Àwọn Ìwé Mímọ́
Hẹ́lámánì 9


Orí 9

Àwọn oníṣẹ́ rí adájọ́ àgbà tí ó ti kú lórí ìtẹ́ ìdájọ́—Nwọ́n fi nwọ́n sínú tũbú, nwọ́n sì tún tú nwọn sílẹ̀—Nípa ìmísí Nífáì fi Síátúmì hàn bĩ apànìyàn nã—Díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn nã gba Nífáì gẹ́gẹ́bí wòlĩ. Ní ìwọ̀n ọdún 23–21 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Ẹ kíyèsĩ, nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Nífáì ti sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, àwọn kan tí nwọ́n wà lãrín nwọn sáré lọ sí ibi ìtẹ́ ìdájọ́; bẹ̃ni, àní àwọn marun ni ó lọ, nwọ́n sì wí lãrín ara nwọn, bí nwọ́n ṣe nlọ pé:

2 Ẹ kíyèsĩ, nísisìyí àwa yíò mọ̀ dájúdájú bóyá wòlĩ ni ọkurin yĩ tí Ọlọ́run sì pãláṣẹ fún un láti sọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ohun ìyanu irú èyí fún wa. Ẹ kíyèsĩ, àwa kò gbàgbọ́ pé ó pãláṣẹ fún un; bẹ̃ni, àwa ko gbàgbọ́ pé wòlĩ ni; bíótilẹ̀ríbẹ̃, bí ohun yĩ tí ó sọ nípa adájọ́ àgbà bá jẹ́ òtítọ́, pé ó ti kú, nígbànã ni àwa yíò gbàgbọ́ pé òtítọ́ ni àwọn ọ̀rọ̀ yókù tí ó ti sọ.

3 Ó sì ṣe tí nwọ́n sáré tagbáratagbára, tí nwọ́n sì wọlé sí ibi ìtẹ́ ìdájọ́; ẹ sì kíyèsĩ, adájọ́ àgbà nã ti ṣubú lulẹ̀, ó sì wà nínú ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀.

4 Àti nísisìyí, ẹ kíyèsĩ, nígbàtí nwọ́n rí èyí ẹnu yà nwọ́n gidigidi, tóbẹ̃ tí nwọ́n ṣubú lulẹ̀; nítorítí nwọn kò gba ọ̀rọ̀ tí Nífáì sọ nípa adájọ́-àgbà gbọ́.

5 Ṣùgbọ́n nísisìyí nígbàtí nwọ́n rí ohun yĩ nwọ́n gbàgbọ́, ẹ̀rù sì bà nwọ́n pé gbogbo ìdájọ́ tí Nífáì ti sọ nípa rẹ̀ yíò dé bá àwọn ènìyàn nã; nítorínã ni nwọ́n ṣe wárìrì, tí nwọ́n sì ṣubú lulẹ̀.

6 Nísisìyí, ní kété tí nwọ́n ti pa adájọ́ nã—arákùnrin rẹ̀ ni ó sì gún un lọ́bẹ nínú ẹ̀wù tí ó wọ̀ tí ẹnìkẹ́ni kò lè dáa mọ̀, ó sì sálọ, àwọn ìránṣẹ́ nã sì sáré lọ í sọ fún àwọn ènìyàn nã, tí nwọ́n sì nkígbe ìpàniyan lãrin nwọn;

7 Ẹ sì kíyèsĩ àwọn ènìyàn nã sì kó ara nwọn jọ sí ibi ìtẹ́ ìdájọ́ nã—ẹ sì kíyèsĩ, sí ìyàlẹ́nu nwọn, nwọ́n rí àwọn ọkùnrin marun nnì tí nwọ́n ti ṣubú lulẹ̀.

8 Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, àwọn ènìyàn nã kò mọ́ ohunkóhun nípa àwọn ọ̀gọ̃rọ̀ ènìyàn tí nwọ́n ti pèjọ́ nínú ọgbà Nífáì; nítorínã nwọ́n sọ lãrín ara nwọn pé: Àwọn ọkùnrin yĩ ni àwọn tí ó pa onidajọ, Ọlọ́run sì ti lù nwọ́n tí nwọn kò lè sálọ kúrò lọ́wọ́ wa.

