Àwọn Ìwé Mímọ́
Hẹ́lámánì 5


Orí 5

Nífáì àti Léhì lo ara nwọn fún iṣẹ́ ìwãsù—Orúkọ nwọn tọ́ka nwọn sí gbígbé ayé nwọn ní ìbámu pẹ̀lú bí àwọn bàbá nlá nwọn ṣe gbé ayé nwọn—Krístì ṣe ìràpadà fún àwọn tí ó ronúpìwàdà—Nífáì àti Léhì yí ọkàn ènìyàn púpọ̀ padà a sì jù nwọ́n sínú tũbú, iná sì yí nwọn ká—Ìkũku tí ó ṣókùnkùn sì bò àwọn ọgọ̃rún mẹ́ta ènìyàn—Ayé mì tìtì, ohùn kan sì pàṣẹ fún àwọn ènìyàn láti ronúpìwàdà—Nífáì àti Léhì bá àwọn ángẹ́lì sọ̀rọ̀, iná sì yí àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã ká. Ní ìwọ̀n ọdún 30 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe nínú ọdún yĩ kannã, kíyèsĩ, Nífáì fi ìtẹ́ ìdájọ́ nã sílẹ̀ fún ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ njẹ Sẹ́sórámù.

2 Nítorítí gẹ́gẹ́bí ó ṣe wà pé nípa ohùn àwọn ènìyàn ni a ṣe fi àwọn òfin nwọn àti àwọn ìjọba nwọn lélẹ̀, àti pé àwọn tí ó yan búburú pọ̀ ju àwọn tí ó yan rere, nítorínã nwọ́n nmúrasílẹ̀ de ìparun ara nwọn, nítorítí àwọn òfin ti díbàjẹ́.

3 Bẹ̃ni, èyí nìkan sì kọ́; nwọ́n jẹ́ ọlọ́rùnlíle ènìyàn, tóbẹ̃ tí kò ṣeéṣe láti ṣe àkóso lórí nwọn pẹ̀lú òfin tabi àìṣègbè, láìjẹ́ fún ìparun nwọn.

4 Ó sì ṣe tí Nífáì kãrẹ nítorí àìṣedẽdé nwọn; ó sì fi ìtẹ́ ìdájọ́ sílẹ̀, ó si fi ara rẹ̀ fún wíwãsù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní gbogbo ìyókù ọjọ́ ayé rẹ̀, àti arákùnrin rẹ̀ Léhì pẹ̀lú, ní ìyókù gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀;

5 Nítorítí nwọ́n rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí bàbá nwọn Hẹ́lámánì bá nwọn sọ. Èyí sì ni àwọn ọ̀rọ̀ tí ó bá nwọn sọ:

6 Ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin ọmọ mi, mo fẹ́ kí ẹ̀yin ó rántí láti pa òfin Ọlọ́run mọ́; èmi sì fẹ́ kí ẹ̀yin ó kéde àwọn ọ̀rọ̀ yĩ fún àwọn ènìyàn. Ẹ̀ kíyèsĩ, èmi ti fún nyín ní orúkọ àwọn òbí wa àkọ́kọ́ tí nwọn jáde wa láti ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù; mo sì ṣe èléyĩ pé nígbàtí ẹ̀yin ó bá rántí orúkọ nyín pé ẹ̀yin ó lè rántí nwọn; tí ẹ̀yin bá sì rántí nwọn ẹ̀yin yiò rántí àwọn iṣẹ́ nwọn; nígbàtí ẹ̀yin bá sì rántí àwọn iṣẹ́ nwọn ẹ̀yin yíò mọ̀ pé a ti sọọ́, a sì ti kọọ́, pé nwọ́n dára.

7 Nítorínã, ẹ̀yin ọmọ mi, mo fẹ́ kí ẹ̀yin ó ṣe èyítí ó dára, kí a lè sọ nípa nyín, àti kí a kọọ́, àní gẹ́gẹ́bí a ti sọọ́ àti bí a sì ti kọọ́ nípa nwọn.

