Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Iṣẹ́ Ìríjú Wa ti Ilẹ̀ Ayé
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2022


Iṣẹ́ Ìríjú Wa ti Ilẹ̀ Ayé

Mo jẹ́ ẹ̀rí pé àwọn ìbùkún nlá ti ẹ̀mí ní a ṣèlérí fún àwọn tí wọ́n fẹ́ràn tí wọ́n sì nṣe ìtọ́jú fún ilẹ̀ ayé àti àwọn akẹgbẹ́ wọn lọ́kùnrin àti lóbìnrin.

Nígbàtí a nṣe àbẹ̀wò sí orílẹ̀ ìbí wa ni France, ìyàwó mi àti èmi ní àìpẹ́ yí ní ìdùnnú ti mímú díẹ̀ lára àwọn ọmọ-ọmọ wa láti lọ wo ọgbà títóbi kan tí ó wà ní ìlú kékeré ti Giverny. A gbádùn rírìnkiri ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀ láti wo àwọn arẹwà òdòdó, àwọn ẹyẹ ojú omi dáradára, àti ṣíṣeré díẹ̀ ní ibi àwọn adágún.

Àwòrán
Ọgbà Giverny

Ibi yíyanilẹ́nu yi jẹ́ àbájáde ìṣẹ̀dá àtinúwá ti ọkùnrin kan: akọ̀dà nlá Claude Monet, ẹnití, fún ogójì ọdún, fi tìfẹ́tìfẹ́ ṣe ẹ̀dá tí ó sì mú ọgbà rẹ̀ dàgbà láti fi ṣe ààyè ibi iṣẹ́ ọ̀dà kíkùn rẹ̀. Monet ri ara rẹ̀ sínú ọlánlá ti àdánidá; nígbànáà, pẹ̀lú búrọ́ṣì ìkùn-ọ̀dà rẹ̀, /o ngbé àwọn ìṣílétí tí ó ti ní ìmọ̀lára rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìlà àwọ̀ àti ìmọ́lẹ̀. Bí ọdún ṣe nkọjá lọ, ó ti ṣe akójọ ọgọgọ́rũn àwọn ọ̀dà kíkùn tí kò wọ́pọ̀, tí ìmísí wọn wá tààrà nípasẹ̀ ọgbà rẹ̀.

Àwòrán
Kíkùn Monet ti Ọgbà

Omi àwọn Òdòdó àti Afár áàwọn Japan, 1899, nípasẹ̀ Claude Monet

Ẹyin arákùnrin àti ẹ̀yín arábìnrin, ajọṣepọ̀ wa pẹ̀lú àwọn ẹwà ti àdánidá ní ayíyá le pèsè díẹ̀ lára àwọn ìrírí dídùnmọ́ni tí ó jẹ́ onímisí jùlọ nínú ayé. Àwọn ẹ̀dùn ọkàn tí a nní ìmọ̀lára rẹ̀ nmú iná èrò ìjìnlẹ̀ ti ìmoore wá nínú wa fún Baba wa Ọ̀run àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, ẹnití ó dá ilẹ̀ ayé títóbi yi—pẹ̀lú àwọn òkè àti ìṣàn omi, àwọn ewéko àti àwọn ẹranko rẹ̀—àti àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Adámù àti Éfà.1

Iṣẹ́ Ìṣẹ̀dá kìí ṣe òpin nínú ara rẹ̀. Ó jẹ́ ara ètò Ọlọ̀run fún àwọn ọmọ Rẹ̀. Èrèdí rẹ̀ ni láti pèsè àgbékalẹ̀ nínú èyítí ọkùnrin àti obìnrin le jẹ́ dídánwò, lo òmìnira wọn láti yàn, rí ayọ̀, kí wọn ó sì kọ́ ẹ̀kọ́ kí wọn ó sì tẹ̀síwájú, kí wọn ó le padà lọ́jọ́ kan sí ọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dã wọn kí wọn ó sì jogún ìyè ayérayé.

