Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 32


Orí 32

Álmà nkọ́ àwọn tálákà ènìyàn tí ìpọ́njú nwọn ti rẹ̀ wọn sílẹ̀—Ìgbàgbọ́ jẹ́ ìrètí nínú ohun èyítí a kò rí tĩ ṣe òtítọ́—Álmà jẹ́rĩ pé àwọn ángẹ́lì a máa jíṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin, àti àwọn ọmọdé—Álmà fi ọ̀rọ̀ nã wé irúgbìn—A níláti gbìn ín kí a sì bọ́ ọ—Yíò sì dàgbà di igi lara eyi tí a ó ká èso ìyè àìnípẹ̀kun. Ní ìwọ̀n ọdún 74 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe tí nwọ́n jáde lọ, tí nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí wãsù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí àwọn ènìyàn nã, tí nwọ́n sì nwọ inú àwọn sínágọ́gù nwọn, àti inú ilé nwọn; bẹ̃ni, nwọn sì nwãsù ọ̀rọ̀ nã nínú àwọn ìgboro nwọn.

2 Ó sì ṣe lẹ́hìn tí nwọ́n ti ṣe lãlã púpọ̀ lãrín wọn, nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí ní àṣeyọrí lãrín àwọn tálákà ènìyàn nwọn; nítorí kíyèsĩ, nwọ́n lé nwọn jáde kúrò nínú àwọn sínágọ́gù wọn nítorí aṣọ nwọn tí kò níyelórí—

3 Nítorínã, nwọn kò jẹ́ kí nwọn wọ inú àwọn sínágọ́gù nwọn láti sin Ọlọ́run, nítorítí wọ́n kà nwọ́n sí ẹni-elẽrí; nítorínã nwọ́n jẹ́ tálákà; àní, àwọn arákùnrin wọn kà nwọ́n sí ìdàrọ́; nítorínã nwọ́n jẹ́ tálákà nípa àwọn ohun ti ayé; nwọ́n sì jẹ́ oníròbìnújẹ́ ọkàn ènìyàn.

4 Nísisìyí, bí Álmà ti nkọ́ni tí ó sì nbá àwọn ènìyàn nã sọ̀rọ̀ lórí òkè Onídà, ọ̀pọ̀ ènìyàn tọ̃ wá, tí nwọn íṣe àwọn tí a ti nsọ nípa wọn ṣãjú, tí nwọn íṣe oníròbìnújẹ́ ọkàn ènìyàn, nítorípé nwọ́n jẹ́ aláìní nípa àwọn ohun ti ayé.

5 Nwọ́n sì tọ Álmà wá; ẹnìkan nínú nwọn èyítí íṣe aṣãjú nwọn sì wí fún un pé: Wõ, kíni kí àwọn arákùnrin mi wọ̀nyí ó ṣe, nítorítí gbogbo ènìyàn a máa kẹ́gàn wọn nítorí àìní wọn, bẹ̃ ni, pãpã àwọn àlùfã wa; nítorítí nwọ́n sì ti lé wa jáde kúrò nínú sínágọ́gù wa, tí àwa ti ṣiṣẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ láti kọ́ pẹ̀lú ọwọ́ ara wa; nwọ́n sì ti lé wa jáde nítorí ipò àìní wa èyítí ó tayọ; àwa kò sì ní ibi tí àwa yíò ti máa sin Ọlọ́run wa; sì wõ, kíni àwa yíò ṣe?

6 Àti nísisìyí nígbàtí Álmà gbọ́ eleyĩ, ó yí ojú rẹ̀ sọ́dọ̀ nwọn, ó sì dojúkọ ọ́, ó sì ṣe àkíyèsí pẹ̀lú ayọ̀ nlá; nítorítí ó kíyèsĩ pé ìpọ́njú nwọn ti rẹ̀ nwọ́n sílẹ̀ nítõtọ́, tí nwọ́n sì wà ní ipò ìṣetán láti gbọ́ ọ̀rọ̀ nã.

7 Nítorínã, kò bá àwọn ènìyàn nã sọ̀rọ̀ mọ́; ṣùgbọ́n ó na ọwọ́ rẹ̀ jáde, ó sì kígbe sí àwọn tí ó nwò, tí nwọ́n sì ti ronúpìwàdà nítõtọ́, ó sì wí fún nwọn pé:

8 Èmi ṣe àkíyèsí pé onírẹ̀lẹ̀-ọkàn ni ẹ̀yin íṣe; bí ó bá sì rí bẹ̃ alábùkún-fún ni ẹ̀yin íṣe.

