Àwọn Ìwé Mímọ́
Hẹ́lámánì 14


Orí 14

Sámúẹ́lì sọ ìsọtẹ́lẹ̀ pé ìmọ́lẹ̀ yíò wà ní álẹ́ àti pé ìràwọ̀ titun yíò wà ní àkokò bíbí Krístì—Krístì ṣe ìràpadà fún àwọn ènìyàn kúrò lọ́wọ́ ikú ara àti ti ẹ̀mí—Àwọn àmì ikú rẹ̀ ní ọjọ́ mẹ́ta tí òkùnkùn ṣú bo ilẹ̀, fífọ́ àwọn òkè, ati ìrúkèrúdò nínú ayé. Ní ìwọ̀n ọdún 6 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí ó sì ṣe tí Sámúẹ́lì, ará Lámánì nnì, sọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ohun púpọ̀ síi tí a kò lè kọ sílẹ̀.

2 Ẹ sì kíyèsĩ, ó wí fún nwọn pé: Ẹ kíyèsĩ èmi yíò fún un nyín ní àmì kan; nítorítí ọdún marun sì nbọ̀wá, ẹ sì kíyèsĩ, nígbànã ni Ọmọ Ọlọ́run yíò wá láti ra gbogbo àwọn tí yíò gbà orúkọ rẹ̀ gbọ́ padà.

3 Ẹ sì kíyèsĩ, èyí ni èmi yíò fún nyín gẹ́gẹ́bí àmì tí yíò sẹ́ nígbàtí ó bá dé; nítorí kíyèsĩ, ìmọ́lẹ̀ tí ó tóbí yíò wà lọ́run tóbẹ̃ tí kò ní sí òkùnkùn ní òru ọjọ́ tí ó ṣãjú ọjọ́ bíbọ̀ rẹ̀, tóbẹ̃ tí yíò dàbí ọ̀sán lójú àwọn ènìyàn.

4 Nítorínã a ó ní ọ̀sán kan àti alẹ́ kan àti ọ̀sán kan, bí èyítí ó jẹ́ ọjọ́ kan tí kò sì sí òru; èyí ni yíò sì wà gẹ́gẹ́bí àmì fún nyín; nítorítí ẹ̀yin yíò mọ̀ nípa títàn oòrùn àti wíwọ̀ rẹ̀; nítorínã nwọn yíò mọ̀ dájúdájú pé ọ̀sán méjì àti òru kan yíò wà; bíótilẹ̀ríbẹ̃ òru kò ní ṣókùnkùn; yíò sì jẹ́ òru ọjọ́ tí a o bĩ.

5 Ẹ sì kíyèsĩ, ìràwọ̀ tuntun kan yíò yọ, èyítí ẹ̀yin kò rí irú rẹ̀ rí; èyí pẹ̀lú yíò sì jẹ́ àmì fún nyín.

6 Ẹ kíyèsĩ kò tán síbẹ̀, àwọn ohun àmì àti ìyanu púpọ̀ yíò wà lọ́run.

7 Yíò sì ṣe tí ẹnu yíò yà nyín, tóbẹ̃ tí ẹ̀yin yíò ṣubú lulẹ̀.

8 Yíò sì ṣe tí ẹnìkẹ́ni tí ó bá gba Ọmọ Ọlọ́run nã gbọ, òun nã ni yíò ní ìyè títí ayé.

9 Ẹ sì kíyèsĩ, báyĩ ni Olúwa ti pãláṣẹ fún mi, láti ọwọ́ ángẹ́lì rẹ̀, pé kí èmi wá láti sọ ohun yĩ fún nyín; bẹ̃ni, ó ti pàṣẹ pé kí èmi ó sọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ohun wọ̀nyí fún nyín; bẹ̃ni, ó ti sọ fún mi pé: Kígbe sí àwọn ènìyàn yĩ, ẹ ronúpìwàdà kí ẹ sì tún ọ̀nà Olúwa ṣe.

10 Àti nísisìyí, nítorípé ará Lámánì ni èmi í ṣe, tí mo sì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti pa láṣẹ fún mi fún nyín, àti nítorípé ó nira fún nyín ní ṣíṣe, ẹ̀yin nbínú sí mi ẹ sì nlépa láti pa mí run, ẹ sì ti lé mi jáde kúrò lãrín nyín.