Àwọn ìṣẹ̀dá ìyanu wọ̀nyí ni a pèsè pátápátá fún ànfààní wa wọ́n sì jẹ́ ẹ̀rí alààyè nípa ìfẹ́ tí Ẹlẹ́dã ní fún àwọn ọmẹ Rẹ̀ Olúwa kéde pé, “Bẹ́ẹ̀ni, gbogbo ohun tí ó jáde láti inú ilẹ̀ … ni a dá fún ànfàní àti fún ìlò ènìyàn láti fún ojú ní ìdùnnú àti ọkàn ní ayọ̀.”2

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ẹ̀bùn àtọ̀runwá ti Ìṣẹ̀dá kìí wá láìsí àwọn iṣẹ́ àti àwọn ojúṣe. Àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí ni a le ṣe àpèjúwe wọn dárajùlọ nípa èrò inú ti iṣẹ́ ìríjú. Ní àwọn èdè ìhìnrere, ọ̀rọ̀ náà iṣẹ́ ìríjú tọ́ka sí ojúṣe mímọ́ ti ẹ̀mí tàbí ti ara láti mojútó ohun kan tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run, fún èyítí a ó jíhìn.3

Bí a ti kọ́ni nínú àwọn ìwé mímọ́, iṣẹ́ ìríjú wa ti ilẹ̀ ayé ní àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ wọ̀nyí nínú:

Ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ kinní: Gbogbo ilẹ̀ ayé, pẹ̀lú gbogbo ohun abẹ̀mí tí ó wà níbẹ̀, jẹ́ ti Ọlọ́run.

Ẹlẹ́dã ti fi àwọn ohun èlò ti ilẹ̀ ayé àti onírúurú abẹ̀mí gbogbo sí abẹ́ ìtọ̀jú wa, ṣùgbọ́n Òun ló ni wọ́n ní kíkún. Ó sọ pé, “Èmi, Olúwa, na àwọn ọ̀run jáde, mo sì dá ilẹ̀ ayé, iṣẹ́ ọwọ́ mi gan; ohun gbogbo tó sì wà nínú rẹ̀ jẹ́ tèmi.”4 Ohun gbogbo tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé jẹ́ ti Ọlọ́run, pẹ̀lú àwọn ẹbí wa, àwọn àgọ́ ara wa, àti ayé wa gan paapaa.5

Ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ kejì: Bíi ìríjú àwọn ìṣẹ̀dá ti Ọlọ́run, a ní iṣẹ́ láti bu ọlá fún kí a sì ṣe ìtọ́jú wọn.

Àwa bíi ọmọ Ọlọ́run, a ti gba àṣẹ láti jẹ́ ìríjú, alámojútó, àti alágbàtọ́ fún àwọn ìṣẹ̀dá àtọ̀runwá Rẹ̀. Olúwa sọ pé Òun mú “gbogbo ènìyàn jíhìn, bíi ìríjú kan lórí àwọn ìbùkún ilẹ̀ ayé, èyítí èmi ti dá tí mo sì pèsè fún àwọn ẹ̀dá mi.”6

Baba wa Ọ̀run fúnwa ní ààyè láti lo àwọn ohun èlò ilẹ̀ ayé ní ìbámu sí òmìnira ifẹ́ inú wa. Síbẹ̀ òmìnira wa láti yàn kò gbọdọ̀ túmọ̀ sí láti lò tàbí jẹ àwọn ọrọ̀ ayé yí láìsí ọgbọ́n tàbí ìjánu. Olúwa fi ìgbaniníyànjú yí fúnni: Ó sì dùn mọ́ Ọlọ́run nínú pé òun ti fi gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí fún ènìyàn; nítorí fún ìdí èyí ni a ṣe dá wọn láti jẹ́ lílò, pẹ̀lú ìdájọ́, kìí ṣe ní àpọ̀jù, tàbí nípa ìrẹ́jẹ.”7

Ààrẹ Russell M. Nelson sọ nígbàkan pé: “Bíi olùjẹ-ànfàní Ìṣẹ̀dá àtọ̀runwá, kínni a níláti ṣe? A níláti ṣe ìtọ́jú fún ilẹ̀ ayé, kí á jẹ́ ọlọgbọ́n ìríjú lórí rẹ̀, kí a sì pa mọ́ fún àwọn ìran ọjọ́ iwájú.”8

