Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 5


Àwọn ọ̀rọ̀ tí Álmà, ẹ̀nití íṣe Olórí Àlùfã gẹ́gẹ́bí ti ẹgbẹ́ mímọ́ Ọlọ́run, fi lélẹ̀ fún àwọn ènìyàn nínú àwọn ìlú ńlá àti ìletò nwọn jákè-jádò ilẹ̀ nã.

Èyítí a kọ sí orí 5.

Orí 5

Lati lè rí ìgbàlà, ènìyàn gbọdọ̀ ronúpìwàdà, kí ó sì pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, kí ó di àtúnbí, kí ó fọ aṣọ rẹ̀ mọ̀ nípa ẹ̀jẹ̀ Krístì, kí ó ní ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn, kí ó sì bọ́ ẹ̀wù ìgbéraga àti ìlara sílẹ̀, kí ó sì máa ṣe iṣẹ́ òdodo—Olùṣọ́-Àgùtàn Rere npe àwọn ènìyàn rẹ̀—Àwọn tí nwọ́n bá nṣe iṣẹ́ búburú ní íṣe ọmọ èṣù—Álmà jẹ́ ẹ̀rí sí òtítọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀ ó sì pã láṣẹ pé kí àwọn ènìyàn ronúpìwàdà—Orúkọ àwọn olódodo ni a ó kọ sínú ìwé ìyè. Ní ìwọ̀n ọdún 83 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Nísisìyí ó sì ṣe tí Álmà bẹ̀rẹ̀sí fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún àwọn ènìyàn nã, ní àkọ́kọ́ ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, àti jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ nã.

2 Àwọn wọ̀nyí sì ni ọ̀rọ̀ tí ó sọ fún àwọn ènìyàn ìjọ-onígbàgbọ́ èyítí a dá sílẹ̀ nínú ìlú nlá Sarahẹ́múlà, gẹ́gẹ́bí àkọsílẹ̀ rẹ̀, tí ó wípé:

3 Èmi, Álmà, ẹnití bàbá mi, Álmà ti yà sọ́tọ̀ láti jẹ́ olórí àlùfã lórí ìjọ-Ọlọ́run, ẹnití ó ní agbára àti àṣẹ láti ọwọ́ Ọlọ́run fún ṣíṣe àwọn ohun wọ̀nyí, kíyèsĩ, Èmi wí fún yín pé òun bẹ̀rẹ̀sí dá ìjọ sílẹ̀ ní ilẹ̀ tí ó wà ní ìhà ilẹ̀ Nífáì; bẹ̃ni, ilẹ̀ èyítí à npè ní ilẹ̀ ti Mọ́mọ́nì; bẹ̃ni, òun sì ri àwọn arákùnrin rẹ̀ bọmi nínú omi Mọ́mọ́nì.

4 Sì kíyèsĩ, mo wí fún yín, a kó nwọn yọ kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ọba Nóà, nípa ãnú àti agbára Ọlọ́run.

5 Sì kíyèsĩ, lẹ́hìn èyíi nì, a mú nwọn wá sínú ìgbèkùn nípa ọwọ́ àwọn ará Lámánì nínú aginjù; bẹ̃ni, mo wí fún yín, nwọ́n wà nínú oko-ẹrú, Olúwa sì tún kó nwọn yọ kúrò nínú oko-ẹrú nípa agbára ọ̀rọ̀ rẹ̀; Olúwa sì mú wa jáde wá sínú ilẹ̀ yí, ní ìhín yĩ ni àwa sì bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìdásílẹ̀ ìjọ-Ọlọ́run jákè-jádò ilẹ̀ yí pẹ̀lú.