11 Ẹ̀yin yíò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, nítorítí, nítorí ìdí èyí ni èmi wá sí órí àwọn ògiri ìlú-nlá yĩ, kí ẹ̀yin kí ó lè gbọ́ kí ẹ sì mọ̀ nípa ìdájọ́ Ọlọ́run èyítí ó ndúró dè nyín nítorí àwọn ìwà àìṣedẽdé nyín, àti kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ nípa ọ̀nà ìrònúpìwàdà;

12 Àti pẹ̀lú kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ nípa bíbọ̀ Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run, Bàbá ọ̀run òun ayé, Ẹlẹ́dã ohun gbogbo láti ìbẹ̀rẹ̀ wá; àti kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ nípa àwọn àmì nípa bíbọ̀ rẹ̀, láti lè mú kí ẹ̀yin ó gbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀.

13 Bí ẹ̀yin bá sì gbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀ ẹ̀yin yíò ronúpìwàdà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ nyín, pé lọ́nà yĩ ẹ̀yin yíò gba ìdáríjì lórí nwọn nípasẹ̀ ìdáláre.

14 Ẹ sì kíyèsĩ, àmì míràn ni èmi yíò tún fún nyín, bẹ̃ni àmì tí ikú rẹ̀.

15 Nítorí ẹ kíyèsĩ, dájúdájú ni yíò kú kí ìgbàlà lè wá; bẹ̃ni, ó níláti rí báyĩ, ó sì jẹ́ èyítí ó yẹ pé kí ó ku, láti mú àjínde òkú kọjá, pé báyĩ a ó mú ènìyàn wá sí iwájú Olúwa.

16 Bẹ̃ni, ẹ kíyèsĩ, ikú yĩ mú àjínde wa, àti ìràpadà gbogbo ènìyàn kúrò nínú ikú àkọ́kọ́—ikú tí ẹ̀mi nnì; nítorítí gbogbo ènìyàn, nípa ìṣubú Ádámù ti di kíké kúrò níwájú Olúwa, wọn sì ti dàbí ẹnití ó kú, sí ohun ti ara àti ohun ẹ̀mí.

17 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, àjínde Krístì nṣe ìràpadà fún ènìyàn, bẹ̃ni, àní gbogbo ènìyàn, ó sì nmú nwọn padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa.

18 Bẹ̃ni, ó sì nmú ọ̀nà ìrònúpìwàdà wá, pé ẹnìkẹ́ni tí ó bá ronúpìwàdà òun nã ni a kò ní ké lulẹ̀ kí a sì sọọ́ sínú iná nnì; ṣùgbọ́n ẹnìkẹ́ni tí kò bá ronúpìwàdà ni a ó ké lulẹ̀ tí a ó sì sọ ọ́ sínú iná nnì; níbẹ sì ni ikú ẹ̀mí yíò tún wá sí órí nwọn, bẹ̃ni, ikú kejì, nítorítí a ó tún ké nwọn kúrò ní ti ohun tí í ṣe ti ọ̀nà òdodo.

19 Nítorínã ẹ ronúpìwàdà, ẹ ronúpìwàdà, ní ìbẹ̀rù pé bí ẹ̀yin ti mọ́ àwọn ohun yĩ tí ẹ kò sì ṣe nwọ́n ẹ̀yin yíò mú ara nyín wá sí abẹ́ ìdálẹ́bi, a ó sì mú nyín wá sínú ikú kejì yĩ.

20 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, gẹ́gẹ́bí èmi ti wí fún nyín nípa àmì míràn, àmì ti ikú rẹ̀, ẹ kíyèsĩ, ní ọjọ́ nã tí yíò kú oòrun yíò ṣókùnkùn yíò sì kọ láti fún nyín ní ìmọ́lẹ̀ rẹ̀; àti òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ pẹ̀lú; kò sì ní sí ìmọ́lẹ̀ lójú ilẹ̀ yĩ, àní láti ìgbà tí yíò kú, fún ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta, títí dé ìgbà tí yíò jínde kúrò ní ipò òkú.