Tayọ pé ó kàn jẹ́ dandan lábẹ́ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹ́nsì tàbí ti ìṣèlú, ìtọ́jú ilẹ̀ ayé àti ti àyíká àdánidá wa jẹ́ ojúṣe mímọ́ tí Ọlọ́run gbé léwa lọ́wọ́, èyítí ó yẹ kí ó kún inú wa pẹ̀lú èrò jíjinlẹ̀ ti ojúṣe àti ìrẹ̀lẹ̀. Bákannáà ó jẹ́ apákan pàtàkì ti pé a jẹ́ ọmọlẹ́hìn. Báwo ni a ṣe le bu ọlá fún kí a sì fẹ́ràn Bàbá Ọ̀run àti Jésù Krístì láìsí bíbu ọlá fún àti fífẹ́ràn àwọn ìṣẹ̀dá Wọn?

Àwọn ohun púpọ̀ wà tí a fi lè ṣe—lápapọ̀ àti bí ẹnìkọ̀ọ̀kan—láti jẹ́ ìríjú rere. Ní gbígbèrò ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ipò wa, olukúlùkù wa le lo ọ̀pọ̀ àwọn ohun èlò ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ọ̀wọ̀ àti ìṣọ́wóná síi. A le ti àwọn aápọn agbègbè lẹ́hìn láti ṣe ìtọ́jú fún ilẹ̀ ayé. A le ṣe àgbàlò irú ìgbé ayé àti àwọn ìhùwàsí ti ara-ẹni kan tí ó bọ̀wọ̀ fún àwọn ìṣẹ̀dá Ọlọ́run àti tí ó mú àwọn àlàfo ìgbé ayé tiwa létò síi, rẹwà síi, àti ní ìmísí síi.9

Nínú iṣẹ́ ìríjú wa lórí àwọn ìṣẹ̀dá Ọlọ́run bákannáà ni, ní ibi gíga jùlọ rẹ̀, ojúṣe mímọ́ kan láti fẹ́ràn, tẹríba, kí a sì ṣe ìtọ́jú fún gbogbo ẹ̀dá ènìyàn pẹ̀lú àwọn ẹni tí a jọ npín ilẹ̀ ayé. Wọ́n jẹ́ ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Ọlọ́run, àwọn arábìnrin wa àti arákùnrin wa, àti pé ìdúnnú ayérayé wọn ni èrèdí iṣẹ́ Ìṣẹ̀dá gan an.

Ònkọ̀wé Antoine de Saint-Exupéry ṣe ìrántí àtẹ̀lé yí: Ní ọjọ́ kan, nígbàtí ó nrin ìrìn àjò nínú ọkọ̀ ojú irin, ó rí ara rẹ̀ ní jíjókòó láàrin àwọn tí wọ́n nsálọ fún ààbò. Nínú ìtara jíjinlẹ̀ nípa àìnírètí tí ó rí ní ojú ọ̀dọ́mọdé kan, ó kígbe pé: “Nígbàtí a bá bí òdòdó titun kan nínú ọgbà nípa àtúnbí, gbogbo àwọn ọlọ́gbà a yọ̀. Wọ́n a ya òdòdó náà sọ́tọ̀, ṣe ìtọ́jú rẹ̀, mójútó o. Ṣùgbọ́n kò sí ọlọ́gbà fún ènìyàn.”10

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi, njẹ́ a kì yío ha jẹ́ ọlọ́gbà fún àwọn akẹgbẹ́ wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin? Njẹ́ a kìí ha ṣe olùpamọ́ arákùnrin wa bí? Jésù paṣẹ fún wa láti fẹ́ràn àwọn aládũgbò wa bíi ara wa.11 Láti ẹnu Rẹ̀, ọ̀rọ̀ náà aládũgbò kò túmọ̀ sí sísún mọ́ra orí ilẹ̀ lásán; ó ntọ́ka sí sísún mọ́ra ti ọkàn. Ó jẹ́ àkópọ̀ gbogbo àwọn olùgbé ìpín ilẹ̀ ayé yi—bóyá wọ́n ngbé nítòsí wa tàbí ní orílẹ̀ èdè jíjìnnà rere, láìka àwọn orísun wọn, àwọn àtilẹ̀wá ara-ẹni wọn, tàbí àwọn ipò wọn sí,

