Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 26


Orí 26

Ámọ́nì ṣògo nínú Olúwa—Olúwa nfi agbára fún àwọn olódodo, ó sì nfún nwọn ní ìmọ̀—Nípa ìgbàgbọ́ ènìyàn lè mú ẹgbẽgbẹ̀rún ọkàn wá sí ìrònúpìwàdà—Ọlọ́run ní gbogbo agbára, ohun gbogbo ni ó sì yée. Ní ìwọ̀n ọdún 90 sí 77 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí, àwọn wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ Ámọ́nì sí àwọn arákùnrin rẹ̀, tí ó wí báyĩ: Ẹ̀yin ará àti ẹ̀yin arákùnrin mi, kíyèsĩ mo wí fún un yín, báwo ni ìdí rẹ ti pọ̀ tó fún ayọ̀ wa; nítorípé njẹ́ àwa lè rõ pé Ọlọ́run lè fún wa ní ìbùkún nlá báyĩ nígbàtí a tẹ síwájú kúrò nínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà?

2 Àti nísisìyí, èmí bẽrè, irú ìbùkún nlá wo ni ó ti fi lé wa lórí? Njẹ́ ẹ̀yin lè sọọ́?

3 Ẹ kíyèsĩ, èmi ṣe ìdáhùn rẹ̀ fún un yín, nítorítí àwọn arákùnrin wa, àwọn ará Lámánì, wà nínú òkùnkùn, bẹ̃ni, àní nínú ọ̀gbun tí ó ṣókùnkùn jùlọ, ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, melo wọn ni a mú wá láti rí ìmọ́lẹ̀ Ọlọ́run tí ó yanilẹ́nu! Èyí sì jẹ́ ìbùkún tí a ti fi lé wa lórí, pé a ti jẹ́ ohun èlò ní ọwọ́ Ọlọ́run láti ṣe iṣẹ́ nlá yĩ.

4 Ẹ kíyèsĩ, ẹgbẹ̃gbẹ̀rún nwọ́n ní ó yọ̀, tí a sì ti mú wá sí inú agbo Ọlọ́run.

5 Ẹ kíyèsĩ, àkokò ti tó fún ìkórè, alábùkún-fún sì ni ẹ̀yin í ṣe, nítorítí ẹ̀yin ti tẹ dòjé nyín bọ ìkórè, ẹ̀yin sì kórè pẹ̀lú agbára nyín, bẹ̃ni, ní gbogbo ọjọ́ ni ẹ̀yin nṣiṣẹ́; ẹ sì kíyèsí iye ìtí nyín! A ó sì kó nwọn jọ sínú àká, kí nwọ́n má bã ṣòfò.

6 Bẹ̃ni, ìjì kò ní lè tẹ̀ nwọ́n pa ní ọjọ́ ìkẹhìn; bẹ̃ni, afẹ́fẹ́ líle kò ní lè fà nwọn tu; ṣùgbọ́n nígbàtí ìjì yíò bá dé, a ó kó nwọn jọ sí ãyè nwọn, tí ìjì nã kò fi ní lè wọ ãrin nwọn; bẹ̃ni, ẹ̀fũfù líle kò ní lè gbé nwọn lọ sí ibi èyítí ó wù tí ọ̀tá fẹ́ gbé nwọn lọ.

7 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, nwọ́n wà ní ọwọ́ Olúwa ìkórè, tirẹ̀ ni nwọ́n sì íṣe; òun yíò sì jí nwọn dìde ní ọjọ́ ìkẹhìn.

8 Ìbùkún ni fún orúkọ Ọlọ́run wa; ẹ jẹ́ kí a kọrin ìyìn rẹ̀, bẹ̃ni, ẹ jẹ́ kí a fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ̀ mímọ́, nítorítí ó nṣíṣẹ òdodo títí láéláé.

9 Nítorípé bí kò bá ṣe pé àwa ti jáde kúrò nínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, àwọn arákùnrin wa ọ̀wọ́n wọ̀nyí, tí nwọ́n fẹ́ràn wa lọ́pọ̀lọpọ̀, ìbá ṣì kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkórira fún wa, bẹ̃ni nwọn yíò sì jẹ́ àjòjì sí Ọlọ́run síbẹ̀.

10 Ó sì ṣe, nígbàtí Ámọ́nì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, Áárọ́nì arákùnrin rẹ̀ bá a wí pé: Ámọ́nì, mo bẹ̀rù pé kí ayọ̀ rẹ má já sí ìyangàn.

