Àwọn Ìwé Mímọ́
Hẹ́lámánì 13


Èyí ni ìsọtẹ́lẹ̀ Sámúẹ́lì, ará Lámánì, sí àwọn ará Nífáì.

Èyítí a kọ sí àwọn orí 13 títí ó fi dé 15 ní àkópọ̀.

Orí 13

Sámúẹ́lì ẹ̀yà Lámánì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìparun àwọn ará Nífáì àfi bí nwọ́n bá ronúpìwàdà—Àwọn àti ọrọ̀ nwọn ni a fi bú—Nwọ́n kọ àwọn wòlĩ tí nwọ́n sì sọ nwọ́n ní okuta, àwọn ẹ̀míkẹ́mi yí nwọn kákiri, nwọ́n sì ńdunnú kiri nínú ìwà àìṣedẽdé. Ní ìwọ̀n ọdún 6 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí ó sì ṣe nínú ọdún kẹrìndínlãdọ́run, àwọn ará Nífáì sì wà nínú ìwà búburú, bẹ̃ni, nínú ìwà búburú tí ó pọ̀, nígbàtí àwọn ará Lámánì sì tẹramọ́ pípa òfin Ọlọ́run mọ́, ní ìbámu pẹ̀lú òfin Mósè.

2 Ó sì ṣe nínú ọdún yìi tí ẹnìkan wà tí à npè orúkọ rẹ̀ ní Sámúẹ́lì, ẹ̀yà Lámánì, ẹnití ó wá sínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, ó sì bẹ̀rẹ̀sí wãsù sí àwọn ènìyàn nã. Ó sì ṣe tí ó wãsù ìronúpìwàdà fún ọjọ́ pípẹ́, sí àwọn ènìyàn nã, nwọ́n sì lée jáde, ó sì ṣetán láti padà sí ilẹ̀ tirẹ̀.

3 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ohùn Olúwa tọ̃ wá, pé kí ó tún padà lọ, kí ó sì sọtẹ́lẹ̀ sí àwọn ènìyàn nã nípa ohunkóhun tí ó bá wá sí ọkàn rẹ̀.

4 Ó sì ṣe tí nwọn kò jẹ́ kí ó wọ inú ìlú nã; nítorínã ó lọ ó sì dúró lórí ògiri rẹ̀, ó sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde ó sì kígbe pẹ̀lú ohùn rara, ó sì sọtẹ́lẹ̀ sí àwọn ènìyàn nã nípa àwọn ohunkóhun tí Olúwa fi sí ọkàn rẹ̀.

5 Ó sì wí fún nwọn pé: Ẹ kíyèsĩ, èmi, Sámúẹ́lì, ará Lámánì, ni ó nsọ ọ̀rọ̀ Olúwa èyítí ó fi sí ọkàn mi; ẹ sì kíyèsĩ ó ti fií sí ọkàn mi láti sọọ́ fún àwọn ènìyàn yĩ pé àìṣègbè idà yíò wà ní gbígbé sókè lórí àwọn ènìyàn yĩ; irínwó ọdún kò sì ní kọjá kí àìṣègbè idà ó tó kọlũ àwọn ènìyàn yĩ.

6 Bẹ̃ni, ìparun tí ó tóbi ndúró de àwọn ènìyàn yĩ, dájúdájú ni ó nbọ̀ lórí àwọn ènìyàn yĩ, kò sì sí ohun tí ó lè gbà nwọ́n bíkòṣe ìrònúpìwàdà àti ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì Olúwa, tí nbọ̀ dájúdájú sínú ayé yĩ, tí yíò sì faradà ohun púpọ̀ àti tí a ó pa fún àwọn ènìyàn rẹ̀.

7 Ẹ kíyèsĩ, ángẹ́lì Olúwa kan ti sọ ọ́ fún mi, ó sì mú ìròhìn ayọ̀ sínú ọkàn mi. Ẹ sì kíyèsĩ, a rán mi láti sọọ́ fún nyín pẹ̀lú, kí ẹ̀yin ó lè ní ìròhìn ayọ̀ ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ ẹ̀yin kò gbà mí.

