Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 20


Orí 20

Olúwa rán Ámọ́nì lọ sí Mídónì láti tú àwọn arákùnrin rẹ̀ tí nwọ́n wà nínú túbú sílẹ̀—Ámọ́nì pẹ̀lú Lámónì pàdé bàbá Lámónì tí íṣe ọba lórí gbogbo ilẹ̀ nã—Ámọ́nì rọ ọba ogbó nnì kí ó fi àṣẹ sí ìtúsílẹ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀. Ní ìwọ̀n ọdún 90 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe, lẹ́hìn tí nwọ́n ti dá ìjọ-onígbàgbọ́ kan sílẹ̀ ní ilẹ̀ nã, tí ọba Lámónì fẹ́ kí Ámọ́nì bá òun lọ sí ilẹ̀ ti Nífáì, pé kí òun kí ó lè fi han bàbá òun.

2 Ohùn Olúwa tọ Ámọ́nì wá, wípé: Ìwọ kò gbọ́dọ̀ lọ sí ilẹ̀ ti Nífáì nã, nítorí kíyèsĩ, ọba nã yíò lépa èmí rẹ láti pa ọ́; ṣùgbọ́n ìwọ yio lọ sí ilẹ̀ Mídónì; nitori kíyèsĩ, arákùnrin rẹ, Áárọ́nì, pẹ̀lú Múlókì àti Ámmà wà nínú túbú.

3 Nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Ámọ́nì ti gbọ́ èyí, ó wí fún Lámónì pé: Kíyèsĩ, àbúrò mi pẹ̀lú àwọn arákùnrin mi nwọ́n wà nínú túbú ní Mídónì, èmi yíò sì lọ kí èmi lè tú nwọn sílẹ̀.

4 Nísisìyí, Lámónì wí fún Ámọ́nì pé: èmi mọ̀ pé nínú agbára Olúwa ìwọ lè ṣe ohun gbogbo. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, èmi yíò bá ọ lọ sí ilẹ̀ Mídónì; nítorípé ọba ilẹ̀ Mídónì, tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Ántíómnò, jẹ́ ọ̀rẹ́ fún mi; nítorínã èmi yíò lọ sí ilọ̀ Mídónì, kí èmi kí ó lè ṣe àpọ́nlé ọba ilẹ̀ nã, òun yíò sì yọ àwọn arákùnrin rẹ kúrò nínú túbú. Nísisìyí, Lámónì wí fún un pé: Tani ó wí fún ọ́ pé àwọn arákùnrin rẹ wà nínú túbú?

5 Ámọ́nì wí fún un pé: Ẹnìkẹ́ni kò wí fún mi bíkòṣe Ọlọ́run; òun sì sọ fún mi—Lọ kí o sì tú àwọn arákùnrin rẹ sílẹ̀, nítorítí nwọ́n wà nínú túbú ní ilẹ̀ Mídónì.

6 Nísisìyí nígbàtí Lámónì gbọ́ ohun yĩ, ó pàṣẹ kí àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ pèsè àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀.

7 Ó sì wí fún Ámọ́nì: Wá, èmi yíò bá ọ lọ sí ilẹ̀ Mídónì, níbẹ̀ ni èmi yíò rọ ọba nã pé kí ó yọ àwọn arákùnrin mi jáde nínú túbú.

8 Ó sì ṣe bí Ámọ́nì àti Lámónì ṣe nrin ìrìnàjò nwọn lọ sí ibẹ̀, nwọ́n pàdé bàbá Lámónì, ẹnití íṣe ọba lórí gbogbo ilẹ̀ nã.

9 Sì kíyèsĩ, bàbá Lámónì wí fún un pé: Kíni ìdí rẹ tí ìwọ kò fi wá sí ibi àpèjẹ ní ọjọ́ nlá nnì tí èmi se àpèjẹ fún àwọn ọmọ mi, àti fún àwọn àrá mi?

10 Òun sì tún wí pé: Níbo ni ìwọ nlọ pẹ̀lú ará Nífáì yí, ẹnití ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ onírọ́ ènìyàn?

11 Ó sì ṣe tí Lámónì sọ gbogbo ibi tí ó nlọ fún un, nítorítí ó bẹ̀rù láti ṣẹ̃.

12 Ó sì tún sọ fún un gbogbo ìdí rẹ tí òun fi ndúró lẹ́hìn nínú orílẹ̀-èdè òun, tí òun kò fi lọ sí ibi àpèjẹ bàbá òun èyítí ó pèsè.

