Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 9


Àwọn ọ̀rọ̀ Álmà, àti àwọn ọ̀rọ̀ Ámúlẹ́kì pẹ̀lú, èyítí a kéde sí àwọn ènìyàn tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Amonáíhà. Àti pẹ̀lú pé a gbé wọn jù sínú túbú, a sì kó wọn yọ nípa ìyanu agbára Ọlọ́run èyítí ó wà nínú wọn, gẹ́gẹ́bí àkọsílẹ̀ ti Álmà.

Èyítí a kọ sí àwọn orí 9 títí ó fi dé 14 ní àkópọ̀.

Orí 9

Álmà pàṣẹ fún àwọn ará Amonáíhà pé kí nwọ́n ronúpìwàdà—Olúwa yíò ṣãnú fún àwọn ará Lámánì ní ọjọ́ ìkẹhìn—Tí àwọn ará Nífáì bá kọ ìmọ́lẹ̀ nã sílẹ̀, a ó pa wọ́n run láti ọwọ́ àwọn ará Lámánì—Ọmọ Ọlọ́run nã fẹ́rẹ̀ dé—Òun yíò ṣe ìràpadà fún àwọn tí ó ronúpìwàdà padà, tí a ṣe ìrìbọmi fún, tí wọn sì ní ìgbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀. Ní ìwọ̀n ọdún 82 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti pẹ̀lú, èmi, Álmà, nítorítí Ọlọ́run ti pã láṣẹ pé kí èmi kí ó mú Ámúlẹ́kì kí a sì tún kọjá lọ wãsù sí àwọn ènìyàn yí, àní àwọn ènìyàn tí wọ́n wà ní ìlú-nlá Amonáíhà, ó sì ṣe, bí èmi ṣe bẹ̀rẹ̀sí wãsù sí nwọn, ni wọ́n bẹ̀rẹ̀sí jà mí níyàn, pé:

2 Tani ìwọ íṣe? Njẹ́ ìwọ ha rò pé àwa yíò gba ẹ̀rí ẹnìkan gbọ́, bí òun tilẹ̀ wãsù sí wa pé ayé yíò rékọjá?

3 Nísisìyí, ọ̀rọ̀ tí wọn nsọ kò yé wọn; nítorítí wọn kò mọ̀ wípé ayé yíò rékọjá.

4 Nwọ́n sì tún wípé: Àwa kò lè gba ọ̀rọ̀ rẹ gbọ́ bí ìwọ tilẹ̀ sọtẹ́lẹ̀ pé ìlú-nlá yíi yíò pàrùn ní ọjọ́ kan.

5 Nísisìyí, wọn kò mọ̀ pé Ọlọ́run lè ṣe iṣẹ́ nlá irú èyí, nítorítí nwọ́n jẹ́ ọlọ́kàn-líle àti ọlọ́rùn-líle ènìyàn.

6 Nwọ́n sì wí pé: tani Ọlọ́run, tí kò rán ju ẹnìkan pẹ̀lú àṣẹ lãrín àwọn ènìyàn yí, láti kéde fún wọn nípa òtítọ́ tí ó wà nínú àwọn ohun nlá àti ohun ìyàlẹ́nu yĩ.

7 Nwọ́n sì dìde láti gbé ọwọ́ wọn lé mi; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, wọn kò sì ṣe eleyĩ. Èmi sì dúró pẹ̀lú ìgboyà láti wí fún wọn pé, bẹ̃ni, èmi jẹ́ ẹ̀rí pẹ̀lú ìgboyà fún wọn pé:

8 Ẹ kíyèsĩ, A! ẹ̀yin ìran búburú àti aláìgbọràn ènìyàn yì, báwo ni ẹ̀yin ṣe ti gbàgbé àṣà àwọn bàbá yín; bẹ̃ni, báwo ni ẹ̀yin ṣe ti gbàgbé awọn òfin Ọlọ́run ní kánkán.

