Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 30


Orí 30

Kòríhọ̀, ẹni aṣòdìsí-Krístì, nfi Krístì, Ètùtu, àti ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀ ṣe ẹlẹ́yà—Ó nkọ́ni pé kò sí Ọlọ́run, pé kò sí ìṣubú ènìyàn, pé kò sí ìjìyà fún ẹ̀ṣẹ̀, àti pé kò sí Krístì—Álmà jẹ́rĩ pé Krístì yíò dé, àti pé ohun gbogbo fihàn pé Ọlọ́run kan nbẹ—Kòríhọ̀ bẽrè fún àmì kan ó sì ya odi—Èṣù ni ó ti farahàn Kòríhọ̀ ṣãjú gẹ́gẹ́bí ángẹ́lì, tí ó sì kọ́ ọ ní ohun tí yíò sọ—A tẹ Kòríhọ̀ mọ́lẹ̀, ó sì kú. Ní ìwọ̀n ọdún 76 sí 74 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Kíyèsĩ, báyĩ ni ó sì ṣe lẹ́hìn tí àwọn ènìyàn Ámọ́nì ti gbilẹ̀ lórí ilẹ̀ Jẹ́ṣónì, bẹ̃ni, àti lẹ́hìn tí a ti lé àwọn ará Lámánì jáde kúrò lórí ilẹ̀ nã, tí àwọn ará ilẹ̀ nã sì ti gbé àwọn tí ó kú nínú nwọn sin—

2 Nísisìyí nwọn kò ka àwọn tí ó kú nínú nwọn nítorípé iye nwọn pọ̀ tayọ; bẹ̃nã ni nwọn kò ka àwọn tí ó kú nínú àwọn ará Nífáì—ṣùgbọ́n ó sì ṣe lẹ́hìn tí wọn ti sin àwọn tí ó kú nínú nwọn tán, àti lẹ́hìn tí àwọn ọjọ́ ãwẹ̀ gbígbà, àti ọ̀fọ̀ ṣíṣe, àti àdúrà gbígbà ti rékọjá, (èyí tí íṣe ọdún kẹrìndínlógún ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì) àlãfíà sì wà jákè-jádò orílẹ̀-èdè nã.

3 Bẹ̃ni, àwọn ènìyàn nã sì gbiyanju láti pa òfin Olúwa mọ́; nwọ́n sì múná nínú ṣíṣe àwọn ìlànà Ọlọ́run, ní ìbámu pẹ̀lú òfin Mósè; nítorítí a ti kọ́ nwọn láti pa òfin Mósè mọ́ títí a ó fi múu ṣẹ.

4 Báyĩ sì ni ó rí tí àwọn ènìyàn nã kò rí ìyọlẹ́nu kankan nínú gbogbo ọdún kẹrìndínlógún ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì.

5 Ó sì ṣe nínú ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kẹtàdínlógún ìjọba àwọn onídàjọ́, tí àlãfíà sì wà títí.

6 Ṣùgbọ́n ó sì ṣe ní àkokò tí ọdún kẹtàdínlógún fẹ́rẹ̀ dópin, ọkùnrin kan wá sínú orílẹ̀-èdè Sarahẹ́múlà, ó sì jẹ́ Aṣòdìsí-Krístì, nítorítí ó bẹ̀rẹ̀sí wãsù sí àwọn ènìyàn nã ní ìtakò àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ tí àwọn wòlĩ ti sọ ṣãjú, nípa bíbọ̀ Krístì.

7 Ní àkokò yĩ, kò sí òfin tí ó tako ìgbàgbọ́ ẹnìkẹ́ni; nítorítí ó jẹ́ ohun tí ó tako òfin Ọlọ́run pátápátá pé kí òfin kan wà èyítí yíò mú kí ẹlẹ́yà-mẹ̀yà wà lãrín àwọn ènìyàn.

