Àwọn Ìwé Mímọ́
2 Nífáì 26


Ori 26

Krístì yíò ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ará Nífáì—Nífáì rí ìparun àwọn ènìyàn rẹ̀ tẹ́lẹ̀—Wọn yíò sọ̀rọ̀ láti inú eruku—Àwọn Kèfèrí yíò kọ́ àwọn ìjọ onígbàgbọ́ èké àti àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn—Olúwa dá àwọn ènìyàn lẹ́kun láti ṣe oyè àlùfã àrékérekè. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Lẹ́hìn ti Krístì yíò sì ti jínde kúrò nínú òkú òun yíò fi ara rẹ̀ hàn sí yín, ẹ̀yin ọmọ mi, àti ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́; àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí yíò sì sọ sí yín yíò jẹ́ òfin tí ẹ̀yin yíò ṣe.

2 Nítorí kíyèsĩ, mo wí fún yín pé mo ti kíyèsĩ pé ọ̀pọ̀ ìran yíò kọjá lọ, àwọn ogun nlá àti ìjà yíò sì wà lãrín àwọn ènìyàn mi.

3 Lẹ́hìn tí Messia nã yíò dé a ó fi àwọn àmì fún àwọn ènìyàn mi nípa ìbí rẹ̀, àti pẹ̀lú nípa ikú àti àjínde rẹ̀; títóbi àti tí ó banilẹ́rù sì ni ọjọ́ nã yíò jẹ́ sí àwọn ènìyàn búburú, nítorí wọn yíò parun; wọn yíò sì parun nítorí wọ́n sọ àwọn wòlĩ sóde, àti àwọn ènìyàn mímọ́, wọn yíò sì sọ wọ́n ní òkúta, wọn yíò sì pa wọ́n; nítorí-èyi igbe ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ yíò gòkè lọ bá Ọlọ́run láti ilẹ̀ sí wọn.

4 Nítorí-èyi, gbogbo àwọn tí ó gbéraga, tí ó sì nṣe búburú, ọjọ́ nã tí mbọ̀wá yíò jó wọn run, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí, nítorí wọn yíò dàbí àkékù koríko.

5 Àwọn tí ó sì pa àwọn wòlĩ, àti àwọn ènìyàn mímọ́, ibú ilẹ̀ yíò gbé wọn mì, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí; àwọn òkè nlá yíò sì bò wọ́n, ìjì yíò sì gbé wọn kúrò, àwọn ilé yíò sì wó sórí wọn yíò sì rún wọn sí tũtú yíò sì lọ̀ wọ́n sí ẹ̀tù.

6 A ó sì bẹ wọ́n wò pẹ̀lú àrá, àti mànàmáná, àti àwọn ilẹ̀ ríri, àti irú ìparun gbogbo, nítorí iná ìbìnú Olúwa yíò jó sí wọn, wọn yíò sì dàbí àkékù koríko, ọjọ́ nã tí mbọ̀wá yíò sì fi wọ́n jóná, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí.

7 A! ìrora nã, àti àròkàn ọkàn mi fún ìpàdánù àwọn ènìyàn mi tí a pa! Nítorí èmi, Nífáì, ti rí i, ó sì ti fẹ́rẹ̀ run mí níwájú Olúwa; ṣùgbọ́n èmi kò lè ṣe àìkígbe sí Ọlọ́run mi: Àwọn ọ̀nà rẹ jẹ́ títọ́.

8 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àwọn olódodo tí ó fetísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ àwọn wòlĩ, tí wọn kò sì pa wọ́n run, ṣùgbón tí wọ́n nwo iwájú sí Krístì pẹ̀lú ìdúróṣinṣin fún àwọn àmì tí a fi fún ni, l’áìṣírò ti inúnibíni gbogbo—kíyèsĩ, àwọn ni àwọn tí kì yíò parun.

9 Ṣùgbọ́n Ọmọ Òdodo yíò farahàn sí wọn; òun yíò sì wò wọ́n sàn, wọn yíò sì ní àlãfíà pẹ̀lú rẹ̀, títí ìran mẹ́ta yíò fi kọjá lọ, tí ọ̀pọ̀ nínú ìran ẹ̀kẹ́rin yíò sì ti kọjá lọ nínú òdodo.

10 Nígbàtí àwọn ohun wọ̀nyí bá ti kọjá lọ ìparun kánkán kan mbọ̀wá sórí àwọn ènìyàn mi; nítorí l’áìṣírò ọkàn mi ní ìrora, èmi ti rí i; nítorí-èyi, èmi mọ̀ pé yíò ṣẹ; wọn sì ta ara wọn fún asán; nítorí, fún èrè ìgbéraga wọn àti ẹ̀gọ̀ wọn wọn yíò kórè ìparun; nítorítí wọ́n yọ̃da fún èṣù tí wọ́n sì yan àwọn iṣẹ́ òkùnkùn sànju ti ìmọ́lẹ̀, nítorí-èyi wọn gbọ́dọ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀run àpãdì.

