Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ẹwà fún Eérú: Ipa Ọnà Iwòsàn ti Ìdáríjì
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2022


Ẹwà fún Eérú: Ipa Ọnà Iwòsàn ti Ìdáríjì

Láti gbé ní irú ọ̀nà tí ẹ ó fi fúnni ní ẹ̀wà fún eérú ti ìgbé ayé yín ni ìgbésẹ̀ ìgbàgbọ́ tí ó ntẹ̀lé Olùgbàlà.

Iwé 1 Sámúẹ́lì ní ìtàn kan tí a kò mọ̀ dáradára nínú nípa Dáfídì, ọba ọjọ́ iwájú ti Isráẹ́lì, àti obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ jé Abígáẹ́lì.

Lẹ́hìn ikú Sámúẹ́lì, Dáfídì àti awọn ènìyàn rẹ̀ lọ kúrò lọ́dọ̀ Ọba Sáùlù ẹnití nlépa ẹ̀mí Dáfídì. Wọ́n pésé ìtọ́jú fún àwọn agbo ẹran àti àwọn àti àwọn ìránṣẹ́ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Nábálì, ẹnití ó ní ẹmí ahun. Dáfídì rán mẹ́wàá nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ láti kí Nábálì kí wọn ó sì bèèrè fún ounjẹ àti awọn ìpèsè tí wọn nílò gidigidi.

Nábálì fèsì sí ìbéèrè Dáfídì pẹ̀lú èébú ó sì lé àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò ní ọwọ́ òfo.

Pẹ̀lú ìbínú, Dáfídì múra fún àwọn ènìyàn rẹ̀ láti gòkè lọ dojúkọ Nábálì àti ìdílé rẹ̀ wípé, “Òun ti fi ibi san rere fún mi.”1 Ìránṣẹ́ kan sọ fún Abigaẹlì, ìyàwó Nábálì, nípa ìwà àìdára ọkọ rẹ̀ sí àwọn ènìyàn Dáfídì. Abigaẹli yára kó oúnjẹ àti àwọn ìpèsè tí wọ́n nílò gidigidi ó sì lọ ṣe àgbàwí.

Nígbàtí Abigaẹli pàdé rẹ̀, ó “dojúbolẹ̀ níwájú Dáfídì, ó sì tẹ ara rẹ̀ ba sílẹ̀,

“Òun sì wólẹ̀ ní ẹ̀bá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì wípé, olúwa mi, fi ẹ̀ṣẹ̀ yí yá mi. …

“Nígbànáà nísisiyí, … Olúwa ti dá ọ dúró láti wá ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, àti lati wá fi ọwọ́ ara rẹ gbẹ̀san. …

“… Njẹ́ èyí ni ẹ̀bùn tí ìránṣẹ́bìnrin rẹ mú wá fún olúwa mi, jẹ́kí a sì fifún àwọn ọmọkùnrin. …

“Èmi bẹ̀ ọ́, fi ìrékọ́já ìránṣẹ́bìnrin rẹ jì í. …

“Dáfídì sì wí fún Abigailì pé, Alábùkún fún ni Olúwa Ọlọ́run Ísráẹ́lì, tí ó rán ọ lóni yí lati pàdé mi:

“Ibùkún ni fún ọgbọ́n rẹ, alábùkún fún sì ni ìwọ, tí ó dámi dúró lóni yí láti wá ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, àti lati wá fi ọwọ́ mi gbẹ̀san fún ara mi. …

“Bẹ́ẹ̀ni Dáfídì sì gba nkan tí ó múwá fún un ní ọwọ́ rẹ̀, o sì wí fún pé, Gòkè lọ ní àlàáfíà sí ilé rẹ; … Èmi ti gbọ́ ohùn rẹ, inú mi sì dùn sí ọ.”2

Àwọn méjèèjì lọ ní àlàáfíà.