9 Ẹ kíyèsĩ, arákùnrin nyín ti wípé, kíni àwa yíò ṣe?—nítorítí nwọ́n lé wa jáde kúrò nínú àwọn sínágọ́gù wa, tí àwa kò sì lè sin Ọlọ́run wa.

10 Ẹ kíyèsĩ, èmi wí fún nyín, ẹ̀yin ha lérò pé ẹ̀yin kò lè sin Ọlọ́run nyín bíkòṣe nínú àwọn sínágọ́gù nyín nìkan?

11 Ju gbogbo èyĩ, èmi yíò bẽrè, ẹ̀yin ha lérò pé ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ sin Ọlọ́run àfi ni ẹ̃kan ṣoṣo ní ọ́sẹ̀ bi?

12 Èmi wí fún nyín, ó dára tí nwọ́n lée nyín jáde kúrò nínú àwọn sínágọ́gù nyín, kí ẹ̀yin kí ó lè rẹ ara nyín sílẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó sì kọ́ ọgbọ́n, nítorípé ó jẹ́ ohun tí ó yẹ pé kí ẹ̀yin kọ́ ọgbọ́n; nítorítí a lée nyín jáde, tí àwọn arákùnrin nyín sì nkẹ́gàn nyín nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àìní nyín, ni ẹ̀yin ṣe rẹ ọkàn nyín sílẹ̀; nítorí àwọn ohun wọ̀nyí ni ẹ̀yin ṣe rẹ ara nyín sílẹ̀.

13 Àti nísisìyí, nítorítí a ti fi ipá mú nyín rẹ ara nyín sílẹ̀, alábùkún-fún ni ẹ̀yin íṣe; nítorítí ènìyàn, nígbàmíràn, tí a bá fi ipá múu láti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, yíò wá ìrònúpìwàdà; àti nísisìyí dájúdájú, ẹnìkẹ́ni tí ó bá ronúpìwàdà yíò rí ãnú; ẹnití ó bá sì rí ãnú, tí ó sì forítĩ dé òpin, òun nã ni a ó gbàlà.

14 Àti nísisìyí, gẹ́gẹ́bí mo ti wí fún nyín, pé nítorítí a ti fi ipá múu nyín láti rẹ ara nyín sílẹ̀, tí ẹ̀yin di alábùkún-fún, njẹ́ ẹ̀yin kò ha mọ̀ pé àwọn ẹnití ó bá rẹ ara nwọn sílẹ̀ nítõtọ́ nítorí ọ̀rọ̀ nã jẹ́ alábùkún-fún jùlọ?

15 Bẹ̃ni, ẹnití ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ nítõtọ́, tí ó sì ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tí ó sì forítì í dé òpin, òun nã ni a ó bùkún fún—bẹ̃ni, tí a ó bùkún fún un jù àwọn tí a fi ipá mú láti rẹ ara nwọn sílẹ̀ nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àìní nwọn.

16 Nítorínã, alábùkún-fún ni àwọn tí nwọ́n rẹ ara nwọn sílẹ̀ láìjẹ́ wípé a fi ipá mú nwọn láti rẹ ara nwọn sílẹ̀; tàbí kí a wípé, ni ọ̀nà míràn, alábùkún-fún ni ẹni nã tí ó gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbọ́, tí a sì rìí bọmi láì ṣe oríkunkun, bẹ̃ni, láìmọ ọ̀rọ̀ nã, tàbí pé láìfi ipá mú u láti mọ̀, kí wọn tó lè gbàgbọ́.

17 Bẹ̃ni, nwọ́n pọ̀ tí nwọn a máa wípé: Bí ìwọ bá lè fi àmì hàn fún wa láti ọ̀run wá, nígbànã ni àwa yíò mọ̀ pẹ̀lú ìdánilójú; nígbànã ní àwa yíò sì gbàgbọ́.

18 Nísisìyí mo bẽrè, njẹ́ ìgbàgbọ́ ni èyí íṣe? Ẹ kíyèsĩ, èmi wí fún nyín, rárá; nítorípé bí ènìyàn bá mọ́ ohun kan kò sí ìdí fún un láti gbà á gbọ́, nítorítí ó ti mọ̃.

