Àwọn Ìwé Mímọ́
2 Nífáì 4


Ori 4

Léhì gba ìran àtẹ̀lé rẹ̀ níyànjú ó sì súre fún wọn—Ó kú a sì sin ín—Nífáì nṣògo nínú õre Ọlọ́run—Nífáì fi ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ sínú Olúwa títí láé. Ní ìwọ̀n ọdún 588 sí 570 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí, èmi, Nífáì, sọ̀rọ̀ nípa ti àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ nípa èyí tí bàbá mi ti sọ̀, nípa ti Jósẹ́fù, ẹni tí a gbé lọ sí ilẹ̀ Égíptì.

2 Nítorí kíyèsĩ i, ó sọtẹ́lẹ̀ nítõtọ́ nípa ti gbogbo irú-ọmọ rẹ̀. Àwọn ìsotẹ́lẹ̀ èyí tí ó sì kọ, kò sí púpọ̀ tí ó tóbijù. Ó sì sọtẹ́lẹ̀ nípa wa, àti àwọn ìran wa ìgbà tí mbọ̀; a sì kọ wọ́n sórí àwọn àwo idẹ.

3 Nítorí-èyi, lẹ́hìn tí bàbá mi ti fi òpin sí ọ̀rọ̀ sísọ nípa ti àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ ti Jósẹ́fù, ó pe àwọn ọmọ Lámánì, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀, ó sì wí fún wọn: Kíyèsĩ i, ẹ̀yin ọmọkùnrin mi, àti ẹ̀yin ọmọbìnrin mi, tí ó jẹ́ àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin àkọ́bí mi, èmi nfẹ́ wípé kí ẹ fi etí sí àwọn ọ̀rọ̀ mi.

4 Nítorí Olúwa Ọlọ́run ti wípé: Níwọ̀n bí ẹ̀yin bá pa àwọn òfin mi mọ́ ẹ̀yin yíò ṣe rere ní ilẹ̀ nã; níwọ̀n bí ẹ̀yin kò bá sì pa àwọn òfin mi mọ́ a ó gé yín kúrò níwájú mi.

5 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, ẹ̀yin ọmọkùnrin mi àti ẹ̀yin ọmọbìnrin mi, èmi kò lè sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibojì mi àfi tí èmi bá fi ìbùkún sílẹ̀ sórí yín; nítorí kíyèsĩ ì, èmi mọ̀ wípé bí a bá tọ́ yín dàgbà ní ọ̀nà tí ẹ̀yin yíò tọ ẹ̀yin kì yíò kúrò nínú rẹ̀.

6 Nítorí-èyi, bí a bá fi yín gégun, kíyèsĩ i, èmi fi ìbùkún mi sílẹ̀ sórí yín, kí á lè mú ègun nã kúrò lórí yín kí á sì dáhùn rẹ̀ lórí àwọn òbí yín.

7 Nítorí-èyi, nítorí ti ìbùkún mi Olúwa Ọlọ́run kì yíò jẹ́ kí ẹ parun; nítorí-èyi, òun yíò ni-áanú sí yín àti sí irú-ọmọ yín títí láé.

8 Ó sì ṣe tí lẹ́hìn tí bàbá mi ti fi òpin sí ọ̀rọ̀ sísọ sí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin Lámánì, ó jẹ́ kí á mú àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin Lẹ́múẹ́lì wá síwájú òun.

9 Ó sì sọ fún wọn, wípé: Kíyèsĩ i, ẹ̀yin ọmọkùnrin mi àti ẹ̀yin ọmọbìnrin mi, tí ẹ jẹ́ àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin ọmọkùnrin mi èkejì; kíyèsĩ i mo fi fún yín ìbùkún kannã èyí tí mo fi fún àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin Lámánì; nítorí-èyi, a kì yíò pa yín run pátápátá; ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀hìn irú-ọmọ yín ni a ó bùkún fún.

10 Ó sì ṣe tí nígbà tí bàbá mi ti fi òpin sí ọ̀rọ̀ sísọ sí wọn, kíyèsĩ i, ó sọ̀rọ̀ sí àwọn ọmọkùnrin Íṣmáẹ́lì, bẹ̃ni, àti gbogbo agbolé rẹ̀ pãpã.