6 Àti nísisìyí kíyèsĩ, èmi wí fún un yín, ẹ̀yin arákùnrin mi, ẹ̀yin tí íṣe ti ìjọ-onígbàgbọ́ yĩ, njẹ́ ẹ̀yin ní ìrántí tí ó péye tó nípa ìgbèkun àwọn bàbá nyín? Bẹ̃ni, njẹ́ ẹ̀yin ní ìrántí tí ó péye nípa ãnú àti ìpamọ́ra rẹ̀ sí nwọn? Síbẹ̀síbẹ̀ pẹ̀lú, njẹ́ ẹ̀yin ní ìràntí tí ó péye pé òun ti gba ẹ̀mí nwọn kúrò nínú ọ̀run-àpãdì?

7 Kíyèsĩ, ó yí ọkàn nwọn padà; bẹ̃ni, ó ta nwọ́n jí kúrò nínú õrun àsùnwọra, nwọn sì tají sí ìpè Ọlọ́run. Kíyèsĩ, nwọ́n wà nínú òkùnkùn; bíótilẹ̀ríbẹ̃, a tan ìmọ́lẹ̀ sí ọkàn nwọn nípa ìmọ́lẹ̀ ọ̀rọ̀ ayérayé; bẹ̃ni ìdè ikú yí nwọn ká, pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n ọ̀run-àpãdì, ìparun ayérayé sí dúró dè nwọ́n.

8 Àti nísisìyí, èmi bí yín, ẹ̀yin arákùnrin mi, njẹ́ a pa nwọ́n run? Kíyèsĩ èmi wí fún un yín, Rárá, a kò pa nwọ́n run.

9 Èmi tún bí yín, njẹ́ ìdè ikú já? Pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n ọ̀run-àpãdì tí ó dè nwọ́n, njẹ́ a tú nwọn? Èmi wí fún un yín, bẹ̃ni, nwọ́n di títú, ọkàn nwọn sì kún fún ayọ̀ àti inú dídùn, nwọ́n sì kọrin ìfẹ́ ti ìràpadà. Èmi sì wí fún yín pé a gbà nwọ́n là.

10 Àti nísisìyí èmi bí yín pé báwo ni nwọ́n ṣe di ẹni ìgbàlà? Bẹ̃ni, báwo ni nwọ́n ṣe ní ìrètí fún ìgbàlà? Kíni ìdí tí a fi tú nwọn sílẹ̀ nínú ìdè ikú, bẹ̃ni, àti ẹ̀wọ̀n ọ̀run-àpãdì pẹ̀lú?

11 Kíyèsĩ, èmi lè sọ fún un yín—njẹ́ bàbá mi Álmà kò ha gbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ ti a sọ láti ẹnu Ábínádì? Njẹ́ kĩ ha íṣe wòlĩ mímọ́? Njẹ́ kò ha sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ti Bàbá mi Álmà sì gbã wọ́n gbọ́?

12 Gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ rẹ̀ pẹ̀lú, àyípadà nlá sì bá ọkàn rẹ̀, kíyèsĩ, èmi wí fún un yín pé òtítọ́ ni gbogbo nkan wọ̀nyí.

13 Sì kíyèsĩ, ó kéde ọ̀rọ̀ nã fún àwọn bàbá a yín, àyípadà nlá sì bá ọkàn nwọn, nwọ́n sì rẹ ọkàn nwọn sílẹ̀, nwọ́n sì gbẹ́kẹ̀ nwọn lé Ọlọ́run òtítọ́ àti alãyè. Sì kíyèsĩ, nwọ́n jẹ́ olótĩtọ́ títí dé òpin; nítorínã ni a ṣe gbà nwọ́n là.

14 Àti nísisìyí kíyèsĩ, mo bẽrè lọ́wọ́ yín, ẹ̀yin arákùnrin mi nínú ìjọ onígbàgbọ́, njẹ́ a ti bí yin ní ti ẹ̀mí nípa ti Ọlọ́run? Njẹ́ ẹ̀yin ti gba àwòrán rẹ nínú ìrísí yín? Njẹ́ ẹ̀yin ti ní ìrírí ìyípadà nlá yìi ní ọkàn yín bí?

