Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Àjàgà Rẹ̀ Rọrùn Ẹrù Rẹ̀ sì Fúyẹ́
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2022


Àjàgà Rẹ̀ Rọrùn Ẹrù Rẹ̀ sì Fúyẹ́

Ẹ jẹ́kí a rántí pé ènìyàn kọ̀ọ̀kan órí ilẹ̀ ayé yí ni ọmọ Ọlọ́run Òun sì fẹ́ràn ẹnìkọ̀ọ̀kan.

A sọ ìtàn nípa ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Jack tí ó ní olùfẹ́ ajá ọdẹ-ẹyẹ kan tí ó njẹ Cassie. Jack ní ìwúrí púpọ̀ nípa Cassie ó sì máa nfi ìgbà gbogbo fọ́nu nípa bí ó ti jẹ́ ajá tó mọṣẹ́ tó. Láti fi ìdí èyí múlẹ̀, Jack pe àwọn ọ̀rẹ́ díẹ̀ láti wo Cassie lójú iṣẹ́. Lẹ́hìn tí wọ́n dé sí ibi ẹgbẹ́ ọdẹ, Jack fi Cassie sílẹ̀ láti sáré kiri nígbàtí òun wọlé lọ láti ṣètò ìgbàwọlé.

Nígbàtí àkókò tó láti bẹ̀rẹ̀, inú Jack ndùn láti fi àwọn ìmọṣẹ́ yíyanilẹ́nu Cassie yangàn, Ṣùgbọ́n, Cassie nṣe ìṣe àjèjì. Kò gbọ́ràn sí àṣẹ Jack kankan bí ó ti máa nṣe tẹ́lẹ̀ fúnra rẹ̀. Gbogbo ohun tó fẹ́ ṣe ni kí ó kàn wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.

Jack ní ìdààmú àti ojútì àti ìbínú pẹ̀lú Cassie; láìpẹ́ ó dábàá pé kí wọn ó kúrò. Cassie kò tilẹ̀ fò sí ẹ̀hìn ọkọ̀ náà, nítorínáà Jack fi àìnísùúrù gbé e ó sì jù ú sí inú ilé rẹ̀. Ó bínú bí àwọn tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ ti fi ìwà ajá rẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́ ní gbogbo irìn wọn sílé. Jack kò le ní òye ìdí tí Cassie fi nhùwà òdì. A ti kọ́ ọ dáradára, àti pé gbogbo ohun tí ó máa nfẹ́ tẹ́lẹ̀ ni láti tẹ́ ẹ lọ́rùn kí ó sì ṣiṣẹ́ fún un.

Lẹ́hìn tí wọ́n dé ilé, Jack bẹ̀rẹ̀ sí yẹ Cassie wò fún àwọn ìfarapa, ara wíwú, tàbí kòkòrò, bí ó ti máa nṣe. Bí ó ti fi ọwọ́ rẹ̀ sí ibi àyà rẹ̀, ó ní ìmọ̀lára ohun tútù kan ó sì ríi pé ẹ̀jẹ̀ bo ọwọ́ rẹ̀. Sí ìtìjú àti ẹ̀rù rẹ̀, ó ríi pé Cassie ní ọgbẹ́ gígùn àti fífẹ̀ kan dé ibi eegun àyà rẹ̀. Ó rí òmíràn ní ibi ẹsẹ̀ iwájú rẹ̀ ọ̀tún, dé ibi eegun bákannáà.

Jack gbé Cassie sí apá rẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún. Ìtìjú rẹ̀ nípa bí ó ti ṣi ẹjọ́ dá àti bí ó ti ṣe sí i ní agbára jù. Cassie ti nṣe lòdì sí ìhùwàsí rẹ̀ ṣaájú ní ọjọ́ náà nítorípé ó fi ara pa. Ìwà rẹ̀ ti jẹ́ ṣíṣe okùnfà nípa ìrora rẹ̀, ìjìyà rẹ̀, àti àwọn ọgbẹ́ rẹ̀. Kò ní ohunkóhun í ṣe pẹ̀lú àìní ìfẹ́ inú láti gbọ́ràn sí Jack tàbí àìní ìfẹ́ fún un.1

Mo gbọ́ ìtàn yí ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́hìn èmi kò sì tíì gbàgbé rẹ̀ rí. Àwọn ènìyàn mélòó tí wọ́n ní ọgbẹ́ ní a ní láàrin wa? Báwo ni a ti ndá àwọn ẹlòmíràn lẹ́jọ́ nígbàkugba tó nítorí ìfarahàn àti àwọn ìṣe wọn, tàbí àìsí ìṣe, nígbà tí, bí a bá ní òye ní kíkún, dípò bẹ́ẹ̀ a ó hùwà padà pẹ̀lú àánú àti ifẹ́ inú láti ṣe ìrànwọ́ dípò fífikún àwọn ẹrù wọn pẹ̀lú ìdájọ́ wa?

