípa ìkún-omi, gẹ́gẹ́bí ti àwọn wọnnì ní ìgbà Nóà, ṣùgbọ́n yíò jẹ́ nípa ìyàn, àti nípa àjàkálẹ̀-àrùn, àti idà.

23 Ṣùgbọ́n, nípa àdúrà àwọn olódodo ni a fi dáa yín sí; nítorínã, bí ẹ̀yin bá ta olódodo nã nù lãrín yín, nígbàyí ni Olúwa kò ní dá ọwọ́ rẹ dúró; ṣùgbọ́n nínú híhó ìbínú rẹ ni yíò jáde wá kọlũ yí; ni a ó sì fi ìyàn bã yín jà, àti àjàkálẹ̀-àrùn, àti idà; ìgbà nã sì ti dé tán, àfi tí ẹ̀yin bá ronúpìwàdà.

24 Àti nísisìyí ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn nã túbọ̀ bínú sí Ámúlẹ́kì síi, tí nwọ́n sì kígbe sókè wìpé: Ọkùnrin yĩ ni ó ntako òfin wa èyítí ó tọ́, àti àwọn ọlọgbọ́n agbẹjọ́rò wa tí àwa ti yàn.

25 Ṣùgbọ́n Ámúlẹ́kì na ọwọ́ rẹ síwájú, ó sì tún kígbe sí nwọn ju ti àtẹ̀hìnwá lọ, wípé: Á!, ẹ̀yin ìran búburú àti alárèkérekè ènìyàn, kíni ìdíi rẹ̀ tí Sátánì ṣe rí ọkàn an yín gbà tó báyĩ? Kíni ìdí rẹ tí ẹ̀yin yíò jọ̀wọ́ ara yín fún un tí òun yíò ní agbára lórí yín láti fọ́ lójú, tí ọ̀rọ̀ tí àwa nsọ yí kò lè yé yín, gẹ́gẹ́bí òdodo wọn?

26 Nítorí kíyèsĩ, njẹ́ èmi jẹ́rĩ tako òfin yín? Kò yé yín; ẹ̀yin wípé èmi sọ̀rọ̀ tako òfin yín; ṣùgbọ́n èmi kò ṣe bẹ̃, ṣùgbọ́n èmi sọ̀rọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú òfin yín, sí ìdálẹ́bi yín.

27 Àti nísisìyí, èmi wí fún un yín, pé ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìparun àwọn ènìyàn yí ti bẹ̀rẹ̀sí di ìfilọ́lẹ̀ nípasẹ̀ àìṣòdodo àwọn agbẹjọ́rò yín àti àwọn onídàjọ́ yín.

28 Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Ámúlẹ́kì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn nã kígbe takõ, wípé: Àti nísisìyí àwa mọ̀ wípé ọmọ èṣù ni ọkùnrin yĩ íṣe, nítorípé ó ti purọ́ fún wa; nítorítí ó sọ̀rọ̀ tako òfin wa. Nísisìyí òun sì wípé òun kò sọ̀rọ̀ takõ.

29 Àti pẹ̀lú, òun ti kẹ́gàn àwọn agbẹjọ́rò wa, àti àwọn onídàjọ́ wa.

30 Ó sì ṣe tí àwọn agbẹjọ́rò nã tẹ ọ̀rọ̀ yí mọ́ ọkàn nwọn, pé kí wọ́n ó lè rántí àwọn ohun wọ̀nyí láti fi takõ.

31 Ẹnìkan sì wà lãrín nwọn tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Sísrọ́mù. Nísisìyí òun ni ẹni àkọ́kọ́ láti dá Ámúlẹ́kì àti Álmà lẹ́bi, òun sì jẹ́ ọkàn nínú àwọn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ jùlọ lãrín wọn, nítorítí ó ní ìlọsíwájú púpọ̀ lórí iṣẹ́ tí ó nṣe lãrín àwọn ènìyàn nã.

32 Nísisìyí ète àwọn agbẹjọ́rò nã ni láti ní ọ̀pọ̀ owó; wọ́n sì nrí ọ̀pọ̀ owó nípasẹ̀ iṣẹ́ tí wọ́n nṣe.