Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 6


Orí 6

Ìjọ-onígbàgbọ́ ti Sarahẹ́múlà ni a sọ di mímọ́, tí a sì tõ lẹ́sẹsẹ ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà—Álmà lọ sí Gídéónì láti wãsù. Ní ìwọ̀n ọdún 83 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí ó sì ṣe, lẹ́hìn tí Álmà ti parí ọ̀rọ̀ sísọ sí àwọn ènìyàn ìjọ-onígbàgbọ́ nã, èyítí a dá sílẹ̀ ni ìlú-nlá Sarahẹ́múlà, ó yan àwọn àlùfã àti àwọn àgbàgbà, nípa gbígbé ọwọ́ lé nwọn lórí gẹ́gẹ́bí ti ẹgbẹ́ Ọlọ́run, kí nwọ́n sì máa ṣe àkóso kí nwọ́n sì máa dábõbò ìjọ nã.

2 Ó sì ṣe, pé ẹnìkẹ́ni tí kò bá íṣe ti ìjọ-onígbàgbọ́ nã tí ó bá ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ni a rìbọmi sí ìrònúpìwàdà, tí a sì gbà sínú ìjọ nã.

3 Ó sì ṣe tí ẹnìkẹ́ni tí íṣe ti ìjọ nã tí ó bá ṣaláì ronúpìwàdà ìwà búburú rẹ, tí kò sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run—Àní mo wípé àwọn tí wọ́n gbé ara nwọn sókè nínú ìgbéraga ọkan wọn—àwọn wọ̀nyí ni a kọ̀, tí a sì pa orúkọ wọn rẹ́, tí a kò sì ka orúkọ wọn mọ́ ti àwọn olódodo.

4 Báyĩ ni nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí dá ìlànà ìjọ-onígbàgbọ́ sílẹ̀ ní ìlú-nlá Sarahẹ́múlà.

5 Nísisìyí èmi fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó ní ìmọ̀ wípé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà fún gbogbo ènìyàn láìyọ ẹnìkan sílẹ̀, pé kò sí ẹni tí a ta dànù fún pípéjọ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

6 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, àwọn ọmọ Ọlọ́run ni a paṣẹ fún pé kí wọ́n máa péjọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, kí wọ́n sì darapọ̀ nínú ãwẹ̀ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà fún àlãfíà ọkàn àwọn tí kò mọ́ Ọlọ́run.

7 Àti nísisìyí, ó sì ṣe, lẹ́hìn tí Álmà ti ṣe àwọn ètò-ìṣàkóso wọ̀nyí ó jáde kúrò lãrín wọn, bẹ̃ni, kúrò ní ìjọ-onígbàgbọ́ èyítí ó wà nínú ìlú-nlá Sarahẹ́múlà, ó sì lọ sí apá ìlà-oòrùn odò Sídónì, sí àfonífojì Gídéónì, ibi èyítí a ti kọ́ ìlú nlá kan èyítí à npe orúkọ rẹ̀ ní ìlú-nlá Gídéónì, èyítí ó wà ní àfonífojì tí à npè ní Gídéónì, tí a sọọ́ lórúkọ ẹnití a pa láti ọwọ́ Néhórì pẹ̀lú idà.

8 Álmà sì lọ ó sì bẹ̀rẹ̀síi kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún ìjọ nã èyítí a dá sílẹ̀ ní àfonífojì Gídéónì, gẹ́gẹ́bí ìfihàn òtítọ́ ọ̀rọ̀ tí àwọn bàbá rẹ ti sọ, àti gẹ́gẹ́bí ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀ èyítí ó ngbé inú rẹ, gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run, ẹnití nbọ̀wá láti ra àwọn ènìyàn rẹ̀ padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn, àti ti ẹgbẹ́ mímọ́ èyítí a fi pẽ. Báyĩ sì ni a ṣe kọọ́. Àmín.