Nínú àkọsílẹ̀ yí, a lè rí Abigaẹli bí alágbára kan irú tàbí àpẹrẹ Jésù Krístì.3 Nípasẹ̀ ètùtù ìrúbọ Rẹ̀, Òun le tú wa sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ìwúwo ọkàn tó njagun kí ó sì pèsè wa pẹ̀lú àtìlẹ́hìn tí a nílò.4

Gẹ́gẹ́bí Abigaẹli ti ṣetán láti gba ẹ̀ṣẹ̀ Nabalì sí ara rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Olùgbàlà—ní ọ̀nà kan tí a kò le ní òye rẹ̀—gba àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa sí orí ara rẹ̀ àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ti àwọn wọnnì tí wọ́n ti pá wá lára tàbí mú wa bínú.5 Ní Gẹ́tsémánè àti ní orí àgbélèbú, Ó gba àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀nyí. Ó ṣe ọ̀nà kan fún wa láti ju ọkàn gbígba ẹ̀san sílẹ̀. “Ọnà” náà ni nípasẹ̀ dídáríjì—èyítí ó le jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ohún tí ó ṣòro jùlọ tí a ti ṣe rí àti ọ̀kan nínú àwọn ohún tí ó jẹ́ ti ọ̀run tí a ti ní ìrírí rẹ̀ rí. Ní ipa ọ̀nà ìdáríjì, agbára ètùtù Jésù Krístì le ṣàn sínú ayé wa kí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìwòsàn àwọn ihò jíjin ọkàn àti ẹ̀mí.

Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ni pé Olùgbàlà fi agbára fún wa láti dáríjì.

“Nípasẹ̀ Ètùtù àìlópin Rẹ̀, ẹ lè dáríji àwọn tí wọ́n ti ṣe ìpalára fún yín tí wọ́n kò sì lè gba ojúse fún ìwà ìkà wọn sí yín láé.

“Ó máa nsáábà rọrùn láti dariji ẹni tí ó fi tọkàntọkàn àti ìrẹ̀lẹ̀ wá ìdáríjì yín. Ṣùgbọ́n Olùgbàlà yio fún yín ní agbára láti dáríjì ẹnikẹ́ni tí ó ṣe yín níbi ní eyikeyi ọ̀nà. Nígbànáà àwọn iṣe pípanilára wọn kò ní le ṣe ibi fún ẹ̀mí yín.”

Abigaẹli ní mímú ọ̀pọ̀ oúnjẹ àti àwọn ohun èlò wá le kọ́ wa pé Olùgbàlà nfi fún àwọn tí a ti palára tí a sì ti ṣe àtìlẹ́hìn àti ìrànlọ́wọ́ tí a nílò láti di wíwòsàn àti mímú láradá léṣe.7 A kò fi wá sílẹ̀ láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn àbájáde ìgbésẹ̀ àwọn ẹlòmíràn fúnra wa; àwa náà le di mímú láradá àti fífún ní ààyè láti jẹ́ gbígbàlà kúrò nínú ìwúwo ọkàn tó njagun àti èyíkéyi àwọn ìgbésẹ̀ tí ó le tẹ̀lé.

Olúwa ti sọ pé, “Èmi, Olúwa, yíò dáríji ẹnití èmi yíò dáríjì, ṣùgbọ́n ní tiyín ó jẹ́ dandan láti dáríji gbogbo ènìyàn.”8 Olúwa nbèrè lọ́wọ́ wa láti dáríjì fún rere tiwa.9 Ṣùgbọ́n kò sọ fúnwa láti ṣe é láìsí ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀, Ìfẹ́ Rẹ̀, òye Rẹ̀. Nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú wa pẹ̀lú Olúwa, ọ̀kọ̀ọ̀kan wa le gba agbára, ìtọ́ni, àti ìrànlọ́wọ́ tí nfúnni lókun tí a nílò láti le dáríjì àti láti jẹ́ dídáríjì.

