Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 16


Orí 16

Àwọn ará Lámánì pa àwọn ará Amonáíhà run—Sórámù ṣíwájú àwọn ará Nífáì ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ará Lámánì—Álmà àti Ámúlẹ́kì pẹ̀lú àwọn púpọ̀ míràn wãsù ọ̀rọ̀ nã—Nwọ́n nkọ́ni pé lẹ́hìn àjĩnde rẹ̀, Krístì yíò farahàn sí àwọn ará Nífáì. Ní ìwọ̀n ọdún 81 sí 77 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe, ní ọdún kọkànlá ti ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Néfía, ní ọjọ́ kãrún oṣù kejì, lẹ́hìn tí àlãfíà púpọ̀ ti wà nínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, tí kò sí ogun tàbí ìjà fún iye ọdún kan, àní títí di ọjọ́ kãrún oṣù kejì ní ọdún kọkànlá, ìró igbe ogun tàn kálẹ̀ jákè-jádò ilẹ̀ nã.

2 Nítori kíyèsĩ, àwọn ọmọ ogun ará Lámánì ti dé sí ìhà aginjù sínú agbègbè ilẹ̀ nã, àní títí dé ìlú nlá Amonáíhà, tí nwọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀sí pa àwọn ènìyàn, tí nwọ́n sì npa ilú nã run.

3 Àti nísisìyí ó sì ṣe, kí àwọn ará Nífáì tó kó ọmọ ogun tí ó pọ̀ tó jọ láti lé nwọn jáde kúrò nínú ilẹ̀ nã, nwọn ti pa àwọn ènìyàn tí nwọ́n wà nínú ìlú nlá Amonáíhà run, àti pẹ̀lú àwọn tí nwọn wà ní agbègbè etí ìlú Nóà, nwọ́n sì ti kó àwọn míràn ní ìgbèkùn lọ sínú aginjù.

4 Nísisìyí ó sì ṣe tí àwọn ará Nífáì ní ìfẹ́ àti gba àwọn tí nwọ́n ti kó ní ìgbèkùn lọ sínú aginjù padà.

5 Nítorínã, ẹnití nwọ́n ti yàn ní olórí-ológun lórí àwọn ọmọ ogun àwọn ará Nífáì, (orúkọ rẹ̀ sì ni Sórámù, òun sì ní ọmọ-ọkùnrin méjì Léhì àti Áhà)—nísisìyí Sórámù àti àwọn ọmọ rẹ̀ méjẽjì, nítorípé nwọn mọ̀ pé Álmà jẹ́ olórí àlùfã ìjọ-onígbàgbọ́, tí nwọ́n sì ti gbọ́ pé òun ní ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀, nítorínã, nwọ́n tọ̃ lọ, nwọ́n sì ṣe ìwãdí lọ́wọ́ rẹ̀ láti mọ́ ibití Olúwa fẹ́ kí wọn ó lọ nínú aginjù, láti wá àwọn ará nwọn lọ, àwọn tí àwọn ará Lámánì ti kó ní ìgbèkùn.

6 Ó sì ṣe tí Álmà bẽrè lọ́wọ́ Olúwa nípa ọ̀rọ̀ nã. Álmà sì padà bọ ó sì wí fún nwọn pé: Ẹ kíyèsĩ, àwọn ará Lámánì yíò dá odò Sídónì kọjá ní apá gúsù aginjù, kọjá lọ sápá òkè ìhà agbègbè etí ilú ilẹ̀ Mántì. Sì wõ, ibẹ̀ ni ẹ̀yin yíò bá nwọn, ní apá ilà oòrùn odò Sídónì, ibẹ̀ ni Olúwa yíò fi àwọn ara yín tí àwọn ará Lámánì ti kó ní ìgbèkùn lée yín lọ́wọ́.

7 Ó sì ṣe tí Sórámù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ dá odò Sídónì kọjá, pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun wọn, wọ́n sì kọjá lọ sí ìhà àyíká Mántì, bọ́ sínú aginjù tí ó wà ní ìhà gúsù, èyítí ó wà ní ìhà ìlà-oòrùn Sídónì.

8 Nwọ́n sì kọlũ àwọn ọmọ ogun àwọn ará Lámánì, nwọn sì tú àwọn ará Lámánì ká, nwọ́n sì lé nwọn wọ inú aginjù lọ; nwọ́n sì kó àwọn ará nwọn, tí àwọn ará Lámánì ti kó ní ìgbèkùn, kò sì sí ẹnìkan tí ó ṣègbé nínú àwọn tí nwọ́n kó ní ìgbèkùn. Àwọn arákùnrin nwọn sì kó nwọn wá láti jogún ilẹ̀ nwọn.

9 Báyĩ sì ni ọdún kọkànlá àwọn onídàjọ́ dópin, tí a ti lé àwọn ará Lámánì jáde kúrò nínú ilẹ̀ nã, tí nwọ́n sì ti pa àwọn ará Amonáíhà run; bẹ̃ni, gbogbo ohun alãyè tí ó jẹ́ ti ará Amonáíhà ni nwọ́n parun, àti ìlú-nlá nwọn, èyítí nwọ́n ti sọ pé Ọlọ́run kò lè parun, nítorí títóbi rẹ̀.