8 Nítorí báyĩ ni ìwé-mímọ́ wí: Ẹ yan ẹnití ẹ̀yin ó máa sìn ní òní.

9 Nísisìyí, bí ẹnìkẹ́ni bá ní ìfẹ́ láti sin Ọlọ́run, ó jẹ́ ànfàní fun un; tàbí kí a wípé bí ó bá gba Ọlọ́run gbọ́ ó jẹ ànfàní fun un láti sìn ín; ṣùgbọ́n bí òun kò bá gbã gbọ́, kò sí òfin tí ó wípé kí a jẹẹ́ níyà.

10 Ṣùgbọ́n bí ó bá pànìyàn, nwọn fi ìyà jẹ ẹ́ dé ojú ikú; bí ó bá sì fipá jalè, nwọn fi ìyà jẹẹ́ pẹ̀lú; bí ó bá sì jalè, nwọn jẹ̃ níyà pẹ̀lú; bí ó bá sì hu ìwà àgbèrè, nwọn jẹẹ́ níyà pẹ̀lú; bẹ̃ni, fún gbogbo ìwà búburú yĩ, nwọ́n jẹ nwọ́n níyà.

11 Nítorítí òfin kan nbẹ pé a ó ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́bí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Bíótilẹ̀ríbẹ̃, kò sí òfin tí ó tako ìgbàgbọ́ ẹnìkẹ́ni; nítorínã, nwọn fi ìyà jẹ ènìyàn fún ìwà ìrúfin tí ó bá hù; nítorínã gbogbo ènìyàn ni ó jẹ́ ọgbọ̃gba.

12 Ẹni Aṣòdìsí-Krístì yĩ, èyítí orúkọ rẹ̀ íṣe Kòríhọ̀, (ti òfin kò sì lè dẽ) bẹ̀rẹ̀sí wãsù sí àwọn ènìyàn nã pé kò sí Krístì kankan. Ní irú ọ̀nà báyĩ sì ni ó nwãsù, wípé:

13 A!, ẹ̀yin tí a ti dè mọ́lẹ̀ nínú ìrètí aṣiwèrè àti asán, kíni ìdí rẹ̀ tí ẹ̀yin fi àjàgà ohun aṣiwèrè wọ̀nyí kọ́ ọrùn ara nyín? Kíni ìdí rẹ̀ tí ẹ̀yin fi nwá Krístì kan? Nítorípé kò sí ẹnìkẹ́ni tí ó lè mọ̀ nípa ohunkóhun tí nbọ̀wá.

14 Kíyèsĩ, àwọn ohun wọ̀nyí tí ẹ̀yin npè ní àsọtẹ́lẹ̀, tí ẹ̀yin sọ wípé àwọn wòlĩ mímọ́ ni ó gbé nwọn lée nyín lọ́wọ́, ẹ kíyèsĩ, àṣà aṣiwèrè àwọn bàbá nyin ni nwọ́n í ṣe.

15 Báwo ni ẹ̀yin ṣe ní ìdánilójú lórí nwọn? Ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin kò lè mọ̀ nípa àwọn ohun tí ẹ̀yin kò rí; nítorínã ẹ̀yin kò lè mọ̀ bí Krístì kan yíò bá wà.

16 Ẹ̀yin ní ìrètí, tí ẹ sì wípé ẹ ó rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nyín. Ṣùgbọ́n, ẹ kíyèsĩ, àyọrísí ọkàn tí ó sínwín ni èyí í ṣe; ìdàrúdàpọ̀ ọkàn nyín yĩ sì débá nyín nítorí àṣà àwọn bàbá nyin, èyítí ó jẹ́ kí ẹ̀yin ó gba àwọn ohun tí kĩ ṣe òtítọ́ gbọ́.

17 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú àwọn ohun báyĩ ni ó sì sọ fún nwọn, tí ó wí fún nwọn pé kò lè sí ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n olúkúlùkù nínú ayé yĩ nṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìtọ́ni; nítorínã, ènìyàn ní ìlọ̀síwájú gẹ́gẹ́bí òye rẹ̀ ti tó, àti pé olúkúlùkù ènìyàn borí ní ìbámu pẹ̀lú agbára rẹ̀; àti pé kò sí ẹ̀ṣẹ̀ nínú ohunkóhun tí ènìyàn ṣe.

