Àwọn Ìwé Mímọ́
Hẹ́lámánì 1


Ìwé ti Hẹ́lámánì

Ọ̀rọ̀ nípa àwọn ará Nífáì. Àwọn ogun àti ìjà nwọn, àti àwọn ìyapa nwọn. Àti pẹ̀lú àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn wòlĩ mímọ́, ṣãjú bíbọ̀ Krístì, gẹ́gẹ́bí àwọn àkọsílẹ̀ Hẹ́lámánì, ẹnití í ṣe ọmọ Hẹ́lámánì, àti pẹ̀lú gẹ́gẹ́bí àwọn àkọsílẹ̀ àwọn ọmọ rẹ̀, àní títí dé àkokò tí Krístì fi dé. Àti pẹ̀lú pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará Lámánì ni a yí lọ́kàn padà. Ọ̀rọ̀ nípa ti ìyílọ́kànpadà nwọn. Ọ̀rọ̀ nípa ìṣòdodo àwọn ará Lámánì, àti ìwà búburú àti ìwà ìríra àwọn ará Nífáì, gẹ́gẹ́bí àkọsílẹ̀ ti Hẹ́lámánì àti àwọn ọmọ rẹ̀, àní títí dé àkokò tí Krístì fi dé, èyítí a pè ní ìwé Hẹ́lámánì, àti bẹ̃bẹ̃ lọ.

Orí 1

Pahoránì kejì di adájọ́ àgbà, Kíṣkúmẹ́nì sì pã—Pákúmẹ́nì bọ́ sí órí ìtẹ́ ìdájọ́—Kóríántúmúrì ṣãjú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì, ó mú Sarahẹ́múlà, ó sì pa Pákúmẹ́nì—Móróníhà borí àwọn ará Lámánì ó sì gba Sarahẹ́múlà padà, a sì pa Kóríántúmúrì. Ní ìwọ̀n ọdún 52 sí 50 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí kíyèsĩ, ó sì ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ogójì ọdún nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì, ìṣòro nlá kan si bẹrẹ si wa lãrín àwọn ènìyàn ti ara Nífáì.

2 Nítorí kíyèsĩ, Pahoránì ti kú, ó sì ti lọ sí ibi gbogbo ayé nrè; nítorínã asọ̀ líle sì bẹ̀rẹ̀sí wà nípa tani yíò gun ìtẹ́ ìdájọ́ lãrín àwọn arákùnrin nã, tí í ṣe ọmọ Pahoránì.

3 Nísisìyí èyí ni orúkọ àwọn tí nwọ́n jà fún ìtẹ́ ìdájọ́, tí nwọ́n sì mú kí àwọn ènìyàn nã jà: Pahoránì, Pãnkì, àti Pákúmẹ́nì.

4 Nísisìyí kĩ ṣe gbogbo àwọn ọmọ Pahoránì nìwọ̀nyí (nítorítí ó ní púpọ̀), ṣùgbọ́n àwọn yĩ ni àwọn tí nwọ́n jà fún ìtẹ́ ìdájọ́; nítorínã, nwọ́n sì mú ìyà sí ipa mẹ́ta kí ó wà lãrín àwọn ènìyàn nã.

5 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, ó sì ṣe tí a yàn Pahoránì nípa ohùn àwọn ènìyàn nã láti jẹ́ adájọ́ àgbà àti olórí-ìlú lórí àwọn ènìyàn Nífáì.

6 Ó sì ṣe tí Pákúmẹ́nì, nígbàtí ó ríi pé òun kò lè gba ìtẹ́ ìdájọ́, ó sì darapọ̀ mọ́ ohùn àwọn ènìyàn nã.

7 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, Pãnkì, àti ẹ̀yà nínú àwọn ènìyàn nã tí ó ní ìfẹ́ pé kí ó di olórí-ìlú nwọn, bínú lọ́pọ̀lọpọ̀; nítorínã, ó sì ṣetán láti fi ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn mú àwọn ènìyàn nã láti rú sókè ní ìṣọ̀tẹ̀ sí àwọn arákùnrin nwọn.