10 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ní ọjọ́ kanṣoṣo ni ó di ahoro; tí àwọn òkú ènìyàn sì di ìjẹ fún àwọn ajá àti ẹranko ìgbẹ́ ní aginjù.

11 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, lẹ́hìn ọjọ́ pípẹ́, a kó àwọn òkú wọn yí jọ papọ̀ lórí ilẹ̀, nwọ́n sì bò nwọ́n fẹ́rẹ́fẹ́rẹ́. Àti nísisìyí õrùn tí ó njáde láti ibẹ̀ pọ̀ tó bẹ̃ tí àwọn ènìyàn kò lè wọ inú ilẹ̀ Amonáíhà fún ìjogún fún ọdún pípẹ́. A sì pẽ ní Ibi-Ahoro ti àwọn Néhórì; nítorípé àwọn tí a pa jẹ́ ti ipa ti Néhọ́rì; gbogbo ilẹ̀ nwọn sì wà ní ahoro síbẹ̀.

12 Àwọn ará Lámánì kò sì padà bọ̀ wá jagun pẹ̀lú àwọn ará Nífáì mọ́ títí di ọdún kẹrìnlá ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ará Nífáì. Báyĩ sì ni ó rí fún ọdún mẹ́ta tí àwọn ará Nífáì ní àlãfíà lórí ilẹ̀ nwọn gbogbo.

13 Álmà àti Ámúlẹ́kì sì jáde lọ, tí nwọ́n nwãsù ìrònúpìwàdà sí àwọn ènìyàn nã nínú tẹ́mpìlì nwọn, àti nínú ibi-mímọ́ nwọn, àti pẹ̀lú nínú sínágọ́gù nwọn, àwọn èyítí nwọ́n kọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìṣe àwọn Jũ.

14 Gbogbo àwọn tí nwọn yíò bá sì gbọ́ ọ̀rọ̀ nwọn, ni nwọ́n sì fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún, ní àìṣe ojúṣãjú ènìyàn, títí lọ.

15 Báyĩ sì ni Álmà àti Ámúlẹ́kì jáde lọ, àti àwọn míràn pẹ̀lú tí a ti yàn fún iṣẹ́ nã, láti wãsù ọ̀rọ̀ nã jákè-jádò ilẹ̀ nã. Ìdásílẹ̀ ìjọ-onígbàgbọ́ nã sì kárí gbogbo ilẹ̀ nã ní gbogbo agbègbè tí ó yíká kiri, lãrín gbogbo àwọn ará Nífáì.

16 Kò sì sí àìdọ́gba lãrín nwọn; Olúwa sì da Ẹ̀mí rẹ̀ sí órí gbogbo ilẹ̀ nã láti palẹ̀ ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn mọ́, tàbí láti palẹ̀ ọkàn nwọn mọ́ láti gba ọ̀rọ̀ nã èyítí yíò kọ́ nwọn nígbàtí yíò bá dé—

17 Pé kí nwọ́n ó máṣe sé ọkàn le sí ọ̀rọ̀-nã, kí nwọ́n máṣe jẹ́ aláìgbàgbọ́, kí nwọ́n sì lọ sínú ìparun, ṣùgbọ́n pé kí nwọ́n lè gba ọ̀rọ̀-nã pẹ̀lú ayọ̀, àti pé bí ẹ̀ká, kí nwọ́n di lílọ sínú ara àjàrà òtítọ́, tí nwọn yíò sì bọ́ sínú ìsinmi Olúwa Ọlọ́run nwọn.

18 Nísisìyí, àwọn àlùfã nnì tí nwọ́n ti kọjá lọ sí ãrin àwọn ènìyàn nã nwãsù tako gbogbo irọ́-pípa, àti ẹ̀tàn gbogbo, àti ìlara, àti ìjà, àti àrankàn, àti ìpẹ̀gàn, àti olè jíjà, ìfi ipá jalè, ìkógun, ìpànìyàn, híhu ìwà àgbèrè, àti onírurú ìwà ìfẹ́kúfẹ̃, tí nwọn sì nkígbe pé àwọn ohun wọ̀nyí kò gbọ́dọ̀ rí bẹ̃—

19 Tí nwọ́n sì nkéde àwọn ohun tí ó fẹ́rẹ̀ dé; bẹ̃ni, tí nwọn nkéde bíbọ̀ Ọmọ Ọlọ́run, ìjìyà àti ikú rẹ̀, àti àjĩnde òkú.

20 Púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn nã sì nbẽrè nípa ibití Ọmọ Ọlọ́run nã yíò ti wá; a sì kọ́ nwọn pé òun yíò farahàn nwọ́n lẹ́hìn àjĩnde rẹ̀; eleyĩ ni àwọn ènìyàn nã sì gbọ́ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ayọ̀ àti inúdídùn.

21 Àti nísisìyí, lẹ́hìn tí a ti fi ìjọ nã lélẹ̀ jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ nã—tí ó sì ti gba ìṣẹ́gun lórí èṣù, tí a sì nwãsù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní pípé rẹ̀ nínú ilẹ̀ nã gbogbo, tí Olúwa sì nda ìbùkún rẹ̀ sí órí àwọn ènìyàn nã—báyĩ ni ọdún kẹrìnlá ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì dé òpin.