Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìdáhùn Náà Ni Jésù
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2022


Ìdáhùn Náà Ni Jésù

Bí ó ti wù kí àwọn ìpèníjà náà ṣòro tàbí dojúrú tó, ẹ le fi ìgbà gbogbo rántí pé ìdáhùn náà rọrùn; nígbà gbogbo ni ó jẹ́ Jésù.

Ó ti jẹ́ iyì tó láti bá yín sọ̀rọ̀ nínú abala ìpàdé àpapọ̀ yí. Lóni mo nbá yín sọ̀rọ̀ bí ọ̀rẹ́. Nínú Ìhìnrere ti Jòhánnù, Olùgbàlà kọ́ni pé a jẹ́ ọ̀rẹ́ Rẹ̀ bí a bá ṣe ohun tí Ó sọ pé kí a ṣe.1

Ìfẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan wa àti ti àpapọ̀ fún Olùgbàlà, àti àwọn májẹ̀mú wa pẹ̀lú Rẹ̀, ni ó so wá papọ̀. Bí Ààrẹ Eyring ti kọ́ni: “Sí yín mo fẹ́ láti sọ bí Olúwa ti fẹ́ràn yín àti bí Ó ti gbẹ́kẹ̀ lé yín tó. Àti, àní púpọ̀ síi, mo fẹ́ láti sọ fún yín bí Ó ti gbára lé yín tó.”2

Nígbàtí a pè mí bíi Aláṣẹ Gbogbogbò nípasẹ̀ Ààrẹ Nelson, mo kún fún àwọn ẹ̀dùn ọkàn. Ó ní agbára jù. Ìyàwó mi, Julie, àti èmi ndúró pẹ̀lú taratara fún abala ọ̀sán Sátidé ti ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò. Ó jẹ́ ohun tó rẹnisílẹ̀ láti di láti di mímúdúró. Pẹ̀lú ìṣọ́ra mo ka àwọn ìgbésẹ̀ mi sí ibi ìjókòó mi kí nmá ba ṣubú nínú iṣẹ́ yíyàn mi àkọ́kọ́.

Ní ìparí abala náà, ohun kan ṣẹlẹ̀ tí ó ní ipa ìjìnlẹ̀ lára mi. Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ iyejú ṣe ìlà kan wọ́n sì kí wa ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ṣe àbápín ìfẹ́ àti àtìlẹ́hìn wọn. Pẹ̀lú abrazo àtọkànwá wọ́n sọ pé, “Má dààmú—o jẹ́ ara wa.”

Nínú ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Olùgbàlà, Ó máa nwo ọkàn kìí sì ní ìwúrí sí ènìyàn.3 Ẹ gba bí Ó ti yan àwọn Àpóstélì Rẹ̀ rò. Kò kọbiara sí ipò tàbí ọrọ̀. Ó npè wa láti tẹ̀lé Òun, mo sì gbàgbọ́ pé Ó tún nfii dáwalójú pé a jẹ́ ọ̀kan pẹ̀lú Rẹ̀.

Ọ̀rọ̀ yí ní í ṣe nípàtàkì sí àwọn ọ̀dọ́ nínú Ìjọ. Mo rí nínú yín ohún tí Ààrẹ Nelson rí nínú yín. Ó sọ pé “ohun pàtàkì tí kò ṣeé sẹ́ kan wà nípa ìran àwọn ọ̀dọ́ yi. Baba yín Ọ̀run gbọ́dọ̀ ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nlá nínú yín láti rán yín sí ilẹ̀ ayé ní àkókò yí. A bíi yín fún láti di nlá!”4

Mo fi ìmoore hàn fún ohun tí mo ti kọ́ láti ara àwọn ọ̀dọ́. Mo fi ìmoore hàn fún ohun tí àwọn ọmọ mi kọ́ mi, fún ohun tí àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere kọ́ mi, àti fún ohun tí àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n ọmọ àbúrò lọ́kùnrin lóbìnrin ti kọ́ mi.

Kò pẹ́ púpọ̀ sẹ́hìn, mo nṣiṣẹ́ nínó oko wa pẹ̀lú ọmọ ẹ̀gbọ́n mi Nash. Ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́fà ó sì ní ọkàn mímọ́. Òun ni ààyo mi orúkọ rẹ̀ ni Nash, mo sì gbàgbọ́ pé èmi ni ààyò ọnkú rẹ̀ náà tó nsọ̀rọ̀ nínú ìpàdé àpapọ̀ lóni.

