Àwọn Ìwé Mímọ́
Hẹ́lámánì 12


Orí 12

Àwọn ènìyàn a máa ṣe aláìfẹsẹ̀ mulẹ̀ nwọ́n sì jẹ́ aláìgbọ́n nwọ́n sì yára láti ṣe búburú—Olúwa a máa bá àwọn ènìyàn rẹ̀ wí—A fi ipò asán àwọn ènìyàn wé agbára Ọlọ́run—Ní ọjọ́ ìdájọ́, àwọn ènìyàn yíò rí ayé àìnípẹ̀kun gbà tàbí ìdálẹ́bi ayérayé. Ní ìwọ̀n ọdún 6 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti báyĩ àwa lè ríi bí àwọn ọmọ ènìyàn ti jẹ́ aláìṣõtọ́ tó, àti bí ọkàn nwọn ti wà láìdúróṣinṣin tó; bẹ̃ni àwa lè ríi pé Olúwa nínú dídára rẹ̀ nlá, tí kò lópin a máa bùkún fun, a sì máa mú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ nwọn lé e ṣe dẽdé.

2 Bẹ̃ni, àwa sì lè ríi ní àkókò nã gan nígbàtí ó bá bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀, bẹ̃ni, nínú èrè oko nwọn, àwọn ọ̀wọ́ àti agbo ẹran nwọn, àti nínú wúrà àti nínú fàdákà àti nínú onírurú ohun olówó-iyebíye lóríṣiríṣi; tí ó sì dá ẹ̀mí nwọn sí, tí ó sì gba nwọn lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá nwọ́n; tí ó sì mú ọkàn àwọn ọ̀tà nwọn rọ̀ tí nwọn kò sì gbógun tì nwọ́n; bẹ̃ni, àti ní kúkúrú, tí ó ṣe ohun gbogbo fún àlãfíà àti inúdídùn àwọn ènìyàn rẹ̀; bẹ̃ni, nígbànã ni nwọn yíò sé ọkàn nwọn le, tí nwọ́n sì gbàgbé Olúwa Ọlọ́run nwọn, tí nwọn yíò sì tẹ Ẹmí Mímọ́ nnì mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ nwọn—bẹ̃ni, èyí sì rí bẹ̃ nítorítí nwọ́n wà ní ípò ìdẹ̀ra, àti nítorí ọrọ̀ púpọ̀ tí nwọ́n ní.

3 Báyĩ ni àwa sì rí i pé bí kò ṣe pé Olúwa bá àwọn ènìyàn rẹ̀ wí pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú, bẹ̃ni, bí kò ṣe pé ó bẹ̀ nwọ́n wò pẹ̀lú ikú àti ẹ̀rù, àti pẹ̀lú ìyàn, àti pẹ̀lú onírurú àjàkálẹ̀-àrùn, nwọn kò ní rántí rẹ̀.

4 A! báwo ni nwọ́n ti jẹ́ aláìgbọ́n tó, àti olùgbéraga, àti olùṣebúburú, àti ẹlẹmi èṣù, àti báwo ni nwọ́n ti yára tó láti ṣe àìṣedẽdé, àti báwo ni àwọn ọmọ ènìyàn, ti lọ́ra láti ṣe èyítí ó dára tó; bẹ̃ni, báwo ni nwọ́n ti yára tó láti tẹtisi ẹni búburú nnì, àti láti kó ọkàn nwọn lé àwọn ohun asán ayé!

5 Bẹ̃ni, báwo ni nwọ́n ti yára tó láti gbé ọkàn sókè nínú ìgbéraga; bẹ̃ni, báwo ni nwọ́n ti yára làti lérí tó átí láti hu onírurú ìwà àìṣedẽdé; àti báwo ni nwọ́n ti lọ́ra tó láti rántí Olúwa Ọlọ́run nwọn, àti láti fetísí ìmọ̀ràn rẹ̀, bẹ̃ni, báwo ni nwọ́n ti lọ́ra tó láti rìn ní ọ́nà ọgbọ́n!

6 Ẹ kíyèsĩ, nwọn kò ní ìfẹ́ pé kí Olúwa Ọlọ́run nwọn, ẹnití ó dá nwọn, kí ó jọba lórí nwọn; l’áìṣírò ire àti ãnú rẹ̀ pọ̀ sí nwọn, nwọ́n ka ìmọ̀ràn rẹ̀ kún asán, nwọn kò sì fẹ́ kí ó ṣe amọ̀nà nwọn.