11 Lẹ́hìn tí ó sì ti fi òpin sí ọ̀rọ̀ sísọ sí wọn, ó sọ̀rọ̀ sí Sãmú, wípé: alábunkun-fun ni ìwọ, àti irú-ọmọ rẹ; nítorí ìwọ yíò jogún ilẹ̀ nã bí ti arákùnrin rẹ Nífáì. A ó sì ka irú-ọmọ rẹ pẹ̀lú irú-ọmọ rẹ̀; ìwọ yíò sì dàbí ti arákùnrin rẹ pãpã, àti irú-ọmọ rẹ yíò dàbí ti irú-ọmọ rẹ̀; a ó sì bùkún-fún ọ ní gbogbo àwọn ọ́jọ́ rẹ.

12 Ó sì ṣe lẹ̀hìn tí bàbá mi, Léhì, ti bá gbogbo agbolé rẹ̀ sọ̀rọ̀, gẹ́gẹ́bí ìmọ̀ ọkàn rẹ̀ àti Ẹ̀mí Olúwa èyí tí mbẹ nínú rẹ̀, ó darúgbó. Ó sì ṣe tí ó kú, tí a sì sin ín.

13 Ó sì ṣe tí láìpé ojọ́ púpọ̀ lẹ́hìn ikú rẹ̀, Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì àtí àwọn ọmọkùnrin Íṣmáẹ́lì bínú sí mi nítorí ti àwọn ìbáwi Olúwa.

14 Nítorí èmi, Nífáì, ni a rọ̀ láti sọ̀rọ̀ sí wọn, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀; nítorí mo ti sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun sí wọn, àti bàbá mi pẹ̀lú, kí ó tó kú; ọ̀pọ̀lọpọ̀ sísọ èyí tí a kọ sórí àwọn àwo mi míràn; nítorí apákan tí ó jẹ́ ìwé ìtàn jùlọ ni a kọ sórí àwọn àwo mi míràn.

15 Si órí àwọn wọ̀nyí sì ni mo kọ àwọn ohun ọkàn mi, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé-mímọ́ èyí tí a fín sórí àwọn àwo idẹ. Nítorí ọkàn mi yọ̀ nínú ìwé-mímọ́, ọkàn mi sì rò wọ́n, ó sì kọ wọ́n fún ẹ̀kọ́ àti ànfàní àwọn ọmọ mi.

16 Kíyèsĩ i, ọkan mi yọ̀ nínú àwọn ohun Olúwa; ọkàn mi sì nrò títí lọ lórí àwọn ohun èyí tí mo ti rí tí mo sì ti gbọ́.

17 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, l’áìṣírò ti õre nlá Olúwa, ní fífi àwọn iṣẹ́ nlá àti ti ìyanu rẹ̀ hàn mí, ọkàn mi kígbe sókè: A! Èmi ọkùnrin òṣì! Bẹ̃ni, ọkàn mi kún fún ìbànújẹ́ nítorí ti ẹran ara mi; ẹ̀mí mi kẹ́dùn nítorí ti àìṣedẽdé mi.

18 A yí mi ká kiri, nítorí àwọn ìdánwò àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó fi ìrọ̀rùn rọ̀gbàká mi.

19 Nígbàtí mo bá sì fẹ́ láti yọ̀, ọkàn mi nkérora nítorí ti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi; bíótilẹ̀ríbẹ̃, mo mọ́ ẹní tí mo ti gbẹ́kẹ̀lé.

20 Ọlọ́run mi ti jẹ́ alatilẹhin mi; ó ti tọ́ mi já àwọn ìpọ́njú mi nínú ijù; ó sì ti pa mí mọ́ lórí àwọn omi ibú nlá wọnnì.

21 Ó ti fi ìfẹ́ rẹ̀ kún mi, àní sí jíjẹ ẹran ara mi run.

22 Ó ti dãmú àwọn ọ̀tá mi, sí mímú wọn láti gbọ̀n níwájú mi.

23 Kíyèsĩ i, ó ti gbọ́ igbe mi nígbà ọ̀sán, ó sì ti fi ìmọ̀ fún mi nípa ìran ní ìgbà-òru.

24 Nígbà ọ̀sán sì ni mo gbóyà si ní àdúrà tí ó lágbára níwájú rẹ̀; bẹ̃ni, ohùn mi ni mo ti rán lọ sí òkè; àwọn angẹ́lì sì sọ̀kalẹ̀ wá wọ́n sì ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ fún mi.

25 Lórí àwọn ìyẹ́ apá Ẹ̀mí rẹ̀ sì ni a ti gbé ara mi lọ sórí àwọn òkè gíga-gíga. Ojú mi sì ti kíyèsĩ àwọn ohun nlá, bẹ̃ni, àní tí o tóbi jù fún ènìyàn; nítorí-èyi a fi àṣẹ fúnmi ki èmi máṣe kọ wọ́n.

