Àwọn Ìwé Mímọ́
2 Nífáì 22


Ori 22

Ní ọjọ́ ẹgbẹ̀rún ọdún gbogbo ènìyàn yíò yin Olúwa—Òun yíò gbé ní ãrín wọn—Fi Isaiah 12 wé e. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Àti ní ọjọ́ nã ìwọ ó wípé: A! Olúwa, èmi yíò yìn ọ́; bíótilẹ̀jẹ́pé ìwọ bínú sí mi ìbínú rẹ ti yí kúrò, ìwọ sì tù mí nínú.

2 Kíyèsĩ i, Ọlọ́run ni ìgbàlà mi; èmi ó gbẹ́kẹ̀lé e, èmi kì yíò sì bẹ̀rù; nítorí Olúwa Jèhófàh ni agbára mi àti orin mi; òun pẹ̀lú ti di ìgbàlà mi.

3 Nítorínã, pẹ̀lú ayọ̀ ni ẹ̀yin yíò fa omi jáde láti inú kànga ìgbàlà wá.

4 Ní ọjọ́ nã ni ẹ̀yin yíò sì wípé: Yin Olúwa, képe orúkọ rẹ̀, sọ àwọn ìṣe rẹ̀ lãrín àwọn ènìyàn, múu wa sí ìrantí pé orúkọ rẹ̀ ni a gbé lékè.

5 Kọrin sí Olúwa; nítorí ó ti ṣe àwọn ohun dídára; èyí di mímọ̀ ní gbogbo ayé.

6 Kígbe sóde kí o sì hó, ìwọ olùgbe Síónì; nítorí ẹni títóbi ni Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì ní ãrin rẹ.