9 Njẹ́ ẹ̀yin kò ha rántí pé bàbá wa Léhì, ni a mú jáde kúrò nínú Jerúsálẹ́mù nípa ọwọ́ agbára Ọlọ́run? Njẹ́ ẹ̀yin kò ha rántí pé gbogbo wọn ni ó mú la aginjù kọjá?

10 Njẹ́ ẹ̀yin ti gbàbgé ní kánkán àwọn ìgbà tí ó gba àwọn bàbá wa lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn, tí ó sì pa wọ́n mọ́ kúrò nínú ìparun, àní láti ọwọ́ àwọn arákùnrin wọn?

11 Bẹ̃ni, tí kò bá sí ti agbára rẹ̀ aláìláfiwé, àti ãnú rẹ̀, àti ọ̀pọ̀ sũrù sí wa, láìlèyẹ̀ kúrò àwa kì bá ti di kíké kúrò lórí ilẹ̀ ayé ní àtẹ̀hìnwá ṣãjú àkokò yí, ati bóyá tí a ó sì ti kọ̀ wá sí ipò ìbànújẹ́ àti ègbé tí kò nípẹ̀kun.

12 Ẹ kíyèsĩ, nísisìyí mo wí fún un yín pé ó pã láṣẹ pé kí ẹ ronúpìwàdà; tí ẹ̀yin kò bá sì ronúpìwàdà, ẹ̀yin kò lè jogún ìjọba Ọlọ́run rárá. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, èyí nìkan kọ́—òun ti pã láṣẹ pé kí ẹ ronúpìwàdà, bíkòjẹ́ bẹ̃ òun yíò pa yín run pátápátá kúrò lórí ilẹ̀ ayé; bẹ̃ ni, òun yíò bẹ̀ yín wo nínú ìbínú rẹ̀, òun kò sì ní ká ìbínú rẹ̀ èyítí ó pọ̀ jọjọ kúrò.

13 Ẹ kíyèsĩ, njẹ́ ẹ̀yin kò ha rántí àwọn ọ̀rọ̀ èyítí ó sọ fún Léhì, tí ó wípé: Níwọ̀n ìgbàtí ẹ̀yin bá pa òfin mi mọ́, ẹ̀yin yíò ṣe rere lórí ilẹ̀ nã? Àti pẹ̀lú a tún wípé: Níwọ̀n ìgbàtí ẹ̀yin kò bá pa òfin mi mọ́, a o ké yín kúrò níwájú Olúwa.

14 Nísisìyí, èmi ìbá fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó rántí, pé níwọ̀n ìgbàtí àwọn ará Lámánì kò pa òfin Ọlọ́run mọ́, a ké wọn kúrò níwájú Olúwa. Nísisìyí àwa ríi pé ọ̀rọ̀ Olúwa ti ṣẹ nípa ohun yĩ, a sì ti ké àwọn Lámánì kúrò níwájú rẹ̀, láti ìbẹ̀rẹ̀ ìwàìrékọjá wọn ní ilẹ̀ nã.

15 Bíótilẹ̀ríbẹ̃ mo wí fún yín, wípé yíò sàn fún wọn ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún yín lọ, tí ẹ̀yin bá dúró nínú ipò ẹ̀ṣẹ̀ yín, bẹ̃ni, yíò sì rọrùn fún wọn nínú ayé yĩ jù fún yín lọ, àfi bí ẹ̀yin bá ronúpìwàdà.

16 Nítorípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlérí ni a ṣe fún àwọn ará Lámánì; nítorípé nípa àṣà àwọn bàbá wọn ni wọ́n ṣe wà ní ipò àìmọ̀; nítorínã Olúwa yíò ṣãnú fún wọn yíò sì mú kí ìgbà wọn pẹ́ ní órí ilẹ̀ nã.

17 Àti pé ní àkokò kan a ó mú wọn wá sí gbígba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́ àti lati mọ àìpé àṣà bàbá wọn; ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni a ó sì gbàlà, nítorípé Olúwa yíò ṣãnú gbogbo àwọn tí ó pa orúkọ rẹ̀ mọ́.