21 Bẹ̃ni, ní ìgbà tí yíò jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́ ãrá yíò san mọ̀nàmọ́na yio sì wà fún ìwọ̀n wákàtí púpọ̀, ayé yíò sì mì tìtì yíò sì gbọ̀n rìrì; àwọn àpáta tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, tí ó wà lókè àti lábẹ́ ilẹ́, èyítí ẹ̀yin mọ̀ ní àkokò yĩ pe nwọn le, tabi pé púpọ̀ nínú rẹ̀ jẹ́ èyítí ó le ní kíkópọ̀, ni yíò fọ́ sí wẹ́wẹ́.

22 Bẹ̃ni, nwọ́n yíò là sí méjì, lẹhinnã nwọn ó sì wà ní ṣíṣán, àti ní fífọ́ sí wẹ́wẹ́ láti ìgbànã lọ, àti ní àkúfọ́ lórí ilẹ̀ gbogbo ayé, bẹ̃ni, lórí ilẹ̀ àti ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀.

23 Ẹ sì kíyèsĩ, ìjì líle yíò wà, àwọn òkè gíga púpọ̀ ni a ó sì rẹ̀ sílẹ̀, bí àfonífojì, àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibití a sì npè ní àfonífojì ní àkokò yĩ ni yíò di òkè gíga, ti gíga nwọn sì jẹ́ púpọ̀.

24 Àwọn ojú ọ̀nà òpópó púpọ̀ ni yíò sì fọ́ sí wẹ́wẹ́, àwọn ìlú-nlá púpọ̀ ní yíò sì di ahoro.

25 Àwọn isà òkú púpọ̀ ni yíò sì ṣí sílẹ̀, tí nwọn yíò sì gbé púpọ̀ nínú àwọn òkú inú nwọn dìde; àwọn ènìyàn mímọ̀ púpọ̀ ni yíò sì farahàn sí àwọn ènìyàn púpọ̀.

26 Ẹ sì kíyèsĩ, báyĩ sì ni ángẹ́lì nã ti bá mi sọ̀rọ̀; nítorítí ó sọ fún mi pé àrá yíò sán mọ̀nàmọ́na yio sì wà fún ìwọ̀n ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí.

27 Ó sì sọ fún mi pé ní àkokò tí àra nã nsán tí mọ̀nàmọ́na sì nkọ, àti ìjì nã, pé àwọn ohun wọ̀nyí yíò rí bẹ̃, àti pé òkùnkùn yíò bò orí ilẹ̀ gbogbo ayé fún ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta.

28 Ángẹ́lì nã sì wí fún mi pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ yíò rí àwọn ohun tí ó ju eleyĩ, láti lè mú kí nwọn ó gbàgbọ́ pé àwọn àmì àti ohun ìyanu yĩ yíò ṣẹ lórí ilẹ̀ yĩ, láti lè mú àìgbàgbọ́ kúrò lãrín àwọn ọmọ ènìyàn—

29 Èyí sì rí bẹ̃ láti lè mú kí ẹnìkẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ di ẹni ìgbàlà, àti pé ẹnìkẹ́ni tí kò bá nĩ gbàgbọ́, ìdájọ́ òdodo yíò wá sí órí nwọn; àti pẹ̀lú bí a bá dá nwọn lẹ́bi nwọn mú ìdálẹ́bi nwọn wá sí órí ara nwọn.

30 Àti nísisìyí ẹ rántí, ẹ rántí, ẹ̀yin arákùnrin mi, pé ẹnìkẹ́ni tí ó bá ṣègbé, ṣègbé sí ọrùn ara rẹ̀; ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì nṣe àìṣedẽdé, nṣe é sí ọrùn ara rẹ̀; nítorí kiyesĩ, ẹ̀yin di òmìnira; a sì gbà pé kí ẹ ṣe bí ẹ ti fẹ́; nítorí ẹ kíyèsĩ, Ọlọ́run ti fún nyín ní ìmọ̀ ó sì ti sọ nyín di òmìnira.

31 Ó sì ti fifún nyín pé kí ẹ̀yin ó lè dá rere mọ̀ nínú búburú; ó sì ti fi fún nyín pé kí ẹ̀yin lè yan ìyè tàbí ikú; àti kí ẹ̀yin le ṣe rere kí a sì mú yín padàbọ̀sípò sí èyítí ó dára, tàbí pé kí a mú èyítí ó dára padàbọ̀sípò sí yín; tàbí kí ẹ̀yin le sé búburú, kí a sì da èyítí ó burú padàbọ̀sípò sí yín.