Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Àwọn Àwòṣe ti Jíjẹ́ Ọmọ-ẹ́hìn
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2022


Àwọn Àpẹrẹ ti Jíjẹ́ Ọmọ-ẹ́hìn

Kíkọ́ nípa Krístì àti àwọn ọ̀nà Rẹ̀ ndarí wa láti mọ̀ àti láti nífẹ Rẹ̀.

Àwòṣe ti ìgbàgbọ́

Ní òwúrọ̀ yí àwọn ọmọ wa méjì àti àwọn ọmọ-ọmọ mẹ́ta ní Àríwá Amẹ́ríkà àti bí i ìdajì àgbáyé, ti rí ìmọ́lẹ̀ oòrùn tí nyọ lọ́lánlá ní ìlà-oòrùn. Àwọn ọmọ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yòókù àti àwọn ọmọ-ọmọ méje ní Áfíríkà, àti ìdajì ayé yòókù, rí òkùnkùn díẹ̀díẹ̀ tí ó nra sí wọn lórí bí oòrùn ṣe nrì lórí ìràwọ̀ ní ìwọ̀ oòrùn.

Ìdúróṣinṣin àìlákoko yii ti ìbẹ̀rẹ̀ ti ọ̀sán àti alẹ́ jẹ́ olùránnilétí ojoójúmọ́ kan nípa àwọn òtítọ́ tí ó nṣe àkóso àwọn ìgbésí ayé wa tí a kò le yípadà. Nígbàtí a bá bọ̀wọ̀ tí a sì wà ní ìbámu sí ohun tí a nṣe pẹ̀lú àwọn òdodo ayérayé wọ̀nyí, a nní ìrírí àláfíá inú àti ìṣọ̀kan. Nígbàtí a kò bá ṣe é, a kò ní ní fọ̀kànbalẹ̀, àti pé àwọn nkan kìí ṣiṣẹ́ bí a ti retí.

Ọ̀sán àti òru jẹ́ àwòṣe ọ̀nà kan tí Ọlọ́run fi fún gbogbo àwọn tó ti gbé ayé rí, bí àwọn nkan ṣe rí lódodo. Ó jẹ́ òtítọ́ pípé ti ìwàláàyè ènìyàn tí a kò lè ṣe ìdúnadúra ní àyíká gẹ́gẹ́bí àwọn ìfẹ́ tiwa kí a sì mujẹ. A rán mi létí èyí ní gbogbo ìgbà tí mo bá wọ ọkọ̀ òfúrufú láti Afirika láti wá sí ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò, tó ntún aago ara padà sẹ́hìn nípasẹ̀ àwọn wákàtí mẹ́wa ní ọjọ́ kan.

Nígbàkúgbà tí a bá bìkítà láti ṣe àkíyèsí, a nri pé Bàbá Ọ̀run ti fún wa ní àwọn ẹlẹ́ri tí ó pé nípa òtítọ́ láti ṣe àkóso àwọn ìgbésí ayé wa kí a ba lè mọ Ọ àti kí a ní àwọn ìbùkún àlàáfíà àti ayọ̀.

Nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, Ẹ̀mí Olúwa fi múlẹ̀ pé: “Àti lẹ́ẹ̀kan síi, èmi yíò fún yín ní àwòṣe nínú ohun gbogbo, kí a má baà tan yín jẹ; nítorí Satani wà lóde ní ilẹ̀ náà, ó sì njáde lọ káàkiri láti tan àwọn orílẹ̀-èdè jẹ.”1

Korihor alátakò-Krístì ṣubú fún irú ẹ̀tàn bẹ́ẹ̀, ní àìgbàgbọ́ wíwà Ọlọ́run àti bíbọ̀ Krístì. Òun ni wòlíì Álmà jẹ́ri sí pé, “Ohun gbogbo fi hàn pé Ọlọ́run kan mbẹ; bẹ̃ni àní ayé pẹ̀lú, àti ohun gbogbo tí ó wà lójú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ni, àti yíyí rẹ̀, bẹ́ẹ̀ni, àti pẹ̀lú gbogbo àwọn pílánẹ́ẹ̀tì tí nwọ́n nyí ni ipa ọ̀nà nwọn jẹ́ ẹ̀rí pé Ẹlẹ́dã Tí-ó-ga-jùlọ kan nbẹ.”2