18 Báyĩ ni ó sì ṣe nwãsù fún nwọn, tí ó sì ndarí ọkàn púpọ̀ nínú nwọn kúrò, tí ó nmú wọn gbéraga nínú ipò ìwà búburú wọn, bẹ̃ni, tí ó sì ndarí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn obìnrin, àti àwọn ọkùnrin pẹ̀lú, láti hu ìwà àgbèrè—tí ó wí fún wọn pé bí ènìyàn bá ti kú òpin ayé ẹni nã ni èyí.

19 Nísisìyí, ọkùnrin yĩ kọjá lọ sí orílè-èdè Jẹ́ṣónì pẹ̀lú, láti wãsù àwọn ohun wọ̀nyí lãrín àwọn ènìyàn Ámọ́nì, tí nwọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn ará Lámánì ní ìgbà kan rí.

20 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, nwọ́n jẹ́ ọlọgbọ́n-ènìyàn jù púpọ̀ nínú àwọn ará Nífáì; nítorítí nwọ́n múu, nwọ́n sì dè é, nwọ́n sì gbé e wá sí iwájú Ámọ́nì, ẹnití í ṣe olórí àlùfã lórí àwọn ènìyàn nnì.

21 Ó sì ṣe tí ó mú kí nwọ́n gbé e jáde kúrò lórí ilẹ̀ nã. Ó sì wá sí inú ilẹ̀ Gídéónì, ó sì bẹ̀rẹ̀sí wãsù fún àwọn nã pẹ̀lú; kò sì ní àṣeyọrí púpọ̀ ní ibi yĩ, nítorítí nwọ́n mú u nwọ́n sì dè é, nwọ́n sì gbé e lọ sí iwájú olórí àlùfã, tí í sì i ṣe adájọ́ àgbà lórí ilẹ̀ nã.

22 Ó sì ṣe tí olórí àlùfã nã sọ fún un pé: Kíni ìdí rẹ̀ tí ìwọ fi nkãkìri láti yí ọ̀nà Olúwa po? Kíni ìdí rẹ̀ tí ìwọ fi nkọ́ àwọn ènìyàn yì í pé kò ní sí Krístì, láti lè fi òpin sí ayọ̀ nwọn? Kíni ìdí rẹ̀ tí ìwọ fi nsọ̀rọ̀ tako gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ àwọn wòlĩ mímọ́?

23 Nísisìyí, orúkọ olórí àlùfã nã ni Gídónà. Kòríhọ̀ sì wí fún un pé: Nítorípé èmi kò kọ́ni ní àwọn àṣà aṣiwèrè àwọn bàbá rẹ, àti nítorípé èmi kò kọ́ àwọn ènìyàn yĩ pé kí nwọ́n de ara nwọn mọ́lẹ̀ lábẹ́ àwọn ìlànà àti ìṣe aláìgbọ́n, tí àwọn àlùfã ìgbà àtijọ́ gbé kalẹ̀, láti lè ní agbára àti àṣẹ lórí wọn, láti fi nwọ́n sí ipò àìmọ̀, kí nwọn má lè gbé orí wọn sókè, ṣùgbọ́n kí nwọ́n wà ní ipò ìtẹríba sí ọ̀rọ̀ rẹ.

24 Ìwọ wípé àwọn ènìyàn yĩ jẹ́ òmìnira-ènìyàn. Kíyèsĩ, èmi wípé nwọ́n wà nínú oko-ẹrú. Ìwọ wípé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìgbà nì jẹ́ òtítọ́. Kíyèsĩ, èmi wípé ìwọ kò mọ̀ pé òtítọ́ ni nwọ́n íṣe.

25 Ìwọ wípé àwọn ènìyàn yìi jẹ́ ẹni-ìdálẹ́bi àti ẹni-ìṣubú ènìyàn, nítorí ìwà ìrékọjá òbí. Kíyèsĩ, èmi wípé ọmọ kò jẹ́ ẹni ìdálẹ́bi nítorí àwọn òbí rẹ̀.