11 Ṣugbọ́n Ámọ́nì wí fún un: èmi kò yangàn nínú agbára mi, tàbí nínú ọgbọ́n mi; ṣùgbọ́n, kíyèsĩ, ayọ̀ mi kún, bẹ̃ni, ọkàn mi kún rẹ́rẹ́ fún ayọ̀, èmi yíò sì yọ̀ nínú Ọlọ́run mi.

12 Bẹ̃ni, èmi mọ̀ pé èmi kò jẹ́ nkan; nípa ti agbára mi, aláìlera ni èmi í ṣe; nítorínã, èmi kò ní yangàn nípa ara mi, ṣùgbọ́n èmi yíò yangàn nípa Ọlọ́run mi, nítorípé nípasẹ̀ agbára rẹ̀ èmi lè ṣe ohun gbogbo; bẹ̃ni, kíyèsĩ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ìyanu nlá-nlà ni àwa ti ṣe ní ilẹ̀ yĩ, fún èyí tí àwa yíò yin orúkọ rẹ̀ láéláé.

13 Ẹ kíyèsĩ, ẹgbẹ̃gbẹ̀rún mélo nínú àwọn arákùnrin wa ni ó ti tú sílẹ̀ kúrò nínú oró ipò-òkú; tí a sì mú nwọn kọ orin ìfẹ́ ìdãndè, èyí yĩ sì rí bẹ̃ nítorí agbára ọ̀rọ̀ rẹ̀ èyítí ó wà nínú wa, nítorínã njẹ́ àwa kò ha ní ìdí nlá láti yọ̀?

14 Bẹ̃ni, àwa ni ìdí láti yìn ín títí láéláé, nítorítí òun ni Ọlọ́run Tí Ó Ga Jùlọ, ó sì ti tú àwọn arákùnrin wa sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n ọ̀run àpãdì.

15 Bẹ̃ni, òkùnkùn ayérayé àti ìparun ni ó yí nwọn ká; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, òun ti mú nwọn bọ́ sínú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ títí ayé, bẹ̃ni, sínú ìgbàlà títí ayé; à sì yí nwọn ká pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ tí kò lẹ́gbẹ́; bẹ̃ni, àwa sì jẹ́ ohun èlò ní ọwọ́ rẹ̀ ní ṣíṣe ohun ìyanu nlá yĩ.

16 Nítorínã, ẹ jẹ́ kí àwa ṣògo, bẹ̃ni, àwa yíò ṣògo nínú Olúwa; bẹ̃ni, àwa yíò yọ̀, nítorítí ayọ̀ wa kún; bẹ̃ni, àwa yíò yin Ọlọ́run wa títí láéláé. Kíyèsĩ, tani ó lè ṣògo àṣejù nínú Olúwa? Bẹ̃ni, tani ó lè sọ àsọjù nípa agbára nlá rẹ, àti ãnú rẹ̀, àti ìpamọ́ra rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn? Kíyèsĩ, mo wí fún un yín, èmi kò lè sọ díẹ̀ nínú bí èmi ti mọ̀ ọ́ lára mi.

17 Tani ó ha lè rò pé Ọlọ́run wa yõ ní ãnú sí wa tóbẹ̃ láti já wá gbà kúrò nínú ipò búburú, ẹ́ṣẹ̀ àti àìmọ́.

18 Kíyèsĩ, àwa jáde lọ àní nínú ìbínú, pẹ̀lú ìdẹ́rùbà nlá láti pa ìjọ rẹ̀ run.

19 Nigbanã! kíni ìdí rẹ̀ tí òun kò fi sọ wá sínú ìparun búburú, bẹ̃ni, kíni òun kò ṣe jẹ́ kí idà àìṣègbè rẹ̀ ṣubú lù wá, kí ó sì sọ wá sínú ipò àìnírètí ayérayé?

20 Àní, ẹ̀mí mi fẹ́rẹ̀ sá kúrò nínú àgọ́ ara yĩ fún irú èrò yĩ. Ẹ kíyèsĩ, òun kò ṣe àìṣègbè lé wa lórí, ṣùgbọ́n nínú ãnú rẹ tí ó ti pọ̀ púpọ̀, òun mú wa rékọjá lórí ọ̀gbun ayérayé ti ikú àti òṣì, àní sí ìgbàlà ọkàn wa.

21 Àti nísisìyí kíyèsĩ, ẹ̀yin arákùnrin mi, tani ẹni nã nípa ti ara tí ó lè mọ́ ohun wọ̀nyí? Mo wí fún nyín, kò sí ẹnìkan tí ó mọ́ ohun wọ̀nyí, àfi àwọn onírònúpìwàdà.