Àwa bíi ọmọlẹ́hìn Krístì, a ní ojúṣe ọ̀wọ̀ kan láti ṣiṣẹ́ láìkãrẹ̀ fún àlàáfíà àti ìrẹ́pọ̀ láàrin gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè ilẹ̀ ayé. A gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wa láti dáàbò bò kí a sì mú ìtùnú àti ìrànlọ́wọ́ wá fún àwọn aláìlágbára, àwọn aláìní, àti gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n njìyà tàbí tí a njẹ níyà. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ̀bùn ìfẹ́ tí ó tóbi jùlọ tí a le fún àwọn akẹgbẹ́ wa ni láti pín ayọ̀ ìhìnrere pẹ̀lú wọn kí a sì pè wọ́n láti wá sí ọ̀dọ̀ Olùgbàlà wọn nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú àti àwọn ìlànà mímọ́.

Ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ kẹta: A pè wá láti kópa nínú iṣẹ́ ti ìṣẹ̀dá.

Ìlànà àtọ̀runwá ti ìṣẹ̀dá kò tíì pé síbẹ̀. Ní ojoojúmọ́, àwọn ìṣẹ̀dá ti Ọlọ́run tẹ̀síwájú láti máa dàgbà, máa gbòòrò, àti láti máa pọ̀ síi. Ohun yíyanilẹ́nu jùlọ kan ni pé Baba wa Ọ̀run nna ọwọ́ ìfipè sí wa láti kópa nínú iṣẹ́ ìṣẹ̀dá Rẹ̀.

A nkópa nínú iṣẹ́ Ìṣẹ̀dá náà nígbàkugbà tí a bá ro oko ilẹ̀ ayé tàbí ṣe àfikún àwọn ohun kíkọ́ ti arawa sí ayé yí—níwọ̀nbí a bá fi ọ̀wọ̀ hàn fún àwọn ìṣẹ̀dá ti Ọlọ́run. Àwọn ìlọ́wọ́sí wa ni a le fihàn nípasẹ̀ ṣíṣe àwọn iṣẹ́ ọnà, àwòrán, orin, àròkọ, àti àṣà, èyítí ó gbòdekan ní ìpínlẹ̀ ayé wa, ta àwọn iyè wa jí, kí ó sì tan ìmọ́lẹ̀ sí ayé wa. Bákannáà à nlọ́wọ́sí nípasẹ̀ àwọn àwárí sáyẹ́nsì àti ìṣègùn òyìnbó tí npa ilẹ̀ ayé àti ẹ̀mí tí ó wà lórí rẹ̀ mọ́. Aàrẹ Thomas S. Monson ṣe ìkékúrú ìlànà yí pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ rírẹwà wọ̀nyí: “Ọlọ́run fi ayé sílẹ̀ ní àìparí fún ènìyàn láti ṣe iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ lée … kí ènìyàn ó le mọ àwọn ayọ̀ àti àwọn ògo ìṣẹ̀dá.”12

Nínú òwe ti Jésù nípa àwọn tálẹ́ntì, nígbàtí olúwa rẹ̀ padà dé láti ìrìnàjò rẹ̀, ó gbóríyìn ó sì fi èrè fún àwọn ìránṣẹ́ méjì tí wọ́n mú àwọn tálẹ́ntì wọn dàgbà. Ní ìdàkejì, ó pe ìránṣẹ́ tí ó fi tálẹ́ntì àrà ọ̀tọ̀ rẹ̀ pamọ́ sínú ilẹ̀ “láìlérè,” àní ó sì mú èyí tí ó ti gbà tẹ́lẹ̀ kúrò.14

Ní jíjọra, ojúṣe wa bíi olùtọ́jú àwọn ìṣẹ̀dá ti ilẹ̀ ayé kìí ṣe nípa dídààbo bò tàbí pípa wọ́n mọ́ nìkan. Olúwa retí wa láti ṣiṣẹ́ tọkàn tara, bí Ẹmí Mímọ́ bá ṣe darí wa, láti mú dàgbà, tún ṣe, kí a sì mú kí àwọn ohun èlò tí Ó fi sí abẹ́ ìtọ́jú wa dára síi—kìí ṣe fún ànfàní wa nìkan ṣùgbọ́n láti bùkún àwọn ẹlòmíràn.

