Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 46


Orí 46

Amalikíà dìtẹ̀ láti di ọba—Mórónì gbé àsíá òmìnira sókè—Ó kó àwọn ènìyàn nã jọ láti dãbò bò ẹ̀sìn nwọn—Àwọn tí ó gbàgbọ́ nítõtọ́ ni a pè ní Onígbàgbọ́—Ọlọ́run yíò pa nínú ìyókù àwọn àtẹ̀lé Jósẹ́fù mọ́—Amalikíà pẹ̀lú àwọn olùyapa sálọ sí ilẹ̀ Nífáì—Àwọn tí ó kọ̀ láti ti jíjà fún-òmìnira nã lẹ́hìn ni nwọ́n pa. Ní ìwọ̀n ọdún 73 sí 72 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe tí gbogbo àwọn tí kò ní etí ìgbọràn sí àwọn ọ̀rọ̀ Hẹ́lámánì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ kó ara nwọn jọ ní ìtakò sí àwọn ará nwọn.

2 Àti nísisìyí kíyèsĩ, nwọ́n bínú gidigidi, tó bẹ̃ tí nwọ́n pinnu láti pa nwọ́n.

3 Nísisìyí olórí àwọn tí nbínú sí àwọn arákùnrin nwọn ni ọkùnrin títóbi àti alágbára kan; orúkọ rẹ̀ sì ni Amalikíà.

4 Amalikíà sì fẹ́ láti jẹ ọba; àwọn ènìyàn tí nwọn nbínú nã sì fẹ́ kí ó jẹ́ ọba nwọn; púpọ̀ nínú nwọn ni nwọ́n sì jẹ́ onídàjọ́ ní ilẹ̀ nã, nwọ́n sì nwá agbára.

5 Ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn Amalikíà sì darí nwọn, pé bí nwọ́n bá ti òun lẹ́hìn tí nwọ́n sì fi òun ṣe ọba nwọn pé òun yíò fi nwọ́n ṣe olórí lórí àwọn ènìyàn nã.

6 Báyĩ sì ni Amalikíà darí nwọn lọ sí tí ìyapa, l’áìṣírò fún ìwãsù Hẹ́lámánì àti àwọn arákùnrin rẹ̀, bẹ̃ni, l’áìṣírò fún ìtọ́jú nlá tí nwọn fún ìjọ-onígbàgbọ́ nã, nítorí olórí àlùfã ni nwọn í ṣe lórí ìjọ nã.

7 Púpọ̀ ni ó sì wà nínú ìjọ nã tí nwọ́n gba ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn Amalikíà gbọ́, nítorínã nwọ́n yapa kúrò nínú ìjọ onígbàgbọ́ nã pãpã; báyĩ sì ni ìṣe àwọn ènìyàn Nífáì wà ní ipò àìdánilójú àti ewu, l’áìṣírò fún ìṣẹ́gun nlá tí nwọ́n ti ní lórí àwọn ará Lámánì, àti ayọ̀ nlá tí nwọ́n ti ní nítorí ìtúsílẹ̀ nwọn nípa ọwọ́ Olúwa.

8 Báyĩ ni a ríi bí àwọn ọmọ ènìyàn ṣe yára tó láti gbàgbé Olúwa Ọlọ́run nwọn, bẹ̃ni, bí nwọ́n ṣe yára tó láti ṣe àìṣedẽdé, àti láti ṣìnà nípasẹ̀ ẹni búburú nnì.

9 Bẹ̃ni, a sì tún rí ìwà búburú nlá tí ẹyọ ènìyàn kan tí ó burú púpọ̀ lè mú kí ó ṣẹlẹ̀ lãrín àwọn ọmọ ènìyàn.

10 Bẹ̃ni, a ríi pé Amalikíà, nítorípé ó jẹ́ ẹni ọlọ́gbọ́n àrekérekè àti ẹni tĩ máa sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn púpọ̀, pé ó darí ọkàn àwọn ènìyàn púpọ̀ sí ṣíṣe búburú; bẹ̃ni àti láti lépa láti pa ìjọ Ọlọ́run run, àti láti pa ìpilẹ̀ṣẹ̀ òmìnira èyítí Ọlọ́run ti fifún nwọn, tàbí ìbùkún nnì èyítí Ọlọ́run ti rán wa sí orí ilẹ̀ ayé nítorí àwọn olódodo.

11 Àti nísisìyí ó sì ṣe pé nígbàtí Mórónì, ẹnití í ṣe olórí ológun àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Nífáì, ti gbọ́ nípa àwọn ìyapa wọ̀nyí, ó bínú sí Amalikíà.