8 Nítorínã, báyĩ ni Olúwa wí: Nítorí líle ọkàn àwọn ènìyàn ará Nífáì, bíkòṣepé nwọ́n ronúpìwàdà, èmi yíò mú ọ̀rọ̀ mi kúrò lọ́dọ̀ nwọn, èmi yíò sì mú Ẹ̀mí mi kúrò lọ́dọ̀ nwọn, èmi kò sì ní gbà nwọ́n lãyè mọ́, èmi yíò sì yí ọkàn àwọn arákùnrin nwọn takò nwọ́n.

9 Irínwó ọdún kò sì ní kọjá kí èmi ó tó mú kí nwọn ó kọlũ nwọ́n; bẹ̃ni, èmi yíò bẹ̀ nwọ́n wò pẹ̀lú idà, àti pẹ̀lú ìyàn àti pẹ̀lú àjàkálẹ̀-àrùn.

10 Bẹ̃ni, èmí yíò bẹ̀ nwọ́n wò nínú gbìgbóná ìbínú mi, nínú àwọn ìran kẹrin àwọn ọ̀tá nyín, yíò sì wà lãyè, láti rí ìparun nyín pátápátá; èyí yíò sì rí bẹ̃ bíkòṣepé ẹ̀yin ronúpìwàdà, ni Olúwa wí; àwọn ìran kẹrin nnì yíò sì mú ìparun bá nyín.

11 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ronúpìwàdà kí ẹ sì yí padà sí ọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run yín èmi yíò mú ìbínú mi kúrò, ni Olúwa wí; bẹ̃ni, báyĩ ni Olúwa wí, alábùkún-fún ni àwọn tí yíò ronúpìwàdà tí nwọn yíò sì yí padà sí ọ́dọ̀ mi, ṣùgbọ́n ègbé ni fún ẹnití kò ronúpìwàdà.

12 Bẹ̃ni, ègbé ni fún ìlú-nlá Sarahẹ́múlà títóbi yĩ; nítorítí ẹ kíyèsĩ, nítorí àwọn tí ó jẹ́ olódodo ni a ṣe gbà á là; bẹ̃ni, ègbé ni fún ìlú-nlá títóbí yĩ, nítorítí mo wòye, ni Olúwa wí, pé púpọ̀ nínú nwọn ni ó wà, bẹ̃ni, àní èyítí ó jù nínú àwọn ará ìlú-nlá títóbí yĩ, tí yíò sé àyà nwọn le sí mi, ni Olúwa wí.

13 Ṣùgbọ́n alábùkún-fún ni àwọn tí yíò ronúpìwàdà, nítorítí àwọn ni èmi yíò dá sí. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, bí kò bá ṣe nítorí àwọn olódodo tí ó wà nínú ìlú-nlá títóbí yĩ, ẹ kíyèsĩ, èmi ìbá mú kí iná bọ́ láti ọ̀run kí ó sì pã run.

14 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, nítorí àwọn olódodo ni a ṣe dáa sí. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, àkokò nã dé tán, ni Olúwa wí, nígbàtí ẹ̀yin yíò lé àwọn olódodo kúrò lãrín yín, nígbànã ní ẹ̀yin yíò ṣetán fún ìparun; bẹ̃ni, ègbé ni fún ìlú-nlá títóbi yĩ, nítorí ìwà búburú àti ìwà ẽrí tí ó wà nínú rẹ̀.

15 Bẹ̃ni, ègbé sì ní fún ìlú-nlá Gídéónì, nítorí ìwà búburú àti ìwà ẽrí tí ó wà nínú rẹ̀.

16 Bẹ̃ni, ègbé sì ni fún gbogbo àwọn ìlú-nlá tí ó wà ní ilẹ̀ àyíká, èyítí àwọn ará Nífáì ní ní ìní, nítorí ìwà búburú àti ìwà ẽrí tí ó wà nínú nwọn.

