Àwọn Ìwé Mímọ́
3 Nífáì 2


Orí 2

Ìwà búburú àti àwọn ohun ìríra npọ̀ síi lãrín àwọn ènìyàn nã—Àwọn ará Nífáì àti àwọn ará Lámánì darapọ̀ láti dãbò bò ara nwọn lọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà Gádíátónì—Àwọn ará Lámánì tí a ti yí lọ́kàn padà di afúnláwọ̀ a sì npè wọ́n ní ará Nífáì. Ní ìwọ̀n ọdún 5 sí 16 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe ní báyĩ tí ọdún karundinlọgọrun kọjá pẹ̀lú, tí àwọn ènìyàn nã sì bẹ̀rẹ̀sí gbàgbé àwọn àmì àti ohun ìyanu èyítí nwọn ti gbọ́ nípa nwọn, tí àdínkù sì nwà síi nínú ìyàlẹ́nu nípa ohun àmì tàbí ohun ìyanu láti ọ̀run wá, tóbẹ̃ tí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí le nínú ọkàn nwọn, àti tí nwọ́n sì fọ́jú nínú ẹ̀mí nwọn, tí nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí ṣe áláìgbàgbọ́ àwọn ohun wọ̀nyí èyítí nwọn ti gbọ́ àti tí nwọn ti rí—

2 Tí nwọ́n sì ngbèrò ohun asán nínú ọkàn wọn, wípé àwọn ènìyàn ni ó ṣe nwọ́n nípa agbára èṣù, láti ṣì nwọ́n lọ́nà àti láti tàn ọkàn àwọn ènìyàn nã; báyĩ sì ni Sátánì tún gba ọkàn àwọn ènìyàn nã ní ìní, tóbẹ̃ tí ó fọ́ nwọ́n lójú tí ó sì ṣì wọ́n lọ́nà láti gbàgbọ́ pé ẹ̀kọ́ Krístì jẹ́ ohun aṣiwèrè àti ohun asán.

3 Ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn nã bẹ̀rẹ̀sí lágbára síi nínú ìwà búburú àti àwọn ohun ìríra; tí nwọn ko sì gbàgbọ́ pé a fún nwọn ní àwọn àmì àti ohun ìyanu síi; tí Sátánì sì nlọ kiri, tí ó nmú ọkàn àwọn ènìyàn nã ṣìnà, tí ó ndán wọn wò, àti tí ó nmú kí nwọn ó hùwà búburú nlá lórí ilẹ̀ nã.

4 Báyĩ sì ni ọdún kẹrindinlọgọrun kọjá; àti ọdún kẹtàdínlọ́gọ̀rún; àti ọdún kejìdínlọ́gọ̀rún pẹ̀lú; àti ọdún kọkàndínlọ́gọ̀rún;

5 Àti ọgọ́rún ọdún pẹ̀lú ni ó ti kọjá láti ìgbà Mòsíà, ẹnití íṣe ọba lórí àwọn ènìyàn ará Nífáì ní àkokò kan rí.

6 Ẹgbẹ̀ta ọdún àti mẹ́sán sì ti kọjá lẹ́hìn tí Léhì ti jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù.

7 Ọdún mẹ́sán sì ti kọjá láti ìgbà tí a ti fún nwọn ní àmì nã, èyítí àwọn wòlĩ ti sọ nípa rẹ̀, pé Krístì yíò wá sínú ayé.

8 Nísisìyí àwọn ará Nífáì bẹ̀rẹ̀sí ṣírò ọjọ́ nwọn láti ìgbà yĩ tí a ti fún nwọn ní àmì nã, tàbí láti ìgbà tí Krístì ti dé; nítorínã, ọdún mẹ́sán ti kọjá.

9 Nífáì, ẹnití íṣe bàbá Nífáì, ẹnití ó ni àwọn àkọsílẹ̀ nã ní ìtọ́jú, kò sì padà sí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, a kò sì ríi mọ́ níbikíbi ní gbogbo ilẹ̀ nã.