9 Ó sì ṣe tí nwọ́n mú nwọn, nwọ́n sì dè nwọ́n nwọ́n sì jù nwọ́n sínú tũbú. Nwọ́n sì ránṣẹ́ jáde lãrín àwọn ènìyàn nã pé nwọ́n ti pa adájọ́, àti pé nwọ́n ti mú àwọn apànìyàn nã nwọ́n sì ti jù nwọ́n sínú tũbú.

10 Ó sì ṣe ní ọjọ́ kejì tí àwọn ènìyàn nã sì péjọ pọ láti ṣọ̀fọ̀ àti láti gbãwẹ̀, níbití nwọ́n gbé nsin òkú onidajọ-àgbà olókìkí nnì tí nwọ́n pa.

11 Àti báyĩ pẹ̀lú ni àwọn onidajọ nnì tí nwọ́n wà ní ọgbà Nífáì, tí nwọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, nã péjọ pọ̀ sí ibi ìsìnkú nã.

12 Ó sì ṣe tí nwọ́n nbẽrè lãrín àwọn ènìyàn nã, wípé: Àwọn marun nã tí a rán láti lọ ṣe ìwãdí nípa adájọ́ àgbà nã bóyá ó ti kú dà? Nwọ́n sì dáhùn nwọ́n wípé: Nípa àwọn marun yĩ ti ẹ̀yin ní ẹ ran níṣẹ́, àwa kò mọ̀; ṣùgbọ́n àwọn marun kan wà tí nwọn í ṣe apànìyàn, tí àwa sì ti jù sínú tũbú.

13 Ó sì ṣe tí àwọn onidajọ nã ní kí nwọn mú nwọn wá; nwọn sì mú wọn wá, sì kíyèsĩ àwọn ni àwọn marun tí nwọ́n ti rán níṣẹ́; ẹ sì kíyèsĩ àwọn onidajọ nã bẽrè lọ́wọ́ nwọn láti mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ nã, nwọ́n sì sọ fún nwọn nípa gbogbo ohun tí àwọn tí ṣe, wípé:

14 Àwa sáré a sì dé ibi ìtẹ́ ìdájọ́, nígbàtí àwa sì rí ohun gbogbo àní bí Nífáì ti jẹrisi, ẹnu yà wá tóbẹ̃ tí àwa ṣubú lu ilẹ̀; nígbàtí àwa sì ta jí kúrò nínú ìyàlẹ́nu wa, kíyèsĩ nwọn ti jù wá sínú tũbú.

15 Nísisìyí, nípa ti pípa ọkùnrin yĩ, àwa kò mọ́ ẹnití ó ṣeé; ohun tí àwa mọ̀ kòju èyí, a sáré a sì wá gẹ́gẹ́bí ẹ̀yin ti fẹ́, kí ẹ sì kíyèsĩ ó ti kú, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Nífáì.

16 Àti nísisìyí ó sì ṣe tí àwọn onidajọ nã sì ṣe àlàyé ọ̀rọ̀ nã fún àwọn ènìyàn nã, tí nwọ́n sì kígbe tako Nífáì, wípé: Ẹ kíyèsĩ, àwa mọ̀ wípé Nífáì yĩ ti gbìmọ̀ pẹ̀lú ẹnìkan láti pa onidajọ nã, lẹ́hìn nã ni yíò sì sọ fún wa, láti lè yí wa padà sí ìgbàgbọ́ tirẹ̀, láti lè gbé ara rẹ̀ sókè pé ènìyàn nlá ni òun, ẹni tí Ọlọ́run yàn, tí í sì í ṣe wòlĩ.

17 Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, àwa yíò wá ọkùnrin yĩ rí, òun yíò sì jẹ́wọ́ ẹ̀bi rẹ̀ tí yíò sì fi ẹnití ó pa onidajọ yĩ hàn wá.