17 Ẹ sì kíyèsĩ, a ó fi ilẹ̀ nã bú, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí, nítorí àwọn ènìyàn tí ó wà lórí ilẹ̀ nã, bẹ̃ni, nítorí ìwà búburú àti ìwà ẽrí nwọn.

18 Yíò sì ṣe, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí, bẹ̃ni, Ọlọ́run wa alágbára àti òlótítọ́, pé ẹnìkẹ́ni tí ó bá kó ìṣúra pamọ́ lórí ilẹ̀ ayé kò ní rí nwọn mọ́, nítorí ègún nlá tí ó wà lórí ilẹ̀ nã, àfi bí ó bá jẹ́ olódodo ènìyàn tí yíò sì fi pamọ́ nínú Olúwa.

19 Nítorítí èmi fẹ́, ni Olúwa wí, pé kí nwọ́n fi ìṣúra nwọn pamọ́ nínú mi; ègbé sì ni fún àwọn tí kò bá fi ìṣùra nwọn pamọ́ sínú mi; nítorítí kò sí ẹnití nfi ìṣúra rẹ̀ pamọ́ nínú mi bíkòṣe olódodo ènìyàn; ẹnití kò bá sì fi ìṣúra rẹ̀ pamọ́ sínú mi, ègbé ni fún un, àti ìṣúra nã, kò sì sí èyítí yíò rã padà nítorí ègún tí ó wà lórí ilẹ̀ nã.

20 Ọjọ́ nã sì nbọ̀ tí nwọn yíò fi ìṣura nwọn pamọ́, nítorípé nwọ́n ti kó ọkàn nwọn lé ọrọ̀; àti nítorípé nwọn ti kó ọkàn nwọn lé ọrọ̀ nwọn, tí nwọn yíò sì fi ìṣúra nwọn pamọ́ nígbàtí nwọ́n bá sálọ kúrò níwájú àwọn ọ̀tá nwọn; nítorípé nwọn kọ̀ láti fi nwọ́n pamọ́ nínú mi, ègbé ni fún nwọn àti àwọn ìṣúra nwọn; ní ọjọ́ nã ni a ó sì kọlũ nwọ́n, ni Olúwa wí.

21 Ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin ènìyàn ìlú-nlá títóbi yĩ, kí ẹ sì fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ mi; bẹ̃ni kí ẹ sì fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ tí Olúwa wí; nítorí ẹ kíyèsĩ, ó wípé a fi yín bú nítorí ọrọ̀ nyín, àti pẹ̀lú pé a ti fi ọrọ̀ nyín bú nítori ẹ̀yin tí kó ọkàn nyín le nwọn, tí ẹ̀yin kò sì fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ ẹni nã tí ó fi nwọn fún nyín.

22 Ẹ̀yin kò rántí Olúwa Ọlọ́run nyín nínú ohun tí ó ti fi bùkún nyín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin a máa rántí ọrọ̀ nyín ní gbogbo ìgbà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò dúpẹ́ lọ́wọ́ Olúwa Ọlọ́run nyín fún nwọ́n; bẹ̃ni, ọkàn nyín kò fà sí ọ̀dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n nwọn gbé sókè pẹ̀lú ìgbéraga tí ó tóbi, sí lílérí àti sí ìbínú líle, owú-jíjẹ, ìjà, àrakàn, inúnibíni, ìpànìyàn, àti onírurú ìwà àìṣedẽdé.

23 Ní ìdí èyí ni Olúwa Ọlọ́run mú kí ègún ó wá sí órí ilẹ̀ nã, àti sí órí àwọn ọrọ̀ nyín pẹ̀lú, èyí sì rí bẹ̃ nítorí ìwà àìṣedẽdé nyín.