26 Ìwọ sì tún sọ wípé Krístì yíò wá. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, èmi wípé ìwọ kò mọ̀ pé Krístì kan yíò wà. Ìwọ sì tún sọ pẹ̀lú pé a ó pa á nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aráyé—

27 Báyĩ sì ni ìwọ ṣe darí àwọn ènìyàn yìi sí ipa àṣà àwọn bàbá rẹ, àti gẹ́gẹ́bí ìfẹ́-inú rẹ; tí ìwọ sì tẹrí wọn bá, àní bí ẹnití ó wà nínú oko-ẹrú, kí ìwọ kí ó lè máa gbáyùnùn nínú lãlã nwọn, kí nwọ́n má lè gbé ojú sókè pẹ̀lú ìgboyà, àti kí nwọ́n má lè gbádùn ẹ̀tọ́ àti ànfãní tí í ṣe tiwọn.

28 Bẹ̃ni, nwọn kò lè lo ohun tí í ṣe tiwọn, ní ìbẹ̀rù fún ṣíṣẹ̀ àwọn àlùfã nwọn, tí nwọn gbé àjàgà wọ̀ nwọ́n lọ́rùn gẹ́gẹ́bí ìfẹ́-inú nwọn, tí nwọ́n sì ti mú nwọn gbàgbọ́, nípa àṣà nwọn, àti ìrètí nwọn, àti ìdùnnú nwọn, àti ìran rírí nwọn, àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ èké nwọn, pé bí wọn kò bá ṣe gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ wọn, wọn ṣẹ̀ sí ẹ̀dá àìmọ̀ kan, ẹnití nwọ́n sọ wípé í ṣe Ọlọ́run—ẹ̀dá tí ẹnìkẹ́ni kò rí rí tàbí tí ẹnìkẹ́ni kò mọ̀, tí kò sí rí, tí kò sì lè sí.

29 Nísisìyí, nígbàtí olórí àlùfã àti adájọ́-àgbà rí líle ọkàn rẹ̀, bẹ̃ni, nígbàtí nwọn ríi pé yíò pẹ̀gàn Ọlọ́run pãpã, nwọn kò fèsì ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́; ṣùgbọ́n nwọ́n mú kí nwọ́n dè é; nwọ́n sì fi lé ọwọ́ àwọn olórí, nwọ́n sì fi ránṣẹ́ sí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, kí nwọ́n lè mú u wá síwájú Álmà, àti adájọ́-àgbà, ẹnití í ṣe bãlẹ̀ lórí gbogbo ilẹ̀ nã.

30 Ó sì ṣe nígbàtí nwọ́n mú u dé iwájú Álmà àti adájọ́-àgbà, ó tún tẹ̀síwájú gẹ́gẹ́bí ó ti ṣe ní ilẹ̀ Gídéónì; bẹ̃ni, ó tẹ̀síwájú láti sọ̀rọ̀ búburú sí ohun mímọ́.

31 Ó sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ohùn líle níwájú Álmà, tí ó sì pẹ̀gàn àwọn àlùfã, àti àwọn olùkọ́ni, tí ó fẹ̀sùn kàn wọ́n pé àwọn ni ó ndarí àwọn ènìyàn nã lọ sí ipa ti àṣà òmùgọ̀ àwọn bàbá nwọn, láti lè máa gbáyùnùn nínú lãlã àwọn ènìyàn nã.

32 Nísisìyí, Álmà wí fún un pé: Ìwọ mọ̀ pé àwa kò gbáyùnùn nínú lãlã àwọn ènìyàn yĩ; nítorí kíyèsĩ, èmi ti ṣe lãlã láti ìgbàtí ìjọba àwọn onídàjọ́ ti bẹ̀rẹ̀ títí dé àkokò yĩ, pẹ̀lú ọwọ́ ara mi fún ìrànlọ́wọ́ ara mi, l’áìṣírò ìrìnàjò mi púpọ̀ kãkiri orílẹ̀-èdè nã láti kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún àwọn ènìyàn mi.

33 Àti l’áìṣírò ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ lãlã tí èmi ti ṣe nínú ìjọ-onígbàgbọ́, èmi kò gba èrè ẹyọ owó kan rí fún iṣẹ́ lãlã mi; bákannã sì ni ẹnìkẹ́ni nínú àwọn arákùnrin mi, bíkòṣe lórí ìtẹ́ ìdájọ́; bẹ̃ sì ni àwa gbã ní ìbámu pẹ̀lú òfin lórí àkokò tí a bá lò tí a bá fi ṣe ìdájọ́.

