Àwọn Ìwé Mímọ́
Hẹ́lámánì 2


Orí 2

Hẹ́lámánì, ọmọ Hẹ́lámánì, di onidajọ-àgbà—Gádíátónì jẹ́ olùdarí fún ẹgbẹ́ Kíṣkúmẹ́nì—Ìránṣẹ́ Hẹ́lámánì pa Kíṣkúmẹ́nì, àwọn ẹgbẹ́ Gádíátónì sì sálọ sínú aginjù. Ní ìwọ̀n ọdún 50 sí 49 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe ní ọdún kejìlélógójì nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, lẹ́hìn tí Móróníhà ti tún fi àlãfíà lélẹ̀ lãrín àwọn ará Nífáì àti àwọn ará Lámánì, kíyèsĩ kò sí ẹnití yíò bọ́ sí órí ìtẹ́ ìdajọ́; nítorínã ni asọ̀ tún bẹ̀rẹ̀ lãrín àwọn ènìyàn nã lórí ẹnití yíò bọ́ sí órí ìtẹ́ ìdájọ́.

2 Ó sì ṣe tí a yan Hẹ́lámánì, ẹnití í ṣe ọmọ Hẹ́lámánì, láti bọ́ sí órí ìtẹ́ ìdájọ́, nípa ohùn àwọn ènìyàn nã.

3 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, Kíṣkúmẹ́nì, ẹnití ó pa Pahoránì dúró ní ìkọ̀kọ̀ láti pa Hẹ́lámánì pẹ̀lú; àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ sì tĩ lẹ́hìn, àwọn tí nwọ́n ti dá májẹ̀mú pé ẹnìkẹ́ni kò ní mọ́ ohun búburú tí ó ṣe.

4 Nítorítí ẹnìkan wà tí orúkọ rẹ̀ í ṣe Gádíátónì, tí ó já fáfá nínú ọ̀rọ̀ sísọ, àti ọgbọ́n àrékérekè rẹ̀, láti tẹ̀ síwájú nínú ìwà ìpànìyàn àti olè jíjà ní ìkọ̀kọ̀; nítorínã ó di olórí fun ẹgbẹ́ Kíṣkúmẹ́nì.

5 Nítorínã ó ntàn wọ́n, àti Kíṣkúmẹ́nì pẹ̀lú, pé bí nwọ́n bá fi òun sí órí ìtẹ́ ìdájọ́ òun yíò jẹ́ kí nwọn ó fi àwọn tí ó wà nínú ẹgbẹ́ òun sí ipò agbára àti àṣẹ lãrín àwọn ènìyàn nã; nítorínã Kíṣkúmẹ́nì lépa láti pa Hẹ́lámánì.

6 Ó sì ṣe bí ó ṣe nlọ sí ibi ìtẹ́ ìdájọ́ láti pa Hẹ́lámánì, kíyèsĩ ọ̀kan nínú àwọn iranṣẹ Hẹ́lámánì, tí ó ti jáde ní ìbojú ní òru, tí ó sì ti fi ète gba imọ nípa àwọn èwé tí ẹgbẹ́ yĩ ti wé láti pa Hẹ́lámánì—

7 Ó sì ṣe tí ó bá Kíṣkúmẹ́nì pàdé, ó sì fún un ní àmì kan; nítorínã Kíṣkúmẹ́nì fi ìfẹ́ inú rè hàn fun un; sì fẹ́ kí ó mú òun lọ sí ibi ìtẹ́ ìdájọ́ kí ó lè pa Hẹ́lámánì.

8 Nígbàtí ìránṣẹ́ Hẹ́lámánì nã sì ti mọ́ gbogbo ohun tí ó wà ní ọ́kàn Kíṣkúmẹ́nì, àti bí ó ṣe jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀ láti pànìyàn, ati pẹ̀lú pé ìfẹ́ gbogbo àwọn tí ó wà nínú ẹgbẹ́ rẹ̀ ni láti pànìyàn, àti láti jalè, àti láti gba agbára, (èyí sì ni ète òkùnkùn wọn, àti ẹgbẹ wọn) ìránṣẹ́ Hẹ́lámánì nã sọ fún Kíṣkúmẹ́nì pé: Jẹ́ kí àwa ó lọ sí ibi ìtẹ́ ìdájọ́ nã.

9 Nísisìyí èyí sì dùn mọ́ Kíṣkúmẹ́nì nínú gidigidi, nítorítí ó lérò wípé òun yíò mú èté òun di síṣe; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ìránṣẹ́ Hẹ́lámánì nã, bí nwọ́n ṣe nlọ sí ibi ìtẹ́ ìdájọ́ nã, ni ó sì gún Kíṣkúmẹ́nì lọ́bẹ àní ní ọkàn rẹ̀, tí ó sì ṣubú lulẹ̀ láìkérora. Ó sì sáré lọ sọ fún Hẹ́lámánì àwọn ohun tí ó ti rí, àti tí ó ti gbọ́, àti tí ó ti ṣe.

10 Ó sì ṣe tí Hẹ́lámánì ránṣẹ́ jáde pé kí nwọn ó mú ẹgbẹ́ àwọn olè àti apànìyàn ìkọ̀kọ̀ wọ̀nyí, pé kí a lè pa nwọ́n ní ìbámu pẹ̀lú òfin.

11 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, nígbàtí Gádíatónì ti ríi pé Kíṣkúmẹ́nì kò padà mọ́ ẹ̀rù bã pé nwọn yíò pãrun; nítorínã ó mú kí àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ tẹ̀lé oun. Nwọ́n sì sá jáde kúrò ní ilẹ̀ nã, ní ọ̀nà ìkọ̀kọ̀, sínú aginjù; báyĩ ni ó sì rí nígbàtí Hẹ́lámánì ránṣẹ́ jáde láti mú àwọn ènìyàn nã a kò rí nwọn níbikíbi.

12 A ó sì sọ síwájú síi nípa Gádíátónì yĩ lẹ́hìn èyí. Báyĩ sì ni ọdún kejìdínlógójì nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì parí.

13 Sì kíyèsĩ, ní òpin ìwé yĩ ẹ̀yin ó ríi pé Gádíátónì yĩ ni ó bí ìsubú nã, bẹ̃ni, èyítí ó fẹ́rẹ̀ fa ìparun àwọn ènìyàn Nífáì pátápátá.

14 Kíyèsĩ èmi kò sọ wípé òpin ìwé Hẹ́lámánì, ṣùgbọ́n mo wípé òpin ìwé Nífáì, nínú èyítí mo ti mú gbogbo àkọsílẹ̀ tí èmi ti kọ.