11 Nítorí Ẹ̀mí Olúwa kì yíò bá ènìyàn gbìyànjú nígbà-gbogbo. Nígbàtí Ẹ̀mí bá sì dáwọ́dúró láti bá ènìyàn gbìyànjú nígbànã ni ìparun kánkán yíò dé, èyí sì mú ọkàn mi kẹ́dùn.

12 Bí mo sì tí sọ̀rọ̀ nípa fífi òye yé àwọn Jũ, pé Jésù ni Krístì gan-an, o di dandan ki a fi òye yé àwọn Kèfèrí pẹ̀lú pé Jésù ni Krístì, Ọlọ́run Ayérayé;

13 Àti pé ó fi ara rẹ̀ hàn sí gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́ nínú rẹ̀, nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́; bẹ̃ni, sí gbogbo orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè, àti ènìyàn, tí ó nṣe iṣẹ́ ìyanu nlá, àmì àti ìyanu, lãrín àwọn ọmọ ènìyàn gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ wọn.

14 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, mo sọ tẹ́lẹ̀ sí yín nípa àwọn ọjọ́ ìkẹhìn; nípa àwọn ọjọ́ nígbàtí Olúwa Ọlọ́run yíò mú àwọn ohun wọ̀nyí jáde wá sí àwọn ọmọ ènìyàn.

15 Lẹ́hìn tí irú-ọmọ mi àti írú-ọmọ àwọn arákùnrin mi yíò ti rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́, tí a ó sì ti lù wọ́n nípa ọwọ́ àwọn Kèfèrí; bẹ̃ni, lẹ́hìn tí Olúwa Ọlọ́run yíò ti pa àgọ́ yí wọn ká, tí yíò sì ti gbógun tì wọ́n pẹ̀lú òkè, tí yíò sì gbé àwọn odi sókè sí wọn; àti lẹ́hìn tí a ó ti mú wọn wá sílẹ̀ nínú eruku, àní tí wọn kò sí, síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ olódodo ni a ó kọ, àwọn àdúrà àwọn olóotọ́ ni a ó sì gbọ́, a kò sì ní gbàgbé gbogbo àwọn wọnnì tí ó ti rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́.

16 Nítorí àwọn tí a ó parun yíò bá wọn sọ̀rọ̀ láti ilẹ̀ wá, ọ̀rọ̀ wọn yíò sì rẹ̀lẹ̀ láti inú eruku wá, ohùn wọn yíò sì dàbí ti ẹnìkan tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́; nítorí Olúwa Ọlọ́run yíò fi agbára fún un, kí ó lè sọ̀rọ̀ jẹ́jẹ́ nípa wọn, àní bí ẹnipé láti ilẹ̀ wá; ọ̀rọ̀ wọn yíò sì dún láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀ wá.

17 Nítorí báyĩ ni Olúwa Ọlọ́run wí: Wọn yíò kọ àwọn ohun tí a ó ṣe lãrín wọn, a ó sì kọ wọ́n a ó sì fi èdídì dì wọ́n ní ìwé, àwọn wọnnì tí ó ti rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́ kì yíò ní wọn, nítorí wọ́n nwá láti pa àwọn ohun Ọlọ́run run.

18 Nítorí-èyi, bí àwọn ti a ti parun wọnnì ni a ti parun kánkán; àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹni búburú wọn yíò dàbí ìyàngbò tí ó kọjá lọ—bẹ̃ni, báyĩ ni Olúwa Ọlọ́run wí: Yíò rí bẹ̃ nísisìyí, lójijì—

19 Yíò sì ṣe, tí a ó lu àwọn wọnnì tí ó ti rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́ nípa ọwọ́ àwọn Kèfèrí.

20 Àwọn Kèfèrí ni a sì gbé sí okè ní ìgbéraga ojú wọn, wọ́n sì ti kọsẹ̀, nítorí ti títóbi ohun ìkọ̀sẹ̀ wọn, tí wọ́n ti dá ìjọ onígbàgbọ́ púpọ̀ sílẹ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃, wọ́n kẹ́gàn agbára àti iṣẹ́ ìyanu Ọlọ́run, wọ́n sì nwãsù sí ara wọn ọgbọ́n tiwọn àti ẹ̀kọ́ tiwọn, kí wọ́n lè rí èrè kí wọ́n sì lọ̀ sórí ojú àwọn tálákà.

21 Òpọ̀lọ́pọ̀ ìjọ onígbàgbọ́ ni a sì dá sílẹ̀ tí ó nfa ìlara, àti ìjà, àti odì.

22 Àwọn ẹgbẹ̀ òkùnkùn sì wà pẹ̀lú, àní bí ti ìgbà àtijọ́, gẹ́gẹ́bí àwọn ẹgbẹ́ èṣù, nítorí òun ni olùdásílẹ̀ gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí; bẹ̃ni, olùdásílẹ̀ ìpànìyàn, àti àwọn iṣẹ́ òkùnkùn; bẹ̃ni, ó sì fà wọ́n pẹ̀lú okùn rírọ̀ lọ́rùn wọn, títí ìgbà tí ó ti fi dì wọ́n pẹ̀lú okùn líle rẹ̀ títí láé.