Ẹ jọ̀wọ́ ẹ mọ̀ pé dídáríjì ẹnìkan kò túmọ̀ sí pé ẹ fi ara yín sínú ipò kan níbití ẹ ó ti tẹ̀síwájú láti máa jẹ́ pípalára. “A le ṣiṣẹ́ sí ìhà dídáríjì ẹnìkan kí a sì ní ìmọ̀lára ìṣílétí láti ọ̀dọ̀ Ẹmí láti yàgò fún wọn.”10

Gẹ́gẹ́bí Abigaẹli ti ran Dáfídì lọ́wọ́ kí ó máṣe ní “ìkọ̀sẹ̀ ti ọkàn”11 àti láti gba ìrànlọ́wọ́ tí ó nílò, bẹ́ẹ̀ ni Olùgbàlà yío ràn ọ́ lọ́wọ́. Ó fẹ́ràn rẹ, Ó sì npàdé rẹ ní ipa ọ̀nà rẹ “pẹ̀lú ìwòsàn ní apá Rẹ̀.”12 Ó nfẹ́ àlàáfíà yín.

Mo ti fúnra ara mi rí ìyanu ti Krístì tó nṣe ìwòsàn fún ọkàn mi tó njagun. Pẹ̀lú ìyọ̀nda baba mi, mo nsọ fún y/in pé mo dàgbà nínú ilé kan níbití èmi kò ti nfi ìgbà gbogbo ní ìmọ̀lára ààbò nítorí ìlòkulò ní ti ẹ̀dùn ọkàn àti ọ̀rọ̀ ẹnu, Ní àwọn ọdún ìgbà ọ̀dọ́mọdé àti ọ̀dọ́-àgbà mi, mo kórĩra baba mi mo sì ní ìbínú nínú ọkàn mi láti inú ìpalára náà.

Bí ọdún ti nkọjá àti nínú ìtiraka mi láti rí àláfíà àti ìwòsàn ní ipa ọ̀nà ìdáríjì, mo dáa mọ̀ ní ọ̀nà ìjìnlẹ̀ kan pé Ọmọ Ọlọ́run kannáà tí ó ṣe ètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi ni Olùràpadà kannáà tí yío gba àwọn tí wọ́n ti pámílára jinlẹ̀ là bákannáà. Èmi kò le gba òtítọ́ àkọ́kọ́ gbọ́ nítòótọ́ láì gbàgbọ́ nínú èkejì.

Bí ìfẹ́ mi fún Olùgbàlà ṣe ti dàgbà, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́-inú mi láti dí ipò ìpalára àti ìbínú pẹ̀lú ìpara ìwòsàn Rẹ̀. Ó ti jẹ́ ìlànà kan fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, tí ó ngba ìgboyà, àìlera, ìpamọ́ra, àti ẹ̀kọ́ kíkọ́ láti gbẹ́kẹ̀lé agbára àtọ̀runwá ti Olùgbàlà láti gbàlà àti láti wòsàn. Mo ní iṣẹ́ láti ṣe síbẹ̀, ṣùgbọ́n okàn mi kò sí lóri ipa ọ̀nà ogun mọ́. A ti fúnmi ní “ọkàn tuntun kan”13—ẹni tí ó ti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ ìjìnlẹ̀ tí ó sì nbáni gbé ti Olùgbàlà araẹni kan, tí ó dúró ní ẹ̀gbẹ́ mi, ntí ó fi pẹ̀lú jẹ́jẹ́ àti sùúrù darí mi sí ibi dídára jùlọ kan, tí ó sọkún pẹ̀lú mi, tí ó mọ ìbànújẹ́ mi.

Olúwa ti rán àwọn ìbùkún gbà-mábínú sí mi gẹ́gẹ́bí Ábígáẹ́lì ti mú ohun tí Dáfídì nílò wá. Ó ti rán àwọn olùtọ́ni sí inú ayé mi. Èyí tí ó sì dùn jùlọ àti tí ó nyínipadà jùlọ nínú gbogbo rẹ̀ ni ìbáṣepọ̀ mi pẹ̀lú Baba mi Ọ̀run. Nípasẹ̀ Rẹ̀, mo ti fi pẹ̀lú ìmoore mọ ìfẹ́ jẹ́jẹ́, tí ndáàbò bò, àti ìfẹ́ ìtọ́ni ti Baba pípé kan.

