Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Nínú Àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Olúwa
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2022


Nínú Àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Olúwa

Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere ti Jésù Krístì kéde ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ti àjọṣepọ̀ kíkún ní àárín ọkùnrin àti obìnrin, méjèjì ní ayé ikú àti ní ayérayé.

Ní àwọn oṣù díẹ̀ àkọ́kọ́ ti ìgbéyàwó wa, ìyàwó mi ọ̀wọ́n fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn láti kẹ́kọ orin. Níní èrò láti mú inú rẹ̀ dùn, mo pinnu láti ṣe ìyanu nlá, àtọkànwá fún ẹni bí ọkàn mi. Mo lọ sí ilé-ìtàjà àwọn ohun-èlò olórin mo sì ra dùrù bí ẹ̀bùn kan fun. Mo fi inúdídùn fi ìwé ọjà náà sínú àpótí kan pẹ̀lú ẹ̀ṣọ́ rírẹwà kan mo sì fi fún un, ní ìrètí ìtújáde ìwà ìmoore fún olùfẹ́ni àti olùfarabalẹ̀ aláìníwọ̀n ọkọ rẹ̀.

Nígbàtí ó ṣí àpótí kékeré náà tí ó sì rí ohun tó wà níbẹ̀, ó wò mí pẹ̀lú ìfẹ́ ó sì wípé, “Ah, àyànfẹ́ mi, o jẹ́ oníyanu! Ṣùgbọ́n jẹ́ kí nbèèrè ìbèèrè kan lọ́wọ́ rẹ: ṣe ẹ̀bùn ni èyí tàbí gbèsè?” Lẹ́hìn dídámọ̀ràn papọ̀ nípa ìyanu náà, a pinnu láti dá ọjà náà padà. À ngbé lórí ìṣúná akẹ́kọ, bí ọ̀ràn náà ti jẹ́ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìgbeyàwó. Ìrírí yí ràn mí lọ́wọ́ láti dá ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ pàtàkì ti àjọṣepọ̀ kíkún nínú ìbáṣepọ̀ ìgbeyàwó àti bí lílò rẹ̀ ṣe lè ran ìyàwó mi lọ́wọ́ àti ẹ̀mi láti jẹ́ ọ̀kan kan àti inú kan.1

Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere ti Jésù Krístì kéde ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ti àjọṣepọ̀ kíkún ní àárín ọkùnrin àti obìnrin, méjèjì ní ayé ikú àti ní ayérayé. Bíótilẹ̀jẹ́pé ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ìwà àti ojúṣe yíyàn àtọ̀runwá pàtó, obìnrin àti ọkùnrin kún ojúṣe ìbádọ́gba pàtàkì àti kókó nínú ètò ìdùnnú Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Rẹ̀.2 Èyí hàn láti ìbẹ̀rẹ̀ gan an nígbàtí Olúwa kéde pé “kò dára kí ọkùnrin kí ó nìkan wà; nítorínáà [Òun yíò] ṣe olùrànlọ́wọ́ kan fún un.”3

Nínú ètò Olúwa, “olùrànlọ́wọ́” kan ni ojúgbà ẹnití yíò rìn ní èjìká sí èjìká pẹ̀lú Ádámù nínú àjọṣepọ̀ kíkún.4 Nitootọ́, Éfà jẹ́ ìbùkún tọ̀run nínú ayé Ádámù. Nípasẹ̀ ìwà-ẹ̀dá tọ̀run àti ìwà ti-ẹ̀mí rẹ̀, ó nmísí Ádámù láti ṣiṣẹ́ ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ láti ṣe àṣeyọrí ètò ìdùnnú fún gbogbo ènìyàn.5

Ẹ jẹ́ kí a yẹ àwọn kókó ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ tí ó nfún àjọṣepọ̀ lókun làárín ọkùnrin àti obìnrin lókun. Ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ àkọ́kọ́ ni pé gbogbo wa rí bákannáà sí Ọlọ́run.6 Gẹ́gẹ́bí ẹ̀kọ́ ìhìnrere, ìyàtọ̀ ní àárín obìnrin àti ọkùnrin kò yí àwọn ìlérí ayérayé tí Ọlọ́run ní fún àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ́ dànù. Ẹnìkan kò ní àwọn ìṣeéṣe títóbijùlọ fún ògo sẹ̀lẹ́stíà ju òmíràn nínú ayérayé.7 Olùgbàlà Fúnrarẹ̀ pe gbogbo wa, àwa ọmọ Ọlọ́run, láti wá sọ́dọ̀ Rẹ, láti ṣe àbápín ìwàrere Rẹ̀, Òun kò sì sẹ́ ẹnikẹ́ni tí ó bá wá sọ́dọ̀ Rẹ̀.”8 Nítorínáà, nínú ọ̀ràn yí, gbogbo wa ní ó dọ́gba níwájú Rẹ̀.