Nígbàtí Kòríhọ̀r tẹnumọ pé kí wọn fún òun ní àmì kan kí òun tó lè gbàgbọ́, Álmà mú kí ó yadi. Níní ìrẹlẹ̀ nípa ìpọ́njú rẹ̀, Korihor jẹ́wọ́ fúnrarẹ̀ bí èṣù ṣe tan òun jẹ.

A kò níláti jẹ́ títàn jẹ. Iṣẹ́ ìyanu òye ti ìgbésí ayé nhàn míwájú wa nígbàgbogbo. Àti wíwò ní ṣókì àti rírònù lórí àwọn ìyanu tọ̀run tí a ṣe lọ́ṣọ pẹ̀lú àìníye ìràwọ̀ àti àwọn àgbáyé nṣí ẹ̀mí ọkàn onígbàgbọ́ létí láti kéde pé, “Ọlọ́run mi, bí ẹ ti tóbi tó!”3

Bẹ́ẹ̀ni, Ọlọ́run Bàbá wa Ọ̀run wà láàyè, Ó sì nfi ara Rẹ̀ hàn fún wa ní gbogbo ìgbà ní ọ̀nà púpọ̀.

Àwòṣe ìrẹ̀lẹ̀

Ṣùgbọ́n láti jẹ́wọ́, gbàgbọ́, àti láti tẹ̀síwájú nínú Ọlọ́run, ọkàn wa nílò láti gba Ẹ̀mí òtítọ́. Álmà kọ́ni pé ìrẹ̀lẹ̀ ni ó nṣáájú ìgbàgbọ́.4 Mọmọnì fi kún un pé kò ṣeé ṣe fún ẹnikẹ́ni tí kìí ṣe “ọlọ́kàn tútù àti onírẹ̀lẹ̀” láti ní ìgbàgbọ́ àti ìrètí àti láti gba Ẹ̀mí Ọlọ́run.5 Ọba Bẹ́ńjámínì kéde pé ẹnikẹ́ni tó bá fi ògo ayé ṣáájú jẹ́ “ọ̀tá Ọlọ́run.”6

Nípa fífi arasílẹ̀ fún ìrìbọmi láti mú gbogbo òdodo ṣẹ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ó jẹ́ olódodo àti mímọ́, Jésù Kristi júwe pé ìrẹ̀lẹ̀ níwájú Ọlọ́run jẹ́ ìwà ìpìlẹ̀ àwọn ọmọ ẹ̀hìn Rẹ̀.7

Gbogbo ọmọ-ẹhin titun ni ó nílò láti fi ìrẹ̀lẹ̀ hàn níwájú Ọlọ́run nípasẹ̀ ìlànà ìrìbọmi. Bayi, “gbogbo àwọn tí wọ́n rẹ ara wọn sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run, tí wọ́n sì fẹ́ ṣe ìrìbọmi, tí wọ́n sì jáde wá pẹ̀lú àwọn ọkàn ìrora àti àwọn ẹ̀mí ìròbìnújẹ́ … ni a ó gbà nípasẹ̀ ìrìbọmi sínú ìjọ rẹ̀.”8

Ìrẹ̀lẹ̀ nfi ọkàn ọmọ-ẹ̀hìn sí ọ̀nà ìrònúpíwàdà àti ìgbọ́ran. Ẹ̀mí Ọlọ́run lè mú òtítọ́ wá sí ọkàn náà, yìò sì rí ọ̀nà àbáwọlé.9

Àìní ìrẹ̀lẹ̀ ló mú kí àsọtẹ́lẹ̀ àpọ́sítélì Páùlù ní ìmúṣẹ ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn wọ̀nyí:

“Nítorí àwọn ènìyàn yío jẹ́ olùfẹ́ ti ara wọn, olùfẹ́ owó, olójúkòkòrò, agbéraga, asọ̀rọ̀ buburú, aṣàìgbọràan sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìmọ́.