12 Ó sì ṣe tí ó fa ẹ̀wù rẹ̀ ya; tí ó sì mú ìrépé nínú rẹ̀, ó sì kọ lé orí rẹ̀—Ní ìrántí Ọlọ́run wa, ẹ̀sìn wa, àti òmìnira, àti àlãfíà wa, àwọn ìyàwó wa, àti àwọn ọmọ wa—ó sì soó mọ́ ìkangun ọ̀pá kan.

13 Ó sì dé ìhámọ́ra àṣíborí rẹ̀, àti àwo àyà rẹ̀, àti àwọn asà àti apata rẹ̀, ó sì de ìhámọ́ra rẹ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ rẹ̀; ó sì mú ọ̀pá nã, èyítí ẹ̀wú rẹ̀ tí ó ya wà ní ìkangun rẹ̀, (ó sì pẽ ní àsíá òmìnira) ó sì wólẹ̀ lórí ilẹ̀, ó sì gbàdúrà tagbáratagbára sí Ọlọ́run rẹ̀ kí ìbùkún òmìnira lè bà lé àwọn arákùnrin rẹ̀, níwọ̀n ìgbàtí agbo àwọn Krístíánì bá fi lè kù tí yíò ní ilẹ̀ nã ní ìní—

14 Nítorí báyĩ ni gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́ nínú Krístì nítõtọ́, tí nwọ́n jẹ́ ti ìjọ Ọlọ́run njẹ́ pípè láti ọwọ́ àwọn tí kò jẹ́ ti ìjọ Ọlọ́run.

15 Àwọn tí nwọ́n sì jẹ́ ti ìjọ nã jẹ́ olódodo; bẹ̃ni, gbogbo àwọn tí nwọ́n jẹ́ onígbàgbọ́ òtítọ́ nínú Krístì, gba orúkọ Krístì tayọ̀tayọ̀, tàbí Krístíánì ni a ti npè nwọ́n, nítorí ti ìgbàgbọ́ nwọn nínú Krístì èyítí nbọ̀wá.

16 Nítorínã ẹ̀wẹ̀, ní àkokò yĩ, Mórónì gbàdúrà pé kí ìjà-òmìnira àwọn Krístíánì, àti ti ilẹ̀ nã kí ó rí ojúrere Ọlọ́run.

17 Ó sì ṣe pé nígbàtí ó ti fi tọkàn-tọkàn gbàdúrà sí Ọlọ́run, ó pe gbogbo ilẹ̀ tí ó wà ní ìhà gũsù ilẹ̀ nã ní Ibi-Ahoro, bẹ̃ni, àti ní ṣókí, gbogbo ilẹ̀ nã, pẹ̀lú èyítí ó wà ní ìhà àríwá àti ní ìhà gũsù—Ilẹ̀ ãyò, àti ilẹ̀ òmìnira.

18 Ó sì wípé: Dájudájú Ọlọ́run kì yíò jẹ́ kí àwa, tí nwọ́n ti pẹ̀gàn wa nítorípé a gba orúkọ Krístì, kí nwọ́n borí wa kí nwọ́n sì pa wá run, títí àwa yíò fi múu wá sórí wa nípasẹ̀ ìwàirékọjá wa.

19 Nígbàtí Mórónì sì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tán, ó kọjá lọ sí ãrin àwọn ènìyàn nã, tí ó sì nju ìrépé ẹ̀wú rẹ̀ ní òfúrufú, pé kí gbogbo nwọn lè rí ohun tí òun ti kọ lé ìrépé ẹ̀wù rẹ̀ nã, tí ó sì nkígbe pẹ̀lú ohùn rara, wípé:

20 Ẹ kíyèsĩ, ẹnìkẹ́ni tí yíò bá mú àṣíá yĩ dúró lórí ilẹ̀ yĩ, kí nwọ́n jáde wá ní agbára Olúwa, kí ó sì dá májẹ̀mú pé nwọn yíò mú ẹ̀tọ́ nwọn dúró, àti ẹ̀sìn nwọn, kí Olúwa Ọlọ́run kí ó lè bùkún nwọn.

21 Ó sì ṣe nígbàtí Mórónì ti ṣe ìkéde àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, kíyèsĩ, àwọn ènìyàn nã sáré wá pẹ̀lú ìhámọ́ra nwọn ní ẹ̀gbẹ́ nwọn, tí nwọ́n fa ẹ̀wù nwọn ya gẹ́gẹ́bí àmì, tàbí gẹ́gẹ́bí májẹ̀mú, pé nwọn kò ní kọ̀ Olúwa Ọlọ́run nwọn sílẹ̀; tàbí, kí a wípé, bí nwọ́n bá ré àwọn òfin Ọlọ́run kọjá, tàbí kí nwọ́n ṣubú sínú ìrékọjá, tí ojú sì tì nwọ́n láti gba orúkọ Krístì, Olúwa yíò fà nwọ́n ya àní gẹ́gẹ́bí nwọn ti ṣe fa ẹ̀wù nwọn ya.