Mo ti jẹ̀bi èyí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ní ìgbésí ayé mi, ṣùgbọ́n Olúwa ti fi sùúrù kọ́ mi nípasẹ̀ àwọn ìrírí ti araẹni àti bí mo ti nfetísílẹ̀ sí àwọn ìrírí ayé ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Mo ti wá mọ rírì ní kíkún síi àpẹrẹ ti Olùgbàlà wa ọ̀wọ́n bí Ó ti lo púpọ̀ nínú àkókò Rẹ̀ ní ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú ìfẹ́.

Ìrírí ìgbé ayé ọmọbìnrin mi tó kéré jùlọ ti ní àwọn ìpèníjà ìlera ẹ̀dùn ọkàn nínú látìgbà tí ó ti wà ní ọmọdébìnrin kékeré. Àwọn àkókò púpọ̀ ló ti wà láàrin ìgbé ayé rẹ̀ tí ó ti ní ìmọ̀lára bíi pé òun kò le tẹ̀síwájú. A ó fi títí láé dúpẹ́ fún àwọn ángẹ́lì ti ilẹ̀ ayé tí wọ́n ti wà níbẹ̀ láàrin àwọn àkókò wọ̀nyí: ní jíjókòó pẹ̀lú rẹ̀; fífetísílẹ̀ sí i; sísọkún pẹ̀lú rẹ̀, àti ṣíṣe àbápín àwọn ẹ̀bùn àìláfiwé papọ̀ , níní òye ti ẹ̀mí, àti àjùmọ̀ṣepọ̀ ìfẹ́. Ní irú àwọn ipò ìfẹ́ni bẹ́ẹ̀, à ti gbé àwọn ẹrù àwọn ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ní gbogbo ìgbà.

Alàgbà Joseph B. Wirthlin, ní síṣe àtúnsọ 1 Kọ́rintì, sọ pé, “Bí mo tilẹ̀ nfọ onirúurú èdè ti ènìyàn àti ti àwọn ángẹ́lì, tí èmi kò sì ní ìfẹ́, èmi dàbí idẹ tó ndún, tàbí kímbálì olóhun goro.”2

Ó tẹ̀síwájú:

“Ọ̀rọ̀ Paulù sí àwọn ẹgbẹ́ titun ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ yi jẹ́ rírọrùn àti tààrà: Kò sí ohun tí ẹ lè ṣe tí ó le mú ìyàtọ̀ púpọ̀ wá bí ẹ kò bá ní ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́. Ẹ lè sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn èdè, ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀, ní òye àwọn ohun ìjìnlẹ̀, ní gbogbo ìmọ̀; àní bí ẹ tilẹ̀ ní ìgbàgbọ́ láti ṣí àwọn òkè ní ìdí, láìsí ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ kò le jẹ́ èrè fún yín rárá.

“’Ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ jẹ́ ìfẹ́ àìlábàwọ́n ti Jésù Krístì’ [Moroni 7:47]. Olùgbàlà fi àpẹrẹ ìfẹ́ náà hàn.”2

Nínú Jòhánnù a kà pé, “Nípa èyíni gbogbo ènìyàn yíò mọ̀ pé ẹ jẹ́ ọmọẹ̀hìn mi, bí ẹ bá fẹ́ràn ara yín3

Àwọn ọ̀rọ̀ púpọ̀ ni a ti fifúnni láti ẹnu àwọn olùdarí Ìjọ wa lórí ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́, ìṣọ̀kan, ìfẹ́, inú rere, ìṣàánú, ìdáríjì, àti àánú. Mo gbàgbọ́ pé Olùgbàlà npè wá láti gbé ní ọ̀nà gíga síi, mímọ́ síi4ọ̀nà ìfẹ́Rẹ̀níbi tí ẹni gbogboti le ní ìmọ̀lára pé wọ́n jẹ́ ara kan a sì nílò wọn.

A pàṣẹ fúnwa láti fẹ́ràn àwọn ẹlòmíràn,5 kìí ṣe láti dá wọn lẹ́jọ́.6 Ẹ jẹ́kí a gbé ẹrù wíwúwo náà sílẹ̀; kìí ṣe tiwa láti gbé.7 Dípò bẹ́ẹ̀, a le gbé àjàgà Olùgbàlà ti ìfẹ́ àti àánú.