19 Àti nísisìyí, báwo ni ègún orí ẹni nã yíò ha ti pọ̀ tó, tí ó mọ́ ìfẹ́-inú Ọlọ́run, tí kò sì ṣeé, ju ti ẹnití ó gbàgbọ́ nìkan, tàbí tí ó ní ìdí láti gbàgbọ́, tí ó sì ṣubú sí inú ìwàìrékọjá?

20 Nísisìyí, nínú eleyĩ ni kí ẹ ti ṣe ìdájọ́. Ẹ kíyèsĩ, mo wí fún nyín, pé bákannã ni ó rí ní ìhà kan àti èkejì; yíò sì rí fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

21 Àti nísisìyí, bí èmi ti sọ nípa ti ìgbàgbọ́—ìgbàgbọ́ kĩ ṣe kí ènìyàn ní ìmọ̀ pípé nípa ohun gbogbo; nítorínã, bí ẹ̀yin bá ní ìgbàgbọ́, ẹ̀yin ní ìrètí fún àwọn ohun tí a kò rí, èyítí íṣe òtítọ́.

22 Àti nísisìyí, ẹ kíyèsĩ, èmi wí fún nyín, èmi sì fẹ́ kí ẹ rántí, pé Ọlọ́run nṣãnú fún gbogbo àwọn tí wọ́n bá gba orúkọ rẹ̀ gbọ́; nítorínã ó fẹ́, lọ́nà àkọ́kọ́, pé kí ẹ̀yin gbàgbọ́, bẹ̃ni, àní nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀.

23 Àti nísisìyí, ó fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún ènìyàn nípasẹ̀ àwọn ángẹ́lì, bẹ̃ni, kĩ ṣe àwọn ọkùnrin nìkan, ṣùgbọ́n àwọn obìnrin nã pẹ̀lú. Nísisìyí, èyí kĩ ṣe gbogbo rẹ̀; àwọn ọmọdé nã ni ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run a máa fún nwọn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, èyítí a máa da àwọn ọlọgbọ́n àti àwọn amòye lãmú.

24 Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, bí ẹ̀yin ṣe fẹ́ kí èmi kí ó sọ fún nyín ohun tí ẹ̀yin ó ṣe nítorípé nwọ́n npọ́n nyín lójú tí nwọ́n sì lée nyín jáde—nísisìyí èmi kò fẹ́ kí ẹ rò pé èmi fẹ́ láti dáa nyín lẹ́jọ́ àfi gẹ́gẹ́bí èyítí í ṣe òtítọ́—

25 Nítorípé èmi kò lérò pé gbogbo nyín ni a ti fi ipá mú láti rẹ ara nyín sílẹ̀; nítorítí èmi gbàgbọ́ pé àwọn kan wà lãrín nyín tí nwọn ò rẹ ara nwọn sílẹ̀, jẹ́ kí nwọ́n wà ní ipòkípò tí nwọn ìbá wà.

26 Nísisìyí, bí èmi ti sọ nípa ìgbàgbọ́—pé kĩ ṣe ìmọ̀ pípé—bẹ̃ nã ni ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí rí. Ẹ̀yin kò lè mọ̀ nípa ìdánilójú nwọn nígbà àkọ́kọ́, ní kíkún, jù pé ìgbàgbọ́ jẹ́ ìmọ̀ pípé.

27 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, bí ẹ̀yin bá lè jí kí ẹ̀yin sì ta ọkàn nyín jí, àní sí àgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ mi, kí ẹ̀yin sì ní ìgbàgbọ́ kékeré, bẹ̃ni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé kí ẹ̀yin má ṣe jù pé kí ẹ ní ìfẹ́ láti gbàgbọ́, ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ yĩ ṣiṣẹ́ nínú nyín, àní títí ẹ̀yin yíò gbàgbọ́ ní ọ̀nà tí ẹ̀yin yíò gba ohun tí ẹ̀mí nsọ.