34 Àti nísisìyí, bí àwa kò bá gba ohunkóhun fún iṣẹ́ lãlã wa nínú ìjọ-onígbàgbọ́, kíni èrè wa fún iṣẹ́ lãlã tí àwa nṣe nínú ìjọ-onígbàgbọ́, bí kò bá ṣe pé láti kéde òtítọ́, kí àwa lè ní ìdùnnú nínú ayọ̀ àwọn arákùnrin wa?

35 Nígbànã kíni ìdí rẹ tí ìwọ fi wípé àwa nwãsù fún àwọn ènìyàn yĩ láti rí èrè gbà, nígbàtí ìwọ tìkararẹ̀ mọ̀ wípé àwa kò gba èrè rárá? Àti nísisìyí, njẹ́ ìwọ gbàgbọ́ pé àwa ntan àwọn ènìyàn yĩ, tí àwa sì nfún wọn ní ayọ̀ irú èyí ni ọkàn nwọn?

36 Kòríhọ̀ sì dá a lóhùn wípé, Bẹ̃ni.

37 Nígbànã ni Álmà wí fún un pé: Njẹ́ ìwọ gbàgbọ́ pé Ọlọ́run kan nbẹ?

38 Ó sì dáhùn wípé: Rara.

39 Nígbàyí ni Álmà wí fún un pé: Njẹ́ ìwọ yíò tún sẹ́ pé Ọlọ́run kan nbẹ, àti pé ìwọ ó tún sẹ́ Krístì nã? Nítorí kíyèsĩ, èmi wí fún ọ, èmi mọ̀ pé Ọlọ́run kan nbẹ, àti pé Krístì yíò wá.

40 Àti nísisìyí, ẹ̀rí wo ni ìwọ ní pé Ọlọ́run kò sí, tàbí pé Krístì kì yíò wá? Èmi wí fún ọ pé ìwọ kò ní, àfi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ nìkan.

41 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, mo ní ohun gbogbo gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí pé àwọn nkan wọ̀nyí jẹ́ òtítọ́; ìwọ pẹ̀lú sì ní àwọn nkan wọ̀nyí gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí sí ọ pé ọ̀títọ́ ni nwọ́n í ṣe; njẹ́ ìwọ yíò ha sẹ́ wọn bí? Njẹ́ ìwọ gbàgbọ́ pé otítọ́ ni àwọn nkan wọ̀nyí í ṣe?

42 Kíyèsĩ, èmi mọ̀ pé ìwọ gbàgbọ́, ṣùgbọ́n ẹ̀mí irọ́-pípa wà nínú rẹ, ìwọ sì ti pa Ẹ̀mí Ọlọ́run tì, tí kò sì gbé inú rẹ mọ́; ṣùgbọ́n èṣù ni ó lágbára lórí rẹ, ó sì ndarí rẹ, tí ó sì nta ọgbọ́n àrékérekè láti pa àwọn ọmọ Ọlọ́run run.

43 Àti nísisìyí Kòríhọ̀ wí fún Álmà pé: Bí ìwọ bá lè fi àmì kan hàn mí, ki emi le ni ìdánilójú pé Ọlọ́run kan wà, bẹ̃ni, fi hàn mí pé ó ní agbára, ìgbànã ni èmi yíò ní ìdánilójú nípa òtítọ́ ọ̀rọ̀ rẹ gbogbo.