8 Ò sì ṣe bí ó ti fẹ́ ṣe eleyĩ, kíyèsĩ, nwọ́n múu, nwọ́n sì dá ẹjọ́ fún un gẹ́gẹ́bí ohùn àwọn ènìyàn nã, nwọ́n sì dájọ́ ikú fún un; nítorípé ó rú ìṣọ̀tẹ̀sí sókè ó sì lépa láti pa òmìnira àwọn ènìyàn nã run.

9 Nísisìyí nígbàtí àwọn ènìyàn nnì tí nwọn fẹ́ kí ó jẹ̀ olórí-ìlú fún nwọn ríi pé a ti dájọ́ ikú fún un, nítorínã nwọ́n bínú, sì kíyèsĩ, nwọ́n rán ẹnìkan tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Kíṣkúmẹ́nì lọ, àní lọ sí ìtẹ́ ìdájọ́ Pahoránì, o sì pa Pahoránì bí ó ṣe joko lórí ìtẹ́ ìdájọ́.

10 Àwọn ìránṣẹ́ Pahoránì sì sá tẹ̀lée; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, eré tí Kíṣkúmẹ́nì sá pọ̀ púpọ̀ tó bẹ̃ tí ẹnìkẹ́ni kò lè lée bá.

11 Ó sì lọ sí ọ́dọ̀ àwọn tí ó rán an, gbogbo nwọ́n sì bá ara nwọn dá májẹ̀mú, bẹ̃ni, nwọ́n sì búra pẹ̀lú Ẹlẹ́da ayérayé nwọn, pé nwọn kò ní sọ fún ẹnìkẹ́ni pé Kíṣkúmẹ́nì ni ó pa Pahoránì.

12 Nítorínã, a kò mọ́ Kíṣkúmẹ́nì lãrin àwọn ènìyàn Nífáì, nítorítí ó bò ojú ara rẹ̀ ní ìgbàtí ó lọ pa Pahoránì. Kíṣkúmẹ́nì àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí nwọ́n ti bã dá májẹ̀mú, sì darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn nã, ní ọ̀nà tí nwọn kò fi lè rí nwọn mú; ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí nwọ́n rí mú ni nwọ́n dájọ́ ikú fún.

13 Àti nísisìyí sì kíyèsĩ, a yan Pákúmẹ́nì gẹ́gẹ́bí ohùn àwọn ènìyàn nã, láti jẹ́ adájọ́-àgbà àti olórí-ìlú lórí àwọn ènìyàn nã, láti jọba rọ́pò arákùnrin rẹ̀ tí í ṣe Pahoránì; ó sì wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀tọ́ rẹ̀. Gbogbo eleyĩ ni a sì ṣe ní ogojì ọdún nínú ìjọba àwọn onídàjọ́; ó sì ní òpin.

14 Ó sì ṣe ní ọdún kọkànlélógójì nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, tí àwọn ará Lámánì kó àìníye ẹgbẹ ọmọ-ogun jọ, tí nwọ́n sì di ìhámọ́ra ogun fún nwọn pẹ̀lú idà, àti símẹ́tà àti ọrun, àti ọfà, àti ìborí, àti ìgbàyà-ogun, àti pẹ̀lú onírũrú apata lóríṣiríṣi.

15 Nwọ́n sì tún sọ̀kalẹ̀ wá láti gbógun ti àwọn ará Nífáì. Ẹnìkan tí orúkọ rẹ̀ í ṣe Kóríántúmúrì ni ó sì ṣãjú nwọn; ó sì jẹ́ àtẹ̀lé Sarahẹ́múlà; ó sì jẹ́ olùyapa kúrò lãrín àwọn ará Nífáì; ènìyàn títóbi tí ó sì lágbára ní í ṣe.