24 Bẹ̃ni, ègbé ni fún àwọn ènìyàn yĩ, nítorí àkokò yĩ tí ó ti dé, tí ẹ̀yin lé wòlĩ jáde, tí ẹ sì nfi nwọ́n ṣe ẹlẹ́yà, tí ẹ sì nsọ nwọ́n ní okuta, tí ẹ sì pa nwọn, tí ẹ sì hu onírurú ìwà àìṣedẽdé sí nwọn, àní bí àwọn ará ìgbà nnì ti ṣe.

25 Àti nísisìyí nígbàtí ẹ̀yin bá nsọ̀rọ̀, ẹ̀yin nsọ wípé: Bí àwa bá wà láyé ní ìgbà àwọn bàbá nlá wa, àwa kì bá ti pa àwọn wòlĩ nnì; àwa kì bá ti sọ nwọ́n ní okuta, kí a sì lé nwọn jáde.

26 Ẹ kíyèsĩ ẹ̀yin burú jù nwọ́n lọ; nítorítí bí Olúwa ti wà lãyè, bí wòlĩ bá wá sí ãrín nyín tí ó sì sọ ọ̀rọ̀ Olúwa pẹ̀lú nyín, tí ó jẹ́rĩ sí ẹ̀ṣẹ̀ àti àìṣedẽdé nyín, ẹ̀yin yíò bínú síi, ẹ̀yin yíò sì lée jáde ẹ̀yin yíò sì wá onírurú ọ̀nà láti pã run; bẹ̃ni, ẹ̀yin yíò wípé wòlĩ èké ni í ṣe, àti pé ẹlẹ́ṣẹ̀ nií ṣe, àti ti èṣù, nítorípé ó jẹ́rĩ pé iṣẹ́ ọwọ́ nyín jẹ́ èyítí ó burú.

27 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, bí ẹnìkan bá wá sí ãrín nyín tí ó sì wípé: Ẹ ṣe eleyĩ, pé kò sì sí àìṣedẽdé; ẹ ṣe tọ̀hún pé ẹ̀yin kò sì ní jìyà; bẹ̃ni tí òun wípé: Ẹ máa rìn nínú ìgbéraga ọkàn nyín; bẹ̃ni, ẹ máa rìn nínú ìgbéraga ojú nyín, kí ẹ sì máa ṣe ohunkóhun tí ọkàn nyín bá fẹ́—bí ẹnìkan bá sì wá sí ãrin nyín tí ó sọ èyí, ẹ̀yin yíò gbã, ẹ ó sì sọ wípé wòlĩ ni.

28 Bẹ̃ni, ẹ̀yin yíò gbée ga, ẹ̀yin yíò sì fún un nínú ohun ìní nyín; ẹ̀yin yíò fún un nínú wúrà nyín, àti nínú fàdákà nyín, ẹ̀yin yíò sì wọ ẹ̀wù olówó-iyebíye síi lọ́rùn; àti nítorípé ó nsọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn pẹ̀lú nyín, tí òun sì sọ pé dáradára ni ohun gbogbo, nígbànã ni ẹ̀yin kò ní rí ohun tí ó burú nínú rẹ̀.

29 A! ẹ̀yin ènìyàn ìkà àti ìran aláìṣõtọ́ yĩ; ẹ̀yin aláìgbọ́ran àti ọlọ́rùn líle ènìyàn yĩ, báwo ni yíò ti pẹ́ tó ti ẹ̀yin rò pé Olúwa yíò gbà fún nyín? Bẹ̃ni, báwo ni yíò ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin yíò jẹ́ kí aṣiwèrè àti afọ́jú ènìyàn ó darí nyín? Bẹ̃ni, báwo ni yíò ti pẹ́ tó ti ẹ̀yin yíò yan òkùnkùn dípò ìmọ́lẹ̀?

