Àwọn Ìwé Mímọ́
2 Nífáì 21


Ori 21

Kùkùté Jéssè (Krístì) yíò ṣe ìdájọ́ ní òdodo—Ìmọ̀ Ọ́lọ́run yíò bò ayé ní Ẹgbẹ̀rún-ọdún—Olúwa yíò gbé ọ̀págun sókè yíò sì kó Isráẹ́lì jọ—Fi Isaiah 11 wé e. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Ọ̀pa kan yíò sì jáde láti inú kùkùté Jéssè wá, ẹ̀ka kan yíò sì hù jáde láti inú gbòngbò rẹ̀.

2 Ẹ̀mí Olúwa yíò sì bà lée, ẹ̀mí ọgbọ́n àti òye, ẹ̀mí ìgbìmọ̀ àti agbára, ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ìbẹ̀rù Olúwa;

3 Yíò sì ṣe é ní òye tãrà ní ìbẹ̀rù Olúwa; òun kì yíò sì dájọ́ nípa ìrí ojú rẹ̀, bẹ̃ni kì yíò dájọ́ nípa gbígbọ́ etí rẹ̀.

4 Ṣùgbọ́n pẹ̀lú òdodo ni yíò ṣe ìdájọ́ àwọn tálákà, yíò sì báni wi pelu ìṣòtítọ́ fún àwọn ọlọ́kàn tútù ayé; òun yíò sì lu ayé pẹ̀lú ọ̀gọ ẹnu rẹ̀, àti pẹ̀lú ẽmí àwọn ètè rẹ̀ ni òun yíò sì pa àwọn ènìyàn búburú.

5 Òdodo yíò sì jẹ́ àmùrè ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, àti ìsọ̀títọ́ àmùrè inú rẹ̀.

6 Ìkõkò pẹ̀lú yíò ma bá ọ̀dọ́-àgùtàn gbé, ẹkùn yíò sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ọmọ ewúrẹ́, àti ọmọ màlũ àti ọmọ kìnìún àti ẹgbọ̀rọ̀ ẹran àbọ́pa papọ̀; ọmọ kékeré kan yíò sì ma dà wọ́n.

7 Àti màlũ àti béárì yíò sì ma jẹ; àwọn ọmọ wọn yíò dùbúlẹ̀ pọ̀; kìnìún yíò sì jẹ koríko bí màlũ.

8 Ọmọ ọmú yíò sì ṣiré ní ihò pãmọ́lẹ̀, ọmọ tí a já lẹ́nu-ọmú yíò sì fi ọ́wọ́ rẹ̀ sí ihò gùnte.

9 Wọn kì yíò panilára bẹ̃ni wọn kì yíò panirun ní gbogbo òkè mímọ́ mi, nítorí ayé yíò kún fún ìmọ̀ Olúwa, gẹ́gẹ́bí omi ti bò ojú òkun.

10 Àti ní ọjọ́ nã kùkùté Jéssè kan yíò wà, tí yíò dúró fún òpágun àwọn ènìyàn; òun ni àwọn Kèfèrí yíò wá rí; ìsimi rẹ̀ yíò sì ní ògo.

11 Yíò sì ṣe ní ọjọ́ nã tí Olúwa yíò tún nawọ́ rẹ̀ ní ìgbà èkejì láti gba àwọn ènìyàn rẹ̀ ìyókù padà tí yíò kù, láti Assíríà, àti láti Égíptì, àti láti Pátrósì, àti láti Kúṣì, àti láti Elámù, àti láti Ṣínárì, àti láti Hámátì, àti láti àwọn erékùṣù òkun.

12 Òun yíò sì gbé ọ̀págun kan dúró fún àwọn orílẹ̀-èdè, yíò sì gbá àwọn àṣàtì Isráẹ́lì jọ, yíò sì kó àwọn tí a túká ní Júdà jọ láti igun mẹ́rin ayé wá.

13 Ìlara Efráímù yíò lọ kúrò pẹ̀lú, àwọn ọ̀tá Júdà ni a ó sì gé kúrò; Efráímù kì yíò ṣe ìlara Júdà, Júdà kì yíò sì bá Efráímù nínú jẹ́.

14 Ṣùgbọ́n wọn yíò sì fò mọ́ èjìká àwọn Filístínì síhà ìwọ̀-oòrùn; wọn yíò jùmọ̀ ba àwọn ti ìlà-oòrùn jẹ́; wọn yíò sì gbé ọwọ́ wọn le Édómù àti Móábù; àwọn ọmọ Ámọ́nì yíò sì gbọ́ràn sí wọ́n lẹ́nu.

15 Olúwa yíò sì pa ahọ́n òkun Égíptì run tũtú; pẹ̀lú ẹ̀fũfù líle rẹ̀ yíò sì mi ọwọ́ rẹ̀ lórí odò nã, ti yíò pín in sí odò ṣíṣàn méje, tí àwọn ènìyàn yíò sì lã kọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ.

16 Ọ̀nà òpópó kan yíò sì wà fún ìyókù àwọn ènìyàn rẹ tí yíò kù, láti Assíríà, gẹ́gẹ́bí ó ti rí fún Isráẹ́lì ní ọjọ́ tí ó gòkè jáde kúrò ní ilẹ̀ Égíptì.