Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 62


Orí 62

Mórónì kọjá lọ láti ran Pahoránì lọ́wọ́ ní ilẹ̀ Gídéónì—Nwọ́n pa awọn afọbajẹ tí nwọ́n kọ̀ láti dãbò bò orílẹ̀-èdè nwọn—Pahoránì àti Mórónì gba Nífáìhà padà—Àwọn ará Lámánì púpọ̀ darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn Ámọ́nì—Tíákúmì pa Ámmórọ́nì nítorí ìdí èyí ni nwọ́n sì pa òun nã—À lé àwọn ará Lámánì kúrò ní ilẹ̀ nã, a sì fi àlãfíà lélẹ̀—Hẹ́lámánì padà sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ó sì gbé iṣẹ́ Ìjọ-Ọlọ́run sókè. Ní ìwọ̀n ọdún 62 sí 57 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Mórónì ti gba ìwé yĩ, ó gba ìmúlọ́kànle, ó sì kún fún ayọ̀ púpọ̀ nítorí ìgbàgbọ́ Pahoránì, pé kĩ ṣe ọlọ̀tẹ̀ sí òmìnira àti ìjà-òmìnira ti orílẹ̀-èdè rẹ̀.

2 Ṣùgbọ́n ó sì kẹ́dùn ọkàn lọ́pọ̀lọpọ̀ pẹ̀lú nítorí àìṣedẽdé àwọn tí nwọ́n lé Pahoránì kúrò lórí ìtẹ́ ìdájọ́, bẹ̃ni, ní kúkúrú nítorí ti àwọn tí nwọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí orílẹ̀-èdè nwọn àti sí Ọlọ́run nwọn pẹ̀lú.

3 Ó sì ṣe tí Mórónì mú díẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Pahoránì, ó sì fún Léhì àti Tíákúmì ní àṣẹ lórí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí ó kù, ó sì kọjá lọ sí apá ilẹ̀ Gídéónì.

4 Ó sì gbé àsíá òmìnira sókè níbikíbi tí ó bá wọ̀, ó sì kó gbogbo ọmọ ogun tí ó bá ṣeéṣe fún un láti kójọ bí ó ti nkọjá lọ sí apá ilẹ̀ Gídéónì.

5 Ó sì ṣe tí ẹgbẽgbẹ̀rún nwọn sì darapọ̀ mọ̀ ọ́, tí nwọ́n sì gbé idà nwọn láti dãbò bò òmìnira nwọn, pé kí nwọ́n má lè bọ́ sínú oko-ẹrú.

6 Àti báyĩ, nígbàtí Mórónì ti kó gbogbo àwọn ọmọ ogun tí ó rí jọ pọ̀ bí ó ti nkọjá lọ, ó dé ilẹ̀ Gídéónì; nígbàtí ó sì ti da àwọn ọmọ ogun rẹ̀ mọ́ ti Pahoránì nwọ́n ní ágbára lọ́pọ̀lọpọ̀, àní nwọ́n ní ágbára ju àwọn ọmọ ogun Pákúsì, tĩ ṣe ọba àwọn olùyapa nnì tí nwọ́n lé àwọn ẹnití nwá òmìnira nnì jáde kúrò nínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà tí nwọ́n sì ti gba ilẹ̀ nã.

7 Ó sì ṣe tí Mórónì àti Pahoránì kọjá lọ pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn sínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, tí nwọ́n sì jáde lọ ní ìkọlù ìlú-nlá nã, nwọ́n sì bá àwọn ọmọ ogun Pákúsì pàdé, tóbẹ̃ tí nwọ́n sì wá bá nwọn jagun.

8 Ẹ kíyèsĩ, a pa Pákúsì a sì kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lẹ́rú, a sì dá Pahoránì padà sórí ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀.

9 Àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Pákúsì sì gba ìdájọ́ nwọn, ní ìbámu pẹ̀lú òfin, àti àwọn afọbajẹ nnì tí a ti mú tí a sì tĩ jù sínú túbú; a sì pa nwọ́n ní ìbámu pẹ̀lú òfin; bẹ̃ni, àwọn ọmọ ogun Pákúsì nnì àti àwọn afọbajẹ nnì, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti gbé ohun ìjà-ogun ní ìdãbò bò orílè-èdè rẹ̀, ṣùgbọ́n tí yíò bã jà, ni a sì pa.

