Àwọn Ìwé Mímọ́
3 Nífáì 27


Orí 27

Jésù pàṣẹ fún wọn pé kí wọn ó pe Ìjọ nã ní orúkọ òun—Iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ àti ẹbọ-ọrẹ ètùtù rẹ̀ jẹ́ ìhìn-rere rẹ̀—A pàṣẹ fún àwọn ènìyàn kí wọn ó ronúpìwàdà kí a sì ṣe ìrìbọmi fun wọn ki a bá lè yà wọ́n sí mímọ́ nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́—Wọ́n níláti rí bí Jésù ti rí pãpã. Ní ìwọ̀n ọdún 34 sí 35 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe bí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Jésù ti nrin ìrìn-àjò kiri tí wọ́n sì nwãsù nípa àwọn ohun tí wọn ti gbọ́ àti tí wọ́n ti rí pẹ̀lú, tí wọ́n sì ńṣe ìrìbọmi ní orúkọ Jésù, ó sì ṣe tí àwọn ọmọ-ẹ̀hìn kó ara wọn jọ tí wọ́n sì wà ní ìṣọ̀kan nínú ìgbóná àdúrà àti ãwẹ̀.

2 Jésù sì tún fi ara rẹ̀ hàn sí wọn, nítorítí wọn ngbàdúrà sí Bàbá ní orúkọ rẹ̀; Jésù sì wá, ó sì dúró lãrín wọn, ó sì wí fún wọn pé: Kíni ẹ̀yin nfẹ́ kí èmi ó fi fún yín?

3 Wọ́n sì wí fún un pé: Olúwa, àwa fẹ́ kí ìwọ ó sọ fún wa orúkọ tí àwa ó pe ìjọ yìi; nítorípé àríyànjiyàn wà lãrín àwọn ènìyàn yĩ nípa ọ̀rọ̀ yĩ.

4 Olúwa sì wí fún wọn pé: Lóotọ́, lóotọ́, ni mo wí fún yín, kíni ìdí rẹ̀ tí àwọn ènìyàn yĩ fi nráhùn tí wọ́n sì njiyàn nítorí ohun yĩ?

5 Njẹ́ wọn kòha ka ìwé-mímọ́, èyítí ó ní kí ẹ̀yin ó gba orúkọ Krístì, èyítí íṣe orúkọ mi? Nítorípé orúkọ yĩ ni a ó máa pè yín ní ọjọ́-ìkẹhìn;

6 Ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì gba orúkọ mi, tí ó sì forítì dé òpin, ohun kannã ni a ó gbàlà ní ọjọ́-ìkẹhìn.

7 Nítorínã, ohunkóhun tí ẹ̀yin ó bá ṣe, kí ẹ̀yin ó ṣeé ní orúkọ mi; nítorínã ni ẹ̀yin ó pe ìjọ nã ní orúkọ mi; ẹ̀yin ó sì ké pe Bàbá ní orúkọ mi, kí ó lè súre fún ìjọ nã nítorí mi.

8 Báwo ni yíò sì ṣe jẹ́ ìjọ mi bí a kò bá pẽ ní orúkọ mi? Nítorípé bí a bá pe ìjọ kan ní orúkọ Mósè, ìjọ Mósè ni íṣe nígbànã; tàbí bí a bá pẽ ní orúkọ ẹnìkan, ìjọ ẹnìkan ni íṣe nígbànã; ṣùgbọ́n bí a bá pẽ ní orúkọ mi, ìjọ mi ni íṣe nígbànã, bí ó bá jẹ́ wípé orí ìhìn-rere mi ni a kọ́ wọn lé.

9 Lóotọ́ ni mo wí fún yín, pé orí ìhìn-rere mi ni a kọ́ yín lé; nítorínã ni ẹ̀yin ó fún ohunkóhun tí ẹ̀yin yíò fún ní orúkọ, ní orúkọ mi; nítorínã bí ẹ̀yin bá ké pe Bàbá, fún ìjọ nã, bí o bá ṣe ní orúkọ mi, Bàbá yíò gbọ́ yín;

10 Bí ó bá sì jẹ́ wípé a kọ́ ìjọ nã lé orí ìhìn-rere mi, nígbànã ni Bàbá yíò fi àwọn iṣẹ́ ara rẹ̀ hàn nínú rẹ̀.

11 Ṣùgbọ́n bí a kò bá kọ́ ọ lé orí ìhìn-rere mi, tí a sì kọ́ọ lé orí iṣẹ́ ènìyàn, tàbí lé orí iṣẹ́ èṣù, lóotọ́ ni mo wí fún yín, wọn ó ní ayọ̀ nínú iṣẹ́ wọn fún ìgbà díẹ̀, láìpẹ́ ọjọ́ ni òpin yíò dé, tí a ó ké wọn lulẹ̀ kí a sì sọ wọ́n sínú iná, láti inú èyítí kò sí ìpadàbọ̀.