15 Njẹ́ ẹ̀yin ní ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà ẹni nã tí ó dáa yín? Njẹ́ ẹ̀yin nwo iwájú pẹ̀lú ojú ìgbàgbọ́, tí ẹ̀yin sì nwòye ara kíkú yĩ tí a gbé dìde ní aìkú, àti ara ìdibàjẹ́ yĩ tí a gbé dìde ní àìdíbàjẹ́, kí ẹ̀yin lè dúró níwájú Ọlọ́run fún ìdájọ́ lórí àwọn ohun tí a ti ṣe nínú ara kíkú?

16 Èmi wí fún yín, njẹ́ ẹ̀yin lè wòye pé ẹ gbọ́ ohùn Olúwa, tí yíò wí fún yín, ní ọjọ́ nã: Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin alábùkún-fún, nítorí kíyèsĩ, àwọn iṣẹ́ rẹ ti jẹ́ iṣẹ́ òdodo ni orí ilẹ̀ ayé?

17 Bóyá ẹ̀yin lérò wípé ẹ̀yin lè purọ́ níwájú Olúwa ní ọjọ́ nã, kí ẹ̀yin sì wípé—Olúwa, òdodo ni àwọn iṣẹ́ wa ní orí ilẹ̀ áyé—tí òun yíò sì gbà yín là?

18 Tàbí, ẹ̀wẹ̀, njẹ́ ẹ̀yin wòye pé tí a bá mú un yín wá sí iwájú ìdájọ́ Ọlọ́run pẹ̀lú ọkàn an yín tí ó kún fún ẹ̀bi àti àbámọ̀, tí ẹ̀yin sì ní ìrántí fún gbogbo ẹ̀bi yín, bẹ̃ni, ìrántí tí ó yè koro fún gbogbo ìwà búburú u yín, bẹ̃ni, ìrántí pé ẹ̀yin ti ṣe àìbìkítà àwọn òfin Ọlọ́run?

19 Èmi wí fún un yín, njẹ́ ẹ̀yin le gbe ojú sókè si Ọlọ́run ni ọjọ naa pẹlu ọkan mimọ ati ọwọ ti ko ni èérí? Mo wi fun yin, njẹ́ ẹ̀yin lè gbé ojú sókè, wípé ẹ̀yà àwòrán Ọlọ́run ti di fífín sí ìrísí nyín?

20 Mo wí fún un yín, njẹ́ ẹ̀yin lè gbèrò láti rí ìgbàlà nígbàtí ẹ̀yin ti jọ̀wọ́ ara yín láti jẹ́ ọmọ-lẹ́hìn èṣù bí?

21 Mo wí fún yín, ẹ̀yin yíò mọ̀ ní ọjọ́ nnì pé ẹ̀yin kò lè rí ìgbàlà; nítorĩ a kò lè gba ẹnìkẹ́ni là àfi tí a bá sọ ẹ̀wù nwọn di funfun; bẹ̃ni, ẹ̀wù rẹ̀ níláti di mímọ́ títí a ó fi wẹ gbogbo ẽrí kúrò lára nwọn, nípa ẹ̀jẹ̀ ẹni nã ẹnití a ti sọ nípa rẹ̀ láti ẹnu àwọn bàbá wa, ẹnití ó nbọ̀wá láti ra àwọn ènìyàn rẹ̀ padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ nwọn.

22 Àti nísisìyí èmi bẽrè lọ́wọ́ ọ yín, ẹyin arákùnrin mi, báwo ni ẹnìkẹ́ni nínú u yín yíò ṣe rò, tí ẹ bá dúró níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run, tí aṣọ yín sì ní àbàwọ́n ẹ̀jẹ̀ àti onírurú ẹ̀gbin? Wòo, kí ni àwọn ohun wọ̀nyí jẹ́rĩ sí nípa yín?