10 Báyĩ sì ni ó di ohun tí ó tọ́ pé kí àwọn ará Nífáì ó pa òfin yĩ mọ́ fún ìpamọ́ orílẹ̀-èdè nwọn; bẹ̃ni, àti pé ẹnikẹ́ni tí a bá rí tí ó ntako òmìnira nwọn ni a pa ní kíákíá ní ìbámu òfin nã.

11 Báyĩ sì ni ọgbọ̀n ọdún nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì parí; Mórónì àti Pahoránì sì ti dá àlãfíà padà sórí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, lãrín àwọn ènìyàn nwọn, nwọ́n sì ti pa gbogbo àwọn tí kò ṣe òtítọ́ sí ìjà òmìnira nã.

12 Ó sì ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kọkànlélọ́gbọ̀n nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì, Mórónì mú kí a fi ìpèsè oúnjẹ ránṣẹ́ ní kíákíá, àti ọ̀wọ́ ọmọ ogun ẹgbẹ̀rún mẹ́fà sí Hẹ́lámánì, láti ràn án lọ́wọ́ fún ìdãbò bò apá ilẹ̀ nã tí ó wà.

13 Ó sì mú kí nwọ́n fi ọ̀wọ́ ọmọ ogun ẹgbẹ̀rún mẹ́fà pẹ̀lú oúnjẹ tí ó tó, ránṣẹ́ sí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Léhì àti Tíákúmì. Ó sì ṣe tí nwọ́n ṣe èyí láti lè dãbò bò ilẹ̀ nã lọ́wọ́ àwọn ará Lámánì.

14 Ó sì ṣe tí Mórónì àti Pahoránì, ti nwọ́n fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun sẹ́hìn ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, nwọ́n kọjá lọ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun sí ilẹ̀ Nífáìhà, nítorítí nwọ́n pinnu láti lé àwọn ará Lámánì kúrò nínú ìlú-nlá nnì.

15 Ó sì ṣe pé bí nwọ́n ṣe nrin ìrìnàjò nwọn lọ sínú ilẹ̀ nã, nwọ́n mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ogun àwọn ará Lámánì, nwọ́n sì pa nwọ́n, nwọ́n sì kó àwọn ìpèsè oúnjẹ nwọn àti àwọn ohun ìjà-ogun nwọn.

16 Ó sì ṣe lẹ́hìn tí nwọ́n ti mú nwọn, nwọ́n mú kí nwọ́n dá májẹ̀mú pé nwọn kò ní gbé ohun ìjà-ogun nwọn ti àwọn ará Nífáì mọ́.

17 Nígbàtí nwọ́n sì ti dá májẹ̀mú yĩ tán nwọ́n rán wọn láti máa bá àwọn ará Ámọ́nì gbé, nwọ́n sì pọ̀ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rin tí í ṣe àwọn tí a kò pa.

18 Ó sì ṣe nígbàtí nwọ́n ti rán nwọn jáde tán nwọ́n sì mú ìrìnàjò nwọn lọ sí apá ilẹ̀ Nífáìhà. Ó sì ṣe nígbàtí nwọ́n dé ìlú-nlá Nífáìhà, ni nwọ́n sì pàgọ́ nwọn sínú ọ̀dàn Nífáìhà, èyítí ó wà nítòsí ìlú-nlá Nífáìhà.

19 Nísisìyí Mórónì ní ìfẹ́ kí àwọn ará Lámánì jáde wá láti bá nwọn jà, lori ọ̀dàn nã; ṣùgbọ́n nítorítí àwọn ará Lámánì mọ̀ nípa ìgboyà nlá tí nwọ́n ní, àti tí nwọ́n sì rí pípọ̀ tí nwọ́n pọ̀ púpọ̀, nítorínã nwọn kò jẹ́ jáde wá láti kọlũ nwọ́n; nítorínã nwọn kò jáde láti jà ní ọjọ́ nã.

20 Nígbàtí alẹ́ sì lẹ́, Mórónì kọjá lọ nínú òkùnkùn alẹ́, ó sì wá sí órí odi ìlú nã láti ṣe amí apá ibití àwọn ará Lámánì pàgọ́ sí pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn.

