Àwọn Ìwé Mímọ́
Hẹ́lámánì 8


Orí 8

Àwọn adájọ́ oníbàjẹ́ wá ọ̀nà láti ru àwọn ènìyàn lọ́kàn sókè sí Nífáì—Ábráhámù, Mósè, Sénọ́sì, Sénọ́kì, Ésíásì, Isaiah, Jeremíàh, Léhì, àti Nífáì gbogbo nwọn ni ó jẹ́rĩ nípa Krístì—Nípa ìmísí Nífáì kéde pípa tí nwọn yíò pa adájọ́ àgbà. Ní ìwọ̀n Ọdun 23 sí 21 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Nífáì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ẹ kíyèsĩ, àwọn ọkùnrin kan wà tí nwọn jẹ́ adájọ́, tí nwọ́n tún wà nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn Gádíátónì, nwọ́n sì bínú nwọ́n sí kígbe jáde láti takõ nwọ́n sì wí fún àwọn ènìyàn nã pé: Èéṣe tí ẹ̀yin kò mú ọkùnrin yĩ kí ẹ sì múu wá, kí àwa ó lè dájọ́ fún un ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ èyítí ó ti ṣẹ̀?

2 Báwo ni ẹ̀yin ṣe nwo ọkùnrin yĩ, àti tí ẹ̀yin nfetísílẹ̀ síi bí ó ṣe nkẹ́gàn àwọn ènìyàn yĩ àti òfin wa?

3 Nítorí ẹ kíyèsĩ, Nífáì ti bá nwọn sọ̀rọ̀ nípa ìdíbàjẹ́ òfin nwọn; bẹ̃ni, àwọn ohun púpọ̀ ni Nífáì sọ èyítí a kò lè kọ; àti pé kò sí ohun tí ó sọ tí ó lòdì sí òfin Ọlọ́run.

4 Àwọn adájọ́ nnì sì bínú síi nítorípé ó sọ̀rọ̀ òtítọ́ sí nwọn nipa àwọn iṣẹ́ òkùnkùn tí nwọn nṣe ní ìkọ̀kọ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃, nwọn kò lè fi ọwọ́kàn án, nítorítí nwọ́n bẹ̀rù pé àwọn ènìyàn nã yíò kígbe takò nwọ́n.

5 Nítorínã nwọ́n kígbe sí àwọn ènìyàn nã, wípé: Èéṣe ẹ̀yin ṣe gba ọkùnrin yĩ lãyè láti kẹ́gàn wa? Nítorí ẹ kíyèsĩ ó ti dá àwọn ènìyàn yĩ lẹ́bi, àní sí ìparun, bẹ̃ni, àti pẹ̀lú pé nwọn yíò gba àwọn ìlú-nlá wa títóbi wọ̀nyí lọ́wọ́ wa, tí àwa kò sì ní ní ìpín nínú nwọn.

6 Àti nísisìyí àwa sì ti mọ̀ pé eleyĩ kò lè rí bẹ̃, nítorí kíyèsĩ, alágbára ni àwa í ṣe, àwọn ìlú-nlá wa sì tóbi, nítorínã àwọn ọ̀ta wa kò lè lágbára lé wa lórí.

7 Ó sì ṣe tí nwọ́n sì ru àwọn ènìyàn nã sókè ní ìbínú sí Nífáì, tí nwọ́n sì mú kí ìjà ó bẹ̀rẹ̀ lãrín nwọn; nítorítí àwọn kan wà tí ó kígbe wípé: Ẹ fi ọkùnrin yĩ sílẹ̀, nítorítí ènìyàn rere ni í ṣe, àwọn ohun tí ó sì nsọ yíò ṣẹ ní tõtọ́ àfi bí àwa bá ronúpìwàdà;

8 Bẹ̃ni, ẹ kíyèsĩ, gbogbo ìdájọ́ tí ó jẹ́rĩ sí yĩ ní yíò bá wa; nítorítí àwa mọ̀ pé ó ṣe ijẹrisi òdodo fún wa nípa àwọn àìṣedẽdé wa. Ẹ sì kíyèsĩ nwọ́n pọ̀, òun sì mọ́ ohun gbogbo tí yíò ṣẹ sí wa gẹ́gẹ́bí òun ti mọ̀ nípa àwọn àìṣedẽdé wa;

9 Bẹ̃ni, ẹ sì kíyèsĩ, bí kò bá ṣe pé wòlĩ ni í ṣe òun kò lè ṣe ijẹrisi nípa àwọn ohun wọnnì.

10 Ó sì ṣe tí a fi ipa mú àwọn ènìyàn nnì tí nwọ́n lépa láti pa Nífáì nítorítí nwọ́n bẹ̀rù, tí nwọn kò sì fi ọwọ́ kàn án; nítorínã ó sì tún bẹ̀rẹ̀sí bá nwọn sọ̀rọ̀, nígbàtí ó ríi pé òun ti rí ojú rere díẹ̀ nínú nwọn, tóbẹ̃ tí àwọn tí ó kù sì bẹ̀rù.