23 Ẹ kíyèsĩ njẹ́ nwọn kò ní jẹ́rĩ pé apànìyàn ni ẹ̀yin íṣe, bẹ̃ni, àti pé ẹ̀yin jẹ̀bi onírũrú ìwà búburú bí?

24 Ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin arákùnrin mi, njẹ́ ẹ̀yin lérò pé irú ẹni báyĩ ni ãyè láti jókõ nínú ìjọba Ọlọ́run, pẹ̀lú Ábráhámù, pẹ̀lú Ísãkì, ati pẹ̀lú Jákọ́bù, àti pẹ̀lú gbogbo àwọn wòlĩ mímọ́, tí aṣọ nwọn ti mọ́, tí nwọ́n sì wà láìlẽrĩ, láìlábàwọ́n àti ní funfun?

25 Mo wí fún yín, Rárá; àfi bí ẹ̀yin bá mú Ẹlẹ́dã wa ní èké láti ìbẹ̀rẹ̀ wá, tàbí kí ẹ rò pé èké ni íṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ wá ẹ̀yin kò ní èrò pé irú eleyĩ lè ní ãyè nínú ìjọba ọ̀run; ṣùgbọ́n a ó ta wọ́n nù, nítorítí ọmọ ìjọba èṣù ni wọn íṣe.

26 Àti nísisìyí kíyèsĩ, mo wí fún un yín, ẹ̀yin arákùnrin mi, tí ẹ̀yin bá ti rí ìyípadà ọkàn, tí ẹ̀yin bá sì fẹ́ láti kọ orin ìfẹ́ ti ìràpadà, mo bẽrè, njẹ́ ẹ̀yin sì fẹ́ bẹ̃ bí?

27 Njẹ́ ẹ̀yin ha ti nrìn, tí ẹ sì npa ara nyín mọ́ láìlẹ́bi níwájú Ọlọ́run? Njẹ́ ẹ̀yin lè sọ, nínú ọkàn an yín, tí a bá yàn an fún un yín láti kú ní báyĩ, pé ẹ̀yin ti rẹ ara yín sílẹ̀ tó bẹ̃? Pé aṣọ ọ yín ti wà láìlẽrĩ, ó sì ti di funfun nípa ẹ̀jẹ̀ Krístì, ẹnití yíò wá láti ra àwọn ènìyàn rẹ̀ padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀?

28 Ẹ kíyèsĩ, njẹ́ ẹ̀yin ti bọ́ èwù ìgbéraga sílẹ̀? Mo wí fún yín, tí kò bá rí bẹ̃ ẹ̀yin kò ì tĩ ṣetán láti bá Ọlọ́run pàdé. Kíyèsĩ ẹ̀yin níláti múrasílẹ̀ ní kánkán; nítorí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀, irú eleyĩ kò sì ní ìyè àìnípẹ̀kun.

29 Ẹ kíyèsĩ, mo wípé, njẹ́ a rí nínú yín ẹnití kò bọ́ ẹ̀wù ìlara? Mo wí fún yín pé eleyĩ kò tĩ múrasílẹ̀; èmi sì rọ̃ pé kí ó múrasílẹ̀ kánkán, nítorítí wákàtí nã ti dé tán, òun kò sì mọ́ àkokò tí ìgbà nã yíò dé; nítorítí a kò ní ṣe aláì dá eleyĩ lẹ́bi.

30 Èmi sì tún wí fún yín, njẹ́ a rí nínú u yín ẹnití ó nfi arákùnrin rẹ̀ ṣe ẹlẹ́yà, tàbí tí ó nṣe inúnibíni sí bí?

31 Ègbé ni fún eleyĩ, nítorítí kò wà ní ìmúrasílẹ̀, àkokò nã sì ti dé tán tí o níláti ronúpìwàdà, bí kò rí bẹ̃, a kò lè gbã là!

32 Bẹ̃ni, ègbé ni fún gbogbo ẹ̀yin oníṣẹ ẹ̀ṣẹ̀; ẹ ronúpìwàdà, ẹ ronúpìwàdà, nítorítí Olúwa Ọlọ́run ni ó wíi !

33 Ẹ kíyèsĩ, ó rán ìpè sí gbogbo ènìyàn, nítorípé ó na ọwọ́ ãnú rẹ̀ sí nwọn, òun sì wípé: Ẹ ronúpìwàdà, èmi yíò sì gbà yín.

34 Bẹ̃ni, ó wípé: Ẹ wá sí ọ̀dọ̀ mi, ẹ̀yin yíò sì pín nínú èso igi ìyè nã; bẹ̃ni, ẹ̀yin yíò jẹ, ẹ ó mú nínú oúnjẹ àti omi ìyè nã lọ́fẹ̃;

35 Bẹ̃ni, ẹ wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí ẹ sì mú iṣẹ́ ìṣòdodo yín wá, a kò sì ní kée yín lulẹ̀ kí a sì sọ yín sínú iná—

36 Nítorí ẹ kíyèsĩ, àkokò nã ti dé tán tí ẹnìkẹ́ni tí kò bá mú èso rere jáde wá, tàbí ẹnìkẹ́ni tí kò bá ṣe iṣẹ́ rere, eleyĩ ni yíò pohùnréré ẹkún, tí yíò ṣọ̀fọ̀.

37 A! ẹ̀yin aláìṣedẽdé; ẹ̀yin tí ẹ gbé ọkàn an yín sókè nínú àwọn ohun asán ayé, ẹ̀yin tí ẹ ti jẹ́wọ́ tẹ́lẹ̀rí pé ẹ̀yin ti mọ́ ọ̀nà òdodo, bíótilẹ̀ríbẹ̃ tí ẹ ti ṣáko lọ, gẹ́gẹ́bí àgùtàn tí kò ní olùṣọ́, l’áìṣírò, olùṣọ́-àgùtàn ti ké pè yín, ó sì nké pè yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò tẹ́tí sí ohùn rẹ̀!

38 Ẹ kíyèsĩ, mo wí fún yín, pé olùṣọ́-àgùtàn rere nã npè yín; bẹ̃ni, ní orúkọ rẹ̀ ni ó npè nyín, èyítí íṣe orúkọ Krístì, tí ẹ̀yin kò bá sì gbọ́ ohùn olùṣọ́-àgùtàn rere nã, sí orúkọ nã, èyítí a fi npè yín, kíyèsĩ, ẹ̀yin kĩ ṣe àgùtàn ti olùṣọ́-àgùtàn rere nã.

39 Àti nísisìyí, tí ẹ̀yin kò bá íṣe àgùtàn ti olùṣọ́-àgùtàn rere nã, agbo tani ẹ̀yin íṣe? Ẹ kíyèsĩ, mo wí fún un yín, pé èṣù ni olùṣọ́-àgùtàn yín, ẹ̀yin sì ni agbo rẹ̀; àti nísisìyí, tani ó lè sẹ́ eleyĩ? Ẹ kíyèsĩ, mo wí fún yín, ẹnìkẹ́ni tí ó bá sẹ eleyĩ, èké ni, ọmọ èṣù sì ni.

40 Nítorínã ni mo ṣe wí fún un yín pé ẹnìkẹ́ni tí ó bá jẹ́ dáradára, ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ó ti wá, ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì jẹ́ búburú, ọ̀dọ̀ èṣù ni ó ti wá.

41 Nítorínã, tí ènìyàn bá mú iṣẹ́ rere jáde wá, ó ngbọ́ràn sí ohùn olùṣọ́-àgùtàn rere, ó sì ntẹ̀lée; ṣùgbọ́n ẹnìkẹ́ni tí ó bá nmú iṣẹ́ búburú jáde, èyí kannã ló di ọmọ èṣù, nítorítí ó ngbọ́ràn sí ohùn rẹ̀, ó sì ntẹ̀lée.

42 Ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì nṣe eleyĩ níláti gba èrè láti ọwọ́ rẹ̀; nítorínã, fún èrè iṣẹ́ rẹ̀, yíò gba ikú nípa àwọn ohun tí íṣe ti ìwà òdodo, nítorítí ó ti kú nínú gbogbo iṣẹ́ rere.

43 Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi rọ̀ yín pé kí ẹ gbọ́ mi, nítorítí èmi nsọ̀rọ̀ pẹ̀lú gbogbo agbára ẹ̀mí mi; nítorí kíyèsĩ, èmi ti bá yín sọ̀rọ̀ dájúdájú, tí ẹ̀yin kò sì lè kọsẹ̀, tàbí pé èmi ti sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́bí ìpaláṣẹ Ọlọ́run.

44 Nítorípé a pè mí láti sọ̀rọ̀ báyĩ, nípa ẹgbẹ́ mímọ́ ti Ọlọ́run, èyítí ó wà nínú Krístì Jésù; bẹ̃ni, a pã láṣẹ fún mi láti dúró kí èmi sì jẹ́ ẹ̀rí fún àwọn ènìyàn yíi, nípa àwọn ohun tí àwọn bàbá wa ti sọ nípa àwọn ohun tí nbọ̀ wá.

45 Èyí nìkan kọ́, njẹ́ ẹ̀yin kò mọ̀ pé èmi mọ̀ nípa àwọn ohun wọ̀nyí fúnra mi? Kíyèsĩ, èmi jẹ́ ẹ̀rí síi fún un yín pé èmi mọ̀ pé àwọn ohun tí èmi ti sọ̀rọ̀ nípa nwọn wọ̀nyí jẹ́ òtítọ́. Báwo sì ni ẹ̀yin ṣe rò pé èmi mọ́ òtítọ́ nwọn?

46 Ẹ kíyèsĩ, èmi wí fún un yín pé Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run ni ó fi wọ́n hàn mí. Wõ, èmi ti gba ãwẹ̀ mo sì ti gbàdúrà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ kí èmi kí ó lè mọ́ ohun wọ̀nyí fúnra mi. Àti nísisìyí èmi sì mọ̀ ọ́ fúnra mi pé òtítọ́ ni nwọ́n; nítorítí Olúwa Ọlọ́run ti fi nwọ́n hàn mí nípa Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀; èyí sì ni ẹ̀mí ìfihàn èyítí ó wà nínú mi.

47 Àti pẹ̀lú, èmi wí fún yín pé báyĩ ni a ti fi hàn mí, pé òtítọ́ ni àwọn ọ̀rọ̀ tí bàbá wa sọ, àní pãpã nípasẹ̀ ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀ èyí tí nbẹ nínú mi, tí ó sì tún jẹ́ nípasẹ̀ ìfihàn agbára Ẹ̀mí Ọlọ́run.

48 Mo wí fún yín pé èmi mọ̀ fúnra mi pé ohunkóhun tí èmi yíò wí fún yín, nípa èyítí ó nbọ̀wá, jẹ́ òtítọ́; èmi sì wí fún yín, pé èmi mọ̀ wípé Jésù Krístì nbọ̀wá, bẹ̃ni, Ọmọ nã, tí íṣe Ọmọ-bíbí-kanṣoṣo ti Bàbá, tí ó kún fún õre-ọ̀fẹ́, àti ãnú àti òtítọ́. Ẹ kíyèsĩ, òun ni ó nbọ̀wá tí yíò kó gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ, bẹ̃ni, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ẹnìkẹ́ni tí ó bá gba orúkọ rẹ̀ gbọ́ ní ìdúróṣinṣin.

49 Àti nísisìyí, mo wí fún yín pé èyí ní irú ọ̀nà tí a gbà pè mí, bẹ̃ni, láti wãsù sí àwọn arákùnrin mi àyànfẹ́, bẹ̃ni, àti gbogbo ẹni tí ó ngbé inú ilẹ̀ nã; bẹ̃ni, láti wãsù sí ènìyàn gbogbo, àgbà àti ọmọdé, ẹrú àti òmìnira; bẹ̃ni, mo wí fún yín, ẹ̀yin ogbó, àti ẹ̀yin àgbà, àti ìran tí ó nbọ̀; bẹ̃ni, láti kígbe pè wọn, pé kí wọ́n ronúpìwàdà, kí wọ́n sì di àtúnbí.

50 Bẹ̃ni, báyĩ ni Ẹ̀mí Ọlọ́run wí: Ẹ ronúpìwàdà, gbogbo ẹ̀yin ìkangun ayé, nítorí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀; bẹ̃ni, Ọmọ Ọlọ́run nã nbọ̀wá nínú ògo rẹ̀, nínú ipá, ọlá-nlá, agbára àti ìjọba rẹ̀. Bẹ̃ni, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, èmi wí fún un yín, pé Ẹ̀mí Ọlọ́run wípé: Kíyèsĩ ògo Ọba gbogbo ayé; àti Ọba ọ̀run yíò tàn jáde láìpẹ́ lãrín àwọn ọmọ ènìyàn gbogbo.

51 Ẹ̀mí Ọlọ́run sì tún sọ fún mi pé, bẹ̃ni, ó nkígbe sí mi pẹ̀lú ohùn rara, pé: Lọ jáde kí o sì wí fún àwọn ènìyàn yí pé—Ẹ ronúpìwàdà, ti ẹ̀yin kò bá sì ronúpìwàdà, ẹ̀yin kó lè jogún ìjọba ọ̀run.

52 Èmi tún wí fún un yín, Ẹ̀mí-Ọlọ́run wípé: Kíyèsĩ, a ti fi ãké lélẹ̀ ní ẹ̀bá gbòngbò igi; nítorínã, igi èyíkéyĩ tí kò bá so èso rere jáde ni a ó ké lulẹ̀, tí a ó sì jũ sínú iná, bẹ̃ni, iná èyítí kò lè kú, àní iná èyítí a kò lè pa. Kíyèsĩ, kí ẹ sì rántí, Ẹní Mímọ́ nã ni ó wíi.

53 Àti nísisìyí ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, èmi wí fún un yín, njẹ́ ẹ̀yin lè ṣe àìbìkítà sí ohun wọ̀nyí; bẹ̃ni, njẹ́ ẹ̀yin le fo nwọn ru, kí ẹ̀yin sì tẹ Ẹní Mímọ́ nnì mọ́lẹ̀ ní abẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ yín; bẹ̃ni, njẹ́ ẹ̀yin lè ru ọkàn an yín sókè nínú ìgbéraga; bẹ̃ni, njẹ́ ẹ̀yin yíò ha tún wọ ẹ̀wù olówó iyebíye, kí ẹ̀yin kí ó sì fi ọkàn tán ohun asán ayé àti àwọn ọrọ̀ọ yín?

54 Bẹ̃ni, njẹ́ ẹ̀yin yíò ha tẹramọ́ èrò ọkàn an yín pé ẹ̀yin dáraju ẹlòmíràn lọ; bẹ̃ni, njẹ́ ẹ̀yin yíò ha teramọ́ ṣíṣe inúnibíni sí àwọn arákùnrin yín, tí nwọ́n rẹ ara nwọn sílẹ̀ tí nwọ́n sì nrìn ní ẹgbẹ́ ọ̀nà mímọ́ Ọlọ́run, nípasẹ̀ èyítí a ti mú wọn wá sínú ìjọ-onígbàgbọ́ yíi, tí a ti sọ nwọ́n di mímọ́ nípa Ẹ̀mí Mímọ́, tí nwọ́n sì nṣe iṣẹ́ èyítí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà—

55 Bẹ̃ni, njẹ́ ẹ̀yin yíò sì tún tẹramọ́ ṣíṣe ìkóríra àwọn tálákà, àti àwọn aláìní, kí ẹ̀yin sì pa ohun ìní yín mọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn?

56 Ní àkótán, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ tẹramọ́ ṣíṣe ìwà búburú, èmi wí fún yín pé àwọn wọ̀nyí ni a ó ke lulẹ̀ tí a ó sì wọ́ nwọn jù sínú iná, àfi tí nwọ́n bá ronúpìwàdà kánkán.

57 Àti nísisìyí mo wí fún yín, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ ṣe àfẹ́rí láti tẹ̀lé ohùn olùṣọ́-àgùtàn rere, ẹ jáde kúrò lãrín àwọn ẹni-búburú, kí ẹ sì ya àrã yín sọ́tọ̀, kí ẹ másì ṣe fi ọwọ́ kan àwọn ohun àìmọ́ nwọn; sì kíyèsĩ, a ó pa orúkọ nwọn rẹ́, nítorí orúkọ àwọn ènìyàn búburú ni a kò ní kà mọ́ orúkọ àwọn ènìyàn rere, kí a lè mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣẹ, èyítí ó sọ wípé: Orúkọ àwọn ènìyàn búburu kò ní dàpọ̀ mọ́ orúkọ àwọn ènìyàn mi;

58 Nítorítí a o kọ orúkọ wọn ènìyàn rere sínú ìwé ìyè, àwọn sì ni èmi yíò fún ni ibi ìjòkó ní ọwọ́ ọ̀tún mi. Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi, kíni ẹ̀yin rí sọ tí ó lòdì sí èyí? Èmi wí fún un yín, tí ẹ̀yin bá sọ̀rọ̀ ìlòdì sí èyí, kò já mọ́ nkankan, nítorípé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ ṣẹ.

59 Njẹ́ a rí olùṣọ́-àgùtàn nã lãrín yín, tí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àgùtàn, tí kò ṣọ́ nwọn, tí ìkokò kì yíò wọlé kí ó pa ọ̀wọ́ ẹran rẹ̀ jẹ? Sì kíyèsĩ, bí ìkõkò bá wọ̀ inú ọ̀wọ́ ẹran rẹ̀ njẹ́ kò ní lée jáde? Bẹ̃ni, ní ìgbẹ̀hìn, tí ó bá ṣeéṣe, yíò pã run.

60 Àti nísisìyí mo wí fún un yín pé olùṣọ́-àgùtàn rere npè yín; tí ẹ̀yin bá sì gbọ́ ohun rẹ̀ òun yíò mú nyín wá sínú agbo rẹ̀, ẹ̀yin sì ni àgùtàn rẹ̀; òun sì pã láṣẹ pé kí ẹ̀yin máṣe gba ìkõkò apanirun lãyè láti wọ ãrin yín kí ẹ̀yin kí ó máṣe parun.

61 Àti nísisìyí èmi, Álmà, pã láṣẹ fún un yín ní èdè ẹnití ó ti pã láṣẹ fún mi, pé kí ẹ̀yin kí ó kíyèsí àti ṣe àwọn ọ̀rọ̀ tí èmi ti sọ fún yín.

62 Èmi bá ẹ̀yin tí íṣe ti ìjọ nã sọ̀rọ̀; gẹ́gẹ́bí ìpàṣẹ; àti sí àwọn tí nwọn kĩ ṣe ti ìjọ nã, èmi bã yín sọ̀rọ̀ níti ìpè, wípé: Ẹ wá ṣe ìrìbọmi sí ìrònúpìwàdà, kí ẹ̀yin nã lè di alájọpín nínú èso igi ìyè nã.