Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 61


Orí 61

Pahoránì sọ fún Mórónì nípa ìṣọ̀tẹ̀ àti ìtàpásí ìjọba nã—Àwọn afọbajẹ nã gba Sarahẹ́múlà nwọ́n sì bá àwọn ará Lámánì ní àjọṣepọ̀—Pahoránì bẽrè fún ìrànlọ́wọ́ ọmọ ogun láti lè kọlũ àwọn ọlọ̀tẹ̀ nã. Ní ìwọ̀n ọdún 62 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Kíyèsĩ, nísisìyí ó sì ṣe, pé ní kété tí Mórónì ti fi ìwé rẹ̀ ránṣẹ́ sí aláṣẹ àgbà nã, ó gba ìwé láti ọ̀dọ̀ Pahoránì aláṣẹ àgbà. Àwọn yĩ sì ni ọ̀rọ̀ tí ó gbà:

2 Èmi, Pahoránì, tí í ṣe aláṣẹ àgbà lórí ilẹ̀ yĩ, fi àwọn ọ̀rọ̀ yĩ ránṣẹ́ sí Mórónì, tí í ṣe olórí ológun lórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun. Kíyèsĩ, mo wí fún ọ́, Mórónì, pé inú mi kò dùn nípa ìpọ́njú nyín tí ó pọ̀ púpọ̀, bẹ̃ni, ó bá ọkàn mi jẹ́.

3 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àwọn kan wà tí inú nwọn ndùn sí ìpọ́njú nyín, bẹ̃ni, tóbẹ̃ tí nwọ́n ti dìde ní ìṣọ̀tẹ̀ sí mi, àti sí àwọn ènìyàn mi tí nwọn jẹ́ àwọn tí nwá òmìnira, bẹ̃ni, àwọn tí nwọ́n dìde sì pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀.

4 Àti pé àwọn tí nwọn nlépa láti gba ìtẹ́ ìdájọ́ lọ́wọ́ mi ni nwọ́n nṣe àìṣedẽdé nlá yĩ; nítorítí nwọ́n lo ẹ̀tàn nlá, nwọ́n sì ti darí ọkàn àwọn ènìyàn púpọ̀ sí ṣíṣe búburú, èyítí yíò fa ìpọ́njú tí ó pọ̀ lãrín wa; nwọ́n ti dáwọ́ fífún wa ní ìpèsè oúnjẹ wa dúró nwọ́n sì ti dẹ́rùba àwọn ènìyàn olómìnira wa tóbẹ̃ tí nwọn kò lè wá bá nyín.

5 Sì kíyèsĩ, nwọ́n ti lé mi jáde kúrò níwájú wọn, èmi sì ti sálọ sí ilẹ̀ Gídéónì, pẹ̀lú iye àwọn ọmọ ogun tí ó ṣeéṣe fún mi láti mú tọwọ.

6 Sì kíyèsĩ, èmi ti kọ ìwé ikede ránṣẹ́ jákè-jádò apá ilẹ̀ tí ó wà ní ibi yĩ; sì kíyèsĩ, nwọ́n darapọ̀ mọ́ wa lójojúmọ́, láti gbé ohun ìjà ogun nwọn, ní ìdãbò bò orílẹ̀-èdè nwọn àti òmìnira nwọn, àti láti gbẹ̀san ìwà ìkà nwọn.

7 Nwọ́n sì ti wá bá wa, tóbẹ̃ tí nwọn ntako àwọn tí nwọ́n ti dìde ní ìṣọ̀tẹ̀ sí wa, bẹ̃ni, tóbẹ̃ ti nwọn bẹru wa tí nwọn kò lè dá àbá láti jáde wá dojú ìjà kọ wá.

8 Nwọ́n ti gba ilẹ̀ nã, tàbí olú ìlú nã, Sarahẹ́múlà; nwọ́n ti yan ọba lórí nwọn, òun sì ti kọ̀wé sí ọba àwọn ará Lámánì, nínú èyítí ó ti bã ní májẹ̀mú àjọṣepọ̀; nínú àjọṣepọ̀ èyítí ó gbà láti dãbò bò ìlú-nlá Sarahẹ́múlà, ìdãbò bò èyítí òun lérò wípé yíò mú kí àwọn ará Lámánì lè ṣẹ́gun èyítí ó kù nínú ilẹ̀ nã, tí nwọn ó sì fi jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn yĩ nígbàtí àwọn ará Lámánì yíò ṣẹ́gun nwọn.