8 Àti nísisìyí ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ kíyèsĩ mo ní ohun kan tí èmi tún fẹ́ kí ẹ̀yin ó ṣe, ohun nã sì ni, pé kí ẹ̀yin ó máṣe ṣe àwọn ohun wọ̀nyí láti gbéraga, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin ó ṣe àwọn ohun wọ̀nyí láti lè to ìṣura jọ fún ara nyín ní ọ̀run, bẹ̃ni, èyítí ó wà láéláé, àti èyítí kò lè parẹ́; bẹ̃ni, kí ẹ̀yin kí ó lè ní ẹ̀bùn iyebíye nnì tí í ṣe ìyè àìnípẹ̀kun, èyítí àwa mọ̀ dájú wipé a ti fifún àwọn bàbá nlá wa.

9 A!, rántí, ẹ rántí, ẹ̀yin ọmọ mi, àwọn ọ̀rọ̀ èyítí ọba Bẹ́njámínì sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀; bẹ̃ni, ẹ rántí pé kò sí ọ̀nà míràn tàbí ipa ọ̀nà èyítí a fi lè gba ènìyàn là, àfi nípa ìṣètùtù ẹ̀jẹ̀ Jésù Krístì, tí nbọ̀wá; bẹ̃ni, kí ẹ rántí pé ó nbọ̀wá láti ra aráyé padà.

10 Ẹ sì tún rántí àwọn ọ̀rọ̀ ti Ámúlẹ́kì sọ fún Sísrọ́mù, nínú ìlú-nlá Amonáíhà; nítorítí ó wí fún un pé Olúwa nbọ̀ dájúdájú láti ra àwọn ènìyàn rẹ̀ padà, ṣùgbọ́n kò lè wá láti rà nwọ́n padà nínú ìwà ẹ̀ṣẹ̀ nwọn, ṣùgbọ́n láti rà nwọ́n padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ nwọn.

11 À sì ti fi agbára fún un láti ọ̀dọ̀ Bàbá láti rà nwọ́n padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ nwọn nítorí ìrònúpìwàdà; nítorínã ni ó ṣe rán àwọn ángẹ́lì rẹ̀ láti kéde ìròhìn ayọ̀ nípa ti ìrònúpìwàdà, èyítí í mú ènìyàn wá sínú agbára Olùràpadà nã, sí ti ìgbàlà ọkàn nwọn.

12 Àti nísisìyí, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ rántí, ẹ rántí pé lórí àpáta Olùràpadà wa, ẹnití íṣe Krístì, Ọmọ Ọlọ́run, ni ẹ̀yin níláti kọ́ ìpìlẹ̀ nyín lé, pé nígbàtí èṣù bá sì fẹ́ ẹ̀fũfù líle rẹ̀ wá, bẹ̃ni, ọ̀pá rẹ̀ nínú ìjì, bẹ̃ni, nígbàtí gbogbo àwọn òkúta yìnyín rẹ̀ àti ìjì líle rẹ̀ bá rọ̀ lé yín kò lè ní agbára lórí yín láti fà yín sínú ọ̀gbun òṣì àti ègbé aláìlópin, nítorí àpáta èyítí a kọ́ yín lé lórí, èyítí íṣe ìpìlẹ̀ tí o dájú, ìpìlẹ̀ èyítí ènìyàn kò lè ṣubú lórí rẹ̀ bí nwọ́n bá kọ́ lé e lórí.

13 Ó sì ṣe tí èyí sì jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí Hẹ́lámánì fi kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀; bẹ̃ni, ó kọ́ nwọn ní ohun púpọ̀ tí a kò kọ sílẹ̀, àti àwọn ohun púpọ̀ tí a kọ sílẹ̀.

14 Nwọ́n sì rántí ọ̀rọ̀ rẹ̀; nítorínã nwọ́n sì jáde lọ, ní pípa òfin Ọlọ́run mọ́, láti kọ́ni ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lãrín gbogbo àwọn ènìyàn Nífáì, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀ láti ìlú-nlá Ibi-Ọ̀pọ̀;

15 Àti láti ibẹ̀ lọ sí ìlú-nlá Gídì; àti láti ìlú-nlá Gídì lọ sí ìlú-nlá Múlẹ́kì;

16 Àní nwọ́n sì lọ láti ìlú-nlá kan dé òmíràn, títí nwọn fi lọ lãrín gbogbo àwọn ènìyàn Nífáì tí nwọn wà ní ilẹ̀ tí ó wà lápá gũsù; àti láti ibẹ̀ lọ sí inú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, lãrín àwọn ará Lámánì.