22 Bẹ̃ni, ẹnití ó bá ronúpìwàdà tí ó sì lo ìgbàgbọ́, tí ó sì mú iṣẹ́ rere jáde wá, tí ó sì ngbàdúrà ní àìsìmì—àwọn wọ̀nyí ni a fún ní ànfàní láti mọ́ ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run; bẹ̃ni, àwọn wọ̀nyí ni a ó fún ní ànfàní ìfihàn àwọn ohun tí a kò fihàn rí; bẹ̃ni, a ó sì fún àwọn wọ̀nyí ní ànfàní láti mú ẹgbẽgbẹ̀rún ọkàn wá sí ìrònúpìwàdà, àní bí a ti fi fún wa láti mú àwọn arákùnrin wa wọ̀nyí wá sí ìrònúpìwàdà.

23 Nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi, njẹ́ ẹ̀yin ha rántí pé àwa sọ fún àwọn arákùnrin wa ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, pé àwa yíò kọjá lọ sí ilẹ̀ Nífáì, láti wãsù sí àwọn arákùnrin wa, àwọn ará Lámánì, tí nwọn sì fi wá rẹ̃rín ẹlẹ́yà?

24 Nítorítí nwọ́n wí fún wa pé: Njẹ́ ẹ̀yin lérò pé ẹ lè mú àwọn ará Lámánì wá sí ìmọ̀ òtítọ́? Njẹ́ ẹ̀yin rò wípé ẹ lè yí àwọn ará Lámánì lọ́kàn padà lórí àìpé àṣà àwọn bàbá nwọn, bí nwọ́n ṣe jẹ́ ọlọ́rùn-líle ènìyàn tó nnì; tí ọkàn nwọn a máa yọ̀ nínú ìtàjẹ̀sílẹ̀; tí nwọ́n ti lo àkokò nwọn nínú àìṣedẽdé èyítí ó burú jùlọ; tí ọ̀nà nwọn sì ti jẹ́ ti olùrékọjá láti ìbẹ̀rẹ̀ wá? Nísisìyí ẹ̀yin arákùnrin mi, ẹ̀yin rántí pé báyĩ ni nwọ́n wí fún wa.

25 Lẹ́hìnnã, nwọ́n tún wípé: Ẹ jẹ́ kí a gbé ogun tì nwọ́n, kí àwa kí ó lè pa nwọ́n run ati ìwà àìṣedẽdé nwọn kúrò lórí ilẹ̀ nã, kí nwọ́n má bã borí wa, kí nwọ́n sì pa wá run.

26 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, wíwá sínú aginjù wá kĩ ṣe láti pa àwọn arákùnrin wa run, ṣùgbọ́n pẹ̀lú èrò àti gba ọkàn díẹ̀ nínú nwọn là.

27 Nísisìyí nígbàtí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn wa, tí a sì fẹ́ padà sẹ́hìn, ẹ kíyèsĩ, Olúwa tù wá nínú, ó sì wípé: Ẹ kọjá lọ sãrin àwọn arákùnrin nyín, àwọn ará Lámánì, kí ẹ sì faradà ìpọ́njú nyín pẹ̀lú sũrù, Èmi yíò sì fún nyín ní àṣeyọrí.

28 Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, àwa ti wá, àwa sì ti lọ lãrín nwọn; àwa sì ti faradà ìpọ́njú a sì ti faradà onírũrú àìní; bẹ̃ni, àwa ti rin ìrìnàjò láti ilé dé ilé, tí àwa sì gbíyèlé ãnú aráyé—kĩ ṣe lé ãnú aráyé nìkan, ṣùgbọ́n lé ãnú Ọlọ́run pẹ̀lú.

29 Àwa sì ti wọ inú ilé nwọn, a sì kọ́ nwọn lẹ̃kọ́, àwa sì ti kọ́ nwọn ní ojú òpópó; bẹ̃ni, àwa ti kọ́ nwọn lórí àwọn òkè nwọn; àwa sì ti wọ inú tẹ́mpìlì nwọn pẹ̀lú, àti inú sínágọ́gù nwọn, a sì ti kọ́ nwọn lẹ́ẹkọ́; ṣùgbọ́n nwọ́n lé wa jáde, nwọ́n fi wá ṣe ẹlẹ́yà, nwọ́n sì tutọ́ sí wa lára, nwọn sì gbá wa lẹ́nu; nwọ́n sì tún sọ wá ní òkúta, tí nwọn sì dè wá pẹ̀lú okùn tí ó le, tí nwọ́n sì sọ wa sínú tũbú; ṣùgbọ́n nípa agbára àti ọgbọ́n Ọlọ́run a tún ti rí ìkóyọ.