44 Ṣùgbọ́n Álmà wí fún un pé: Ìwọ ti rí àmì tó; ìwọ yíò ha dán Ọlọ́run rẹ wò bí? Njẹ́ ìwọ yíò wípé, fi àmì kan hàn mí, nígbàtí ìwọ ní ẹ̀rí gbogbo àwọn arákùnrin rẹ wọ̀nyí, àti gbogbo àwọn wòlĩ mímọ́ pẹ̀lú? Àwọn ìwé-mímọ́ hàn sí ọ kedere, bẹ̃ni, àti pẹ̀lú pé ohun gbogbo fi hàn pé Ọlọ́run kan nbẹ; bẹ̃ni àní ayé pẹ̀lú, àti ohun gbogbo tí ó wà lójú rẹ̀, bẹ̃ni, àti yíyí rẹ̀, bẹ̃ni, àti gbogbo àwọn ogun ọ̀run pẹ̀lú tí nwọ́n sì nyí ni ipa ọ̀nà nwọn jẹ́ ẹ̀rí pé Ẹlẹ́dã Tí-ó-ga-jùlọ kan nbẹ.

45 Síbẹ̀síbẹ̀ njẹ́ ìwọ kò ha lọ kákiri, tí ó sì ndarí ọkàn àwọn ènìyàn yĩ kúrò, tí ó njẹ́rĩ fún nwọn pé Ọlọ́run kò sí? Ẹ̀wẹ̀, njẹ́ ìwọ lè sẹ́ gbogbo ẹ̀rí wọ̀nyí? Ó sì wípé: Bẹ̃ni, èmi yíò sẹ́ ẹ, àfi bí ìwọ bá fi àmì kan hàn mí.

46 Àti nísisìyí ó sì ṣe ti Álmà wí fún un pé: Kíyèsĩ, inú mi bàjẹ́ nítorí líle ọkàn rẹ, àní, tí ìwọ sì nkọjú ìjà sí ẹ̀mí-òtítọ́, pé kí ẹ̀mí rẹ lè parun.

47 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ó sàn kí ẹ̀mí rẹ̀ kí ó parun, jù kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí ti ipasẹ̀ rẹ bọ́ sí ìparun, nípa ọ̀rọ̀ irọ́ àti ẹ̀tàn rẹ; nítorínã, bí ìwọ yíò bá tún sẹ́ẹ, kíyèsĩ, Ọlọ́run yíò kọlũ ọ́, tí ìwọ yíò sì yadi, tí ìwọ kò sì ní lè la ẹnu rẹ̀ mọ́, kí ìwọ kí ó má lè tan àwọn ènìyàn yĩ mọ́.

48 Nísisìyí, Kòríhọ̀ wí fún un pé: Èmi kò sẹ́ pé Ọlọ́run kan nbẹ, ṣùgbọ́n èmi kò gbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọ́run kan; èmi sì tún sọ pẹ̀lú, wípé ìwọ kò mọ̀ pé Ọlọ́run kan nbẹ; bí ìwọ kò bá sì lè fi àmì hàn mí, èmi kò ní gbàgbọ́.

49 Nísisìyí Álmà wí fún un pé: Eleyĩ ni èmi yíò fi fún ọ fún àmì kan, pé ìwọ yíò yadi, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ mi; èmí sì sọ pé, ní orúkọ Ọlọ́run, ìwọ ó yadi, tí ìwọ kò sì ní lè fọhùn mọ́.

50 Nísisìyí nígbàtí Álmà ti sọ àwọn ohun wọ̀nyí tán, Kòríhọ̀ yadi, tí kò si lè fọhùn mọ́, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Álmà.

51 Àti nísisìyí, nígbàtí adájọ́ àgbà rí èyí, ó na ọwọ́ rẹ̀ jáde ó sì kọọ́ sí Kòríhọ̀, pé: Njẹ́ ìwọ ha ti ní ìdánilójú nípa agbára Ọlọ́run? Ara tani ìwọ ha ti fẹ́ kí Álmà fi àmì rẹ̀ hàn? Ìwọ ha fẹ́ kí ó kọlũ ẹlòmíràn bí, láti fi àmì hàn ọ́? Kíyèsĩ, ó ti fi àmì hàn ọ́; àti nísisìyí ìwọ ó tún jìyàn síi báyĩ?

52 Kòríhọ̀ sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde ó sì kọọ́ pé: Èmi mọ̀ pé mo ti yadi, nítorítí èmi kò lè fọhùn; èmi sì mọ̀ pé kò sí ohunkóhun bíkòṣe agbára Ọlọ́run ni ó lè mú eleyĩ dé bá mi; bẹ̃ni, èmi sì ti mọ̀ látẹ̀hìnwá pé Ọlọ́run kan nbẹ.