12 Nítorípé iṣẹ́ wọn ntọ̀ wọ́n lẹ́hìn, nítorítí a ó ké wọn lulẹ̀ nítorí iṣẹ́ wọn; nítorínã kí ẹ̀yin ó rántí àwọn ohun tí èmi ti sọ fún yín.

13 Ẹ kíyèsĩ èmi ti fi ìhìn-rere mi fún yín, èyí sì ni ìhìn-rere èyítí èmi ti fi fún yín—pé mo wá sínú ayé láti ṣe ìfẹ́ Bàbá mi, nítorípé Bàbá mi ni ó rán mi.

14 Bàbá mi sì rán mi kí a lè gbé mi sókè sí órí àgbélèbú; lẹ́hìn tí a sì ti gbé mi sókè sí órí àgbélèbú, kí èmi ó lè fà gbogbo ènìyàn wá sí ọ̀dọ̀ mi, pé gẹ́gẹ́bí ènìyàn ti gbé mi sókè bẹ̃ nã ni Bàbá yíò gbé ènìyàn sókè, láti dúró níwájú mi, láti gba ìdájọ́ iṣẹ́ wọn, bóyá rere ni wọ́n, tàbí bóyá búburú ni wọn—

15 Àti nítọrínã ni a fi gbé mi sókè; nítorínã nípa agbara Bàbá ni èmi yíò fá gbogbo ènìyàn wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí a lè dá wọn lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ wọn.

16 Yíò sì ṣe, pé ẹnìkẹ́ni tí ó bá ronúpìwàdà tí a sì se ìrìbọmi fun ní orúkọ mi, òun ni yíò kún fún Ẹ̀mí Mímọ́; bí ó bá sì forítì dé òpin, ẹ kíyèsĩ, òun ni èmi yíò kà kún aláìjẹ̀bi níwájú Bàbá mi ní ọjọ́ nã nígbàtí èmi yíò dúró ní ìdájọ́ lórí ayé.

17 Ẹnití kò bá sì forítì dé òpin òun kannã ni ẹnití a ó ké lulẹ̀ pẹ̀lú, àti tí a ó sọ ọ́ sínú iná, nínú ibití wọn kò lè padà bọ́ mọ́, nítorí àìṣègbè Bàbá.

18 Èyí sì ni ọ̀rọ̀ nã tí ó ti fi fún àwọn ọmọ ènìyàn. Àti nítorí ìdí yĩ ni ó fi mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó ti fi fún ni ṣẹ, òun kò sì purọ́, ṣùgbọ́n ó mú gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ.

19 Kò sì sí ohun àìmọ́ kan tí ó lè wọ inú ìjọba rẹ̀; nítorínã ni kò sì sí ohunkóhun tí ó wọ inú ìsinmi rẹ̀ bíkòṣe àwọn tí ó ti fọ aṣọ wọn nínú ẹ̀jẹ̀ mi, nítorí ìgbàgbọ́ wọn, àti ìronúpìwàdà lórí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn, àti òtítọ́ wọn títí dé òpin.

20 Nísisìyí èyí ni àṣẹ nã: Ẹ ronúpìwàdà, gbogbo ẹ̀yin ìkangun ayé, ẹ sì wá sí ọ̀dọ̀ mi kí ẹ sì ṣe ìrìbọmi ní orúkọ mi, kí ẹ̀yin ó di mímọ́ nípa gbígba Ẹ̀mí Mímọ́, kí ẹ̀yin ó lè dúró ní àìlábàwọ́n níwájú mi, ní ọjọ́ ìkẹhìn.