28 Nísisìyí, àwa yíò fi ọ̀rọ̀ nã wé irúgbìn. Nísisìyí, tí ẹ̀yin bá gba ohun tí èmi nsọ, pé kí a gbin irúgbìn nã sínú ọkàn nyín, ẹ wõ, bí ó bá ṣe irúgbìn òtítọ́, tàbí irúgbìn rere, tí ẹ̀yin kò bá fã tu nípa àìgbàgbọ́ nyín, kí ẹ̀yin tako Ẹ̀mí Olúwa, ẹ kíyèsĩ, yíò bẹ̀rẹ̀sí wú nínú ọkàn nyín; bí ẹ̀yin bá sì ní irú àpẹrẹ ọkàn wíwú báyĩ, ẹ̀yin yíò bẹ̀rẹ̀sí sọ nínú ara nyín pé ó níláti jẹ́ pé—ó di dandan ki eyi jẹ irúgbìn rere, tàbí pé rere ni ọ̀rọ̀ nã í ṣe, nítorítí ó bẹ̀rẹ̀sí mú ìdàgbàsókè bá ẹ̀mí mi; bẹ̃ni, ó bẹ̀rẹ̀sí tan ìmọ́lẹ̀ sí òye mi, bẹ̃ni, ó bẹ̀rẹ̀sí fún mi ní ayọ̀.

29 Nísisìyí ẹ kíyèsí i, njẹ́ eleyĩ kò ha ní mú ìgbàgbọ́ nyín tóbi síi bí? Mo wí fún nyín, bẹ̃ni; bíótilẹ̀ríbẹ̃, kòì tĩ dàgbà dé ibi ìmọ̀ pípé.

30 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, bí irúgbìn nã ṣe nwú síi, tí ó sì hù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀sí dàgbà, ẹ̀yin nã níláti sọ wípé irúgbìn nã dára; nítorítí, ẹ kíyèsĩ pé ó wú, ó sì hù, ó sì bẹ̀rẹ̀sí dàgbà. Àti nísisìyí, ẹ wõ, èyĩ kò ha ní mú kí ìgbàgbọ́ nyín dàgbà síi bí? Bẹ̃ni, yíò mú ìgbàgbọ́ nyín dàgbà síi: Nítorítí ẹ̀yin yíò wípé mo mọ̀ pé irúgbìn dáradára ni èyí íṣe; nítorítí ẹ kíyèsĩ ó hù ó sì bẹ̀rẹ̀sí dàgbà.

31 Àti nísisìyí, ẹ kíyèsĩ, njẹ́ ó dá nyín lójú pé irúgbìn dáradára ni èyĩ ṣe? Èmi wí fún un yín, bẹ̃ni; nítorípé irúgbìn dáradára yíò mú èso irú ara rẹ̀ jáde wá.

32 Nítorínã, bí irúgbìn bá dàgbà, dáradára ni íṣe, ṣùgbọ́n bí kò bá dàgbà, ẹ kíyèsĩ, kĩ ṣe dáradára, nítorínã a ó mú u kúrò.

33 Àti nísisìyí, ẹ kíyèsĩ, nítorípé ẹ̀yin ti ṣe ìdánwò nnì, tí ẹ ti gbin irúgbìn nã, tí ó sì wú, tí ó sì hù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀sí dàgbà, ẹ̀yin níláti mọ̀ pé irúgbìn nã dára.

34 Àti nísisìyí, ẹ kíyèsĩ, njẹ́ ìmọ̀ nyín ha pé bí? Bẹ̃ni, ìmọ̀ nyín pé nínú ohun nã, ìgbàgbọ́ nyín sì wà láìlò; èyí rí bẹ̃ nítorípé ẹ mọ̀, nítorítí ẹ̀yin mọ̀ pé ọ̀rọ̀ nã ti wú ọkàn nyín sókè, ẹ̀yin sì tún mọ̀ pé ó ti hù, pé ìmọ́lẹ̀ sì ti ntàn sí òye nyín, ìmọ̀ ọkàn nyín sì ti bẹ̀rẹ̀sí pọ̀ síi.

35 A! njẹ́ báyĩ, èyí kò ha jẹ́ òdodo? Èmi wí fún nyín, bẹ̃ni, nítorípé ìmọ́lẹ̀ ni íṣe; ohunkóhun tĩ bá sĩ ṣe ìmọ́lẹ̀, ó jẹ́ èyítí ó dára, nítorípé a mọ́ ìyàtọ̀ rẹ̀ lãrín àwọn yõkù, nítorínã, ẹ̀yin níláti mọ̀ pé ó dára; àti nísisìyí kíyèsĩ, lẹ́hìn tí ẹ̀yin ti tọ́ ìmọ́lẹ̀ yí wò, njẹ́ ìmọ̀ nyín pé bí?

