Àwọn Ìwé Mímọ́
2 Nífáì 13


Ori 13

Júdà àti Jerúsálẹ́mù ni a ó jẹ níyà fún àìgbọ́ran wọn—Olúwa bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ó sì dájọ́ fun wọn—Àwọn ọmọbìnrin Síónì ni a fi bú tí a sì dá lóró fún ìfẹ́ ayé wọn—Fi Isaiah 3 wé é. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Nítorí kíyèsĩ i, Olúwa, Olúwa àwọn Ọmọ-ogun, mú kúrò nínú Jerúsálẹ́mù, àti nínú Júdà, ìdádúró àti ọ̀pá, gbogbo ọ̀pá oúnjẹ, àti gbogbo ìdádúró omi—

2 Alágbára ọkùnrin, àti ọkùnrin ogun, onídàjọ́, àti wòlĩ, àti amòye, àti àgbà;

3 Balógun ãdọ́ta, àti ọkùnrin ọlọ́lá, àti olùdámọ́ràn, àti alárèkérekè oníṣọnà, àti alásọdùn tí ó mọ́ ọ̀rọ̀ sọ.

4 Èmi yíò sì fi àwọn ọmọdé fún wọn láti jẹ́ ọmọ-aládé wọn, àwọn ọmọ-ọwọ́ ni yíò sì má a ṣe àkóso wọn.

5 Àwọn ènìyàn ni a ó sì ni lára, olúkúlùkù lọ́wọ́ ẹnìkejì, àti olúkúlùkù lọ́wọ́ aládũgbò rẹ̀; ọmọdé yíò hùwà ìgbéraga sí àgbà, àti àìlọ́lá sí ọlọ́lá.

6 Nígbàtí ènìyàn kan yíò di arákùnrin rẹ̀ ti ilé bàbá rẹ̀ mú, yíò sì wípé: Ìwọ ní aṣọ, máa ṣe alákõso wa, kí o má sì jẹ́ kí ìparun yí wá lábẹ́ ọwọ́ rẹ—

7 Ní ọjọ́ nã ni yíò búra, wípé: Èmi kì yíò ṣe oníwòsàn; nítorí ní ilé mi kò sí oúnjẹ tàbí aṣọ; má ṣe fi èmi ṣe alákõso àwọn ènìyàn nã.

8 Nítorí Jerúsálẹ́mù di ìparun, Júdà sì ṣubú, nítorí ahọ́n wọn àti ìṣe wọn lòdì sí Olúwa, láti mú ojú ògo rẹ̀ bínú.

9 Ìwò ojú wọn njẹ́rĩ í sí wọn, ó sì nfi ẹ̀ṣẹ̀ wọn hàn àní bí Sódómù, wọn kò sì lè pa á mọ. Egbé ni fún ọkàn wọn, nítorí wọ́n ti fi ibi san á fún ara wọn!

10 Ẹ sọ fún olódodo pé ó dára fún wọn; nítorí wọn yíò jẹ èso iṣe wọn.

11 Ègbé ni fún ènìyàn búburú, nítorí wọn yíò parun; nítorí èrè ọwọ́ wọn yíò wà lórí wọn!

12 Àti àwọn ènìyàn mi, àwọn ọmọdé ni olùnilára wọn, àwọn obìnrin sì njọba lórí wọn. A! ẹ̀yin ènìyàn mi, àwọn tí ntọ́ ọ sọ́nà mú ọ láti ṣìnà àti láti pa ipa ọ̀nà rẹ run.

13 Olúwa dìde dúró láti sìpẹ̀, ó sì dìde láti dá àwọn ènìyàn nì ẹjọ́.

14 Olúwa yíò lọ sínú ìdájọ́ pẹ̀lú àwọn àgbà ènìyàn rẹ̀ àti àwọn ọmọ-aládé inú wọn; nítorí ẹ̀yin ti jẹ ọgbà-àjàrà nì run àti ẹrú àwọn tálákà nínú ilé yín.

15 Kíni ẹ̀yin rò? Ẹ fọ́ àwọn ènìyàn mi sí wẹ́wẹ́, ẹ sì fi ojú àwọn tálákà rinlẹ̀, ni Olúwa Ọlọ́run àwọn Ọmọ-ogun wí.

16 Pẹlupẹlu, Olúwa wípé: Nítorí tí àwọn ọmọbìnrin Síónì gbéraga, tí wọ́n sì nrìn pẹ̀lú ọrùn nína jáde àti ojú ìfẹ́kúfẹ́, tí wọ́n nrìn tí wọ́n sì nyan bí wọ́n ti nlọ, tí wọ́n sì n ró wõro pẹ̀lú ẹsẹ̀ wọn—

17 Nítorínã Olúwa yíò lu adé orí àwọn ọmọbìnrin Síónì pẹ̀lú ẽpá, Olúwa yíò sì jágbọ́n àwọn ipa àṣírí wọn.

18 Ní ọjọ́ nã Olúwa yíò mú ìgboyà àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wọn tí nró wõro kúrò, àti àwọn iweri irun, àti àwọn ohun ọ̀ṣọ́ ti o dabi òṣùpá;

19 Àwọn ẹ̀wọ̀n ọ̀ṣọ́, àti àwọn jufù, àti àwọn ìbojú;

20 Àwọn akẹ̀tẹ̀, àti àwọn ohun ọ̀ṣọ́ ẹsẹ̀, àti àwọn ọ̀já-orí, àti àwọn ago olõrùn dídùn, àti àwọn òrùka etí;

21 Àwọn òrùka, àti ọ̀ṣọ́-imú;

22 Ìpãrọ̀ àwọn aṣọ wíwọ̀, àti àwọn aṣọ ilékè, àti àwọn ìborùn, àti àwọn ìkótí;

23 Àwọn dígi, àti aṣọ ọ̀gbọ dáradára, àti àwọn ìborí, àti àwọn ìbojú.

24 Yíò sì ṣe, dípò õrùn dídùn õrùn búburú yíò wà; àti dípò àmùrè, àkísà; àti dípò irun dídì dáradára, orí pípá; àti dípò ìgbàyà, sísán aṣọ ọ̀fọ̀; ìjóná dípo ẹwà.

25 Àwọn ọkùnrin yín yíò ti ipa idà ṣubú àti àwọn alágbára yín ní ogun.

26 Àwọn ibodè rẹ̀ yíò sì pohùnréré ẹkún wọn yíò sì ṣọ̀fọ̀; òun yíò sì di ahoro, yíò sì jókó lórí ilẹ̀.