Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 3


Orí 3

Àwọn Ámlísì ti ṣe àmì sí ára wọn gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀—Àwọn ará Lámánì ti di ẹni-ìfibú fún ìṣọ̀tẹ̀ nwọn—Ènìyàn ni ó nmú ìfibú wá sí órí ara nwọn—Àwọn ará Néfáí borí ẹgbẹ́ ọmọ ogun miran ti àwọn ará Lámánì. Ní ìwọ̀n ọdún 87 sí 86 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe nígbàtí àwọn ará Nífáì tí a kò pa nipa awọn ohun ìjà ogun, lẹhin tí nwọ́n ti sin àwọn tí a pa—nísisìyí a kò ka iye àwọn tí a pa nítorítí nwọ́n pọ̀ pupọ̀—lẹ́hìn tí nwọ́n ti sin àwọn tí ó kú tán, gbogbo nwọn padà sí ilẹ̀ nwọn, àti sí ilé nwọn, àti àwọn aya nwọn, àti àwọn ọmọ nwọn.

2 Nísisìyí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn obìnrin pẹ̀lú àwọn ọmọdé ni a ti pa pẹ̀lú idà, àti pẹ̀lú púpọ̀ nínú àwọn agbo-ẹran àti ọwọ́-ẹran nwọn; àti pẹ̀lú púpọ̀ nínú àwọn oko wóró irúgbìn nwọn ni a run, nítorítí ogunlọ́gọ̀ àwọn ènìyàn tẹ̀ nwọ́n pa.

3 Àti nísisìyí, gbogbo àwọn ará Lámánì àti àwọn ará Ámlísì tí a ti pa ní bèbè odò Sídónì ni a sọ sínú omi Sídónì; sì kíyèsĩ egungun nwọn wà ní ìsàlẹ̀ òkun, nwọ́n sì pọ̀.

4 Àwọn ará Ámlísì wà ní ìdáyàtọ̀ kúrò lãrín àwọn ará Nífáì, nítorítí nwọ́n ti kọ ara nwọn ní àmì pupa ní iwájú orí nwọn, gẹ́gẹ́bí ìṣe àwọn ará Lámánì; bíótilẹ̀ríbẹ̃ wọn kò fá orí nwọn gẹ́gẹ́bí àwọn ará Lámánì ti ṣe.

5 Nísisìyí, àwọn ará Lámánì fárí, nwọn kò sì wọ aṣọ, àfi awọ tí nwọ́n sán mọ́ ìbàdí, àti ìhámọ́ra nwọn pẹ̀lú, èyítí nwọ́n sán mọ́ra, àti ọrún nwọn, àti ọfà nwọn, àti òkúta-wẹ́wẹ́ nwọn, àti kànnà-kànnà nwọn, àti bẹ̃ bẹ̃ lọ.

6 Àwọ̀ ara àwọn ará Lámánì sì sú, gẹ́gẹ́bí àmì tí a ti fi lé àwọn bàbá nwọn lára, èyítí íṣe ìfibú lórí nwọn, nítorí ìwàìrékọjá nwọn, àti ìṣọ̀tẹ̀ nwọn sí àwọn arákùnrin nwọn, tí nwọn íṣe Nífáì, Jákọ́bù, Jósẹ́fù, àti Sãmú, tí nwọ́n jẹ́ ènìyàn títọ àti ẹni mímọ́.

7 Tí àwọn arákùnrin nwọn lépa láti pa nwọ́n run, nítorínã ni a fi fi nwọ́n bú; tí Olúwa Ọlọ́run sì fi àmì lé nwọn lára, bẹ̃ni sí órí Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì, àti àwọn ọmọ Íṣmáẹ́lì pẹ̀lú, àti àwọn obìnrin ilé Íṣmáẹ́lì.

8 A sì ṣe eleyĩ kí a lè mọ́ irú ọmọ wọn lãrín irú-ọmọ àwọn arákùnrin wọn pé nípa èyí nã Olúwa Ọlọ́run yíò pa àwọn ènìyàn rẹ̀ mọ́, tí nwọn kò sì ní dàpọ̀ mọ́ àwọn arákùnrin nwọn, kí nwọ́n sì gba àṣà tí kò tọ̀nà gbọ́, èyítí yíò jẹ́ ìparun fún nwọn.

9 Ó sì ṣe, wípé ẹnìkẹ́nì tí ó bá da irú-ọmọ rẹ̀ pọ̀ mọ́ ti àwọn ará Lámánì mú ìfibú kannã sí órí irú-ọmọ tirẹ̀.

10 Nítorínã, ẹnìkẹ́ni tí ó bá jẹ́ kí àwọn ará Lámánì ṣi òun lọ́nà ni nwọ́n npè ni ábẹ́ àmì yíi, a sì fi àmì nã lée.

11 Ó sì ṣe wípé ẹnìkẹ́ni tí kò bá gbàgbọ́ nínú àṣà àwọn ará Lámánì, ṣùgbọ́n tí ó gbàgbọ́ nínú àwọn ìwé ìrántí tí a mú jáde kúrò ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, àti nínú àṣà àwọn bàbá nwọn, èyítí ó pé, tí ó gbàgbọ́ nínú awọn òfin Ọlọ́run tí ó sì pa nwọ́n mọ́, ni a pè ní àwọn ará Nífáì, tàbí àwọn ènìyàn Nífáì, láti ìgbà nã lọ—

12 Àwọn sì ni ó ti tọ́jú àwọn ìwé ìrántí tí ó jẹ́ òtítọ́ nípa àwọn ènìyàn nwọn, àti pẹ̀lú nípa àwọn ará Lámánì.