10 Ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn nã sì dúró nínú ipò ìwà búburú síbẹ̀, l’áìṣírò ìkàsí fún ìwãsù àti ìsọtẹ́lẹ̀ tí ó pọ̀ èyítí a fi ránṣẹ́ lãrín nwọn; báyĩ sì ni ọdún kẹẹ̀wá kọjá pẹ̀lú; ọdún kọkànlá nã sì kọjá pẹ̀lú nínú ipò àìṣedẽdé.

11 Ó sì ṣe ní ọdún kẹtàlá tí àwọn ogun àti ìjà bẹ̀rẹ̀sí wà jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ nã; nítorítí àwọn ọlọ́ṣà Gàdíátónì ti pọ̀ púpọ̀, tí nwọ́n sì pa púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn nã, tí nwọ́n sì run ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú-nlá, tí nwọ́n sì tan ọ̀pọ̀lọpọ̀ ikú àti ìpakúpa ènìyàn jákè-jádò ilẹ̀ nã, tí ó fi di èyítí ó tọ́ kí gbogbo àwọn ènìyàn nã, àti àwọn ará Nífáì àti àwọn ará Lámánì, kí nwọn ó gbé ohun ìjà-ogun láti dojú kọ nwọn.

12 Nítorí nã, gbogbo àwọn ará Lámánì tí nwọ́n ti di ẹnití a yí lọ́kàn padà sí ọ́dọ̀ Olúwa sì darapọ̀ mọ́ àwọn arákùnrin nwọn, àwọn ará Nífáì, nwọ́n sì níláti gbé ohun ìjà-ogun kọlũ àwọn ọlọ́ṣà Gádíátónì nnì, fún ìdãbò bò ẹ̀mí nwọn àti àwọn obirin nwọn àti àwọn ọmọ nwọ́n, bẹ̃ni, àti láti di ẹ̀tọ́ nwọn mú, àti àwọn ànfàní ìjọ nwọn àti ti ìjọsìn nwọn, àti ominira nwọn àti ìdásílẹ̀ nwọn.

13 Ó sì ṣe, kí ọdún kẹtàlá yĩ ó tó kọjá, a dẹ́rùba àwọn ará Nífáì pẹ̀lú ìparun pátápátá nitorí ogun yĩ, èyítí ó ti di kíkan jùlọ.

14 Ó sì ṣe tí a ka àwọn ará Lámánì nnì tí nwọ́n ti darapọ̀ mọ́ àwọn ará Nífáì;

15 A sì mú ègún kúrò lórí nwọn, tí àwọ̀ ara nwọn sì di funfun gẹ́gẹ́bí ti àwọn ará Nífáì;

16 Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin nwọn sì lẹ́wà púpọ̀púpọ̀, a sì kà nwọ́n mọ́ àwọn ará Nífáì, a sì pè nwọ́n ní ará Nífáì. Báyĩ sì ni ọdún kẹtàlá parí.

17 Ó sì ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kẹrìnlá, ogun èyítí ó wà lãrín àwọn ọlọ́ṣà nã àti àwọn ènìyàn Nífáì sì tẹ̀síwájú tí ó sì di kíkan lọ́pọ̀lọpọ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃, àwọn ènìyàn Nífáì borí àwọn ọlọ́ṣà nã, tóbẹ̃ tí nwọ́n lé nwọn padà jáde kúrò lórí ilẹ̀ nwọn lọ sínú àwọn òkè gíga àti lọ sínú àwọn ibi ìkọ̀kọ̀ nwọn.

18 Báyĩ sì ni ọdún kẹrìnlá nã parí. Ní ọdún kẹẹ̀dõgún ni nwọ́n sì jáde kọlũ àwọn ènìyàn Nífáì; àti nitori ìwà búburú àwọn ènìyàn Nífáì, àti àwọn ìjà àti ìyapa nwọn tí ó pọ̀, àwọn ọlọ́ṣà Gádíátónì nã sì borí nwọn lọ́pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà.

19 Báyĩ sì ni ọdún kẹẹ̀dógún parí, báyĩ sì ni àwọn ènìyàn nã wà ní ipò ìpọ́njú tí ó pọ̀; tí idà ìparun sì gbé sókè sí nwọn, tóbẹ̃ tí ó ti fẹ́rẹ̀ ké nwọn lulẹ̀, ó sì rí bẹ̃ nítorí ìwà àìṣedẽdé nwọn.