26 Njẹ́, bí èmi bá ti rí àwọn ohun nlá báyĩ, bí Olúwa ní ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn bá ti bẹ àwọn ènìyàn wò ní ãnú púpọ̀ báyĩ, ẽṣe tí ọkàn mi yíò fi sọkún tí ẹ̀mí mi yíò sì fi lọ́ra ní àfonífojì ìrora-ọkàn, tí ẹran ara mi yíò sì ṣòfò kúrò, tí agbára mí yíò sì fi fàsẹ́hìn, nítorí ti àwọn ìpọ́njú mi?

27 Èéṣe tí èmi yíò sì fi yọ̃da sí ẹ̀ṣẹ̀, nítorí ẹran ara mi? Bẹ̃ni, ẹ̃ṣe tí èmi yíò fi ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn ìdánwò, tí ẹni búburú nì yíò ní ãyè ní ọkàn mi láti pa àlãfíà mi run kí ò sì pọ́n ẹ̀mí mi lójú? Èéṣe tí èmi fi nbínú nítorí ọ̀tá mi?

28 Jí, ọkàn mi! Máṣe soríkọ́ ní ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. Yọ̀, A! ọkàn mi, kí o másì ṣe fi ãyè fún ọ̀tá ọkàn mi mọ́.

29 Máṣe tún bínú nítorí àwọn ọ̀tá mi. Máṣe fa agbára mi sẹ́hìn nítorí àwọn ìpọ́njú mi.

30 Yọ̀, A! ọkàn mi, sì kígbe sí Olúwa, sì wípé: A! Olúwa, èmi yíò yìn ọ́ títí láé; bẹ̃ni, ọkàn mi yíò yọ̀ nínú rẹ, Ọlọ́run mi, àti àpáta ìgbàlà mi.

31 A! Olúwa, ìwọ yíò ha ra ẹ̀mí mi padà bí? Ìwọ yíò ha gbà mí sílẹ̀ kúrò ní ọwọ àwọn ọ̀tá mi bí? Ìwọ yíò ha mú mi kí èmi lè gbọ̀n ní ìfarahàn ẹ̀ṣẹ̀ bí?

32 Kí àwọn ilẹ̀kùn ọ̀run àpãdì máa tì títí níwájú mi, nítorí tí ọkàn mi ti ní ìrora ẹ̀mí mi sì ti ní ìròbìnújẹ́! A! Olúwa, ìwọ kì yíò ha tí ilẹkùn òdodo rẹ níwájú mi bí, kí èmi lè rìn ní ipa-ọ̀nà ti àfonífojì tí kò ga, kí èmi lè mú ògírí ní ọ̀nà tí ó tẹ́jú!

33 A! Olúwa, ìwọ yíò ha rọ̀gbà yí mi ká ní ẹ̀wù òdodo rẹ bí! A! Olúwa, ìwọ yíò ha ṣe ọ̀nà fun ìsálà mi níwájú àwọn ọ̀tá mi bí! Ìwọ yíò ha mú ipa-ọ̀nà mi tọ́ níwájú mi bí! Ìwọ kì yíò ha fi ohun ìdigbòlù sí ọ̀nà mi bí—ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó gbá ọ̀nà mi mọ́ níwájú mi, kí o másì ṣe so ọgbà yí ọ̀nà mi ká, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀nà ọ̀tá mi.

34 A! Olúwa, èmi ti gbẹ́kẹ̀lé ọ, èmi yíò sì gbẹ́kẹ̀lé ọ títí láé. Èmi kì yíò fi ìgbẹ́kẹ̀lé mi sí apá ẹran ara; nítorí mo mọ̀ wípé ègbé ni fún ẹni tí ó fi ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ sí apá ẹran ara. Bẹ̃ni, ègbé ni fún ẹni tí ó fi ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ sí ènìyàn tàbí tí ó fi ẹran ara ṣe agbára rẹ̀.

35 Bẹ̃ni, mo mọ̀ wípé Ọlọ́run yíò fi fún ẹni tí ó bá bẽrè ní ọlọ̀lọpọ̀. Bẹ̃ni, Ọlọ́run mi yíò fi fún mi, bí èmi kò bá ṣì bèrè; nítorí-èyi èmi yíò gbé ohùn mi sókè sí ọ; bẹ̃ni, èmi yíò kígbe sí ọ, Ọlọ́run mi, àpáta òdodo mi. Kíyèsĩ i, ohùn mi yíò gòkè sí ọ títí láé, àpáta mi àti Ọlọ́run àìnípẹ̀kun mi. Àmín.