16 Nítorínã, ọba àwọn ará Lámánì, ẹnití orúkọ rẹ̀ í ṣe Túbálọ́tì, tí í ṣe ọmọ Ámmórọ́nì, lérò wípé Kóríántúmúrì, nítorítí ó jẹ́ alágbára ènìyàn, yíò lè dojúkọ àwọn ará Nífáì, pẹ̀lú agbára rẹ̀ àti pẹ̀lú ọgbọ́n nlá rẹ̀, tóbẹ̃ tí yíò borí àwọn ará Nífáì bí òun bá rán an lọ—

17 Nítorínã, ó rú nwọn sókè ní ìbínú, ó sì kó àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ jọ, ó sì yan Kóríántúmúrì láti jẹ́ olórí nwọn, ó sì mú kí nwọn ó kọjá lọ sínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà láti dojúkọ àwọn ará Nífáì.

18 Ó sì ṣe nítorípé asọ̀ púpọ̀ àti ìṣòro púpọ̀ wà nínú ìjọba nã, tí nwọn kò ní àwọn ẹ̀ṣọ́ tí ó pọ̀ tó ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà; nítorítí nwọ́n ti rò pé àwọn ará Lámánì kò lè dábá láti wọ inú ilẹ̀ nwọn wá láti kọlũ ìlú-nlá Sarahẹ́múlà títóbi nnì.

19 Ṣùgbọ́n ó sì ṣe tí Kóríántúmúrì sì kọjá lọ níwájú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ nlá, tí nwọn sì kọlu àwọn tí ngbé inú ìlú-nlá nã, ìrìn nwọn sì yá tóbẹ̃ tí kò sí àkokò fún àwọn ará Nífáì láti kó àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn jọ.

20 Nítorínã Kóríántúmúrì ké àwọn ẹ̀ṣọ́ tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà ìlú-nã lulẹ̀, ó sì kọjá lọ pẹ̀lú gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ sínú ìlú-nlá nã, nwọ́n sì pa gbogbo àwọn tí ó takò nwọ́n, tóbẹ̃ tí nwọ́n fi mú ìlú-nlá nã pátápátá.

21 Ó sì ṣe tí Pákúmẹ́nì, ẹnití í ṣe adájọ́-àgbà, sí sá níwájú Kóríántúmúrì, àní lọ sí ibi odi ìlú-nlá nã. Ó sì ṣe tí Kóríántúmúrì lù ú mọ́ ara ògiri nã, tóbẹ̃ tí ó fi kú. Báyĩ sì ni ọjọ́ ayé Pákúmẹ́nì ṣe parí.

22 Àti nísisìyí nígbàtí Kóríántúmúrì ríi pé òun ti mú ìlú-nlá Sarahẹ́múlà nã, tí ó sì ríi pé àwọn ará Nífáì ti sá níwájú nwọn, tí a sì pa nwọ́n tí a sì ti mú nwọn, tí a sì ti jù nwọ́n sínú tũbú, àti pé òun ti mú ibi-ìsádi nwọn tí ó lágbára jù ní ìní ní gbogbo ilẹ̀ nã, ó ní ìgboyà tóbẹ̃ tí ó ṣetán láti jáde lọ láti kọlũ gbogbo ilẹ̀ nã.

23 Àti nísisìyí kò sì dúró nínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, ṣùgbọ́n ó kọjá lọ pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun nlá kan, àní sí ìhà ìlú-nlá Ibi-Ọ̀pọ̀; nítorípé ó jẹ́ ìpinnu rẹ̀ láti lọ kí ó sì fi idà gba ilẹ̀ nã, kí ó lè gba àwọn ilẹ̀ nã tí ó wà ní apá àríwá.

24 Àti pé ó lérò wípé inú ãrin ilẹ̀ nã ni agbára nwọn pọ̀ sí, nítorínã ó kọjá lọ, tí kò sì fún nwọn lãyè láti kó ara nwọn jọ bíkòṣe ní ọ̀wọ́ kékèké; ní ipò yĩ ni nwọ́n sì ṣe kọlù nwọ́n tí nwọ́n sì ké nwọn lulẹ̀.