13 Nísisìyí, àwa yíò tún padà sórí àwọn ará Ámlísì, nítorítí àwọn nã ní àmì tí a fi lé nwọn lára; bẹ̃ni, nwọ́n sì fi àmì nã lé ara nwọn, bẹ̃ni, àní àmì pupa lé iwájú orí nwọn.

14 Báyĩ gẹ́gẹ́ ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di mímúṣẹ, nítorípé àwọn wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ tí ó bá Nífáì sọ: Kíyèsĩ, àwọn ará Lámánì ni èmi ti fi bú, èmi yíò sì fi àmì lé nwọn lára, pé àwọn pẹ̀lú àwọn irú ọmọ nwọn, ni a o pín níyà kúrò lãrín ìwọ àti àwọn irú-ọmọ rẹ, láti ìsisìyí lọ, àti títí láéláé, àfi tí nwọn bá ronúpìwàdà kúrò nínú ìwà búburú wọn, kí nwọ́n sì padà tọ̀ mí wá, kí èmi kí ó lè ṣãnú fún nwọn.

15 Àti pẹ̀lú: Èmi yíò fi àmì lé ẹni nã tí ó bá da irú-ọmọ rẹ̀ pọ̀ mọ́ àwọn arákùnrin rẹ pé kí a fi nwọ́n bú pẹ̀lú.

16 Àti pẹ̀lú: Èmi yíò fi àmì lé ẹni nã tí ó bá bá ọ jà àti irú-ọmọ rẹ.

17 Àti pẹ̀lú, èmi wípé ẹni nã tí ó bá yapa kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ ni a kò lè pè ní èso rẹ mọ́; èmi yíò sì bùkún fún ọ, àti fún ẹnikẹ́ni tí a pè ní èso rẹ, láti ìsisìyí lọ àti láéláé; àwọn wọ̀nyí sì ni àwọn ìlérí Olúwa sí Nífáì àti sí irú ọmọ rẹ̀.

18 Nísisìyí àwọn ará Ámlísì kò sì mọ̀ wípé àwọn nmú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ré kọjá ni, nígbàtí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí fi àmì lé iwájú orí ara nwọn; bíótilẹ̀ríbẹ̃, nwọ́n ti jáde wá ní ìṣọ̀tẹ ní gbangba si Ọlọ́run; nítorínã, ó jẹ́ ohun ẹ̀tọ́ kí ègún nã kí ó ré lù nwọ́n.

19 Nísisìyí, èmi fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó ríi pé àwọn ni nwọ́n fa ègún nã sí órí àra nwọn; àti pé bẹ̃ni gbogbo ẹni tí a bá ti fi gé ègún ni ó mú ìdánilẹ́bi wá sí órí ara rẹ̀.

20 Nísisìyí, ó sì ṣe tí kò pẹ́ lẹ́hìn ìjà tí nwọ́n jà ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, lãrín àwọn ara Lámánì àti àwọn ará Ámlísì, tí ẹgbẹ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì míràn tún ṣí ti àwọn ará Nífáì, ní ojú ibi tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun àkọ́kọ́ ti pàdé àwọn ará Ámlísì.

21 Ó sì ṣe tí a rán àwọn ọmọ ogun kan láti lé nwọn jáde kúrò lórí ilẹ̀ nwọn.

22 Nísisìyí Álmà fúnrãrẹ nítorítí ó gbọgbẹ́, kò lọ sí ójú ogun ní àkókò yí láti dojúkọ àwọn ará Lámánì;

23 Ṣùgbọ́n ó rán àwọn ogunlọ́gọ̀ ọmọ ogun sí nwọn; nwọn sì lọ, nwọ́n sì pa púpọ̀ nínú àwọn ará Lámánì, nwọ́n sì lé àwọn tí ó kù nínú nwọn jáde kúrò ní agbègbè ilẹ̀ nwọn.

24 Nwọ́n sì tún padà, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí fi àlãfíà lélẹ̀ ní ilẹ̀ nã, tí àwọn ọ̀tá nwọn kò sì yọ nwọ́n lẹ́nu mọ́ fún ìgbà kan.

25 Nísisìyí, gbogbo ohun wọ̀nyí ni ó ṣẹlẹ̀, bẹ̃ni, gbogbo àwọn ogun àti ìjà yíi bẹ̀rẹ̀ nwọ́n sì parí ní ọdún kãrún ní ìjọba àwọn onídàjọ́.

26 Nínú ọdún kan sí ní ẹgbẹ̀rún àti ẹgbẹ̃gbẹ̀rún ẹ̀mí kọjá lọ sí ayé àìnípẹ̀kun, kí nwọ́n lè kórè gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ nwọn, bí ó jẹ́ rere, tàbí ó jẹ́ búburú, kí nwọ́n lè kórè ayọ̀ àìnípẹ̀kun, tàbí ìrora àìnípẹ̀kun, gẹ́gẹ́bí ẹ̀mí tí nwọ́n gbọ́ran sí, bí ó jẹ́ ẹ̀mí dáradára tàbí búburú.

27 Nítorípé gbogbo ènìyàn yíò gba èrè lọ́wọ́ ẹni tí òun gbọ́ran sí, èyí sì jẹ́ gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀; nítorínã, jẹ́ kí ó rí bẹ̃ gẹ́gẹ́bí òtítọ́. Báyĩ sì ni ọdún kãrún ìjọba àwọn onídàjọ́.