18 Ó sì ṣe tí nwọ́n tú àwọn marun nã sílẹ̀ ní ọjọ́ ìsìnkú nã. Bíótilẹ̀ríbẹ̃ nwọ́n bá àwọn onidajọ nã wí ní ti ọ̀rọ̀ tí nwọ́n ti sọ tako Nífáì, nwọ́n sì bá nwọn jà lọ́kọ̃kan tóbẹ̃ tí nwọ́n sì dàmú nwọn.

19 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, nwọ́n mú kí nwọn ó mú Nífáì kí nwọn ó sì dẽ kí nwọn sì múu wá síwájú àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí bĩ lẽrè lonírurú ọnà láti lè múu tako ara rẹ̀, tí nwọn ó sì pè é lẹ́jọ́ ikú—

20 Nwọ́n sì wí fún un pé: Ìwọ wà ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ẹnìkan; tani ẹni nã tí ó ṣe ìpànìyàn yĩ? Nísisìyí sọ fún wa, kí ó sì gbà pé ó jẹ̀bi; nwọ́n tún wípé: Kíyèsĩ owó rẽ; àti pẹ̀lú pé àwa yíò dá ẹ̀mí rẹ sí bí ìwọ bá lè sọ fún wa, tí ìwọ sì jẹ́wọ́ sí àdéhùn tí ìwọ ti ṣe pẹ̀lú rẹ̀.

21 Ṣùgbọ́n Nífáì wí fún nwọn pe: A! ẹ̀yin aláìmòye ènìyàn yĩ, ẹ̀yin aláìkọlà ní ọkàn ènìyàn yĩ, ẹ̀yin afọ́jú ènìyàn, àti ọlọ́rùn líle ènìyàn, njẹ́ ẹ̀yin ha mọ̀ bí yíò ti pẹ́ tó tí Olúwa Ọlọ́run nyín yíò gbà nyín lãyè láti tẹ̀síwájú nínú ipa ẹ̀ṣẹ̀ nyín yĩ?

22 A! ó yẹ kí ẹ̀yin ó bẹ̀rẹ̀sí pohùnréré ẹkún kí ẹ sì kẹ́dùn ọkàn, nítorí ìparun nlá nnì tí ó dúró dè nyín ní àkokò yĩ, àfi bí ẹ̀yin bá ronúpìwàdà.

23 Ẹ kíyèsĩ ẹ̀yin sọ wípé mo ti ni àdéhùn pẹ̀lú ẹnìkan pé kí ó pa Sísórámù, onidajọ-àgbà wa. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, èmi wí fún nyín, pé nítorítí mo jẹrisi nyín kí ẹ̀yin ó lè mọ̀ nípa ohun yĩ ni ẹ̀yin ṣe sọ eleyĩ; bẹ̃ni, àní sí ijẹrisi fún nyín, pé èmi mọ̀ nípa ìwà búburú àti ìwà ẽrí èyítí ó wà lãrín nyín.

24 Àti nítorítí èmi ṣe eleyĩ, ẹ̀yin ní èmi ti ní àdéhùn pẹ̀lú ẹnìkan láti ṣe nkan yĩ; bẹ̃ni, nítorípé mo fi àmì yĩ hàn yín ẹ̀yin nbínú sí mi, ẹ sì nlépa láti pa mi run.

25 Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, èmi yíò fi àmì míràn hàn nyín, láti ríi bóyá ẹ̀yin yíò lépa láti pa mí run nínú ohun yĩ.

26 Ẹ kíyèsĩ mo wí fún nyín: Ẹ lọ sí ilé Síátúmì, ẹnití í ṣe arákùnrin Sísórámù, kí ẹ sì wí fún un pé—

27 Njẹ́ Nífáì, wòlĩ èké nnì, tí nsọ ìsọtẹ́lẹ̀ ohun búburú nípa àwọn ènìyàn yĩ, ha bá ọ ní àdéhùn, nínú èyítí o pa Sísórámù, ẹnití í ṣe arákùnrin rẹ bí?