7 A! báwo ni ipò asán àwọn ọmọ ènìyàn ti tóbi tó, bẹ̃ni, àní nwọn kò dára tó erùpẹ̀ ilẹ̀.

8 Nítorí kíyèsĩ, erùpẹ̀ ilẹ̀ a máa lọ sihin àti sọhun, a sì fọ́nká, ní ìgbọ́ran sí àṣẹ Ọlọ́run wa ayérayé tí ó tóbi.

9 Bẹ̃ni, ẹ kíyèsĩ ó sọ̀rọ̀ àwọn òkè kékèké àti àwọn òkè gíga wá rìrì nwọ́n sì mì tìtì.

10 Nípa agbára ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ni nwọ́n fọ́ sí wẹ́wẹ́, nwọ́n sì di pẹ̀tẹ́lẹ̀, bẹ̃ni àní bí àfonífojì.

11 Bẹ̃ni, nípa agbára ohùn rẹ ní gbogbo ayé ni tìtì.

12 Bẹ̃ni, nípa agbára ohun rẹ, ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé mì tìtì, àní tí ó fi dé agbedeméjì rẹ̀.

13 Bẹ̃ni, bí ó bá sì sọ fún ayé wípé—Ṣí ipò padà—yíò ṣí ípò padà.

14 Bẹ̃ni, bí o bá sọ fún ayé wípé—Ìwọ yíò sún padàsẹ́hìn, kí ó lè mú kí ojúmọ́ kí ó gùn síi fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí—ó sì rí bẹ̃;

15 Àti báyĩ, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ayé sún padà sẹ́hìn, lójú ọmọ ènìyàn ó sì dàbí èyítí oòrùn dúró lójúkan; bẹ̃ni, ẹ sì kíyèsĩ, èyí sì rí bẹ̃; nítorítí dájúdájú ayé ni ó ṣípòpadà kĩ sĩ ṣe oòrùn.

16 Ẹ sì kíyèsĩ, pẹ̀lú, bí ó bá sọ fún àwọn omi inú ibú nlá wípé—Ẹ di gbígbẹ—ó rí bẹ̃.

17 Ẹ kíyèsĩ, bí ó bá sọ fún òkè gíga yĩ—Dìde, kí ó sì bọ́ sí ìhín kí o wó lu ìlú-nlá nnì, kí ó sì di bíbòmọ́lẹ̀ pátápátá—ẹ kíyèsĩ ó rí bẹ̃.

18 Ẹ sì kíyèsĩ, bí ẹnìkan bá fi ìṣúra pamọ́ sínú ilẹ̀, tí Olúwa sì wípé: Kí ó di ìfibú, nítorí ìwà àìṣedẽdé ẹnití ó fi pamọ́—ẹ kíyèsĩ, yíò di ìfíbú.

19 Bí Olúwa bá sì wípé—Kí ìwọ ó di ìfibú, kí ẹnìkẹ́ni ó má lè rí ọ mọ́ láti àkokò yĩ lọ àti títí láéláé—ẹ kíyèsĩ, ẹnìkẹ́ni kò lè ríi mọ́ láti àkokò yĩ lọ àti títí láéláé.

20 Ẹ kíyèsĩ, bí Olúwa yíò bá wí fún ẹnìkan pé—Nítorí àwọn àìṣedẽdé rẹ, ìwọ yíò di ìfibú títí láéláé—yíò rí bẹ̃.

21 Bí Olúwa yíò bá sí wípé—Nítorí àwọn àìṣedẽdé rẹ̀ ìwọ yíò di kíké kúrò níwájú mi—yíò sì mú kí ó rí bẹ̃.

22 Ègbé sì ni fún ẹnití yíò sọ eleyĩ fún, nítorítí yíò rí bẹ̃ fún ẹnití ó bá ṣe àìṣedẽdé, a kò sì lè gbã là; nítorínã, fún ìdí èyí, láti lè gba ènìàyn là, ni a ti sọ nípa ìrònúpìwàdà.

23 Nítorínã, alábùkún-fún ni àwọn tí yíò ronúpìwàdà tí nwọn yíò sì tẹtisi ohùn Olúwa Ọlọ́run nwọn; nítorítí àwọn yĩ ni a ó gbàlà.

24 Kí Ọlọ́run kí ó jẹ́, nínú pípé rẹ̀, kí a mú àwọn ènìyàn sí ìrònúpìwàdà àti iṣẹ́ rere, kí a lè fún nwọn ní õre-ọ̀fẹ́ kún õre-ọ̀fẹ́, gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ nwọn.

25 Èmi sì fẹ́ kí gbogbo ènìyàn di gbìgbàlà. Ṣùgbọ́n a ríi kà pé ní ọjọ́ ìkẹhìn nlá nnì àwọn kan wà tí a ó lé jáde, bẹ̃ni, tí a ó lé kúrò ní iwájú Olúwa;

26 Bẹ̃ni, àwọn ni a ó yàn sí ipò ìrora tí kò lópin, báyĩ sì ni nwọn yíò mú ọ̀rọ̀ nã ṣẹ tí ó wípé: Àwọn tí ó ti ṣe rere yíò ní ìyè àìlópin; àwọn tí ó sì ti ṣe búburú yíò ní ìdálẹ́bi àìlópin. Báyĩ sì ni ó rí. Àmín.