21 Lóotọ́, lóotọ́, ni mo wí fún yín, èyí ni ìhìn-rere mi; ẹ̀yin sì mọ́ àwọn ohun tí ẹ̀yin níláti ṣe nínú ìjọ mi; nítorípé àwọn iṣẹ́ tí ẹ̀yin ti rí tí èmi ṣe, òun ni kí ẹ̀yin ó máa ṣe pẹ̀lú; nítorípé ohun tí ẹ̀yin ti rí tí èmi ṣe òun pãpã ni kí ẹ̀yin ó ṣe;

22 Nítorínã, bí ẹ̀yin bá ṣe àwọn ohun wọ̀nyí alábùkún ni ẹ̀yin íṣe, nítorípé a ó gbé yín sókè ní ọjọ́ ìkẹhìn.

23 Ẹ kọ àwọn ohun tí ẹ̀yin ti rí àti tí ẹ̀yin ti gbọ́ sílẹ̀, àfi àwọn tí a dáa yín lẹ́kun rẹ̀ ní kíkọ.

24 Ẹ kọ àwọn iṣẹ́ àwọn ènìyàn yĩ sílẹ̀, tí yíò sì rí bẹ̃, gẹ́gẹ́bí a ti kọọ́, nípa èyítí ó ti wà tẹ́lẹ̀rí.

25 Nítorí ẹ kíyèsĩ, láti inú àwọn ìwé tí a ti kọ, àti èyítí a ó kọ, ni a ó ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn yĩ, nítorí nípa wọn ni àwọn ìṣe wọn yíò di mímọ̀ sí ènìyàn.

26 Ẹ sì kíyèsĩ, nípasẹ̀ Bàbá ni a kọ ohun gbogbo; nítorínã láti inú àwọn ìwé tí a ó kọ ni a ó ṣe ìdájọ́ ayé.

27 Kí ẹ̀yin kí ó sì mọ̀ pé ẹ̀yin ni onidajọ àwọn ènìyàn yĩ, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìdájọ́ tí èmi yíò fi fún yín, èyítí ó tọ́. Nítorínã, irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ̀yin ó jẹ́? Lóotọ́ ni mo wí fún yín, àní gẹ́gẹ́ bí mo ti rí.

28 Àti nísisìyí èmi ó lọ sí ọ̀dọ̀ Bàbá mi. Àti lõtọ́ ni mo wí fún yín, ohunkóhun tí ẹ̀yin yíò bẽrè lọ́wọ́ Bàbá ní orúkọ mi, a ó fi fún yín.

29 Nítorínã, ẹ bẽrè, ẹ ó sì rí gbà; ẹ kànkùn, a ó sì ṣíi sílẹ̀ fún yín; nítorípé ẹnìkẹ́ni tí ó bá bẽrè, yíò rí gbà; ẹnití ó bá sì kànkùn ni a ó ṣíi fún.

30 Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, ayọ̀ mi pọ̀, àní tí ó kún, nítorí yín, àti ìran yĩ; bẹ̃ni, Bàbá pẹ̀lú nyọ̀, àti gbogbo àwọn ángẹ́lì mímọ́ pẹ̀lú, nítorí yín àti ìran yĩ; nítorípé kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó sọnù.

31 Ẹ kíyèsĩ, mo fẹ́ kí ó yé yín; nítorípé àwọn tí èmi nsọ nípa wọn ni àwọn tí ó sì wà lãyé nínú ìran yĩ; kò sì sí ọ̀kan nínú wọn tí ó sọnù; nínú wọn sì ni èmi ní ẹ̀kún ayọ̀.

32 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, mo ní ìrora-ọkàn nítorí ìran ẹ̀kẹ́rin sí ìran yĩ, nítorítí ó mú wọn ní ìgbèkùn, àní gẹ́gẹ́bí ó ti mú ọmọ-ègbé nnì; nítorítí wọn yíò tà mí nítorí fàdákà àti wúrà, àti nítorí èyítí kòkòrò yíò bàjẹ́ àti tí àwọn olè lè wọlé kí wọn ó jalè. Ní ọjọ́ nã ni èmi ó sì bẹ̀ wọ́n wò, àní ní dídá iṣẹ́ ọwọ́ wọn lé orí ara wọn.

33 Ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti parí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ pé: Ẹ bá ẹnu-ọ̀nà híhá wọlé; nítorí híhá ni ẹnu-ọ̀nà nã, tõró sì ni ojú-ọ̀nà nã èyítí ó lọ sí ti ìyè, díẹ̀ sì ni àwọn ẹnití nríi; ṣùgbọ́n gbõrò ni ojú-ọ̀nà nã èyítí ó lọ sí ti ikú, púpọ̀ sì ni àwọn tí nrìn lójú ọ̀nà nã, tí òru sì dé nínú èyítí ẹnìkan kò lè ṣiṣẹ́.