25 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ogun Kóríántúmúrì yĩ tí ó mú kọjá lọ sí ãrin inú ilẹ̀ nã fún Móróníhà ní ànfãní púpọ̀ lórí nwọn, l’áìṣírò bí àwọn ará Nífáì tí nwọ́n ti pa ti pọ̀ tó.

26 Nítorí kíyèsĩ, Móróníhà ti rò wípé àwọn ará Lámánì kò lè dábã láti wá sínú ãrin ilẹ̀ nã, ṣùgbọ́n pé nwọn yíò kọlũ àwọn ìlú-nlá tí ó wà ní agbègbè etí ilẹ̀ nã gẹ́gẹ́bí nwọ́n ti í ṣe tẹ́lẹ̀rí; nítorínã ni Móróníhà ṣe mú kí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn tí ó lágbára dábõ bò àwọn ilẹ̀ tí ó wà ní agbègbè etí ilẹ̀ nã.

27 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àwọn ará Lámánì kò ní íbẹ̀rù gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n nwọ́n ti wá sínú ãrin ilẹ̀ nã nwọ́n sì ti gba olú-ìlú ilẹ̀ nã èyítí i ṣe ìlú-nlá Sarahẹ́múlà, nwọ́n sì nkọjá lọ sí àwọn ibití ó ṣe pàtàkì jùlọ nínú ilẹ̀ nã, tí nwọ́n sì npa àwọn ènìyàn nã ní ìpakúpa, àwọn ọkùnrin, àti àwọn obìnrin, àti àwọn ọmọdé, tí nwọ́n sì ngba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú-nlá àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ibi ìsádi.

28 Ṣùgbọ́n nígbàtí Móróníhà ti rí èyí, lójúẹsẹ̀ ni ó rán Léhì lọ pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan kãkiri láti lọ ṣãjú nwọn kí nwọn ó tó dé ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀.

29 Báyĩ ni ó sì ṣe; ó sì ṣãjú nwọn kí nwọn ó tó dé ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀, ó sì bá nwọn jagun, tóbẹ̃ tí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí sá padà sínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà.

30 Ó sì ṣe tí Móróníhà bọ́ síwájú nwọn nínú sísá padà nwọn, tí ó sì bá nwọn jagun, tóbẹ̃ tí ó di ogun tí ó gbóná lọ́pọ̀lọpọ̀; bẹ̃ni, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni nwọ́n pa, nínú àwọn tí nwọ́n pa ni a ti rí Kóríántúmúrì.

31 Àti nísisìyí, kíyèsĩ, àwọn ará Lámánì kò lè sá padà lọ́nà kan tàbí òmíràn, bóyá ní apá àríwá, tàbí ní apá gũsù, tàbí ní apá ìlà oòrùn, tàbí ní apá ìwọ oòrùn, nítorítí àwọn ará Nífáì yí nwọn ká ní gbogbo ìhà.

32 Báyĩ sì ni Kóríántúmúrì ṣe tí ó lé àwọn ará Lámánì sí ãrin àwọn ará Nífáì tóbẹ̃ tí nwọ́n fi wà ní ìkáwọ́ agbára àwọn ará Nífáì, tí nwọ́n sì pa òun tìkararẹ̀, tí àwọn ará Lámánì sì jọ̀wọ́ ara nwọn lé àwọn ará Nífáì lọ́wọ́.

33 Ó sì ṣe tí Móróníhà tún gba ìlú-nlá Sarahẹ́múlà, tí ó sì mú kí àwọn ará Lámánì tí nwọ́n ti kó lẹ́rú ó jáde kúrò lórí ilẹ̀ nã ní àlãfíà.

34 Báyĩ sì ni ọdún kọkànlélógójì nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ dópin.