“Aláìnífẹ, aláìle-daríji-ni, abanijẹ́, aláìle-kó-ara-wọn-níjanu, ònrorò, aláìnífẹ ohun rere.”10

Ìpè Olùgbàlà láti kọ́ nípa Rẹ̀ jẹ́ ìpè láti yípadà kúrò nínú ìtanni ti ayé àti láti dà bí Òun ṣe jẹ́—ọlọ́kàn tútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn, ìrẹ̀lẹ̀. Lẹ́hìnnáà a ní ànfàní láti gba àjàgà Rẹ̀ kí a sì ṣe ìwárí pé ó rọrùn—pé ọmọ-ẹ̀hìn kìí ṣe ẹrú pẹ̀lú ayọ̀, gẹ́gẹ́bí Ààrẹ Nelson ti kọ́ wa lọ́nà mímọ ọ̀rọ̀-sísọ àti léraléra.

Àwòṣe ìfẹ́

Kíkọ́ nípa Krístì àti àwọn ọ̀nà Rẹ̀ ndarí wa láti mọ̀ àti láti nífẹ Rẹ̀.

Ó fi hàn nípa àpẹrẹ pé pẹ̀lú ìwà ìrẹ̀lẹ̀, ó ṣeéṣe nítòótọ́ láti mọ̀ àti láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run Baba pẹ̀lú gbogbo wíwà wa àti láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíràn gẹ́gẹ́bí a ti nífẹ̀ẹ́ ara wa, láìṣẹ́ ohunkóhun kù sẹ́hìn. Iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, nínú èyí tí Ó fi ìfẹ́ Rẹ̀ àti ara Rẹ̀ sílẹ̀ lórí pẹpẹ, jẹ́ àwòṣe fún fífisílílò àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ wọ̀nyí lórí èyí tí a ti fi ìhìnrere Rẹ̀ lélẹ̀. Àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ méjèèjì jẹ́ ìwò òde àti pé ó jẹ́ nípa bí a ṣe ntan sí àwọn miran, kìí ṣe nípa wíwá ìtẹ́lọ́rùn tàbí ògo ti ara ẹni.

Àfiwé ìyàlẹ́nu rẹ̀ ni pé nígbà tí a bá dojúkọ àwọn akitiyan wa tí ó dára jùlọ lórí ìfẹ́ni Ọlọ́run àti àwọn miran, á lè ṣe àwárí ìtọ́sí tọ̀run ti arawa nítòótọ́, gẹ́gẹ́bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìrin Ọlọ́run, pẹ̀lú àláfíà àti ayọ̀ pípé tí ìrírí yi nmú wá.

A di ọ̀kan pẹ̀lú Ọlọ́run àti pẹ̀lú ara wa nípasẹ̀ ìfẹ́ àti iṣẹ́ ìsìn. Nígbànáà a lè gba ẹ̀rí Ẹ̀mí Mímọ́ ti ìfẹ́ mímọ́ náà, èso tí Léhì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ gẹ́gẹ́bí “aládùn jù lọ, ju gbogbo èyí tí mo ti tọ́ wò rí.”11

Adé èyití Krístì gbà nípa fífúnni àti ṣíṣe ohun gbogbo nínú agbára Rẹ̀ láti gbé àwòṣe ti ìfẹ́ni Baba kalẹ̀ àti ìfẹ́ni wa ni làti gba gbogbo agbára, pàápàá ohun gbogbo tí Baba ní, èyí tí ó jẹ́ ìgbéga.12