9 Àti nísisìyí, nínú ọ̀rọ̀ rẹ ìwọ ti bá mi wí, ṣùgbọ́n kò já mọ́ nkan; èmi kò bínú, ṣùgbọ́n mo láyọ̀ nínú ìdúróṣinṣin rẹ. Èmi, Pahoránì, kò lépa agbára, bíkòṣe láti lè di ìtẹ́ ìdájọ́ mi mú kí èmi ó lè pa ẹ̀tọ́ àti òmìnira àwọn ènìyàn mi mọ́. Ọkàn mi dúró ṣinṣin nínú òmìnira nã nínú èyítí Ọlọ́run ti sọ wá di òmìnira.

10 Àti nísisìyí, kíyèsĩ, àwa yíò tako ìwà búburú àní títí dé ojú ìtàjẹ̀sílẹ̀. Àwa kò ní ta ẹ̀jẹ̀ àwọn ará Lámánì silẹ bí nwọn yíò bá dúró nínú ilẹ̀ nwọn.

11 Àwa kò ní ta ẹ̀jẹ̀ àwọn arákùnrin wa sílẹ̀ bí nwọn kò bá dìde ní ìṣọ̀tẹ̀ kí nwọ́n sì gbé idà kọlũ wá.

12 Àwa yíò fi ara wa fún àjàgà oko-ẹrú tí ó bá wà ní ìbámu pẹ̀lú àìṣègbè Ọlọ́run, tàbí bí ó bá pãláṣẹ fún wa láti ṣe bẹ̃.

13 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ òun kò pãláṣẹ fún wa pé kí àwa ó fi ara wa fún àwọn ọ̀tá wa, ṣùgbọ́n pé kí àwa ó gbẹ́kẹ̀ wa lé e, òun yíò sì gbà wá.

14 Nítorínã, arákùnrin mi àyànfẹ́, Mórónì, ẹ jẹ́ kí àwa ó tako èyítí ó burú, àti pé ohun búburú èyítí ó wù tí àwa kò bá lè takò pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wa, bẹ̃ni, gẹ́gẹ́bí ìṣọ̀tẹ̀sí àti ìyapa, ẹ jẹ́ kí a takò nwọn pẹ̀lú idà wa, kí àwa ó lè di òmìnira wa mú, kí àwa ó lè yọ nínú anfãni nla ti ìjọ-onígbàgbọ́ wa, àti nínú ipa ti ìfẹ́ Olùràpadà wá àti Ọlọ́run wa.

15 Nítorínã, wá sí ọ̀dọ̀ mi ní kánkán pẹ̀lú díẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ, kí o sì fi àwọn tí ó kù sí abẹ́ Léhì àti Tíákúmì; fún nwọn ní àṣẹ láti ja ogun ní ilẹ̀ tí ó wà ní apá ibẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú Ẹ̀mí Ọlọ́run, èyítí í ṣe ẹ̀mí ìtúsílẹ̀ èyítí nbẹ nínú nwọn.

16 Kíyèsĩ èmi ti fi ìpèsè oúnjẹ díẹ̀ ránṣẹ́ sí nwọn, kí nwọn ó má bã ṣègbé títí ẹ̀yin ó fi wá bá mi.

17 Kó àwọn ọmọ ogun èyíkeyĩ tí ìwọ bá rí jọ nígbàtí ẹ̀yin bá nbọ̀wá sí ìhín, àwa yíò sì lọ kánkán láti kọlũ àwọn olùyapa nnì, nínú ipá Ọlọ́run wa ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tí ó wà nínú wa.

18 Àwa yíò sì gba ìlú-nlá Sarahẹ́múlà, kí àwa ó lè rí oúnjẹ síi láti fi ránṣẹ́ sí Léhì àti Tíákúmì; bẹ̃ni, àwa yíò lọ láti kọlũ nwọ́n nínú ipá Olúwa, àwa yíò sì fi òpin sí ìwà àìṣedẽdé nlá yĩ.

19 Àti nísisìyí, Mórónì, inú mi dùn láti gba ìwé rẹ, nítorípé agara dá mi nípa ohun tí ó yẹ kí àwa ó ṣe, bóyá ó tọ́ fún wa láti kọlũ àwọn arákùnrin wa.

20 Ṣùgbọ́n ìwọ ti wípé, àfi bí nwọ́n bá ronúpìwàdà Olúwa ti pãláṣẹ fún ọ pé kí ìwọ ó kọlũ nwọ́n.

21 Kí o ríi pé o ti Léhì àti Tíákúmì lẹ́hìn nínú ìgbàgbọ́ nwọn nínú Olúwa; wí fún nwọn pé kí nwọn máṣe bẹ̀rù, nítorítí Ọlọ́run yíò gbà nwọ́n, bẹ̃ni, àti gbogbo àwọn tí ó dúró ṣinṣin nínú òmìnira nnì nínú èyítí Ọlọ́run ti sọ nwọ́n di òmìnira. Àti nísisìyí èmi parí ọ̀rọ̀ mi sí arákùnrin mi àyànfẹ́, Mórónì.