53 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, èṣù ni ó ti tàn mí; nítorítí ó farahàn mí ní ẹ̀yà ángẹ́lì, tí ó sì wí fún mi pé: Lọ gba àwọn ènìyàn yĩ padà, nítorítí nwọn ti ṣìnà nípa títẹ̀lé Ọlọ́run àìmọ̀ kan. Òun sì wí fún mi pé: Kò sí Ọlọ́run; bẹ̃ni, òun sì kọ́ mi ní ohun tí èmi yíò sọ. Èmi sì ti kọ́ni ní àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀; èmi sì ṣe ìkọ́ni ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nítorípé nwọ́n dùn mọ́ ọkàn ti ara; èmi sì nṣe ìkọ́ni wọn, àní títí èmi fi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣeyọrí, tó bẹ̃ tí èmi fi gbàgbọ́ dájúdájú pé òtítọ́ ni nwọ́n í ṣe; nítorí ìdí èyí ni èmi ṣe kọjú ìjà sí èyítí í ṣe òtítọ́, àní títí èmi fi mú ẹ̀gún nlá yĩ sí órí mi.

54 Nísisìyí nígbàtí ó ti sọ eleyĩ, ó sì fi ẹ̀bẹ̀ rọ Álmà pé kí ó gbàdúrà sí Ọlọ́run kí ègún nã lè kúrò lórí òun.

55 Ṣùgbọ́n Álmà wí fún un pé: Tí ègún yĩ bá kúrò lórí rẹ, ìwọ yíò tún darí ọkàn àwọn ènìyàn wọ̀nyí kúrò; nítorínã kí ó rí fún ọ àní gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ ti Olúwa.

56 Ó sì ṣe tí a kò mú ègún nã kúrò lórí Kòríhọ̀; ṣùgbọ́n nwọ́n lé e jáde, ó sì nlọ kákiri láti ilé dé ilé, tí ó ntọrọ oúnjẹ jẹ.

57 Nísisìyí, ní kété ni nwọ́n kéde ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Kòríhọ̀ jákè-jádò ilẹ̀ nã; bẹ̃ni, adájọ́-àgbà ni ó fi ìkéde nã ránṣẹ́ sí gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ílẹ̀ nã, tí ó sì kéde sí àwọn tí nwọ́n ti gba ọ̀rọ̀ Kòríhọ̀ gbọ́ pé nwọ́n níláti ronúpìwàdà kankan, kí irú ìdájọ́ kannã má bã dé bá wọn.

58 Ó sì ṣe ti gbogbo nwọn ní ìdánilójú nípa ìwà búburú Kòríhọ̀; nítorínã gbogbo nwọn yípadà sọ́dọ̀ Olúwa; èyí ni ó sì fi òpin sí àìṣedẽdé irú èyítí Kòríhọ̀ hù. Kòríhọ̀ sì nlọ kákiri láti ilé dé ilé, tí ó ntọrọ oúnjẹ fún ìrànlọ́wọ́ ara rẹ̀.

59 Ó sì ṣe tí ó kọjá lọ sí ãrin àwọn ènìyàn, bẹ̃ni, lãrín àwọn ènìyàn tí nwọ́n ti yapa kúrò lára àwọn ará Nífáì tí nwọ́n sì pe ara nwọn ní ará Sórámù, nítorípé ẹnì kan tí orúkọ rẹ̀ í ṣe Sórámù ni ó ndarí wọn—bí ó sì ti kọjá lọ sí ãrin wọn, kíyèsĩ, nwọn tẹ̃ mọ́lẹ̀, àní títí ó fi kú.

60 Báyĩ ni a sì rẹ́hìn ẹni nã tí ó nyí ọ̀nà Olúwa po; báyĩ ni àwa sì ríi pé èṣù kò ni ti àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́hìn ní ọjọ́ ìkẹhìn, ṣùgbọ́n òun yíò fà nwọ́n sínú ọ̀run àpãdì kankan.