36 Ẹ kíyèsĩ, mo wí fún nyín, Rárá; ẹ̀yin kò sì gbọ́dọ̀ pa ìgbàgbọ́ nyín tì, nítorípé ẹ̀yin ti lo ìgbàgbọ́ nyín láti gbin irúgbìn nã, kí ẹ̀yin kí ó lè sapá nínú ìdanwò nnì láti ríi bóyá dáradára ni irúgbìn nã í ṣe.

37 Sì kíyèsĩ, bí igi nã ṣe ndàgbà, ẹ̀yin yíò wípé: Ẹ jẹ́ kí a tọ́ọ dàgbà dáradára, kí ó lè ta gbòngbò, kí ó lè dàgbà, kí ó sì so èso fún wa. Àti nísisìyí i, ẹ kíyèsĩ, bí ẹ̀yin bá tọ́ ọ dáradára, yíò ta gbòngbò, yíò sì dàgbà, yíò sì so èso jáde wá.

38 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá pa igi nã tì, tí ẹ kò sì bìkítà fún bíbọ́ rẹ̀, ẹ kíyèsĩ kì yíò ní gbòngbò kankan; nígbàtí ìgbóná oòrùn bá sì dé tí ó sì jó o, nítorípé kò ní gbòngbò, yíò rẹ̀ dànù ẹ̀yin ó sì fã tu sọnù.

39 Nísisìyí, eleyĩ kò rí bẹ̃ nítorípé irúgbìn nã kò dára, tàbí nítorípé èso rẹ̀ kò dára; ṣùgbọ́n ó rí bẹ̃ nítorípé ilẹ̀ nyín ti ṣá, ẹ̀yin kò sì tọ́ igi nã dàgbà, nítorínã, ẹ̀yin kò lè rí èso rẹ̀ gbà.

40 Bákannã ni ó rí tí ẹ̀yin kò bá tọ́ ọ̀rọ̀ nã dàgbà, tí ẹ̀yin sì fojúsọ́nà pẹ̀lú ìgbàgbọ́ sí èso rẹ̀, ẹ̀yin kò lè ká èso igi ìyè láéláé.

41 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin yíò bá tọ́ ọ̀rọ̀ nã dàgbà, àní, bọ́ igi nã nígbàtí ó bẹ̀rẹ̀sí dàgbà, nípa ìgbàgbọ́ nyín pẹ̀lú ìtẹramọ́ nlá, àti ìpamọ́ra pẹ̀lú, tí ẹ̀yin sì fojúsọ́nà sí èso rẹ̀, yíò ta gbòngbò; ẹ sì kíyèsí, yíò sì jẹ́ igi tí yíò máa sun sí ìyè àìnípẹ̀kun.

42 Àti nítorí ìtẹramọ́ nyín àti ìgbàgbọ́ nyín, àti ìpamọ́ra nyín tí ẹ̀yin fi tọ́ ọ̀rọ̀ nã, pé kí ó lè ta gbòngbò nínú nyín, ẹ kíyèsĩ, láìpẹ́ ọjọ́, ẹ̀yin yíò ká èso rẹ̀, èyítí ó jẹ́ iyebíye jùlọ, èyítí ó dùn tayọ gbogbo ohun tí ó dùn, èyítí ó sì funfun tayọ gbogbo ohun tí ó funfun, bẹ̃ni, tí ó sì mọ́ tayọ gbogbo ohun tí ó mọ́; ẹ̀yin yíò sì máa jẹ èso yĩ àní títí ẹ̀yin yíò fi yó, tí ebi kò ní pa nyín, bẹ̃ sì ni òùngbẹ kò ní gbẹ nyín.

43 Nígbànã, ẹ̀yin arákùnrin mi, ẹ̀yin yíò kórè èrè ìgbàgbọ́ nyín, àti ìtẹramọ́ nyín, àti ìpamọ́ra, àti ìfaradà, bí ẹ̀yin ṣe dúró de ìgbàtí igi nã yíò so èso jáde wá fún nyín.