22 Nísisìyí èyí ni májẹ̀mú tí nwọ́n dá, nwọ́n sì bọ́ ẹ̀wù nwọn sí abẹ́ ẹsẹ̀ Mórónì, nwọ́n sì wípé: Àwa bá Ọlọ́run wa dá májẹ̀mú, pé àwa ó parun, àní gẹ́gẹ́bí àwọn arákùnrin wa ní ilẹ̀ tí ó wà ní ìhà àríwá, bí àwa bá ṣubú sínú ìrékọjá; bẹ̃ni, òun yíò fi wá sí abẹ́ ẹsẹ̀ àwọn ọ̀tá wa, àní gẹ́gẹ́bí àwa ti ṣe bọ́ ẹ̀wù wa sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ fún ìtẹ̀mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀, bí àwa bá ṣubú sínú ìrékọjá.

23 Mórónì wí fún nwọn pé: Ẹ kíyèsĩ, iṣẹ́kù irú-ọmọ Jákọ́bù ni àwa í ṣe; bẹ̃ni, ìṣẹ́kù irú-ọmọ Jósẹ́fù ni àwa í ṣe, ẹ̀wù ẹnití àwọn arákùnrin rẹ̀ fàya sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrépé; bẹ̃ni àti nísisìyí kíyèsĩ, ẹ́ jẹ́ kí àwa ó rántí láti pa òfin Ọlọ́run mọ́, láìjẹ́bẹ̃ àwọn arákùnrin wa yíò fa ẹ̀wù wa ya, nwọn ó sì gbé wa sínú tũbú, tàbí kí nwọn tà wá, tàbí pa wá.

24 Bẹ̃ni, ẹ jẹ́ kí a pa òmìnira wa mọ́ gẹ́gẹ́bí ìyókù àwọn àtẹ̀lé Jósẹ́fù; bẹ̃ni, ẹ jẹ́ kí a rántí àwọn ọ̀rọ̀ Jákọ́bù, ṣãjú ikú rẹ̀, nítorí kíyèsĩ, ó ríi pé apá kan nínú ìrépé ẹ̀wù Jósẹ́fù wà ní ìpamọ́ tí kò sì gbó. O sì wípé—Àní gẹ́gẹ́bí ìrépé ẹ̀wù ọmọ mi yĩ ṣe wà ní ìpamọ́, bẹ̃ nã ni ìyókù àwọn àtẹ̀lé irú-ọmọ ọmọ mi yíò wà ní ìpamọ́ nípa ọwọ́ Ọlọ́run, tí yíò sì mú nwọn lọ sí ọ́dọ̀ ara rẹ̀, tí àwọn irú-ọmọ Jósẹ́fù yókù yíò sì parun, àní gẹ́gẹ́bí ìrépé ẹ̀wù rẹ̀.

25 Nísisìyí, ẹ kíyèsĩ, ohun yĩ fún ọkàn mi ní ìbànújẹ́; bíótilẹ̀ríbẹ̃, ọkàn mi yọ̀ nínú ọmọ mi, nítorí ti apá kan irú-ọmọ rẹ̀ nnì èyítí a ó mú lọ sí ọ́dọ̀ Ọlọ́run.

26 Nísisìyí ẹ kíyèsĩ, èyí ni èdè Jákọ́bù.

27 Àti nísisìyí tani ó mọ̀ bóyá ìyókù àwọn àtẹ̀lé irú-ọmọ Jósẹ́fù, èyítí yíò parun gẹ́gẹ́bí ti ẹ̀wù rẹ̀, ni àwọn tí nwọn ti yapa kúrò lára wa? Bẹ̃ni, àti pãpã yíò jẹ́ àwa fúnra wa bí àwa kò bá dúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́ Krístì.

28 Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Mórónì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tán ó jáde lọ ó sì tún ránṣẹ́ lọ sí gbogbo apá ilẹ̀ nã níbití ìyapa wà, ó sì kó gbogbo àwọn ènìyàn tí nwọn ní ìfẹ́ láti di òmìnira nwọn mú papọ̀, láti tako Amalikíà àti àwọn tí nwọ́n ti yapa, tí nwọn npè ní àwọn ará Amalikíà.

29 Ó sì tún ṣe nígbàtí Amalikíà ríi pé àwọn ènìyàn Mórónì pọ̀ púpọ̀ ju àwọn ará Amalikíà lọ—tí ó sì ríi pé àwọn ènìyàn òun nṣiyèméjì nípa àìṣègbè tí nbẹ nínú ìjà èyítí nwọ́n ti dáwọ́lé—nítorínã, nítorípé ó bẹ̀rù pé òun kò ní borí, ó mú nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ tí ó ṣetán nwọ́n sì kọjá lọ sínú ilẹ̀ Nífáì.