11 Nítorínã ó tún níláti bá nwọn sọ̀rọ̀ síi pé: Ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin arákùnrin mi, ẹ̀yin kò ha ríi kà pé Ọlọ́run fi agbára fún ọkùnrin kan, àní Mósè, kí ó lu ojú omi Òkun Pupa, tí nwọ́n sì pínyà sí méjì, tóbẹ̃ tí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì, tí nwọn í ṣe bàbá nlá wa, lã kọjá lórí ilẹ̀ tí ó gbẹ, tí omi nã sì padé mọ́ àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Égíptì tí ó sì gbé nwọn mì?

12 Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, bí Ọlọ́run bá fi irú agbára báyĩ fún ọkùnrin yĩ, nítorínã ẽṣe tí ẹ̀yin ṣe nbá ara nyín jiyàn, tí ẹ wípé òun kò fún mi ní agbára tí èmi ó fi mọ̀ nípa ìdájọ́ tí yíò bá nyín àfi bí ẹ̀yin bá ronúpìwàdà?

13 Ṣùgbọ́n, ẹ kíyèsĩ, kĩ ṣe pé ẹ̀yin sẹ́ ọ̀rọ̀ mi, ṣùgbọ́n ẹ̀yin tún sẹ́ gbogbo ọ̀rọ̀ èyítí àwọn bàbá nlá wa ti sọ, àti pẹ̀lú gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ ti ọkùnrin yĩ, Mósè, ti sọ, ẹnití a fi agbára nlá fún, bẹ̃ni, àwọn ọ̀rọ̀ tí ó sọ nípa bíbọ̀ Messia nã.

14 Bẹ̃ni, òun kò ha jẹ́rĩ wípé Ọmọ Ọlọ́run nã nbọ̀wá bí? Bí ó sì ti gbé ejò idẹ nnì sókè nínú aginjù, àní bẹ̃ni a ó gbé ẹnití nbọ̀wá sókè.

15 Gbogbo àwọn tí yíò sì gbe ójú sókè wo ejò nã ni yíò yè, bẹ̃ni gbogbo àwọn tí yíò gbe ójú sókè wo Ọmọ Ọlọ́run nã pẹ̀lú ìgbàgbọ́, tí nwọ́n ní ẹ̀mí ìròbìnújẹ́, lè yè, àní sí ayé nnì èyítí í ṣe ayérayé.

16 Àti nísisìyí kíyèsĩ, kì í ṣe Mósè nìkan ni ó jẹrisi àwọn ohun yìi, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn wòlĩ mímọ́ pẹ̀lú, láti ìgbà rẹ̀ àní títí dé ìgbà Ábráhámù.

17 Bẹ̃ni, ẹ sì kíyèsĩ, Ábráhámù ri nípa bíbọ̀ rẹ̀, ó sì kún fún inú dídùn ó sì yọ̀.

18 Bẹ̃ni, ẹ sì kíyèsĩ èmi wí fún nyín, pé kĩ ṣe Ábráhámù nìkan ni ó mọ̀ nípa àwọn ohun yĩ, ṣùgbọ́n àwọn púpọ̀ ni ó wà ṣãjú ìgbà Ábráhámù tí a pè ní ti ẹgbẹ́ Ọlọ́run; bẹ̃ni, àní níti ipa Ọmọ rẹ̀; ó sì rí báyĩ kí a lè fi han àwọn ènìyàn nã, ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹgbẹ̃gbẹ̀rún ọdún sãjú bíbọ̀ rẹ̀, pé ìràpadà yíò wá bá nwọn.

19 Àti nísisìyí èmi fẹ́ kí ẹ mọ̀, pé àní láti ìgbà Ábráhámù ni àwọn wòlĩ púpọ̀ ti jẹrisi àwọn ohun yĩ; bẹ̃ni, ẹ kíyèsĩ, wòlĩ Sénọ́sì jẹ́rĩ pẹ̀lú ìgboyà; nítorínã ni nwọ́n sì fi pa á.