21 Ó sì ṣe tí nwọ́n wà ní apá ìlà-oòrùn, lẹbá ọ̀nà àbáwọlé; nwọ́n sì nsùn. Àti nísisìyí ni Mórónì padà sí ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, ó sì mú kí nwọn ṣe àwọn okùn tí ó lágbára àti àwọn àkàbà, láti lè sọ̀ nwọ́n kalẹ̀ sínú ìlú láti orí odi ìlú nã.

22 Ó sì ṣe tí Mórónì mú kí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kọjá lọ kí nwọ́n lọ sí órí odi nã, kí nwọn ó sì sọ̀kalẹ̀ sí ibi apá ìlú-nlá nã, bẹ̃ni, àní ní apá ìwọ̀-oòrùn, níbití àwọn ará Lámánì kò pàgọ́ sí pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn.

23 Ó sì ṣe tí a sọ̀ gbogbo nwọn kalẹ̀ sínú ìlú-nlá nã ní òru, pẹ̀lú àwọn okùn nwọn tí ó lágbára àti àwọn àkàbà nwọn; báyĩ nígbàtí ilẹ̀ mọ́ gbogbo nwọn tí wà nínú odi ìlú-nlá nã.

24 Àti nísisìyí, nígbàtí àwọn ará Lámánì jí tí nwọn sì ríi pé àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mórónì ti wà nínú odi-ìlú nwọn, ẹ̀rù bà nwọ́n lọ́pọ̀lọpọ̀, tóbẹ̃ tí nwọ́n sá jáde láti ẹnu ọ̀nà ìlú.

25 Àti nísisìyí nígbàtí Mórónì ríi pé nwọ́n sálọ níwájú òun, ó mú kí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sá tẹ̀lé nwọn, nwọ́n sì pa púpọ̀, nwọ́n sì ká ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ́, nwọ́n sì mú nwọn lẹ́rú; àwọn tí ó kù sì sá lọ sínú ilẹ̀ Mórónì, tí ó wà létí agbègbè bèbè òkun.

26 Báyĩ sì ni Mórónì àti Pahoránì gba ìlú-nlá Nífáìhà ní áìpàdánù ẹ̀mí kankan; a sì pa púpọ̀ nínú àwọn ará Lámánì.

27 Nísisìyí ó sì ṣe tí púpọ̀ nínú àwọn ará Lámánì tí nwọ́n kó lẹ́rú ní ìfẹ́ láti darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn Ámọ́nì kí nwọ́n sì di ẹni òmìnira.

28 Ó sì ṣe tí a fi fún gbogbo àwọn tí ó ní ìfẹ́ bẹ̃ gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ inú nwọn.

29 Nítorínã, gbogbo àwọn ará Lámánì tí a mú lẹ́rú sì darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn Ámọ́nì, tí nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí ṣiṣẹ́ kárakára, tí nwọ́n dáko, tí nwọn ngbin onírurú ọkà, àti àwọn onírurú agbo àti ọ̀wọ́ ẹran; báyĩ sì ni àwọn ará Nífáì rí ìtura gbà kúrò lọ́wọ́ àjàgà nlá; bẹ̃ni, tóbẹ̃ tí nwọ́n fi rí ìtura lórí gbogbo àwọn ará Lámánì tí nwọ́n mú lẹ́rú.

30 Nísisìyí ó sì ṣe tí Mórónì, lẹ́hìn tí ó ti gba ìlú-nlá Nífáìhà, tí ó sì ti kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ lẹ́rú, èyítí ó mú kí àwọn ẹgbẹ́ ogun Lámánì ó dínkù lọ́pọ̀lọpọ̀, àti lẹ́hìn tí ó ti gba àwọn ará Nífáì tí a ti mú lẹ́rú padà, tí nwọ́n sì fi agbára kún ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mórónì lọ́pọ̀lọpọ̀; nítorínã Mórónì jáde lọ láti inú ilẹ̀ Nífáìhà lọ sínú ilẹ̀ Léhì.

31 Ó sì ṣe nígbàtí àwọn ará Lámánì ríi pé Mórónì nbọ̀ wá kọlũ nwọ́n, ẹ̀rù tún bà nwọ́n, nwọ́n sì sálọ kúrò níwájú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mórónì.