Ànfàní wà láti tọ́jú ìfẹ́ pípẹ́ nínú ẹ̀mí wa fún Ọlọ́run àti aládúgbò wa bẹ̀rẹ̀ ní ilé pẹ̀lú ìwà mímọ́ ti sísopọ̀ pẹ̀lú Bàbá lójoojúmọ́ nínú àdúrà ti ara ẹni àti ti ẹbí ní orúkọ Ọmọ Bíbí Rẹ̀ Kanṣoṣo, kíkọ́ ẹ̀kọ́ papọ̀ nípa Wọn nípasẹ̀ àdúrà ẹnìkọ̀ọ̀kan àti àṣàrò ìwé-mímọ́ ẹbí, ṣíṣe àkíyèsí Ọjọ́-ìsimi papọ̀, àti níní ìkaniyẹ tẹmpili lọ́wọ́lọ́wọ́ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, ati lilo ó papọ̀ nígbàkugbà tí a bá lè ṣé.

Bí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ṣe ndàgbà nínú ìmọ̀ àti ìfẹ́ ti Baba àti Ọmọ, a ndàgbà nínú ìmọyì àti ìfẹ́ fún ara wa. Agbára wa láti nífẹ àti láti sin àwọn ẹlòmíràn níta ilé ni ó ngbòòrò si lọ́pọ̀lọpọ̀.

Ohun tí a nṣe nínú ilé ni ààyè òtítọ́ ti ìfaradà àti ọmọ-ẹ̀hìn aláyọ̀. Àwọn ìbùkún tí ó dùn julọ ti ìhinrere tí a mú padàbọ̀sípò tí ìyàwó mi, Gladys, àti èmi ti gbádùn nínú ilé wa ti wá láti kíkọ́ ẹ̀kọ́ láti mọ̀ àti làti bu ọlá fún Ọlọ́run ní ilé àti láti pín ìfẹ́ Rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìran wa.

Àwòṣe ti iṣẹ́-ìsìn.

Ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti iṣẹ́ ìsìn sí ara wa tí a ntọ́jú ní ilé àti iṣẹ́ ìsìn sí àwọn ẹlòmíràn níta ilé lákòókò ndàgbà sí ìwà ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́.

Èyí bá àwòṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ i`yàsímímọ́ nínú ìjọba Ọlọ́run tí a gbé ka iwájú wa láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì àti àpọ́sítélì alààyè Olúwa. A di ọ̀kan pẹ̀lú wọn.

Lẹ́hìnnáà a fún wa ní agbára láti wo Olúwa, nípasẹ̀ wọn “nínú gbogbo èrò,” kí a máṣe “ṣiyèméjì” tàbí “kí a máṣe bẹ̀ru.”13

Gẹ́gẹ́bí àwọn wòlíì Olúwa àti àwọn àpóstélì, a lè jáde lọ pẹ̀lú “inu … tí ó kún fún ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ sí gbogbo ènìyàn, àti sí agbo ilé ìgbàgbọ́, [pẹ̀lú] ìwà-rere [ní títún èrò wa] ṣe láì-dáwọ́dúró; … [àti ìgbẹ́kẹ̀lé wa] [ní níní agbára] níwájú Ọlọ́run; àti ẹ̀kọ́ oyèàlùfáà … tí ó ndà sórí [ẹ̀mí wa] bí ìrì láti ọ̀run wá.”

Pẹ̀lú àwọn wòlíì àti àpóstélì Olúwa aláàyè, àwa pẹ̀lú lè darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ oníwà-rere ti ìgbàgbọ́ tí a fún lókun nípa iṣẹ́ ìsìn yíyàsímímọ́ nínú èyí tí “Ẹ̀mí Mímọ́ [ni] olùbákẹ́gbẹ́ [wa] nígbàgbogbo, ọ̀pá aládé [wa] ni ọ̀pá aládé òdodo àti òtítọ́ tí kì í yí padà; ìjọba [wa] sì [jẹ́] ìjọba ayérayé kan, àti láìsí àfipáṣe ó [nṣàn] wá sọ́dọ̀ [wa] láé àti títíláé.”14 Nítorí èyí ni ìlérí ètò Baba. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.