30 Bẹ̃ni, ẹ kíyèsĩ, ìbínú Olúwa ti dé tán lórí nyín; ẹ kíyèsĩ, ó ti fi ilẹ̀ nã bú nítorí àìṣedẽdé nyín.

31 Ẹ sì kíyèsĩ, àkokò nã nbọ̀ tí yíò fi ọ̀rọ̀ nyín bú, tí nwọn yíò ma yọ́ bọ́rọ́, tí ẹ̀yin kò ní lè dì nwọ́n mú; ní ọjọ́ àìní nyín ẹ̀yin kò sì ní lè mú nwọn dání.

32 Ní ọjọ́ àìní nyín sì ni ẹ̀yin yíò ké pe Olúwa; lásán ni ẹ̀yin yíò sì kígbe, nítorí ìsọdáhórò nyín ti dé sí órí nyín, ìparun nyín sì ti wà dájúdájú; nígbànã ni ẹ̀yin yíò sọkún tí ẹ̀yin yíò sì ké ní ọjọ́ nã, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí. Nígbànã ni ẹ̀yin yíò pohùnréré ẹkún, tí ẹ ó sì wípé:

33 A! èmi ìbá ti ronúpìwàdà, tí èmi ìbá má sì pa àwọn wòlĩ nì, tí mo sọ nwọ́n ní okuta, tí mo sì lé nwọn jáde. Bẹ̃ni ní ọjọ́ nã ẹ̀yin yíò wípé: Àwa ìbá ti rántí Olúwa Ọlọ́run wa ní ọjọ́ tí ó fún wa ní ọrọ̀, nwọn kì bá sì ti má a yọ́ bọ́rọ́ tí àwa sì pàdánù nwọn; nítorítí ẹ kíyèsĩ, ọrọ̀ wa ti lọ kúrò lọ́dọ̀ wa.

34 Ẹ kíyèsĩ, àwa fi ohun èlò kan sí ibí nígbàtí ó sì di ọjọ́ kejì ó ti lọ; ẹ sì kíyèsĩ, nwọ́n mú àwọn idà wa kúrò lọ́dọ̀ wa ní ọjọ́ tí àwa nwá nwọn láti jagun.

35 Bẹ̃ni, àwa ti fi ìṣúra wa pamọ́ nwọ́n sì ti bọ́ kúrò lọ́wọ́ wá, nítorí ègún orí ilẹ̀ nã.

36 A! àwa ìbá ti ronúpìwàdà ní ọjọ́ nã ti ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ wá wá; nítorí ẹ kíyèsĩ a ti fi ilẹ̀ nã bú, ohun gbogbo sì ti di yíyọ̀ bọ̀rọ̀, àwa kò sì lè dì nwọ́n mú.

37 Ẹ kíyèsĩ, àwọn ẹmikẹmi ni ó yí wa ká, bẹ̃ni, àwọn ángẹ́lì ẹni nã tí ó ti wá ọ̀nà láti pa ọkàn wa run yí wa ká. Ẹ kíyèsĩ, àwọn àìṣedẽdé wa tóbi. A! Olúwa, ìwọ kò ha lè mú ìbínú rẹ̀ kúrò lórí wa bí? Báyĩ sì ní èdè nyín yíò rí ní àwọn ọjọ́ nã.

38 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, ọjọ́ ìdánwò nyín ti parí; ẹ̀yin tí foni-doni lórí ọjọ́ ìgbàlà nyín títí ó fi di èyítí ó pẹ́ ju títí ayé àìnípẹ̀kun, ìparun nyín sì wà dájúdájú; bẹ̃ni, nítorítí ẹ̀yin ti fi gbogbo ọjọ́ ayé nyín wa èyítí ẹ̀yin kò lè rí gbà kiri; ẹ̀yin sì nlépa àlãfíà nínú híhu ìwà àìṣedẽdé, ohun èyítí ó tako ìwà òdodo nnì èyítí nbẹ nínú Ọba Ayérayé wa.

39 A! ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ nã, ẹ̀yin ìbá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi! Èmi sì gbàdúrà kí ìbínú Olúwa kúrò lórí nyín, àti kí ẹ̀yin ó ronúpìwàdà kí a sì gbà nyín là.