32 Ó sì ṣe tí Mórónì àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ sá tẹ̀lé nwọn láti ìlú-nlá dé ìlú-nlá, títí Léhì àti Tíákúmì fi bá nwọn pàdé; àwọn ará Lámánì nã sì sálọ kúrò níwájú Léhì àti Tíákúmì, àní títí dé etí agbègbè bèbè òkun, títí nwọn fi dé ilẹ̀ Mórónì.

33 Àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì sì kójọ papọ̀, tóbẹ̃ tí nwọ́n fi wà ní ọ̀kanṣoṣo nínú ilẹ̀ Mórónì. Nísisìyí Ámmórọ́nì, ọba àwọn ará Lámánì wà pẹ̀lú nwọn pẹ̀lú.

34 Ó sì ṣe tí Mórónì àti Léhì àti Tíákúmì sì pàgọ́ pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn yíká etí ilẹ̀ Mórónì, tóbẹ̃ tí nwọ́n yí àwọn ará Lámánì kákiri ní etí ilẹ̀ tí ó wà lẹba aginjù tí ó wà ní apá gũsù, àti ní etí ilẹ̀ tí ó wà lẹba aginjù tí ó wà ní apá ìlà-oòrùn.

35 Báyĩ sì ni nwọ́n pàgọ́ ní alẹ́ ọjọ́ nã. Nítorí kíyèsĩ, àwọn ará Nífáì àti àwọn ará Lámánì kãrẹ̀ nítorí ìrìnàjò tí ó gùn tí nwọ́n rìn; nítorínã nwọn kò pinnu lé ọgbọ́n àrékérekè kankan nígbàtí alẹ́ lẹ́, àfi Tíákúmì; nítorítí ó bínú gidigidi sí Ámmórọ́nì, tóbẹ̃ tí ó fi rõ pé Ámmórọ́nì, àti Amalikíà arákùnrin rẹ̀, ni nwọ́n ti mú kí ogun nlá wà lãrín nwọn àti àwọn ará Lámánì, èyítí ó ti fa ogun àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ púpọ̀, bẹ̃ni, àti ìyàn púpọ̀.

36 Ó sì ṣe tí Tíákúmì nínú ìbínú rẹ̀ nlá sì kọjá lọ sínú àgọ́ àwọn ará Lámánì, tí ó sì sọ ara rẹ̀ kalẹ̀ láti orí odi ìlú-nlá nã. Ó sì lọ pẹ̀lú okùn, láti ibìkan dé òmíràn, tóbẹ̃ tí ó sì rí ọba nã; ó sì ju ọ̀kọ̀ lũ, èyítí ó gun un lẹba ọkàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ọba nã jí àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ kí ó tó kú, tóbẹ̃ tí nwọ́n sì sá tẹ̀lé Tíákúmì, tí nwọ́n sì pã.

37 Nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Léhì àti Mórónì mọ̀ pé Tíákúmì ti kú nwọ́n banújẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀; nítorí kíyèsĩ ó jẹ́ ẹnìkan tí ó ti jagun pẹ̀lú ìgboyà fún orílẹ̀-èdè rẹ̀, bẹ̃ni, ọ̀rẹ́ òdodo sí òmìnira; ó sì ti faradà ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú tí ó pọ̀ púpọ̀. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ó ti kú, ó sì ti lọ síbití gbogbo ayé nre.

38 Nísisìyí ó sì ṣe tí Mórónì kọjá lọ ní ọjọ́ kejì, ó sì kọlũ àwọn ará Lámánì, tóbẹ̃ tí nwọ́n fi pa nwọ́n ní ìpakúpa; tí nwọ́n sì lé nwọn kúrò lórí ilẹ̀ nã; nwọ́n sì sálọ, àní tí nwọn kò padà ní àkókò nã láti kọlũ àwọn ará Nífáì.

39 Báyĩ sì ni ọdún kọkànlélọ́gbọ̀n nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì dópin; báyĩ sì ni nwọ́n ní àwọn ogun àti ìtàjẹ̀sílẹ̀, àti ìyàn, àti ìpọ́njú, fún ìwọ̀n ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún.