13 Àti nísisìyí nigbati Lámónì ti ṣe àlàyé gbogbo nkan wọ̀nyí fún un kíyèsĩ, fún ìyàlẹ́nu rẹ̀, bàbá rẹ̀ bínú síi, ó sì wí pé: Lámónì, ìwọ fẹ́ tú àwọn ara Nífáì wọ̀nyí sílẹ̀, tí nwọn jẹ́ ìran òpùrọ́. Kíyèsĩ, ó ja àwọn bàbá wa lólè; àti nísisìyí àwọn ọmọ rẹ̀ tún wá sí ãrin wa, pé nípa ọgbọ́n àrékérekè nwọn, pẹ̀lú irọ́ nwọn, nwọn ó tàn wá kí nwọ́n tún lè jà wá lólè ohun ìní wa.

14 Nísisìyí bàbá Lámónì pàṣẹ fún un pé kí ó pa Ámọ́nì pẹ̀lú idà. Òun sì tún pàṣẹ fún un pé kò gbọ́dọ̀ lọ sí ilẹ̀ Mídónì, ṣùgbọ́n kí ó padà pẹ̀lú òun lọ sí ilẹ̀ Íṣmáẹ́lì.

15 Ṣùgbọ́n Lámónì wí fún un pé: Èmi kò ní pa Ámọ́nì, bẹ̃ sì ni èmi kò ní padà lọ sí ilẹ̀ Íṣmáẹ́lì, ṣùgbọ́n èmi yíò lọ sí ilẹ̀ Mídónì, kí èmi lè tú àwọn arákùnrin Ámọ́nì sílẹ̀, nítorítí èmi mọ̀ pé ẹni tí ó tọ́ àti wòlĩ mímọ́ ti Ọlọ́run òtítọ́ ni nwọn íṣe.

16 Nísisìyí, nígbàtí bàbá rẹ ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó bínú síi, ó sì fa idà rẹ yọ pé kí òun kí ó gẽ lulẹ̀.

17 Ṣùgbọ́n Ámọ́nì jáde síwájú, ó sì wí fún un pé: Kíyèsĩ, ìwọ kò gbọ́dọ̀ pa ọmọ rẹ; bíótilẹ̀ríbẹ̃, ó sàn kí ó kú ju kí ìwọ ó kú, nítorí kíyèsĩ, òun ti ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; ṣùgbọ́n tí ìwọ bá kú ní báyĩ, nínú ìbínú rẹ, ẹ̀mí rẹ kò lè rí ìgbàlà.

18 Àti pẹ̀lú, ó jẹ́ ohun tí ó yẹ fún ọ láti máṣe èyí; nítorípé bí ìwọ bá pa ọmọ rẹ, nítorípé aláìṣẹ̀ ènìyàn ni, ẹ̀jẹ̀ rẹ yíò ké láti ilẹ̀ wá sí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ fún ẹ̀san lórí rẹ; bóyá ìwọ yíò sì sọ ẹ̀mí rẹ̀ nu.

19 Nísisìyí nígbàtí Ámọ́nì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún un, ó dáa lóhùn, ó wípé: Èmi mọ̀ pé tí èmi bá pa ọmọ mi, ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ ni èmi ta sílẹ̀; nítorípé ìwọ ni ó wá ọ̀nà láti paá run.

20 Ó sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti pa Ámọ́nì. Ṣùgbọ́n Ámọ́nì dojúkọ lílù rẹ, o si lu ọwọ rẹ kí ó má lè ríi lò.

21 Nísisìyí, nígbàtí ọba nã ríi pé Ámọ́nì lè pa òun, ó bẹ̀rẹ̀sí ṣípẹ̀ pẹ̀lú Ámọ́nì pé kí ó dá ẹ̀mí òun sí.

22 Ṣùgbọ́n Ámọ́nì gbé idà rẹ̀ sókè, ó sì wí fún un pé: Kíyèsĩ, èmi yíò pa ọ́, àfi tí ìwọ bá gbà kí a kó arákùnrin mi jáde kúrò nínú túbú.

23 Nísisìyí nítorítí ọba bẹ̀rù kí ó má sọ ẹ̀mí ara òun nù, ó wípé: Bí ìwọ bá dá mi sí, èmi yíò fún ọ ní ohunkóhun tí ìwọ lè bẽrè, àní títí fi dé ìlàjì ìjọba yí.

24 Nísisìyí nígbàtí Ámọ́nì ríi pé òun ti mú ọba nã ṣe bí òun ti fẹ́, ó wí fún un pé: Bí ìwọ bá gbà kí a kó àwọn arákùnrin mi jáde kúrò nínú túbú, àti kí Lámónì sì tún fi ọwọ́ mú ìjọba rẹ, kí ìwọ má sì bínú síi, ṣùgbọ́n kí ìwọ gbà kí ó ṣe ìfẹ́ rẹ nínú ohunkóhun tí ó lè gbèrò, nígbàyí ni èmi yíò dá ọ sí; bíkòjẹ́bẹ̃ èmi yíò gé ọ lulẹ̀.

25 Nísisìyí nígbàtí Ámọ́nì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tán, ọba nã bẹ̀rẹ̀sí yọ̀ nítorí ẹ̀mí rẹ̀.

26 Nígbàtí ó ríi pé Ámọ́nì kò ní ìfẹ́ láti pa òun run, nígbàtí ó sì tún rí ìfẹ́ nlá èyítí ó ní fún ọmọ òun Lámónì, ẹnu yã púpọ̀púpọ̀, ó sì wípé: Nítorípé èyí nìkan ni ìwọ bẽrè, pé kí èmi tú àwọn arákùnrin rẹ sílẹ̀, àti kí èmi gbà kí Lámónì ọmọ mi sì fi ọwọ́ mú ìjọba tirẹ̀, kíyèsĩ èmi yio gbà fún ọ kí ọmọ mi kí ó fọwọ́ mú ìjọba tirẹ̀ láti ìgbà yí lọ àti títí láéláé; èmi kò sì ní jọba lórí rẹ mọ́.

27 Èmi yíò sì tún gbà fún ọ kí a tú àwọn arákùnrin rẹ sílẹ̀ nínú túbú, kí ìwọ pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ nã sì wá sí ọ̀dọ̀ mi nínú ìjọba mi; nítorípé èmi yíò ṣe àfẹ́rí rẹ lọ́pọ̀lọpọ̀. Nítorípé ẹnu ya ọba nã púpọ̀ fún ọ̀rọ̀ tí ó ti sọ, àti fún ọ̀rọ̀ tí ọmọ rẹ̀ Lámónì ti sọ, nítorínã ó ní ìfẹ́ lati kọ́ nípa awọn ọ̀rọ̀ náà.

28 Ó sì ṣe tí Ámọ́nì àti Lámónì mú ọ̀nà pọ̀n lọ sí ìrìnàjò nwọn sí ilẹ̀ Mídónì. Lámónì sì rí ojú rere ọba ilẹ̀ nã; nítorínã nwọn mú àwọn arákùnrin Ámọ́nì jáde kúrò nínú túbú.

29 Nígbàtí Ámọ́nì sì bá nwọn pàdé, ó kún fún ìbànújẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí kíyèsĩ, ihoho ni nwọ́n wà, awọ ara nwọn sì ti bó kúrò púpọ̀púpọ̀ nítorítí a dè nwọ́n pẹ̀lú okùn líle. Pẹ̀lú pé ebi, òùngbẹ, àti onírurú ìpọ́njú ti jẹ nwọ́n níyà; bíótilẹ̀ríbẹ̃, nwọ́n ní sũrù nínú gbogbo ìjìyà nwọn wọ̀nyí.

30 Bí o sì ti ríi báyĩ, ó jẹ́ ìpín nwọn láti bọ́ sí ọ́wọ́ àwọn ènìyàn líle pẹ̀lú ọlọ́kàn líle; nítorínã nwọn kò gbọ tiwọn, nwọ́n sì jù nwọ́n síta, nwọ́n sì nà nwọ́n, nwọ́n sì ti lé nwọn láti ilé kan dé òmíràn, àti lai ibìkan dé òmíràn, àní títí nwọn fi dé ilẹ̀ Mídónì; níbẹ̀ sì ni nwọ́n ti mú nwọn tí nwọn sì jù nwọ́n sínú túbú, tí nwọ́n sì dè wọ́n pẹ̀lú okùn líle, tí nwọ́n sì fi nwọ́n sínú túbú fún ọjọ́ pípẹ́, tí Lámónì àti Ámọ́nì sì tú nwọn sílẹ̀.