“Ẹ wa sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ó nṣiṣẹ́, tí a sì di ẹrù wúwo lé lórí, èmi yíò sì fi ìsinmi fún yín.

“Ẹ gba ajàgà mi sí ọrùn yín, kí ẹ sì máa kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi; …

“Nítorí àjàgà mi rọrùn, ẹrù mi sì fúyẹ́.”9

Olùgbàlà kìí fi ara mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ṣùgbọ́n Ó nfún wa ní ìfẹ́ Rẹ̀ Ó sì nnawọ́ ìdáríjì nígbàtí a bá ronúpìwàdà. Sí arábìnrin tí a mú nínú àgbèrè, Ó sọ pé, “Bẹ́ẹ̀ni èmi kò dá ọ lẹ́bi: lọ, kí o má sì ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́.”10 Àwọn tí Ó fọwọ́kàn ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Rẹ̀, ìfẹ́ náà sì wò wọ́n sàn ó sì yí wọn padà. Ìfẹ́ Rẹ̀ nmí sí wọn láti fẹ́ láti yí ìgbé ayé wọn padà. Gbígbé ní ọ̀nà Rẹ̀ nmú ayọ̀ àti àlàáfíà wá, Òun sì pè àwọn ẹlòmíràn sí ọ̀nà ti gbígbé pẹ̀lú ìwàpẹ̀lẹ́, inú rere, àti ìfẹ́.

Alàgbà Gary E. Stevenson sọ pé, “Nígbàtí a dojúkọ afẹ́fẹ́ àti ìjì-òjò, àìsàn àti àwọn ìpalára ayé, Olúwa—Olùṣọ́-àgùtàn wa, Olùtọ́jú wa—yíò ṣìkẹ̀ wa pẹ̀lú ìfẹ́ àti inúrere. Òun yíò wo ọkàn wa sàn yíò sì mú ẹmí wa padàbọ̀sípò.”10 Àwa bíi atẹ̀lé Jésù Krístì, njẹ́ kò yẹ kí a ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́?

Olùgbàlà sọ fúnwa láti kọ́ ẹ̀kọ́ ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀11kí a sì ṣe àwọn ohun tí a ti rí I tí ó ṣe.12 Òun ni àpẹrẹ ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́, ti ìfẹ́ àìlábàwọ́n. Bí a ti nkọ́ láti ṣe ohun tí ó sọ fúnwa ní kíkún—kìí ṣe nítorí ojúṣe tàbí fún àwọn ìbùkún tí a le gbà pàápàá ṣùgbọ́n dájú nítorí ìfẹ́ wa fún Òun àti Baba wa Ọ̀run13—ìfẹ́ Rẹ̀ yío ṣàn nípasẹ̀ wa yío sì mú ohun gbogbo tí Ó béèrè ṣeéṣe nìkan kọ́, ṣùgbọ́n yío rọrùn yío sì fúyẹ́ síi ní ìgbẹ̀hìn14 yío sì kún fún ayọ̀ ju bí a ti le fi inú rò láe. Yío gba àṣetúnṣe; ó le gba àwọn ọdún, bí ó ti rí fún mi, ṣùgbọ́n bí a tilẹ̀ ti nfẹ́ láti fi ìfẹ́ ṣe agbára ìwúrí wa, Ó le gba ìfẹ́ náà,15 èso náà, àti nígbẹ̀hìn kí Ó sọ ọ́ di igi arẹ̀wa kan, tí ó kún fún èso dídùn jùlọ.16

A nkọ nínú ìwé orin ìsìn wa ọ̀wọ́n, “Tani èmi láti dá ẹlòmíràn lẹ́jọ́ nígbàtí mo nrìn láìpé? Nínú ọkàn jẹ́jẹ́ ní ìbànújẹ́ tí ojú kò le rí pamọ́ sí.”17 Tani nínú wa tí ó le ní àwọn ìbànújẹ́ tí ó pamọ́? Ọdọ́ kékeré tí ó dàbí olóríkunkun, àwọn ọmọ ìgbéyàwó tó ti dàrú, àdánìkanwà ìyá tàbí bàbá, àwọn wọnnì pẹ̀lú ìpèníjà ìlera àfojúrí tàbí ti ọpọlọ, àwọn tí wọ́n ní ìbéèrè nípa ìgbàgbọ́ wọn, àwọn arúgbó, àwọn ẹ̀ka ẹlẹ́yàmẹyà, àwọn tí wọ́n nní ìmọ̀lára ànìkanwà, àwọn tí wọ́n fẹ́ ṣe ìgbéyàwó, àwọn pẹ̀lú ìwà bárakú tí wọn ò fẹ́, áti àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ míràn tí wọn nṣiṣẹ́ pẹ̀lú oríṣiríṣi àwọn ìrírí ayé tí ó npeni níjà—ní ọ̀pọ̀ ìgbà àní áwọn wọnnì tí ìgbé ayé wọn farahàn bí pípé ní ojú ayé.