28 Ẹ sì kíyèsĩ, yíò wí fún nyín pe, Rárá.

29 Ẹ̀yin yíò sì wí fún un pé: Ìwọ ha pa arákùnrin rẹ bí?

30 Òun yíò sì dúró ní ìbẹ̀rù, kò sì ní mọ́ ohun tí yíò sọ. Ẹ sì kíyèsĩ, òun yíò sẹ́ pípa arákùnrin rẹ̀; òun yíò sì ṣe bí ẹnití ẹnu yà; bíótilẹ̀ríbẹ̃, òun yíò wí fún nyín pé aláìṣẹ̀ ni òun í ṣe.

31 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin yíò ṣe àyẹ̀wò ara rẹ̀ ẹ ó sì rí ẹ̀jẹ̀ lã ẹ̀wù ìlekè rẹ̀.

32 Nígbàtí ẹ̀yin bá sì ti rí èyí, ẹ̀yin yíò wípé: Níbo ni ẹ̀jẹ̀ yĩ ti wá? Àwa kò ha mọ̀ wípé ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ ni í ṣe bí?

33 Nígbànã ni yíò wárìrì, awọ ojú rẹ yíò di ràndànràndàn, àní bí ẹnití ikú ti dé bá.

34 Nígbànã ni ẹ̀yin yíò wípé: Nítorí ìbẹ̀rù yĩ àti ràndànràndàn tí ó dé bá ojú rẹ yĩ, kíyèsĩ, àwa mọ̀ pé o jẹ̀bi.

35 Nígbànã ni ẹ̀rù tí ó tóbi síi yíò dé bã; nígbànã ni yíò sì jẹ́wọ́ fún nyín, tí yíò sì ṣíwọ́ sísẹ́ tí ó nsẹ́ pé òun kọ́ ni ó ṣe ìpànìyàn yĩ.

36 Nígbànã ni yíò wí fún un yín, pé èmi Nífáì kò mọ́ ohunkóhun nípa ọ̀rọ̀ yĩ àfi bí a bá fií fún mi nípa agbára Ọlọ́run. Nígbànã ni ẹ̀yin yíò sì mọ̀ pé olotitọ ènìyàn ni èmi í ṣe, àti pé Ọlọ́run ni ó rán mi sí nyín.

37 Ó sì ṣe tí nwọ́n sì lọ, nwọ́n sì ṣe, àní gẹ́gẹ́bí Nífáì ti wí fún nwọn. Ẹ sì kíyèsĩ, òtítọ́ sì ni àwọn ohun tí ó sọ; nítorítí gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ó sì sẹ́; àti pẹ̀lú gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ó sì jẹ́wọ́.

38 Nwọ́n sì mú u láti fi hàn kedere pé òun tìkararẹ̀ ni apànìyàn nã ní tõtọ́, tóbẹ̃ tí nwọ́n fi tú àwọn marun nnì sílẹ̀, àti Nífáì pẹ̀lú.

39 Àwọn kan nínú àwọn ará Nífáì gba àwọn ọ̀rọ̀ Nífáì gbọ́; àwọn kan sì wà pẹ̀lú tí ó gbàgbọ́ nítorí ẹ̀rí àwọn marun nnì, nítorítí nwọ́n ti yí padà nígbàtí nwọ́n wà nínú tũbú.

40 Àti nísisìyí àwọn kan wà lãrín àwọn ènìyàn nã, tí nwọ́n wípé wòlĩ ni Nífáì í ṣe.

41 Àwọn míràn sì wà tí nwọ́n wípé: Ẹ kíyèsĩ, òrìṣà kan ni í ṣe, nítorítí bí kò bá ṣe pé òrìṣà kan ni í ṣe kò lè mọ̀ nípa ohun gbogbo. Nítorí ẹ kíyèsĩ, ó ti sọ gbogbo èrò ọkàn wa fún wa, àti pẹ̀lú ó ti sọ àwọn nkan fún wa; àti pãpã ó mú kí àwa ó mọ́ ẹnití ó pa adájọ́-àgbà wa ní tõtọ́.