17 Ó sì ṣe tí nwọ́n wãsù pẹ̀lú agbára nlá, tóbẹ̃ tí nwọ́n fi da púpọ̀ nínú àwọn olùyapa kúrò nnì lãmú, àwọn tí nwọ́n ti jáde lọ kúrò lára àwọn ará Nífáì ṣãjú, tóbẹ̃ tí nwọn jáde wá tí nwọ́n sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ nwọn tí a sì rì nwọn bọmi sí ìrònúpìwàdà, nwọ́n sì padà ní ojúkannã lọ bá àwọn ará Nífáì láti gbìyànjú láti ṣe àtúnṣe fún nwọn ní ti àwọn ohun búburú tí nwọ́n ti ṣe.

18 Ó sì ṣe tí Nífáì àti Léhì wãsù sí àwọn ará Lámánì pẹ̀lú agbára àti àṣẹ nlá, nítorípé a ti fún nwọn ní agbára àti àṣẹ láti lè sọ̀rọ̀, a sì ti fún nwọn ní ohun tí nwọn yíò sọ—

19 Nítorínã nwọ́n sì sọ̀rọ̀ sí ìyàlẹ́nu nlá àwọn ará Lámánì, sí ti ìdánilójú fún nwọn, tóbẹ̃ tí àwọn tí a rìbọmi sí ìrònúpìwàdà nínú àwọn ará Lámánì nã tí ó wà ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà jẹ́ ẹgbãrin, tí nwọ́n sì ní ìdánilójú nípa àṣà búburú àwọn bàbá nwọn.

20 Ó sì ṣe tí Nífáì àti Léhì kúrò níbẹ̀ láti lọ sínú ilẹ̀ Nífáì.

21 Ó sì ṣe tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì kan mú nwọn tí nwọ́n sì jù nwọ́n sínú tũbú; bẹ̃ni, àní nínú tũbú kannã nínú èyítí àwọn ìránṣẹ́ Límháì ju Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ sí.

22 Lẹ́hìn tí a sì ti jù nwọ́n sínú tũbú fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ láì fún nwọn ní óúnjẹ, ẹ kíyèsĩ, nwọ́n jáde lọ sínú tũbú nã láti mú nwọn kí nwọ́n sì pa nwọ́n.

23 Ó sì ṣe tí ohun nã èyítí ó rí bí iná yí Nífáì àti Léhì ká, àní tóbẹ̃ tí nwọn kò lè fọwọ́kàn nwọ́n rárá ní ìbẹ̀rù pé àwọn yíò jóná. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, Nífáì àti Léhì kò jóná; nwọ́n sì wà bí ẹnití ó wà nínú iná tí nwọn kò sì jóná.

24 Nígbàtí nwọ́n sì ríi pé ọ̀wọ́ iná ni ó yí nwọn ká, àti pé kò jó nwọn, ọkàn nwọn gba ìkìyà.

25 Nítorítí nwọ́n ríi pé àwọn ará Lámánì kò lè fọwọ́kàn nwọ́n rárá; bẹ̃ni nwọn kò lè súnmọ́ nwọn, ṣùgbọ́n nwọ́n dúró bí èyítí ó yadi pẹ̀lú ìyàlẹ́nu.

26 Ó sì ṣe tí Nífáì àti Léhì dide dúró tí nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí sọ̀rọ̀ sí nwọn, wípé: Ẹ má bẹ̀rù, nítorí ẹ kíyèsĩ, Ọlọ́run ni ẹnití ó fi ohun ìyanu yĩ hàn yín, nínú èyítí a fi hàn nyín pé ẹ̀yin kò lè fi ọwọ́ nyín kàn wá láti pa wá.

27 Ẹ sì kíyèsĩ, nígbàtí nwọ́n sọ àwọn ọ̀rọ̀ yĩ tán, ilẹ̀ mì tìtì púpọ̀púpọ̀, àwọn ògiri inú tũbú nã sì mì tìtì bí èyítí nwọn yíò wó lulẹ̀; ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, nwọn kò ṣùbú lulẹ̀. Ẹ sì kíyèsĩ, àwọn ará Lámánì àti àwọn ará Nífáì tí ó ti yapa ni àwọn tí ó wà nínú tũbú nã.

28 Ó sì ṣe tí ikũku tí ó ṣókùnkùn bò nwọn mọ́lẹ̀, ẹ̀rù nlá sì balé nwọn.