Alàgbà Richard G. Scott wípé: “Ẹ kò le pa ohun tí o ti jẹ́ ṣíṣe rẹ́, ṣùgbọ́n ẹ le dáríjì.14 Ìdáríjì nwo àwọn ọgbẹ́ búburú, ti àjálù sàn, nítorí ó nfi ààyè gba ìfẹ́ Ọlọ́run láti mú májèlé ìkórĩra kúrò nínú ọkàn àti iyè inú yín. Ó nwẹ ìfẹ́ inú láti gbẹ̀san kúrò ní èrò inú yín. Ó nfi ààyè sílẹ̀ fún ìwẹ̀mọ́, ìwòsàn, tó sì nmúpadàbọ̀sípò ìfẹ́ Olúwa.”15

Baba mi ti ayé bákannáà ti ní ìyípadà ọkàn oníyanu kan ní àwọn ọdún tí kò pẹ́ púpọ̀, ó sì ti yípadà sí Olúwa—ohun kan tí èmi ìbá mátilẹ̀ fi ojú sọ́nà fún ní ayé yí. Ẹrí míràn sí mi nípa agbára pípé àti yíyínipadà ti Jésù Krístì.

Mo mọ̀ pé Ó le ṣeé láti wo ẹlẹ́ṣẹ̀ sàn àti gbogbo àwọn tí ó ti ṣẹ̀ sí. Òun ni Olùgbàlà àti Olùràpadà aráyé, ẹnití ó fi ẹ̀mí Rẹ̀ lélẹ̀ kí àwa le yè lẹ́ẹ̀kansíi. Ó wípé: “Ẹ̀mí Olúwa nbẹ lára mi, nítorí ó ti fi àmì òróró yàn mi láti wàásù ìhìnrere fún àwọn òtòṣì, ó ti rán mi láti wò àwọn ọkàn ìròbìnújẹ́ sàn, láti wàásù ìdásílẹ̀ fún àwọn tó wà nígbèkùn, àti ìtúnríran fún àwọn afọ́jú, láti sọ àwọn tí a pa lára di ọ̀mìnira.”16

Sí gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ oníròbìnújẹ́ ọkàn , ìgbèkùn, tí a pa lára, àti bóyá tí a fọ́ lójú nípa ìpalára tàbí ẹ̀ṣẹ̀, Ó fi ìwòsàn, ìmúláradá, àti ìtúsílẹ̀ fúnni. Mo jẹ́ríì pé ìwòsàn àti ìmúláradá tí Ó nfifúnni jẹ́ òtítọ́. Àkókò fún ìwòsàn náà jẹ́ ti olukúlùkù, a kò sì le dájọ́ ti àkókò ẹlòmíràn. Ó ṣe pàtàkì kí a gba ara wa láàyè àkókò tí a nílò láti wòsàn àti láti dára sí ara wa nínú ìlànà náà. Olùgbàlà jẹ́ aláànú àti olùfetísílẹ̀ títíláé, Ó sì dúró ní ṣíṣetán láti pèsè ìrànlọ́wọ́ tí a nílò.17

Ní ipa ọ̀nà ìdáríjì àti ẹ̀ṣẹ̀ ni yíyàn kan wà láti máṣe ṣe ìnfọ́nkiri àwòṣe tàbí àwọn ìbáṣepọ̀ tí kò péye nínú àwọn ẹbí wa tàbí níbòmiràn. Sí ẹni gbogbo ní abẹ́ ipá wa, a le ṣe àánú fún ìrorò, ìfẹ́ fún ìkórĩra, ìwà tútù fún àìbìkítà, ààbò fún ewu, àti àlàáfíà fún ìjà.