30 Àwa sì ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú, gbogbo àwọn nkan wọ̀nyí sì rí bẹ̃ pé bóyá a lè ti ipasẹ̀ wa gba àwọn ọkàn díẹ̀ là; àwa sì lérò wípé ayọ̀ wa yíò kún bí a bá ti ipasẹ̀ wa gbà nínú nwọn là.

31 Nísisìyí kíyèsĩ, àwa lè wò kí a sì rí èrè iṣẹ́ tí àwa ṣe; njẹ́ wọ́n ha kéré bí? Èmi wí fún un yín, rárá, ó pọ̀; bẹ̃ni, àwa sì lè ṣe ìjẹ́rĩ sí òtítọ́-inú nwọn, nítorí ìfẹ́ nwọ́n sí àwọn arákùnrin nwọn àti sí àwa nã pẹ̀lú.

32 Nítorí ẹ sì kíyèsĩ ó sàn fún nwọn láti fi ẹ̀mí nwọn rúbọ ju kí nwọ́n gba ẹ̀mí ọ̀tá nwọn; nwọ́n sì ti ri àwọn ohun ìjà ogun nwọn mọ́ inú ilẹ̀, nítorí ìfẹ́ nwọn sí àwọn arákùnrin nwọn.

33 Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, mo wí fún yín, njẹ́ irú ìfẹ́ nlá báyĩ wà ní gbogbo ilẹ̀ yí rí? Ẹ kíyèsĩ, mò wí fún yín, Rárá, kò sí irú rẹ̀ rí, àní lãrín àwọn ará Nífáì.

34 Nítorí kíyèsĩ, nwọn yíò gbé ohun ìjà sí àwọn arákùnrin nwọn; nwọn kò sì ní jẹ́ kí nwọn pa nwọ́n. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ iye àwọn tí nwọ́n ti fi ẹ̀mí nwọn lélẹ̀; àwa sì mọ̀ pé nwọ́n ti lọ sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nwọn, nítorí ìfẹ́ tí nwọ́n ní àti ìkórira fún ẹ̀ṣẹ̀.

35 Nísisìyí, njẹ́ àwa kò ha ní ìdí fún ayọ̀ bí? Bẹ̃ni, èmi wí fún yín, a kò rí irú ènìyàn bẹ̃ rí tí ó ní ìdí nlá irú èyí láti yọ̀ bí àwa, láti ìgbàtí ayé ti bẹ̀rẹ̀; bẹ̃ni, ayọ̀ mi sì pọ̀ púpọ̀, tó kí èmi fi yangan nínú Ọlọ́run mi; nítorítí ó ní gbogbo agbára, gbogbo ọgbọ́n, àti gbogbo òye; ohun gbogbo ni ó yée, òun sì jẹ́ Ẹni alãnú, àní sí ìgbàlà, fún àwọn tí yíò bá ronúpìwàdà, tí nwọ́n sì gba orúkọ rẹ̀ gbọ́.

36 Nísisìyí tí eleyĩ bá sì íṣe ìyangàn, síbẹ̀ ni èmi yíò yangàn; nítorítí èyí ni ìyè àti ìmọ́lẹ̀ mi, ayọ̀ mi àti ìgbàlà mi, àti ìràpadà mi kúrò nínú ègbé ayérayé. Bẹ̃ni, ìbùkún ni fún orúkọ Ọlọ́run mi, ẹnití ó ti í ṣe ìrántí àwọn ènìyàn yĩ, tí í ṣe ẹ̀ka kan ti ìdílé Ísráẹ́lì, tí ó sì ti yapa kúrò lára rẹ̀ ní ilẹ̀ àjèjì; bẹ̃ni, mo wípé, alábùkún-fún ni orúkọ Ọlọ́run mi, ẹnití ó ṣe ìrántí wa, aṣákolọ nínú ilẹ̀ àjèjì.

37 Nísisìyí ẹ̀yin arákùnrin mi, àwa ríi pé Ọlọ́run a máa ṣe ìrántí ènìyàn gbogbo, ilẹ̀ èyíówù kí nwọ́n wà; bẹ̃ni, ó mọ́ iye àwọn ènìyàn rẹ̀, ọ̀pọ̀ ìyọ́nú rẹ̀ sì nbẹ lórí gbogbo aráyé. Nísisìyí, èyí ni ayọ̀ mi, àti ẹbọ ọpẹ́ nlá mi; bẹ̃ni, èmi yíò sì fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run mi títí láéláé. Àmín.