23 Nítorí kíyèsĩ i, ẹ̀yin arákùnrin mi ayanfẹ, mo wí fún yín pé Olúwa Ọlọ́run kì í ṣiṣẹ́ ní òkùnkùn.

24 Òun kì í ṣe ohunkóhun àfi tí ó bá jẹ́ fún èrè ayé; nítorí ó fẹ́ràn ayé, àní tí ó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ sílẹ̀ kí ó lé mú gbogbo ènìyàn wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Nítorí-èyi, kò pàṣẹ fún ẹníkẹ́ni pé wọn kì yíò pín nínú ìgbàlà rẹ̀.

25 Kíyèsĩ, njẹ́ ó kígbe sí ẹnikẹ́ni, wípé: Lọ kúrò lọ́dọ̀ mi bi? Kíyèsĩ i, mo wí fún yín, Rárá; ṣùgbọ́n ó wípé: Ẹ wá sọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin ikangun ayé, ẹ ra wàrà àti oyin, láìsí owó àti láìsí iye.

26 Kíyèsĩ i, òun ha ti pàṣẹ fún ẹnikẹ́ni pé kí wọ́n lọ kúrò nínú àwọn sínágọ́gù, tàbí kúrò ní àwọn ilé ìjọsìn? Kíyèsĩ i, mo wí fún yín, Rárá.

27 Òun ha ti pàṣẹ fún ẹnikẹ́ni pé kí wọ́n má ní ìpín nínú ìgbàlà rẹ̀? Kíyèsĩ i mo wí fún yin, rara; ṣùgbọ́n ó ti fi fún gbogbo ènìyàn ní ọ̀fẹ́; ó sì ti pàṣẹ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pe kí wọ́n gba gbogbo ènìyàn níyànjú sí ìrònúpìwàdà.

28 Kíyèsĩ i, Olúwa ha ti pàṣẹ fún ẹnikẹ́ní kí wọ́n má pín nínú õre rẹ̀? Kíyèsĩ i mo wí fún yín, Rárá; ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn ni ó ní ànfàní ọ̀kan bí ti èkejì, kò sì sí ẹnìkan tí a dá lẹ́kun.

29 Ó pàṣẹ pé kì yíò sí oyè àlùfã àrékérekè; nítorí, kiyesĩ, oyè àlùfã àrékérekè ni pé àwọn ènìyàn nwãsù wọ́n sì gbé ara wọn sókè fún ìmọ́lẹ̀ sí ayé, kí wọ́n lè rí èrè àti ìyìn ayé gbà; ṣùgbọ́n wọn kò wá àlãfíà Síónì.

30 Kíyèsĩ i, Olúwa ti ka ohun yí lẽwọ̀; nítorí-èyi, Olúwa Ọlọ́run ti fi òfin fún ni kí gbogbo ènìyàn kí ó ní ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́, ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ èyí tí nṣe ìfẹ́. Àti pé bí wọn kò bá ní ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ asán ni wọ́n. Nítorí-èyi, bí wọn bá ní ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ wọn kò ní yọ̃da fún àwọn àṣiṣẹ́ ní Síónì láti parun.

31 Ṣùgbọ́n àṣiṣẹ́ ní Síónì yíò siṣẹ́ fun Síónì; nítorí bí wọ́n bá siṣẹ́ fun owó wọn yíò parun.

32 Àti pẹ̀lú, Olúwa Ọlọ́run ti pàṣẹ pé kí àwọn aráyé máṣe pànìyàn; kí wọn máṣe purọ́; kí wọn máṣe jalè; kí wọn máṣe pe orúkọ Olúwa Ọlọ́run wọn lásán; kí wọn má ṣe ìlara; kí wọn máṣe yan odì; kí wọn máṣe bá ara wọn jà; kí wọn máṣe ní ìwà àgbèrè; àti kí wọn má ṣe èyíkéyí nínú àwọn ohun wọ̀nyí; nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe wọn yíò parun.

33 Nítorí èyíkéyí nínú àwọn àìṣedẽdé wọ̀nyí kò wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa; nítorí ó nṣe èyí tí ó dára lãrín àwọn ọmọ ènìyàn; kò sì ṣe ohunkóhun àfi tí ó ṣe kedere sí àwọn ọmọ ènìyàn; ó sì npe gbogbo wọn láti wá sọ́dọ̀ rẹ̀ kí wọ́n sì pín nínú õre rẹ̀; kò sì kọ̀ fún ẹnikẹ́ni tí ó bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀, dúdú àti funfun, tí ó wà nínú ìdè àti ní òmìnira, akọ àti abo; ó sì rántí àwọn abọ̀rìṣà; gbogbo wọn sì dàbí ọ̀kan sí Ọlọ́run, àti àwọn Jũ àti Kèfèrí.