Kò sí ọ̀kankan nínú wa tó ní ìgbé ayé pípé tàbí ẹbí pípé; dájúdájú èmi kò ní. Nígbàtí a bá lépa láti kẹ́dùn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n nní ìrírí àwọn ìpèníjà àti àwọn àìpé bákannáà , ó le ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára pé àwọn kò dá nìkan wà nínú àwọn ìlàkàkà wọn . Gbogbo ènìyàn nílò láti ní ìmọ̀lára pé nítõtọ́ wọ́n pẹ̀lú nítòótọ́ àti pé a nílò wọ́n nínú ẹgbẹ́ ti Krístì.18 Ìfẹ́ inú nlá ti Sátánì ni láti pín àwọn ọmọ Ọlọ́run níyà, ó sì ti nṣe àṣeyọrí gidi, ṣùgbọ́n agbára nlá wà nínú ìṣọkan.19 Bí a ti nílò tó láti rìn nínú apá sí apá pẹ̀lú ara wa ní ìrìn àjò tí ó npeni níjà ti ayé kíkú yi!

Wòlíì wa, Ààrẹ Russell M. Nelson, sọ pé, “Ẹ̀yíkéyi ilòkulòtàbí ẹtanúsí ẹlòmíràn nítorí orílẹ̀ ẹ̀dẹ̀, àwọ̀, ohun tí a mọ̀ nípa ìbálòpọ̀, ẹ̀yà, àwọn oyè ẹ̀kọ́, àṣà, tàbí àwọn ìfidánimọ̀ pàtàkì míràn jẹ́ ìwà ìbàjẹ́ sí Ẹlẹ́dã wa. Irú ìwà àìdára bẹ́ẹ̀ máa nmú wa gbé ní kíkéré sí ìwọ̀n wa bíi ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin májẹ̀mú Rẹ̀!”20

Nígbàtí Ààrẹ Nelson ti pe ẹni gbogbo láti bọ́ sí kí a sì dúró sí ipa ọ̀nà májẹ̀mú tí ó ndarí padà sí ọ̀dọ̀ Olùgbàlà wa àti Baba wa ní Ọ̀run, bákannáà ó pèsè ìmọ̀ràn tó tẹ̀lé èyi: “Bí àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí … ti gbẹ́sẹ̀ kúrò nínú Ìjọ, ẹ tẹ̀síwájú láti máa fẹ́ràn wọn. Kìí ṣe fún yín láti ṣe ìdájọ́ yíyàn ti ẹlòmíràn ju bí ó ti yẹ kí a takò yín fún dídúró bíi olõtọ́.”21

Ẹyin ọ̀rẹ́, ẹ jẹ́ká rántí pé ẹnìkọ̀ọ̀kan lórí ilẹ̀ ayé jẹ́ ọmọ Ọlọ́run22Ó sì fẹ́ràn olukúlùkù wa.23 Njẹ́ àwọn ènìyàn kan wà ní ipa ọ̀nà yíntí ẹ ti ní ìmọ̀lára láti dá lẹ́jọ́? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ rántí pé ìwọ̀nyí ni àwọn ànfàní fúnwa láti ṣe àṣetúnṣefífẹ́ràn bí Olùgbàlà ti fẹ́ràn.24 Bí a ti ntẹ̀lé àpẹrẹ Rẹ̀, a le jẹ́ dídàpọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀ kí a sì ṣe ìrànlọ́wọ́ dúró fún ìmọ̀lára ìfẹ́ àti wíwà pẹ̀lú nínú ọkàn gbogbo àwọn ọmọ Baba wa.

“A fẹ́ràn rẹ̀, nítorí òun ló kọ́kọ́ fẹ́ràn wa.”26 Nígbàtí a bá kún fún ìfẹ́ Olùgbàlà, àjàgà Rẹ̀ nítòótọ́ le rọrùn, ẹrù Rẹ̀ sì le dàbí pé ó fúyẹ́.27 Nípa èyí ni mo jẹ́ ẹ̀rí ni orúkọ Jésù Krístì, àmín.