18 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, èmi wí fún yín pé bí ẹ̀yin bá tẹramọ́ ṣíṣe ìwà búburú yín, pé ọjọ́ yín kì yíò pẹ́ ní orí ilẹ̀ nã, nítorítí a ó rán àwọn ará Lámánì láti kọlũ yín; tí ẹ̀yin kò bá sì ronúpìwàdà, wọn yíò wá ní àkokò tí ẹ̀yin kò mọ̀, a ó sì fi ìparun pátápátá bẹ̀ yín wò; yíò sì wà ní ìbámu pẹ̀lú ìgbóná ìbínú Olúwa.

19 Nítorítí òun kò ní gbà fún un yín pé kí ẹ̀yin kí ó wà nínú ìwà búburú yín, láti pa àwọn ènìyàn rẹ̀ run. Èmi wí fún un yín, Rárá; ó sàn fún kí ó gbà fún àwọn ará Lámánì láti pa gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ tí à npè ní ará Nífáì run, tí ó bá ṣeéṣe kí wọ́n ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ìrékọjá, lẹ́hìn tí Olúwa Ọlọ́run wọn ti fún nwọn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìmọ́lẹ̀ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìmọ̀;

20 Bẹ̃ni, lẹ́hìntí wọ́n ti jẹ́ ẹni-àyànfẹ́ Ọlọ́run tẹ́lẹ̀rí; bẹ̃ni, lẹ́hìn tí a ti fẹ́ràn wọn ju gbogbo orílẹ̀-èdè, ìbátan, ahọ́n, tàbí ènìyàn; lẹ́hìntí a ti fi ohun gbogbo hàn nwọ́n, gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ inú wọn, àti ìgbàgbọ́ wọn, àti àdúrà, èyítí ó ti kọjá lọ, èyítí ó nbẹ, àti èyítí ó nbọ̀wá;

21 Tí a sì ti bẹ̀ wọ́n wò nípa Ẹ̀mí Ọlọ́run; tí wọ́n ti bá àwọn ángẹ́lì sọ̀rọ̀, tí a sì ti bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ohùn Olúwa; tí nwọ́n sì ní ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀; àti ẹ̀mí ìfihàn, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn, ẹ̀bùn fífi èdè sọ̀rọ̀, àti ẹ̀bùn ìwãsù, àti ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, àti ẹ̀bùn ìtumọ̀ èdè;

22 Bẹ̃ni, lẹ́hìn tí Ọlọ́run sì ti mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, nípa agbára Olúwa; tí a ti kó wọn yọ kúrò nínú ìyàn, àti àìsàn, àti onírurú àrùn lóríṣiríṣi; tí wọn sì ti di alágbára ní ogun, kí wọ́n má lè pa wọ́n run; tí a sì ti mú wọn kúrò nínú oko-ẹrú láti ìgbà dé ìgbà, tí a sì ti pa wọ́n mọ́ títí di àkokò yí; wọ́n sì ti ṣe rere, títí wọ́n fi di ọlọ́rọ̀ nínú onírũrú ohun—

23 Àti nísisìyí ẹ kíyèsí, mo wí fún un yín, pé tí àwọn ènìyàn yí tí wọ́n ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbùkún gbà láti ọwọ́ Olúwa, bá rékọjá ní ìlòdì sí ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ̀ èyítí wọ́n ní, èmi wí fún yín pé tí ó bá rí báyĩ, pé tí wọ́n bá ṣubú sínú ìrékọjá, yíò sàn fún àwọn ará Lámánì jù fún wọn lọ.

24 Nítorí kíyèsí, ìlérí Olúwa tàn dé ọ̀dọ̀ àwọn ará Lámánì, ṣùgbọ́n kò dé ọ̀dọ̀ yín bí ẹ̀yin bá rékọjá; nítorípé, njẹ́ Olúwa kò ha ṣèlérí tí ó sì ṣe òfin èyítí ó múlẹ̀ pé bí ẹ̀yin bá ṣe ọ̀tẹ̀ sí òun, a ó pa yín run pátápátá kúrò lórí ilẹ̀ ayé yĩ?