Ní ààrin gbogbo àwọn àṣeyọrí ènìyàn, kò sí èyí tí ó le dọ́gba pẹ̀lú ìrírí ti jíjẹ́ àjùmọ̀-ṣẹ̀dá pẹ̀lú Ọlọ́run ní fífúnni ní ìyè, tàbí ríran ọmọ kan lọ́wọ́ láti kọ́ ẹ̀kọ́, láti dàgbà, àti láti ṣe rere—bóyá ó jẹ́ bíi àwọn òbí, àwọn olùkọ́, àwọn olùdarí, tàbí nínú èyíkéyí ojúṣe míràn. Kò sí iṣẹ́ olùtọ́jú tí ó jẹ́ mímọ́ síi, tí a le múṣẹ síi, àtì bákannáà tí ó nira ju ti àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Ẹlẹ́dã wa ní pípèsè àwọn àgọ́ ara fún àwọn ọmọ ẹ̀mí Rẹ̀ àti nígbànáà ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti dé ibi agbára àtọ̀runwá wọn.

Ojúṣe àjùmọ̀-ṣẹ̀dá nṣiṣẹ́ bíi ìránnilétí lemọ́lemọ́ pé ìyè àti ara ènìyàn kọ̀ọ̀kan jẹ́ mímọ́, pé wọ́n kìí ṣe ti ẹnìkẹ́ni míràn ju Ọlọ́run lọ, àti pé Ó ti fi wá ṣe alágbàtọ́ láti bọ̀wọ̀ fún, dá ààbò bò, kí a sì ṣe ìtọ́jú wọn. Àwọn òfin Ọlọ́run, èyítí ó nṣàkóso àwọn agbára ìbísí àti ìgbékalẹ̀ àwọn ẹbí ayérayé, ntọ́wa sọ́nà nínú iṣẹ́ olùtọ́jú mímọ́ yí, èyítí ó ṣe pàtàkì púpọ̀ sí ètò Rẹ̀.

Ẹyin arákùnrin àti ẹ̀yin arábìnrin mi, a níláti dá a mọ̀ pé ohun gbogbo jẹ́ ti ẹ̀mí sí Olúwa—àti àwọn abala tí ó jẹ ti ara pẹ̀lú ní ìgbé ayé wa. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé àwọn ìbùkún nlá ti ẹ̀mí ní a ṣèlérí fún àwọn tí wọ́n fẹ́ràn tí wọ́n sì nṣe ìtọ́jú fún ilẹ̀ ayé àti àwọn akẹgbẹ́ wọn lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Bí ẹ ti dúró bí olõtọ́ nínú iṣẹ́ olùtọ́jú mímọ́ yi tí ẹ sì nbu ọlá fún àwọn májẹ̀mú ayérayé yín, ẹ ó dàgbà nínú imọ̀ Ọlọ́run àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, ẹ ó sì ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Wọn àti ipá Wọn ní ọ̀pọ̀ síi nínú ayé yín. Gbogbo èyí yío pèsè yín sílẹ̀ láti gbé pẹ̀lú Wọn kí ẹ sì gba àfikún agbára ìṣẹ̀dá15 ní ayé tó nbọ̀.

Ní òpin ayé kikú yi, Olùkọ́ni yío bèèrè lọ́wọ́ wa láti ṣe ìjíyìn fún iṣẹ́ olùtọ́jú mímọ́ wa, àti bí a ti ṣe ìtọ́jú fún àwọn ẹ̀dá Rẹ̀ pẹ̀lú. Mo gbàdúrà pé nígbànáà a ó gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ìfẹ́ni Rẹ̀ ní sísọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sí ọkàn wa: “Káàbọ̀, ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere àti olõtọ́: ìwọ ṣe olõtọ́ nínú ohun díẹ̀, èmi ó mú ọ ṣe olórí ohun púpọ̀: ìwọ bọ́ sínú ayọ̀ Olúwa rẹ.”16 Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.