20 Àti kí ẹ kíyèsĩ, Sénọ́kì pẹ̀lú, àti Ésíásì pẹ̀lú, àti Isaiah pẹ̀lú, àti Jeremíàh, (Jeremíàh ni wòlĩ kannã tí ó jẹrisi ìparun Jerúsálẹ́mù) àti nísisìyí àwa mọ̀ pé Jerúsálẹ́mù parun ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Jeremíàh. A! njẹ́ nígbànã éṣe tí Ọmọ Ọlọ́run nã kò ha ní wá, ní ìbámu pẹ̀lú ìsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀?

21 Àti nísisìyí njẹ́ ẹ̀yin yíò ha jiyàn pé a pa Jerúsálẹ́mù run? Njẹ́ ẹ̀yin yíò ha wípé a kò pa àwọn ọmọ Sẹdẹkíàh, gbogbo nwọn àfi Múlẹ́kì? Bẹ̃ni, njẹ́ ẹ̀yin kò ha ríi pé irú ọmọ Sẹdẹkíàh wà pẹ̀lú wa, àti pé a lé nwọn jáde kúrò nínú ìlẹ̀ Jerúsálẹ́mù? Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, èyí nìkan kọ́—

22 Nwọ́n lé bàbá wa Léhì jáde kúrò nínú Jerúsálẹ́mù nítorípé ó jẹrisi àwọn ohun wọ̀nyí. Nífáì pẹ̀lú jẹrisi àwọn ohun wọ̀nyí, àti pẹ̀lú èyítí ó pọ̀jù nínú àwọn bàbá nlá wa, àní títí dé àkokò yĩ; bẹ̃ni, nwọ́n ti jẹrisi bíbọ̀ Krístì, nwọ́n sì ti fi ojú sọ́nà, nwọ́n sì ti yọ̀ nínú ọjọ́ rẹ̀ tí nbọ̀wá.

23 Ẹ sì kíyèsĩ, Ọlọ́run ni í ṣe, ó sì wà pẹ̀lú nwọn, ó sì fi ara rẹ̀ hàn sí nwọn, pé òun ni ó rà nwọ́n padà; nwọ́n sì fi ògo fún un, nítorí èyítí nbọ̀wá.

24 Àti nísisìyí, nítorípé ẹ̀yin mọ́ àwọn ohun wọ̀nyí tí ẹ kò sì lè sẹ́ nwọn àfi bí ẹ̀yin ó bá purọ́, nítorínã ni ẹ̀yin ti ṣẹ̀ nínú èyí, nítorítí ẹ̀yin ti kọ gbogbo nkan wọ̀nyí, l’áìṣírò ẹ̀yin ti rí ẹ̀rí tí ó pọ̀ gbà; bẹ̃ni, àní ẹ̀yin ti rí ohun gbogbo gbà, àwọn ohun tí ó wà lọ́rùn, àti ohun gbogbo tí ó wà láyé, gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí pé òtítọ́ ni nwọ́n í ṣe.

25 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin ti kọ òtítọ́, ẹ̀yin sì ti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run nyín mímọ́; àti pãpã ní àkokò yĩ, èyítí ẹ̀yin ìbá to ìṣura jọ fun ara nyín ní ọ̀run, níbití ohunkóhun kò lè bàjẹ́, àti níbití ohunkóhun tí kò mọ́ kò lè wà; ẹ̀yin nkó ìbínú jọ fún ara nyín de ọjọ́ ìdájọ́.

26 Bẹ̃ni, àní ní àkokò yĩ, ẹ̀yin nmúrasílẹ̀, nítorí àwọn ìwà ìpànìyàn nyín àti ìwà àgbèrè àti ìwà búburú nyín, de ìparun ayérayé; bẹ̃ni, àfi bí ẹ̀yin bá ronúpìwàdà yíò dé bá nyín láìpẹ́ ọjọ́.

27 Bẹ̃ni, ẹ kíyèsĩ ó ti dé tán àní sí ẹ̀hìn ilẹ̀kùn nyín; bẹ̃ni, ẹ lọ sí órí ìtẹ́ ìdájọ́ nyín, kí ẹ sì ṣe ìwádĩ; ẹ sì kíyèsĩ, nwọ́n ti pa onidajọ nyín, ó sì dùbúlẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀; arákùnrin rẹ̀ ni ó sì pã, ẹnití ó nlépa láti wà lórí ìtẹ́ ìdájọ́.

28 Ẹ sì kíyèsĩ, àwọn méjẽjì wà nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn nyín nnì, ti olùdásílẹ̀ jẹ Gádíátónì àti ẹni búburú nnì tí nlépa láti pa ọkàn àwọn ènìyàn run.