29 Ó sì ṣe tí ohùn kan sì wá bí èyítí ó wá láti òkè ikũku tí ó ṣókùnkùn nã, tí ó wípé: Ẹ ronúpìwàdà, ẹ ronúpìwàdà, ẹ sì ṣíwọ́ pípa àwọn ìránṣẹ́ mi tí a rán sí nyín láti mú ìhìn-rere wá fún nyín.

30 Ó sì ṣe lẹ́hìn tí nwọ́n gbọ́ ohùn yĩ, tí nwọ́n sì rí i pé kì í ṣe ohùn ãrá, bẹ̃ni tí kì í ṣe ohùn ìrúkèrúdò nlá, ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ohùn pẹ̀lẹ́ dídákẹ́ rọ́rọ́ ni, bí ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, tí ó sì wọ inú ọkàn lọ—

31 Àti l’áìṣírò ohùn nã jẹ́ èyítí ó wà ní pẹ̀lẹ́ dídákẹ́ rọ́rọ́, ẹ kíyèsĩ ilẹ̀ mì tìtì púpọ̀púpọ̀, àwọn ògiri inú tũbú sì tún gbọ̀n rìrì, bí èyítí yíò wó lulẹ̀; ẹ sì kíyèsĩ ikũku tí ó ṣókùnkùn nã, èyítí ó ti bò nwọ́n mọ́lẹ̀, kò túká—

32 Ẹ sì kíyèsĩ ohùn nã tún wá, ó wípé: Ẹ ronúpìwàdà, ẹ ronúpìwàdà, nítorítí ìjọba ọ̀run fẹ́rẹ̀ dé; ẹ sì ṣíwọ́ pípa àwọn ìránṣẹ́ mi. Ó sì ṣe tí ilẹ̀ tún mì tìtì, tí àwọn ògiri sì gbọ̀n rìrì.

33 Àti pẹ̀lú ni ohùn nã tún wá lẹ̃kẹ̀ta, tí ó sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ ìyanu fún nwọn èyítí ẹnìkẹ́ni kò lè sọ; àwọn ògiri nã sì tún gbọ̀n rìrì, ilẹ̀ sì mì tìtì bí ẹnipé yíò pínyà.

34 Ó sì ṣe tí àwọn ará Lámánì kò lè sá nítorí ìkukù tí ó ṣókùnkùn nã èyítí ó bò nwọ́n mọ́lẹ̀; bẹ̃ni, àti pé nwọn kò lè kúrò lójúkan nítorí ẹ̀rù tí ó bà nwọ́n.

35 Nísisìyí ẹnìkan wà lãrín nwọn tí í ṣe ará Nífáì nípa ìbí, ẹnití ó wà nínú ìjọ Ọlọ́run tẹ́lẹ̀ rí ṣùgbọ́n tí ó ti yapa kúrò lára nwọn.

36 Ó sì ṣe tí ó yísẹ̀ padà, sì kíyèsĩ, ó rí ojú Nífáì àti Léhì nínú ikũku tí ó sokunkun nã; ẹ sì kíyèsĩ, nwọ́n ndán yinrinyinrin, àní bí ojú àwọn ángẹ́lì. Ó sì ríi pé nwọ́n gbé ojú nwọn sókè sí ọ̀run; nwọ́n sì wà bí ẹnití nsọ̀rọ̀ tàbí tí ó ngbé ohùn rẹ̀ sókè sí ẹnìkan èyítí nwọ́n nwò.

37 Ó sì ṣe tí ọkùnrin nã sì ké lóhùnrara sí àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã, kí nwọn ó lè yípadà kí nwọn ó sì wò. Sì kíyèsĩ a fún nwọn ní agbára kí nwọ́n lè yípadà kí nwọ́n sì wò; nwọ́n sì rí ojú Nífáì àti Léhì.

38 Nwọ́n sì wí fún ọkùnrin nã pé: Kíyèsĩ, kíni ìtumọ̀ àwọn ohun wọ̀nyí, àti pé tani ẹni nã tí àwọn ọkùnrin yĩ nbá sọ̀rọ̀?

39 Nísisìyí orúkọ ọkùnrin nã ni Ámínádábù. Ámínádábù sì wí fún nwọn pé: Àwọn ángẹ́lì Ọlọ́run ni nwọ́n nbá sọ̀rọ̀.

40 Ó sì ṣe tí àwọn ará Lámánì wí fún un pé: Kíni àwa yíò ṣe, tí ìkũkù tí ó ṣókùnkùn yĩ yíò ká kúrò kí ó má sì bò wá mọ́lẹ̀?