40 Ìpànìyàn, ìjà, àti ìyapa sì ti wà, àti onírurú àìṣedẽdé, lãrín àwọn ènìyàn Nífáì; bíótilẹ̀ríbẹ̃ nítorí àwọn olódodo, bẹ̃ni, nítorí àdúrà àwọn olódodo, Ọlọ́run dá nwọn sí.

41 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, nítorí ogun ọjọ́ pípẹ́ tí ó wà lãrín àwọn ará Nífáì àti àwọn ará Lámánì púpọ̀ nínú nwọn ti sé àyà nwọn le, nítorí ogun ọjọ́ pípẹ́ nã; púpọ̀ nínú nwọn sì rẹ ọkàn nwọn sílẹ̀ nítorí ìpọ́njú nwọn, tóbẹ̃ tí nwọ́n fi rẹ ara nwọn sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run, àní pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrẹra-ẹni sílẹ̀.

42 Ó sì ṣe nígbàtí Mórónì ti fi agbára kún àwọn apá ilẹ̀ wọnnì èyítí ó ṣí sílẹ̀ sí àwọn ará Lámánì, títí ó fi ní ágbára tó, ó padà sínú ìlú-nlá Sarahẹ́múlà; Hẹ́lámánì pẹ̀lú sí padà sí ìlú-ìní rẹ; àlãfíà sì tún padà fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ lãrín àwọn ènìyàn Nífáì.

43 Mórónì sì gbé ìdarí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ lé ọwọ́ ọmọ rẹ̀ ẹnití, orúkọ rẹ̀ njẹ Móróníhà; ó sì padà sí ilè ara rẹ̀ láti lè lo ìyókù ayé rẹ̀ ní àlãfíà.

44 Pahoránì sì padà sí órí ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀; Hẹ́lámánì sì gbà láti tún máa wãsù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí àwọn ènìyàn nã; nítorípé, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun àti ìjà ó ti di ohun tí ó yẹ láti tún fi ìlànà sílẹ̀ nínú ìjọ onígbàgbọ́.

45 Nítorínã, Hẹ́lámánì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jáde lọ, láti kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú agbára nlá sí ti yíyí ọkàn ènìyàn púpọ̀ padà kúrò nínú ìwà búburú nwọn, èyítí ó mú nwọn ronúpìwàdà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ nwọn àti láti rì wọn bọmi sí Olúwa Ọlọ́run nwọn.

46 Ó sì ṣe tí nwọ́n tún fi ìjọ Ọlọ́run lélẹ̀, jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ nã.

47 Bẹ̃ni, nwọ́n sì ṣe àwọn ìlànà nípa ti òfin. Nwọ́n sì yan àwọn onidajọ nwọn, àti àwọn onidajọ àgbà nwọn.

48 Àwọn ènìyàn Nífáì sì tún bẹ̀rẹ̀sí ṣe rere lórí ilẹ̀ nã, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí bí síi àti láti ní agbára púpọ̀ ní ilẹ̀ nã. Nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí ní ọrọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀.

49 Ṣùgbọ́n l’áìṣírò ọrọ̀ nwọn, tàbí agbára nwọn, tàbí ìlọsíwájú nwọn, nwọn kò gbé ara nwọn sókè nínú ìgbéraga; bẹ̃ sì ni nwọn kò lọ́ra láti rántí Olúwa Ọlọ́run nwọn; ṣùgbọ́n nwọ́n rẹ ara nwọn sílẹ̀ púpọ̀púpọ̀ níwájú rẹ̀.

50 Bẹ̃ni, nwọ́n sì rántí àwọn ohun nlá tí Olúwa ti ṣe fún nwọn, pé ó ti gbà nwọ́n kúrò lọ́wọ́ ikú, àti kúrò nínú ìdè, àti kuro nínú tũbú, àti kúrò lọ́wọ́ onírurú ìpọ́njú, ó sì ti gbà nwọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá nwọn.

51 Nwọ́n sì gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run nwọn láìsinmi, tóbẹ̃ tí Olúwa sì bùkún fún nwọn, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀, tí nwọ́n fi ní agbára tí nwọ́n sì nṣe rere lórí ilẹ̀ nã.

52 Ó sì ṣe tí ohun gbogbo wọ̀nyí di ìmúṣẹ. Hẹ́lámánì sì kú, ní ọdún karundínlógójì nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì.