Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 14


Orí 14

A gbé Álmà pẹ̀lú Ámúlẹ́kì sọ sínú túbú, a sì nà nwọ́n—Àwọn tí ó gba Olúwa gbọ́ pẹ̀lú àwọn ìwé mímọ́ nwọn ni a jó níná—Àwọn ajẹ́rĩkú yi ni Olúwa gbà sínú ògo—Ògiri ọgbà ẹ̀wọ̀n nã ya, ó sì wó lulẹ̀—A kó Álmà àti Ámúlẹ́kì yọ, a sì pa àwọn onínúnibíni nwọn. Ní ìwọ̀n ọdún 82–81 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe lẹ́hìn tí ó ti parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sísọ fún àwọn ènìyàn nã, púpọ̀ nínú nwọn sì gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí ronúpìwàdà, nwọ́n sì nwá inú ìwé-mímọ́.

2 Ṣùgbọ́n púpọ̀ nínú nwọn ni nwọ́n fẹ́ kí a pa Álmà pẹ̀lú Ámúlẹ́kì run; nítorítí nwọn nbínú sí Álmà nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó yè koro sí Sísrọ́mù; nwọ́n sì tún sọ wípé Ámúlẹ́kì ti purọ́ fún nwọn, ó sì ti ta ko òfin nwọn, àti àwọn agbẹjọ́rò àti àwọn adájọ́ nwọn pẹ̀lú.

3 Nwọn sì tún nbínú sí Álmà pẹ̀lú Ámúlẹ́kì; nítorítí nwọ́n ti jẹ́ ẹ̀rí ní pàtó sí ìwà búburú nwọn, nwọ́n nwá ọ̀nà láti pa nwọ́n ní ìkọ̀kọ̀.

4 Ṣùgbọ́n ó sì ṣe tí nwọn kò ṣe èyí; ṣùgbọ́n nwọ́n mú nwọn, nwọ́n sì dè nwọ́n pẹ̀lú okùn tí ó yi, tí nwọ́n sì mú nwọn wá sí iwájú adájọ́ àgbà ilẹ̀ nã.

5 Àwọn ènìyàn nã sì jáde lọ jẹ́ ẹ̀rí takò nwọ́n—nwọn njẹ́rĩ pé nwọ́n kẹ́gàn òfin, àti àwọn agbẹjọ́rò àti àwọn adájọ́ ilẹ̀ nã, àti bákannã gbogbo àwọn tí ó wà lórí ilẹ̀ nã; nwọ́n sì jẹ́rĩ pé Ọlọ́run kanṣoṣo ni ó wà, tí yíò sì rán ọmọ rẹ̀ sí ãrin àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n òun kò níláti gbà nwọ́n là; àti púpọ̀ irú ohun báyĩ ni àwọn ènìyàn nã jẹ́rĩ sí tako Álmà àti Ámúlẹ́kì. Àwọn wọ̀nyí ni nwọ́n ṣe níwájú adájọ́ àgbà ilẹ̀ nã.

6 Ó sì ṣe tí ẹnu ya Sísrọ́mù nípa àwọn ohun tí nwọ́n ti sọ; òun sì mọ̀ nípa ìfọ́jú ọkàn nwọn, èyítí ó ti ipasẹ̀ rẹ̀ rí bẹ̃ lãrín àwọn ènìyàn nítorí ọ̀rọ̀ irọ́ rẹ̀ gbogbo; ọkàn rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀sí gbọgbẹ́ nínú ẹ̀bi rẹ̀; bẹ̃ni, ìrora ipò òkú sì bẹ̀rẹ̀sí yíi po.

7 Ó sì ṣe tí ó bẹ̀rẹ̀sí kígbe sí àwọn ènìyàn nã wípé: Ẹ kíyèsĩ, èmi jẹ̀bi, àwọn arákùnrin wọ̀nyí sì wà láìlábàwọ́n níwájú Ọlọ́run. Ó sì bẹ̀rẹ̀sí ṣípẹ̀ fún nwọn láti ìgbà nã lọ; ṣùgbọ́n nwọ́n takõ, wípé: Ìwọ pẹ̀lú ha ti gba èṣù? Nwọ́n sì tu itọ́ síi, nwọ́n sì jũ síta kúrò lãrín nwọn, pẹ̀lú àwọn tí ó gba ọ̀rọ̀ ti Álmà àti Ámúlẹ́kì sọ gbọ́; nwọ́n sì sọ nwọ́n síta, nwọ́n sì rán àwọn ènìyàn kí nwọ́n sọ nwọ́n ní òkúta.

8 Nwọ́n sì kó àwọn aya nwọn àti àwọn ọmọ jọ, pé ẹnìkẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́, tàbí tí a ti kọ́ pé kí ó gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbọ́, nwọ́n jù nwọ́n sínú iná; nwọ́n sì mú àwọn ìwé àkọsílẹ̀ nwọn jáde nínú èyítí àwọn ìwé-mímọ́ wà, nwọ́n jù nwọ́n sínú iná pẹ̀lú, kí nwọ́n lè jóná kí nwọ́n sì parun nínú iná.

9 Ó sì ṣe tí nwọ́n mú Álmà pẹ̀lú Ámúlẹ́kì, tí nwọ́n sì gbé nwọn jáde lọ sí ibi ikú àwọn ajẹ́rĩ ikú, kí nwọ́n lè ṣe ìjẹ́rĩsí ìparun àwọn tí nwọ́n jó pẹ̀lú.

10 Nígbàtí Ámúlẹ́kì rí ìrora àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé tí nwọn njóná nínú iná, òun nã jẹ̀rora; ó sì wí fún Álmà: báwo ni àwa ó ṣe máa wo ohun búburú yíi? Nítorínã, jẹ́ kí a na ọwọ́ wa jáde; kí a lo agbára Ọlọ́run èyítí ó wà nínú wa, kí a sì gbà nwọ́n lọ́wọ́ iná yĩ.

11 Ṣùgbọ́n Álmà wí fún un pé: Ẹ̀mí Mímọ́ rọ̀ mí láti má na ọwọ́ mi jáde, nítorí kíyèsĩ, Olúwa gbà nwọ́n sọ́dọ̀ ara rẹ̀, nínú ògo; òun sì gbà pé kí nwọ́n ṣe èyí, tàbí pé kí àwọn ènìyàn nã ṣe ohun yĩ sí nwọn, ní ìbámu pẹ̀lú líle ọkàn an nwọn, kí ìdájọ́ tí òun yíò ṣe fún nwọn nínú ìbínú rẹ̀ lè tọ́; kí ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ nnì s‘ilè dúró gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí tako nwọn, bẹ̃ni, kí ó sì kígbe rara takò nwọ́n ní ọjọ́ ìkẹhìn.

12 Nísisìyí, Ámúlẹ́kì wí fún Álmà: Kíyèsĩ, boyá nwọn yíò jó àwa nã níná.

13 Álmà sì wí pé: Kí ó rí bẹ̃ gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ Olúwa. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, iṣẹ́ wa kòì tĩ parí; nítorínã nwọn kò lè jó wa níná.

14 Nísisìyí ó sì ṣe, nígbàtí ara àwọn tí a ti jù sínú iná ti jóná, pẹ̀lú àwọn ìwé-àkọsílẹ̀ tí a jù sínú rẹ pẹ̀lú nwọn, adájọ́ àgbà ilẹ̀ nã wá ó sì dúró síwájú Álmà àti Ámúlẹ́kì, bí a ti dè nwọ́n; ó sì gbá nwọn lẹ́nu pẹ̀lú ọwọ́ rẹ, ó sì wí fún nwọn pé: Lẹ́hìn ohun tí ẹ̀yin ti rí, njẹ́ ẹ̀yin yíò tún wãsù sí àwọn ènìyàn yí, pé a o gbé nwọn jù sínú adágún iná àti imí ọjọ́?

15 Kíyèsĩ, ẹ̀yin ríi pé ẹ̀yin kò lágbára láti gba àwọn tí a ti jù sínú iná là; bẹ̃ sì ni Ọlọ́run kò gbà nwọ́n nítorítí òun kannã ni ẹ gbàgbọ́. Adájọ́ nã sì tún gbá nwọn lẹ́nu, ó sì bẽrè: Kíni ẹ̀yin rí sọ fún ara yín?

16 Nísisìyí, adájọ́ yĩ jẹ́ ti ipa ìgbàgbọ́ ti Néhórì, ẹnití ó pa Gídéónì.

17 Ó sì ṣe tí Álmà àti Ámúlẹ́kì ko dáa lóhùn ohunkóhun; ó sì tún lù nwọn, ó sì jọ̀wọ́ nwọn lé ọwọ́ àwọn oníṣẹ́ rẹ, kí nwọ́n jù nwọ́n sínú túbú.

18 Nígbàtí nwọn sì ti jù nwọ́n sínú túbú fún ọjọ́ mẹta, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn agbẹjọ́rò, àti àwọn adajọ, ati àwọn alufaa, ati àwọn olùkọ́ni, tí nwọn jẹ́ ti ipa Néhórì wá; nwọ́n sì wá sínú túbú láti wò nwọ́n, nwọ́n sì bẽrè ọ̀rọ̀ púpọ̀ lọ́wọ́ nwọn; ṣùgbọ́n nwọn kò dáhùn ohunkún.

19 Ó sì ṣe tí adájọ́ nã dide níwájú nwọn, tí ó wípé: Kíni ìdíi rẹ̀ tí ẹ̀yin kò dáhùn ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn yí? Ẹ̀yin kò ha mọ̀ pé èmi ní agbára láti jù yín sínú iná? Ó sì pã láṣẹ fún nwọn pé kí nwọ́n sọ̀rọ̀; ṣùgbọ́n nwọn kò dáhùn ohunkóhun.

20 Ó sì ṣe tí nwọ́n kúrò níbẹ̀, tí nwọ́n sì bá ọ̀nà tiwọn lọ, ṣùgbọ́n nwọn padà ní ọjọ́ kejì; adájọ́ nã sì tún gbá nwọn lẹ́nu. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì jáde wá pẹ̀lú, nwọ́n sì nà nwọ́n, nwọ́n wípé: Njẹ́ ẹ̀yin yíò tún dìde kí ẹ sì rojọ́ mọ́ àwọn ènìyàn yí, kí ẹyin sì tako òfin wa? Tí ẹ̀yin bá ní irú agbára nlá báyĩ, ẹyin kò ṣe lè gba ara yín.

21 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú ohun báyĩ ni nwọ́n nsọ, wọn pa ehin keke si wọn, tí nwọ́n sì ntutọ́ sí nwọn lara, tí nwọ́n wípé: Báwo ni àwa yíò ṣe rí nígbàtí a bá dá wa lẹ́bi?

22 Àti pẹ̀lú irú àwọn ohun báyĩ, bẹ̃ni, onírũrú ohun báyĩ ni nwọ́n nsọ sí nwọn; bẹ̃ gẹ́gẹ́ ni nwọ́n sì ṣe nfi nwọ́n ṣe ẹlẹ́yà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́. Nwọn kò sì fún nwọn ní oúnjẹ, kí ẹbi lè pa nwọ́n, pẹ̀lú omi, kí òrùngbẹ lè gbẹ nwọ́n; nwọ́n sì gba aṣọ lára wọn tí nwọ́n wà ní ìhõhò; báyĩ ni nwọ́n sì dì nwọ́n pẹ̀lú okùn yíyi, tí nwọ́n sì ha nwọn mọ́ inú túbú.

23 Ó sì ṣe, lẹ́hìn tí nwọ́n ti jìyà báyĩ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, (ó sì jẹ́ ọjọ́ kejìlá, ní oṣù kẹẹ̀wá, ní ọdún kẹẹ̀wá ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ará Nífáì) tí adájọ́ àgbà lórí ilẹ̀ Amonáíhà àti púpọ̀ nínú àwọn olùkọ́ni nwọn, àti àwọn agbẹjọ́rò nwọn, tọ Álmà àti Ámúlẹ́kì lọ nínú túbú níbití a gbé dì nwọ́n pẹ̀lú okùn.

24 Adájọ́ àgbà nã sì dúró níwájú nwọn, ó sì tún nà nwọ́n, ó sì wí fún nwọn pé: Tí ẹ̀yin bá ní agbára Ọlọ́run, ẹ gba ara yín kúrò nínú ìdè yìi, nígbànã ni àwa yíò gbàgbọ́ pé Olúwa yíò pa àwọn ènìyàn yí run gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ yín.

25 Ó sì ṣe tí gbogbo nwọn sì kọjá lọ láti nà nwọ́n, tí nwọ́n sì nsọ ohun kannã, títí fi dé ẹnití ó kẹ́hìn; nígbàtí ẹnití ó kẹ́hìn sì ti sọ̀rọ̀ sí nwọn tán, agbara Ọlọ́run bà lé Álmà àti Ámúlẹ́kì, nwọ́n sì dìde dúró lórí ẹsẹ̀ nwọn.

26 Álmà sì kígbe, wípé: Báwo ni yíò ti pẹ́ tó tí àwa yíò faradà ìyà nlá yĩ, Á! Olúwa? Á! Olúwa, fún wa ní agbára gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ wa èyítí ó wà nínú Krístì, àní sí ìdásílẹ̀. Nwọn sì já àwọn okùn tí nwọ́n fi dè nwọ́n; nígbàtí àwọn ènìyàn nã sì rí èyí, nwọ́n bẹ̀rẹ̀sĩ sálọ, nítorípé ẹ̀rù ìparun ti dé bá nwọn.

27 Ó sì ṣe tí ẹ̀rù nwọn pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, tí nwọ́n sì ṣubú lulẹ̀, tí nwọn kò lè dé ẹnu ọ̀nà ìta túbú nã; ilẹ̀ nã sì mì tìtì púpọ̀púpọ̀, àwọn ògiri túbú nã sì ya sí méjì láti òkè dé ìsàlẹ̀, tí nwọ́n sì wó lulẹ̀; adájọ́ àgbà, àti àwọn agbẹjọ́rò, àti àwọn àlùfã àti àwọn olùkọ́ni, tí nwọ́n na Álmà àti Ámúlẹ́kì sì kú nípa wíwólulẹ̀ nwọn.

28 Álmà àti Ámúlẹ́kì sì jáde kúrò nínú túbú, nwọn kò sì farapa; nítorítí Olúwa ti fún nwọn ní agbára, nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nwọn tí ó wà nínú Krístì. Lọ́gán, nwọ́n sì jáde kúrò nínú túbú; a sì tú nwọn sílẹ̀ kúrò nínú ìdè nwọn; túbú sì ti wó lulẹ̀, gbogbo ènìyàn tí ósì wà ní agbègbè ògiri túbú nã, àfi Álmà pẹ̀lú Ámúlẹ́kì, ni a pa; nwọ́n sì jáde lọ́gán lọ sínú ilú nã.

29 Nísisìyí, nígbàtí àwọn ènìyàn gbọ́ ariwo ìró nlá, nwọ́n sáré wa, pẹ̀lú ọ̀gọ̃rọ̀ ènìyàn láti mọ́ ìdí èyí; nígbàtí nwọ́n sì rí Álmà àti Ámúlẹ́kì tí nwọn njáde bọ̀wá láti inú túbú, tí ògiri rẹ̀ ti wó lulẹ̀, ẹ̀rù bà nwọ́n lọ́pọ̀lọpọ̀, nwọn sì sá kúrò níwájú Álmà àti Ámúlẹ́kì àní bí ewúrẹ́ yíò ṣe sá pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ fún kìnìún méjì; báyĩ ni nwọ́n ṣe sá kúrò níwájú Álmà àti Ámúlẹ́kì.