25 Àti nísisìyí, nítorí ìdí èyí, kí ẹ̀yin kí ó má bã parun, Olúwa ti rán àwọn ángẹ́lì rẹ̀ láti bẹ ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ wò, tí ó wí fún wọn pé wọ́n níláti jáde lọ kí wọ́n sì kígbe sí àwọn ènìyàn yí pé: Ẹ ronúpìwàdà, nítorítí ìjọba ọ̀run fẹ̃ dé;

26 Láìpẹ́ ọjọ́ sí àkokò yí, Ọmọ Ọlọ́run yíò wá ní ògo rẹ̀; ògo rẹ̀ yíò sì jẹ́ ògo ti Ọmọ bíbí ti Bàbá nìkanṣoṣo, tí ó kún fún õre-ọ̀fẹ́, ìṣòtítọ́; àti òtítọ́, ó kún fún sũrù, ãnú, ọ̀pọ̀-sũrù, ó sì ṣe kánkán láti gbọ́ igbe àwọn ènìyàn rẹ̀ àti láti gbọ́ àdúrà wọn.

27 Ẹ kíyèsĩ, ó nbọ̀wá láti ra àwọn tí ó ṣe ìrìbọmi sí ìrònúpìwàdà padà, nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀.

28 Nítorínã, ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe; nítorítí àkokò nã ti dé tán tí gbogbo ènìyàn yíò kórè iṣẹ́ nwọn, gẹ́gẹ́bí èyí tí nwọ́n ti jẹ́—bí nwọ́n bá ti jẹ́ olódodo nwọn yíò kórè ìgbàlà ọkàn nwọn, nípa agbára àti ìdásílẹ̀ Jésù Krístì; bí nwọ́n bá sì ti jẹ́ búburú, nwọn yio kórè ìdálẹ́bi àìnípẹ̀kun ọkàn nwọn, gẹ́gẹ́bí agbára àti ìfinisí ìgbèkùn ti èṣù.

29 Nísisìyí kíyèsĩ, èyí ni ohùn ángẹ́lì, tí ó nké pe àwọn ènìyàn.

30 Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, nítorí arákùnrin mi ni ẹ̀yin íṣe, ó sì tọ́ kí ẹ̀yin jẹ́ àyànfẹ́, ó sì tọ́ kí ẹ̀yin ṣe iṣẹ́ èyítí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà, nítorípé ọkàn an yín ti le púpọ̀ sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nítorípé ẹ̀yin jẹ́ ènìyàn ti o ti sọnu tí ó sì ti ṣubú.

31 Nísisìyí ó sì ṣe, pe nígbàtí èmi, Álmà, tí sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, kíyèsí, inú bí àwọn ènìyàn nã sí mi nítorípé èmi sọ fún wọn pé ọlọ́kàn-líle àti ọlọ́rùn-líle ènìyàn ní wọ́n íṣe.

32 Àti pẹ̀lú pé nítorítí èmi wí fún wọn pé wọn ti di ẹni-sísọnù àti ẹni ìṣubú ènìyàn wọ́n bínú sí mi, wọ́n sì wá ọ̀nà láti gbé ọwọ́ wọn lé mi, pé kí wọ́n lè gbé mi jù sínú túbú.

33 Ṣùgbọ́n ó sì ṣe tí Olúwa kò gbà fún wọn pé kí wọ́n mú mi ní ìgbà nã kí wọ́n sì gbé mi jù sínú túbú.

34 Ó sì ṣe tí Ámúlẹ́kì lọ tí ó sì dúró, síbẹ̀ o si bẹ̀rẹ̀ sí wãsù sí wọn pẹ̀lú. Àti nísisìyí a kò kọ gbogbo ọ̀rọ̀ Ámúlẹ́kì, bíótilẹ̀ríbẹ̃, nínú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni a kọ sínú ìwé yĩ.