Láti fúnni ní ohun tí wọ́n ti fi dunni jẹ́ apákan tí ó lágbára nínú ìwòsàn àtọ̀runwá tí ó ṣeéṣe nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì. Láti gbé nínú irú ọ̀nà bẹ́ẹ̀ tí ẹ ó fúnni, bí Isáíàh ti sọ, ẹwà fún eérú ti ìgbé ayé wa18 jẹ́ ìṣe ìgbàgbọ́ tí ó tẹ̀lé àpẹrẹ gígájùlọ ti Olùgbàlà ẹnití ó jìyà ohun gbogbo kí ó le ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ẹni gbogbo.

Jósẹ́fù ti Egíptì gbé ìgbé ayé pẹ̀lú eérú. A kórĩra rẹ̀ láti ọwọ́ àwọn arákùnrin rẹ̀, a jáa kulẹ̀, a tà á sí oko ẹrú, a fi í sí ẹ̀wọ̀n ní àìtọ́, a sì gbàgbé rẹ̀ nípasẹ̀ ẹnití ó ṣèlérí láti ṣe ìrànwọ́. Síbẹ̀ ó gbẹ́kẹ̀ lé Olúwa. “Olúwa wà pẹ̀lú Jósẹ́fù”19 Ó sì ya àwọn àdánwò rẹ̀ sí sọ́tọ̀ sí ìbùkún àti ìdàgbàsókè ara rẹ̀—àti sí gbígba àwọn ẹbí rẹ̀ àti gbogbo Egíptì là.

Nigbàtí Jósẹ́fù pàdé àwọn arákùnrin rẹ̀ bíi olùdarí nlá kan ní Egíptì, ìdáríjì àti àtúnṣe ìwòye rẹ̀ fi ara hàn nínú àwọn ọ̀rọ̀ olóore tí ó sọ:

“Nítorínáà nísisìyí, ẹ máṣe banújẹ́, kí ẹ má sì ṣe bínú sí ara yín, pé ẹ̀yín tà mí sí ìhín: nítorí pé Ọlọ́run ni ó rán mi ṣíwájú yín láti gba ẹ̀mí là. …

“Njẹ́ nísisìyí kì í ṣe ẹ̀yin ni ó rán mi sí ìhín, bíkòṣe Ọlọ́run.”20

Nípasẹ̀ Olùgbàlà, ìgbé ayé Jósẹ́fù di “ẹwà fún eérú”21

Kevin J. Worthen, ààrẹ BYU, ti sọ pé Ọlọ́run “le mú kí rere wá … Kìí ṣe láti inú àwọn àṣeyọrí wa nìkan ṣùgbọ́n bákannáà láti inú àwọn ìjákulẹ̀ wa àti àwọn ìjákulẹ̀ àwọn ẹlòmíràn tí ó nfa ìrora fún wa. Ọlọ́run ṣe bẹ́ẹ̀ dára Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ lágbára.”22

Mo jẹ́ríì pé àpẹrẹ ti ìfẹ́ àti ìdáríjì tí ó ga jùlọ ni ti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, ẹnití ó wí nínú ìrora ìkorò pé, “Baba, dáríjì wọ́n; nítorí wọn kò mọ ohun tí wọ́n ṣe.”23

Mo mọ̀ pé Baba wa ní Ọ̀run fẹ́ ire àti ìrètí fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ Rẹ̀. Nínú Jeremíàh a kà pé, “Nítorí èmi mọ èrò tí mo rò sí i yín, ni Olúwa wí, àní èrò àlàáfíà.”24

Jésù Krístì ni Messia ti araẹni yín, olùfẹ́ni Olùràpadà ati Olùgbàlà yín, ẹnití ó mọ àwọn ẹ̀bẹ̀ ọkàn yín. Ó nfé ìwòsàn àti ìdùnnú yín. Ó fẹ́ràn yín. Ó nsunkún pẹ̀lú yín nínú ìbànújẹ́ yín, Ó sì nyọ̀ láti sọ yín di pípé. Njẹ́ kí a le mọ́kàn kí a sì gba ọwọ́ ìfẹ́ni Rẹ̀ tí ó máa nnà títí25 bí a ṣe nrìn ní ipa ọ̀nà ìwòsàn ti ìdáríjì ni àdúrà mi ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.