41 Ámínádábù sì wí fún nwọn pé: Ẹ níláti ronúpìwàdà kí ẹ sì kígbe pé ohùn nã, àní títí ẹ̀yin ó fi ní ìgbàgbọ́ nínú Krístì, ẹnití Álmà, àti Ámúlẹ́kì, àti Sísrọ́mù ti kọ́ nyín lẹ́kọ̃ nípa rẹ̀; àti nígbàtí ẹ̀yin o bá ṣe eleyĩ, a ó ka ìkũkù tí ó ṣókùnkùn nnì kúrò kí ó má lè bò nyín mọ́lẹ̀ mọ́.

42 Ó sì ṣe tí gbogbo nwọn bẹ̀rẹ̀sí kígbe pé ohùn ẹni nã tí ó ti mí ilẹ̀ tìtì; bẹ̃ni, nwọ́n sì nkígbe àní títí ìkũkù tí ó ṣókùnkùn nã fi túká.

43 Ó sì ṣe nígbàtí nwọ́n wò yíká, tí nwọ́n sì ríi pé ìkũkù tí ó ṣókùnkùn nã tí tuka láti má bò nwọ́n mọ́lẹ̀, ẹ kíyèsĩ, nwọ́n ríi pé ọ̀wọ́ iná yi nwọn ka, bẹ̃ni ọkàn kọ̃kan, pẹ̀lú ọwọ iná.

44 Nífáì àti Léhì sì wà lãrín nwọn; bẹ̃ni, nwọ́n wà ní àkámọ́; bẹ̃ni, nwọ́n wà bí ẹnití ó wà lãrín iná tí njó, síbẹ̀ kò sì pa nwọ́n lára, bẹ̃ni kò sì ràn mọ́ àwọn ògiri inú tũbú; nwọ́n sì kún fún ayọ̀ nnì èyítí ẹnu kò lè sọ àti tí ó kún fún ògo.

45 Ẹ sì kíyèsĩ, Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run sì sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀run, ó sì wọ inú ọkàn nwọn lọ, ó sì kún inú nwọn bí iná, nwọ́n sì lè sọ ọ̀rọ̀ ìyanu jáde.

46 Ó sì ṣe tí ohùn kan jáde tọ̀ nwọ́n wá, bẹ̃ni, ohùn dáradára kan, èyítí ó dàbí ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, tí ó wípé:

47 Àlãfíà, àlãfíà fún nyín, nítorí ìgbàgbọ́ tí ẹ̀yin ní nínú Àyànfẹ́ Ọmọ mi, ẹnití ó ti wà láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé.

48 Àti nísisìyí, nígbàtí nwọ́n gbọ́ èyĩ nwọ́n gbé ojú nwọn sókè bí láti lè wo ibití ohùn nã gbé wá; ẹ sì kíyèsĩ, nwọ́n rí ọ̀run tí ó ṣí sílẹ̀; tí àwọn ángẹ́lì sì sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run jáde wá tí nwọn sì njíṣẹ́ fún nwọn.

49 Ó sì tó bí ènìyàn ọgọrun mẹ́ta tí nwọn rí ti nwọn si gbọ́ ohun wọ̀nyí, a sì ní kí nwọn jáde lọ kí nwọn ó má sì bẹ̀rù, bẹ̃ni kí nwọn ó má ṣe ṣiyèméjì.

50 Ó sì ṣe tí nwọ́n jáde lọ, tí nwọ́n sì njíṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn nã, tí nwọn nsọ gbogbo ohun tí nwọ́n ti gbọ́ àti èyítí nwọ́n ti rí jákè-jádò ilẹ̀ nã, tóbẹ̃ tí púpọ̀ nínú àwọn ará Lámánì nã gba ìdánilójú nípa nwọn, nítorí títóbi ẹ̀rí tí nwọ́n ti gbà.

51 Àti pé gbogbo àwọn tí nwọ́n ti gba ìdánilójú ni ó kó àwọn ohun ìjà nwọn lélẹ̀, àti àwọn ikorira tí nwọ́n ní àti àṣà àwọn bàbá nwọn pẹ̀lú.

52 Ó sì ṣe tí nwọ́n jọ̀wọ́ àwọn ilẹ̀ tí í ṣe ìní àwọn ará Nífáì sílẹ̀ fún nwọn.