Bí ó ti ràn mí lọ́wọ́ pẹ̀lú ojútùú kan sí iṣẹ́ wa, mo sọ pé, “Nash, èrò nlá gidi ni èyí. Báwo ni o ṣe já fáfá tóbẹ́ẹ̀?” Ó wò mí pẹ̀lú ìwò kan ní ojú rẹ̀ tí ó sọ pé, “Ọnkú Ryan, báwo ni ẹ̀yin ò ṣe mọ ìdáhùn sí ìbéèrè yí?

Ó kàn sọ èjìká rẹ̀, ó rẹ́rĩn, àti pẹ̀lú ìdára-ẹni-lójú ó wí pé, “Jésù”

Nash ránmi létí ní ọjọ́ náà nípa ìkọ́ni rírọrùn àti síbẹ̀ jíjinlẹ̀ yí. Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tó rọrùn jùlọ àti sí ìṣoro tí ó díjú jùlọ jẹ́ ọ̀kannáà nígbà gbogbo. Ìdáhùn náà ni Jésù Krístì. Gbogbo ojútùú ni a nrí nínú Rẹ̀.

Nínú Ìhìnrere ti Jòhánnù, Olùgbàlà sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀ pé Òun ó pèsè ààye kan fún wọn. Tómãsì ní ìpòrúrù ọkàn ó sì wí fún Olùgbàlà pé:

“Olúwa, àwa kò mọ ibití ìwọ nlọ; báwo ni àwa ó sì ṣe mọ ọ̀nà?

“Jésù wí fun pé, èmi ni ọ̀nà, ati òtítọ́, ati ìyè: kò sí ẹnikẹ́ni tí ó le wá sí ọ̀dọ̀ Bàbá, bíkòṣe nípasẹ̀ mi.”5

Olùgbàlà kọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀ pé Òun ni ọ̀nà, òtítọ́, àti ìyè. Òun ni ìdáhùn sí ìbéèrè nípa bí a ṣe le wá sí ọ̀dọ̀ Baba Ọ̀run. Gbígba ẹ̀rí kan ní ti ipa àtọ̀runwá Rẹ̀ nínú ayé wa jẹ́ ohun kan tí mo kọ́ bíi ọ̀dọ́mọkùnrin.

Nígbàtí mo nsìn bíi ìránṣẹ́ ìhìnrere ní Argentina, Ààrẹ Howard W. Hunter pè wá láti ṣe ohun kan tí ó ní ipa jíjinlẹ̀ lórí ayé mi. Ó sọ pé: “A gbọ́dọ̀ mọ Krístì ju bí a ṣe mọ̀ ọ́; a gbọ́dọ̀ rántí Rẹ̀ nígbà gbogbo síi ju bí a ti nrántí rẹ̀; a gbọ́dọ̀ sìn ín pẹ̀lú ìgboyà síi ju bí a ti nsìn ín.”6

Ní àkókò náà, mo ti ní àníyàn pẹ̀lú bí mo ti le jẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere dáradára síi. Ìdáhùn náà nìyí—láti mọ Krístì, láti rántí Rẹ̀, àti láti sìn Ín. Àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere jákèjádò àgbáyé ní ìṣọ̀kan nínú èrèdí yí: láti pe “àwọn ẹlòmíràn wá sí ọ̀dọ̀ Krístì nípa rírànwọ́nlọ́wọ́ gba ìhìnrere tí a mú padàbọ̀ sípò nípa ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀ àti Ètùtù Rẹ̀” àti nípasẹ̀ ìrònúpìwàdà, ìrìbọmi, gbígba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, àti fífi ara dà dé òpin.”7 Sí àwọn ọ̀rẹ́ wa tí wọ́n ntẹ́tísí àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere, mo ṣe àfikún ìfipè láti wá sí ọ̀dọ̀ Krístì. Lápapọ̀ a ó tiraka láti mọ̀ Ọ́, láti rántí Rẹ̀, àti láti sìn Ín.

Sísìn ní mísọ̀n jẹ́ àkókò mímọ́ ti ìgbé ayé mi. Nínú ìfọrọ̀wérọ̀ mi tó gbẹ̀hìn pẹ̀lú rẹ̀ bíi ìránṣẹ́ ìhìnrere ní kíkún, Ààrẹ Pincock sọ nípa ìyípadà tó nbọ̀ sí àwọn olúdàrí mísọn, bí òun àti ìyàwó rẹ̀ náà tí nsúnmọ́ ìpárí iṣẹ́ ìsìn wọn. Inú àwa méjèèjì bàjẹ́ láti máa fi ohun kan tí a fẹ́ràn púp\ọ̀ sílẹ̀. Ó le ríi pé mo ní ìdààmú nípa ìrònú ti àìjẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere ní kíkún. Ó jẹ ènìyan tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ga púpọ̀, ó sì fi pẹ̀lú ìfẹ́ni kọ́ mi bí ó ti ṣe fún àwọn ọdún méjì tó kọjá. Ó náwọ́ sí àwòrán Jésù Krístì ní orí tábìlì rẹ̀ ó sì wí pé, “Alàgbà Olsen, gbogbo rẹ̀ nbọ̀ wá dára nítorípé iṣẹ́ Rẹ̀ ni.” Mo ní ìmọ̀lára ìdánilójú ní mímọ̀ pé Olùgbàlà yío ràn wá lọ́wọ́, kìí ṣe nígbàtí a nsìn nìkan ṣùgbọ́n nígbà gbogbo, bí a bá jẹ́kí Òun ṣe bẹ́ẹ̀.

Síbẹ̀ ó kọ́wa láti inú àwọn ibú ọkàn rẹ̀ ní àwọn gbólóhùn èdè Spain tó rọrùn jùlọ. Nígbàtí ó bá sọ pé, “Jesucristo vive,” mo mọ̀ pé ó jẹ́ òtítọ́ àti pé Ó wà láàyè. Nígbàtí ó bá sọ pé, “Elderes y hermanas, les amo,” mo mọ̀ pé ó fẹ́ràn wa ó sì fẹ́ kí á tẹ̀lé Olùgbàlà, nígbà gbogbo.

Ìyàwó mi àti èmi jẹ́ alábùkún láìpẹ́ yí láti sìn bíi olùdarí mísọ̀n láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere pàtàkì ní Uruguay. Èmi ó sọ pé àwọn wọ̀nyí ni ìránṣẹ́ ìhìnrere tó dára jùlọ ní àgbáyé, mo sì gbàgbọ́ pé gbogbo olùdarí míṣọ̀n ní ìmọ̀lára lọ́nà yí. Àwọn ọmọ ẹ̀hìn wọ̀nyí kọ́ wa ní ojojúmọ́ nípa títẹ̀lé Olùgbàlà.

Ní àkókò àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tó máa nwáyé, ọ̀kan lára àwọn arábìnrin ìránṣẹ́ ìhìnrere wa rìn wọnú ọ́físì. Ó jẹ́ aláṣeyege ìránṣẹ́ ìhìnrere, olùkọ́ni tó dára gidi, àti olùdarí tó ní ìfọkànsìn Àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ gbójú lé e àwọn ènìyàn sì fẹ́ràn rẹ̀. Ó jẹ́ olùgbọ́ràn, ,o nítẹríba, ó sì mí ìgbẹ́kẹ̀lé ara ẹni., Àbẹ̀wò wa ìṣaájú dá lórí agbègbè rẹ̀ àti àwọn ènìyàn tí ó nkọ́. Àbẹ̀wò èyí ti yàtọ̀. Bí mo ti bií léèrè pé báwo ni ó ti nṣe, mo le sọ pé ó ní ìdààmú. Ó sọ pé, “Ààrẹ Olsen, èmi kò mọ̀ bóyá mo le ṣe èyí. Èmi kò mọ̀ bóyá mo le dára tó láé. Emi kò mọ̀ bí èmi bá le jẹ́ irú ìránṣẹ́ ìhìnrere tí Olúwa nílò mi láti jẹ́.”

Ó jẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere àrà ọ̀tọ̀ kan. Àrà ọ̀tọ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Irú èyí tí ààrẹ mísọ̀n fi nlá àlá. Èmi kò ti ṣàníyàn nípa àwọn agbára rẹ̀ bíi ìránṣẹ́ ìhìnrere.

Bí mo ti fetísílẹ̀ sí i, mo ntiraka láti mọ ohun tí èmi ó sọ. Mo gbàdúrà jẹ́jẹ́: “Baba Ọ̀run, ìránṣẹ́ ìhìnrere àrà ọ̀tọ̀ kan nìyí. Ó jẹ́ tìrẹ. Ó nṣe ohun gbogbo bí ó títọ́. Èmi kò fẹ́ ba eléyí jẹ́. Jọ̀wọ́ rànmí lọ́wọ́ láti mọ ohun tí èmi ó sọ.”

Àwọn ọ̀rọ̀ náà tọ̀ mí wá. Mo wí pé, “Hermana, mo kaanu gan pé o nní irú ìmọ̀lára yí. Jẹ́kí nbí ọ́ ní ìbéèrè kan. Bí o bá ní ọ̀rẹ́ kan tí o nkọ́ tí ó ní irú ìmọ̀lára yí, kínni ìwọ yío sọ?”

Ó wò mí ó sì rẹ́rĩn. Pẹ̀lú ẹ̀mí àti ìdánilójú ìránṣẹ́ ìhìnrere tí ó hàn kedere, ó sọ pé, “Ààrẹ, èyíinì rọrùn. Èmi ó sọ fún un pé Olùgbàlà mọ̀ ọ́ ní pípé. Èmi ó sọ fún un pé Ó wà láàyè. Ó fẹ́ràn rẹ̀. O dára tó, ìwọ sì ti ní èyí!”

Pẹ̀lú ẹ̀rín kékeré ó sọ pé, “Mo rò pé bí èyí bá wúlò fún àwọn ọ̀rẹ́ wa, ó wúlò fún èmi náà nígbànáà.”

Nígbàtí a bá ní àwọn ìbéèrè tàbí àwọn iyèméjì, a le ní ìmọ̀lára pé àwọn ìyanjú ti díjú jù tàbí pé rírí àwọn ìdáhùn ti jẹ́ ìdààmú jù. Njẹ́ kí a le rántí pé ọ̀tá, àní baba gbogbo àwọn irọ́, ni olùdásílẹ̀ ìrúkèrúdò.7

Olùgbàlà jẹ́ Olúwa ìrọ̀rùn.

Ààrẹ Nelson ti kọ́ni:

Ọ̀tá jẹ́ olùjáfáfá. Fún mìllẹ́níà òun ti mú rere dàbí ibi àti ibi dàbí rere.7 Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí pé ó npariwò, ó gbójú, ó sì nfọ́nnu.

Ṣùgbọ́n, àwọn ọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Bàbá wa Ọ̀run nyàtọ̀ pẹ̀lú yíyanilẹ́nu. Ó nbánisọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìrọ̀rùn, jẹ́jẹ́, àti pẹ̀lú irú ṣíṣe kedere tí ó yanilẹ́nu tó bẹ́ẹ̀ tí a kò lè ṣe àìní ìmọ̀ Rẹ̀.”8

A ti ní ìmoore tó pé Ọlọ́run fẹ́ràn wa tóbẹ́ẹ̀ tí Ó rán Ọmọ Rẹ̀. Òun ni ìdáhùn náà.

Ààrẹ Nelson sọ:

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ìhìnrere Jésù Krístì kò tíì jẹ́ nínílò rí láé ju bí ó ti jẹ́ ní òní.

“… Èyí ṣe àmì sí ìnílò kíakía fún wa láti tẹ̀lé àṣẹ Olúwa sí àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ láti ‘lọ …sí gbogbo ayé, kí wọ́n sì wàásù ìhìnrere sí gbogbo ẹ̀dá.’”10

Sí àwọn wọnnì tí wọn ó yàn láti sìn, mo le jẹ́ ẹ̀rí sí àwọn ìbùkún tí yío wá bí ẹ ti ngbọ́ràn sí ìpè wòlíì. Sísìn kìí ṣe nípa yín; ó jẹ́ nípa Olùgbàlà. A ó pè yín sí ibikan, ṣùgbọ́n ní pàtàkì jùlọ a ó pè yín sí àwọn ènìyàn kan. Ẹ ó ní ojúṣe àti ìbùkún nlá náà ti ríran àwọn ọ̀rẹ́ titun lọ́wọ́ ní òye pé ìdáhùn náà ni Jésù.

Èyí ni Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, àti pé ti ibí yí ní àwa í ṣe. Gbogbo ohun tí Ààrẹ Nelson ti gbàwá níyànjú pẹ̀lú ìfẹ́ni láti ṣe yíò darí wa súnmọ́ Olùgbàlà pẹ́kípẹ́kí.

Àwọn ọ̀dọ́ nlá wa—nínú èyítí ọmọ ẹ̀gbọ́n mi Nash wà—jákèjádò ìgbé ayé yín, bí ó ti wù kí àwọn ìpèníjà náà ṣòro tàbí dojúrú tó, ẹ le fi ìgbà gbogbo rántí pé ìdáhùn náà rọrùn: nígbà gbogbo ni ó jẹ́ Jésù.

Bí mo ti gbọ́ tí àwọn tí a mú dúró bíi wòlíì, àwọn aríran, àti àwọn olùfihàn sọ̀rọ̀ ní àwọn ìgbà púpọ̀, èmi bákannáà sọ pé a fẹ́ràn yín, a dúpẹ́ lọ́wọ́ yín, a sì nílò yín. Èyí ni ti ibi tí ẹ í ṣe.

Mo fẹ́ràn Olùgbàlà. Mo jẹ́ ẹ̀rí orúkọ Rẹ̀, àní Jésù Krístì. Mo jẹ́ri pé Òun ni Olùpilẹ̀sẹ̀ àti Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa,”11 Òun sì ni Olùkọ́ni ìrọ̀rùn. Ìdáhùn náà ni Jésù Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.