30 Nísisìyí Mórónì wòye pé àwọn ará Lámánì kò lè lágbára mọ́; nítorínã o gbèrò láti dínà mọ́ àwọn ará Amalikíà, tàbí kí ó mú nwọn kí ó sì kó nwọn padà, kí ó sì pa Amalikíà; bẹ̃ni, nítorítí ó mọ̀ pé yíò rú àwọn ará Lámánì sókè sí ìbínú sí nwọn, tí yíò sì mú nwọn wá láti bá nwọn jagun; èyí ni ó sì mọ̀ pé Amalikíà yíò ṣe láti lè mú ète rẹ̀ ṣẹ.

31 Nítorínã Mórónì rõ pé ó tọ́ fún òun láti kó àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, tí nwọ́n ti kó ara nwọn jọ, tí nwọ́n sì ti gbé ìhámọ́ra ogun wọ̀, tí nwọ́n sì ti dá májẹ̀mú ìwàlálãfíà—ó sì ṣe tí ó kó ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ tí nwọ́n sì kọjá lọ pẹ̀lú àwọn àgọ́ nwọn sínú aginjù, láti dínà mọ́ Amalikíà nínú aginjù.

32 Ó sì ṣe tí ó ṣe gẹ́gẹ́bí ìfẹ́-inú rẹ̀, tí ó sì kọjá lọ sínú aginjù, tí ó sì lọ ṣíwájú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Amalikíà.

33 Ó sì ṣe tí Amalikíà sá pẹ̀lú díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀, tí a sì fi àwọn tí ó kù lé ọwọ́ Mórónì tí ó sì kó nwọn padà lọ sí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà.

34 Nísisìyí, Mórónì nítorítí ó jẹ́ ẹni tí àwọn onídàjọ́ àgbà àti ohùn àwọn ènìyàn nã yàn, nítorínã ó ní àṣẹ bí ó bá ti fẹ́ lórí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Nífáì, láti fi lọ́lẹ̀ àti láti lõ lórí nwọn.

35 Ó sì ṣe tí ẹnìkẹ́ni nínú àwọn ará Amalikíà tí kò bá dá májẹ̀mú láti ti ìjà-òmìnira nnì lẹ́hìn, láti ní ìjọba olómìnira, ni ó mú kí nwọ́n pa; díẹ̀ sì ni àwọn tí ó sẹ́ májẹ̀mú òmìnira nã.

36 Ó sì tún ṣe pẹ̀lú, tí ó mú kí a ta àṣíá òmìnira nã sókè lórí gbogbo ilé ìṣọ́ gíga tí ó wà ní gbogbo ilẹ̀ nã, èyítí àwọn ará Nífáì ní ní ìní; báyĩ sì ni Mórónì fi àsíá òmìnira lélẹ̀ lãrín àwọn ará Nífáì.

37 Nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí ní àlãfíà ní ilẹ̀ nã; bẹ̃ sì ni nwọ́n wà lálãfíà ní ilẹ̀ nã títí di ìgbà tí ọdún kọkàndínlógún ìjọba àwọn onídàjọ́ fẹ́rẹ̀ dópin.

38 Hẹ́lámánì àti àwọn olórí àlùfã nã pẹ̀lú ṣe àkóso nínú ìjọ nã; bẹ̃ni, àní fún ìwọ̀n ọdún mẹ́rin ni nwọ́n ní ọ̀pọ̀ àlãfíà, àti ayọ̀ ní ti ìjọ nã.

39 Ó sì ṣe tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kú, nínú ìgbàgbọ́ pé ẹ̀mí nwọn ti di ìràpadà nípasẹ̀ Jésù Krístì Olúwa; bẹ̃ sì ni nwọ́n jáde kúrò láyé pẹ̀lú ìdùnnú.

40 Àwọn míràn wà tí nwọ́n kú pẹ̀lú àìsàn ìgbóná-ara, èyítí ó wọ́pọ̀ ní ilẹ̀ nã ní àwọn àkokò kan nínú ọdún—ṣùgbọ́n kì í ṣe ìgbóná-ara ni ó pa nwọ́n tó bẹ̃, nítorípé Ọlọ́run ti pèsè àwọn ewéko àti egbò dídára tí yíò mú àwọn àrun nã kúrò, àwọn èyítí íkọlu ènìyàn gẹ́gẹ́bí afẹ́fẹ́ ilẹ̀—

41 Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó kú lẹ́hìn tí nwọ́n ti di arúgbó; àwọn tí nwọ́n sì kú nínú ìgbàgbọ́ nínú Krístì ní ayọ̀ nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́bí àwa ṣe gbọ́dọ̀ mọ̀.