Nígbàtí àwọn lọ́kọ-láyà bá ní ìmọ̀ tí wọ́n sì fi ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ yí sínú rẹ̀, wọn kìí fi arawọn sípò bí ààrẹ tàbí igbákejì ààrẹ ẹbí wọn. Kò sí gígajù tàbí kíkéréjù nínú ìbáṣepọ̀ ìgbéyàwó, bẹ́ẹ̀ni ẹnìkan kò rìn síwájú tàbí lẹ́hìn èkejì. Wọ́n ńrìn lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́, gẹ́gẹ́bí dídọ́gba, àwọn àtọ̀runwá ọmọ Ọlọ́run. Wọ́n di ọ̀kan ní èrò, ìfẹ́-ọkàn, àti ète pẹ̀lú Baba wa Ọ̀run àti Jésù Krístì,9 tí ndarí àti ṣamọ̀nà ìrẹ́pọ̀ ẹbí papọ̀.

Nínú àjọṣepọ̀ dídọ́gba kan, “ìfẹ́ kìí ṣe ìní ṣùgbọ́n ìkópa … ara olùṣẹ̀dá-ìṣẹ̀dá náà èyí tí ó jẹ́ ìpè ènìyàn.”10 “Pẹ̀lú ìkópa tòótọ́, ọkọ àti aya parapọ̀ sínú ọ̀kan ‘ìjọba àìlópin’ ti´ ‘àìsí ìtumọ pípọndandan’ yíò ṣàn pẹ̀lú ìyè sí wọn àti àtẹ̀lé wọn ‘títíláé àti láéláé.’”11

Ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ pàtàkì ni Òfin ti Wúrà, tí a kọ́ni nípasẹ̀ Olùgbàlà nínú Ìwàásù orí Òkè: “Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin sì ti fẹ́ kí ènìyàn kí ó ṣe sí yín, kí ẹ̀yin kí ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn pẹ̀lú.”12 Ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ yí fi ìwà ìbámu, pàṣípàrọ̀, ìrẹ́pọ̀, àti rírọ̀mọ́ tí ó sì dá lé òfin nlá kejì “Ìwọ yíò fẹ́ran ẹnìkejì rẹ bí ararẹ.”13 Ó darapọ̀ pẹ̀lú àwọn ìwà Krístẹ́nì míràn bíiti ìpamọ́ra, ìwà-pẹ̀lẹ́, ìwà-tútù, àti inúrere.

Láti ní ìmọ̀ ìbèèrèfún ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ yí dáadáa, a lè wo ìsopọ̀ mímọ́ àti ayérayé tí a gbékalẹ̀ nípasẹ̀ Ọlọ́run ní àárín àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà. Wọ́n di ọ̀kan,14 dídá ọ̀nà ìrẹ́pọ̀ tí ó fi ààyè gbà wọ́n láti rìn papọ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀, ìmoore, àti ìfẹ́, gbígbàgbé nípa arawọn àti wíwà ní àláfíà arawọn ní ìrìnàjò wọn sí ayérayé.

Àwọn irú ìhùwàsí kannáà ni ohun tí à ntiraka fún nínú ìrẹ́pọ̀ ìgbeyàwó ní òní. Nípa èdidì tẹ́mpìlì, obìnrin kan àti ọkùnrin kan nwọnú ètò mímọ́ ti ìgbeyàwó nínú májẹ̀mú titun ati ti àìlópin. Nípa ọ̀nà ti ètò oyè-àlùfáà yí, a fún wọ́n ní àwọn ìbùkún àti agbára tọ̀run láti darí àkóso ẹbí wọn bí wọ́n ti ngbé gẹ́gẹ́bí àwọn májẹ̀mú tí wọ́n ti dá. Láti ìgbà náà lọ, wọ́n tẹ̀ síwájú pẹ̀lú rírọ̀mọ́ àti àjọṣepọ̀ kíkún pẹ̀lú Olúwa, nípàtàkì ní ìkàsí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ojúṣe yíyàn tọ̀run ní títọ́jú àti ṣíṣe àkóso nínú ẹbí.15 Títọ́jú àti ṣíṣe báramu àti pé àwọn ojúṣe gbígbékọjá ni, èyí tí ó túmọ̀ sí pé àwọn ìyá àti baba “ní ojúṣe láti ran arawọn lọ́wọ́ bí alábáṣe dídọ́gba”16 àti láti ṣe àbápín jíjẹ́ olórí ti ilé wọn.

“Láti tọ́jú túmọ̀ sí kíkẹ́, kíkọ́, àti títi” àwọn ọmọ ẹbí lẹ́hìn, èyí ni a nṣe nípa ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti “kọ́ àwọn òtítọ́ ìhìnrere àti láti mú ìgbàgbọ́ nínú Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì gbèrú ní àyíká ìfẹ́. Láti ṣe àkóso túmọ̀ sí láti “ṣèrànwọ́ láti darí àwọn ọmọ ẹbí padà láti gbé ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Èyí ni a nṣe nípa sísìn àti kíkọ́ni pẹ̀lú ìwà-pẹ̀lẹ́, ìwà-tútù, àti ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́.” Bákannáà ó pẹ̀lú “dídarí àwọn ọmọ ẹbí nínú àdúrà, àṣàrò ìhìnrere, àti àwọn ìjọsìn míràn. Àwọn òbí nṣiṣẹ́ nínú ìrẹ́pọ,” ní títẹ̀lé àpẹrẹ Jésù Krístì, “láti mú àwọn ojúṣe [méjì nlá] ṣẹ.”17

Ó ṣe pàtàkì láti ṣe àkíyèsí pé ìjọba nínú ẹbí tẹ̀lé àwòṣe ti-babanla, ó yàtọ̀ nínú àwọn kan tí ó kúrò ní jíjẹ́ olórí oyè-àlùfáà nínú ìjọ.18 Àwòṣe ti-babanla ní pé àwọn aya àti ọkọ ní ìjihìn tààrà sí Ọlọ́run fún ìmúṣẹ àwọn ojúṣe mímọ́ wọn nínú ẹbí. Ó pè fún àjọṣepọ̀ kíkún—níní ìfẹ́ gbígba gbogbo ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ti òdodo àti ìjihìn—àti pípèsè àwọn ànfàní fún gbígbèrú nínú àyíká ìfẹ́ àti ìbádọ́gba rírannilọ́wọ́.19 Àwọn ojúṣe pàtàkì wọ̀nyí kò fi ìgbéga hàn kò sì yọ irú ìlòkulò kankan sílẹ̀ pátápátá tàbí lílo àṣẹ ní àìtọ́.

Ìrírí Ádámù àti Éfà, lẹ́hìn tí wọ́n fi Ọgbà Édẹ́nì sílẹ̀, fi ẹwà júwe èrò rírọ̀mọ́ àárín ìyá kan àti baba ní títọ́jú àti ṣíṣe àkóso lórí ẹbí wọn. Bí a ti kọ́ni nínú ìwé Mose, wọ́n ṣiṣẹ́ papọ̀ láti roko nípa óógùn ojú wọn ní èrò láti pèsè fún wíwà dáadáa ti ẹbí wọn;20 wọ́n tọ́ àwọn ọmọ wọn sínú ayé;21 wọ́n npe orúkọ Olúwa papọ̀ wọ́n sì ngbọ́ ohùn Rẹ̀ “láti ọ̀nà síwájú Ọgbà Édẹ́nì”;22 wọ́n gba àwọn òfin tí Olúwa fún wọn wọ́n sì ntiraka papọ̀ láti gbọ́ran sí wọn.23 Nígbànáà wọ́n “fi àwọn ohun [wọ̀nyí] hàn sí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn”24 “wọn kò sì dáwọ́dúró láti pè Ọlọ́run” papọ̀ gẹ́gẹ́bí àwọn ìnílò wọn.25

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, títọ́jú àti ṣíṣé àkóso jẹ́ àwọn ànfàní, kìí ṣe ìdíwọ́ pátápátá. Ẹnìkan lè ní ojúṣe kan fún ohunkan ṣùgbọ́n kí ó má lè jẹ́ pé ẹnìkanṣoṣo ni ó nṣe é. Nígbàtí àwọn olùfẹ́ni òbí bá ní ìmọ̀ kókó àwọn ojúṣe méjì wọ̀nyí, wọn yíò tiraka papọ̀ láti dá ààbò bò àti láti ṣètọ́jú fún ti-ara àti ẹ̀dùn ọkàn wíwà ní àláfíà ti àwọn ọmọ wọn. Bákannáà wọ́n ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dojúkọ àwọn ewu ti ẹ̀mí ọjọ́ wa nípa títọ́jú wọn pẹ̀lú ọ̀rọ̀ rere Olúwa bí a ti fihan àwọn wòlíì Rẹ̀.

Bíótilẹ̀jẹ́pé ọkọ àti ìyàwó nti arawọn lẹ́hìn nínú àwọn ojúṣe tọ̀run tí a yàn, “àlébù, ikú, tàbí àwọn ipò míràn lè mú ìmúyẹ olúkúlùkù ṣeéṣe.”26 Nígbàmíràn lọ́kọláya kan tàbí òmíràn yíò ní ojúṣe ti ṣíṣe ìṣe nínú àwọn ojúṣe méjéjì papọ̀, bóyá ránpẹ́ tàbí títíláé.

Láìpẹ́ mo pàdé arábìnrin kan tí mo pàdé àti arákùnrin kan ẹni tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ngbé nínú ipò yí. Bí àwọn òbí àdáwà, ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn, nínú àyíká ẹbí wọn àti nínú àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Olúwa, ti pinnu láti fi gbogbo ayé wọn sí ìtọ́jú ti ẹ̀mí àti ti ara àwọn ọmọ wọn. Wọ́n ko sọ ìran àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì tí wọ́n dá pẹ̀lú Olúwa nù àti àwọn ìlérí ayérayé pẹ̀lú àwọn ìṣòro ìkọ̀sílẹ̀ wọn. Àwọn méjèjì nwá ìrànlọ́wọ́ Olúwa nínú àwọn ohun gbogbo bí wọ́n ti ntiraka nígbàgbogbo láti foríti àwọn ìpènijà wọn àti láti rìn nínú ipá-ọ̀nà májẹ̀mú. Wọ́n ni ìgbẹ́kẹ̀lé pé Olúwa yíò ṣe ìtọ́jú ti àwọn àìní wọn, kìí ṣe nínú ayé yí nìkan, ṣùgbọ́n ní gbogbo ayérayé. Àwọn méjejì ti tọ́jú àwọn ọmọ wọn nípa ìkọ́ni wọn pẹ̀lú ìwà-pẹ̀lẹ́, ìwà-tútù, àti ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ àní nígbàtí a bá nní ìrírí àwọn ipò ṣíṣòro nínú ayé. Nínú ohun tí mo mọ̀, àwọn òbí àdáwà méjì wọ̀nyí kò dá Ọlọ́run lẹ́bi fún ìpalára wọn Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n nwo iwájú pẹ̀lú ìrètí dídán pípé àti ìgbẹ́kẹ̀lé sí àwọn ìbùkún tí Olúwa ti fi sí ìṣura fún wọn.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìrnin, Olùgbàlà gbé àpẹrẹ pípé kalẹ̀ nípa ìrẹ́pọ̀ àti ìbámú èrèdí àti ẹ̀kọ́ Baba wa ní Ọ̀run. Ó gbàdúrà ní ìtìlẹhìn àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀, ní wíwí pé, “Kí gbogbo wọ́n kí ó lè jẹ́ ọ̀kàn; gẹ́gẹ́ bí bí ìwọ Baba, ti jẹ́ nínú mi, àti èmi nínú rẹ̀, kí àwọn pẹ̀lú kí ó lè jẹ́ ọ̀kan nínú wa: … kí wọ́n kí ó lè jẹ́ ọ̀kan, àní bí a ti jẹ́ ọ̀kannáà.”28

Mo jẹ́ri fún yín pé bí àwa—obìnrin àti ọkùnrin—ti nṣiṣẹ́ papọ̀ ní ìbáṣepọ̀ tòótọ́ tí ó sì dọ́gba, a ó gbádùn ìṣọ̀kan tí Olùgbàlà kọ́ wa bí a ti nmú àwọn ojúṣe àtọ̀runwá ṣẹ nínú àwọn àjọṣepọ̀ ìgbéyàwó wa. Mo ṣe ìlérí fún yín, ní orúkọ Krístì, pé ọkàn yíò “so pọ̀ ní ìṣọ̀kan àti ní ìfẹ́ ọ̀kan sí òmíràn,”28 a ó rí ayọ̀ púpọ̀ síi nínú ìrìn-àjò sí ìyè ayérayé, àti okun wa láti sin ara wa àti pẹ̀lú ara wa yíò pọ̀ si gidi.29 Mo jẹ́ri nípa àwọn òtítọ́ wọ̀nyí ní orúkọ mímọ́ ti Olùgbàlà Jésù Krístì, àmín.