Àwọn Ìwé Mímọ́
2 Nífáì 31


Ori 31

Nífáì sọ ìdí rẹ̀ tí a fi rì Krístì bọmi—Àwọn ènìyàn gbọdọ̀ tẹ̀lé Krístì, kí á rì wọn bọmi, kí wọ́n gba Ẹ̀mí Mímọ́, kí wọ́n sì forítì í dé òpin kí a lè gbà wọ́n là—Ìrònúpìwàdà àti ìrìbọmi ni ẹnu-ọ̀nà sí ojú-ọ̀nà híhá àti tõró—Ìyè àìnípẹ̀kun nwá fún àwọn tí ó bá pa àwọn òfin mọ́ lẹ́hìn ìrìbọmi. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí èmi, Nífáì, fi òpin sí ísọ-tẹ́lẹ̀ mi sí yín, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́. Èmi kò sì lè kọ̀wé àfi àwọn ohun díẹ̀, èyí tí mo mọ̀ pé dájúdájú kò lè ṣàìṣẹ; bẹ̃ni èmi kò le kọ̀we àfi díẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ arákùnrin mi Jákọ́bù.

2 Nítorí-èyi, àwọn ohun èyí tí mo ti kọ tẹ́ mi lọ́rùn, àfi ti àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀ tí èmi gbọdọ̀ sọ nípa ẹ̀kọ́ Krístì; nítorí-èyi, èmi yíò sọ̀rọ̀ fún yín ni kedere, gẹ́gẹ́bí ti kíkedere sísọ-tẹ́lẹ̀ mi.

3 Nítorí ọkàn mi yọ̀ ní kíkedere; nítorí irú ọ̀nà báyĩ ni Olúwa Ọlọ́run gbà nṣiṣẹ́ lãrín àwọn ọmọ ènìyàn. Nítorí Olúwa Ọlọ́run fúnni ní ìmọ́lẹ̀ fún òye; nítorí tí o sọ̀rọ̀ sí ènìyàn gẹ́gẹ́bí èdè wọn, fún oye wọn.

4 Nítorí-èyi, èmi fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó rántí pé èmi ti sọ̀rọ̀ fún yín nípa wòlĩ nì èyí tí Olúwa fihàn sí mi, tí yíò rì Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run bọmi, tí yíò kó àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ.

5 Àti nísisìyí, bí Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run, òun tí ó jẹ́ mímọ́, bá rĩ pé ó tọ́ kí á rì òun bọmi nípa ti omi, láti mú gbogbo òdodo ṣẹ, A! njẹ́, báwo ni o ṣe tọ́ fun wa to, tí a jẹ́ aláìmọ́, láti ṣe ìrìbọmi, bẹ̃ni, àní nípa ti omi!

6 Àti nísisìyí, èmi yíò bí yín, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, nínú kíni Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run ti mú gbogbo òdodo ṣẹ ní mímúu ṣe ìrìbọmi nípati omi?

7 Ẹ̀yin kò ha mọ̀ pé ó jẹ́ mímọ́ bí? Ṣùgbọ́n l’áìṣírò ó jẹ́ mímọ́, ó fihàn sí àwọn ọmọ ènìyàn pé, nípa ti ara òun rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Bàbá, ó sì jẹ́rĩ sí Bàbá pé òun yíò ní ígbọ́ran sí i ní pípa àwọn òfin rẹ̀ mọ́.

8 Nítorí-èyi, lẹ́hìn tí a rì bọmi pẹ̀lú omi Ẹ̀mí Mímọ́ sọ̀kalẹ̀ sí órí rẹ̀ ní ìṣe ti àdàbà.

9 Àti ẹ̀wẹ̀, ó fihàn sí àwọn ọmọ ènìyàn híhá ọ̀nà nã, àti títõró ẹnu-ọ̀nà nã, nípasẹ̀ èyí tí wọn yíò wọlé, níwọ̀n bí òun ti fi àpẹrẹ lélẹ̀ níwájú wọn.

10 Ó sì wí fún àwọn ọmọ ènìyàn: Ẹ̀yin ẹ máa tọ̀ mí lẹ́hìn. Nítorí-èyi, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, àwá ha lè tọ Jésù lẹ́hìn bíkòṣe pe àwa yíò ní ìfẹ́ láti pa àwọn òfin Baba mọ́?

11 Baba nã sì wípé: Ẹ ronúpìwàdà, ẹ ronúpìwàdà, kí á sì rì yín bọmi ní orúkọ Àyànfẹ́ Ọmọ mi.

12 Àti pẹ̀lú, ohùn ti Ọmọ nã wá sọ́dọ̀ mi, ó nwí pé: Ẹni nã tí a bá rìbọmi ní orúkọ mi, sí òun ni Baba yíò fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún, bí tí èmi; nítorí-èyi, ẹ máa tọ̀ mí lẹ́hìn, kí ẹ sì ṣe àwọn ohun tí ẹ ti rí mi tí mo ṣe.

13 Nítorí-èyi, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, mo mọ̀ pé bí ẹ̀yin yíò bá tọ Ọmọ nã lẹ́hìn, pẹ̀lú èrò ọkàn kíkún, láìṣe ìwà àgàbàgebè àti láìsí ẹ̀tàn níwájú Ọlọ́run, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìdí tí o dájú, tí ẹ̀ nronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, tí ẹ̀ njẹ́rĩ sí Baba pé ẹ̀yin ní ìfẹ́ láti gbé orúkọ Krístì lé órí, nípasẹ̀ ìrìbọmi—bẹ̃ni, nípasẹ̀ títọ Olúwa yín àti Olùgbàlà yín lẹ́hìn sọ̀kalẹ̀ sínú omi, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀, kíyèsĩ i, nígbànã ni ẹ̀yin yíò rí Ẹ̀mí Mímọ́ gba; bẹ̃ni, nígbànã ni ìrìbọmi ti iná àti ti Ẹ̀mí Mímọ́ yíò wá; nígbànã sì ni ẹ̀yin lè sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ahọ́n àwọn ángẹ́lì, tí ẹ sì lè pariwo ìyìn sí Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì.

14 Ṣùgbọ́n, kíyèsĩ i, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, báyĩ ni ohùn Ọmọ na a wá sí ọ̀dọ̀ mi, ó nwí pé: Lẹ́hìn tí ẹ̀yin bá ti ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, tí ẹ sì jẹ́rĩ sí Baba pé ẹ̀yin ní ìfẹ́ láti pa àwọn òfin mi mọ́, nípasẹ̀ ìrìbọmi ti omi, tí ẹ sì ti gba ìrìbọmi ti iná àti ti Ẹ̀mí Mímọ́, tí ẹ sì lè sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ahọ́n titun, bẹ̃ni, àní pẹ̀lú ahọ́n àwọn ángẹ́lì, àti lẹ́hìn èyí tí ẹ bá sẹ́ mi, ìbá ti sànjù fún yín kí ẹ̀yin má ti mọ̀ mí.

15 Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀dọ̀ Baba, tí ó nwípé: Bẹ̃ni, àwọn ọ̀rọ̀ Àyànfẹ́ mi jẹ́ òtítọ́ àti òdodo. Ẹni tí ó bá forítì í títí dé òpin, òun nã ni a ó gbàlà.

16 Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, mo mọ̀ nípa èyí pé bíkòṣepé ènìyàn bá forítì í dé òpín, ní títẹ̀lé àpẹrẹ ti Ọmọ Ọlọ́run alãyè, a kò lè gbà á là.

17 Nítorí-èyi, ẹ ṣe àwọn ohun èyí tí mo ti sọ fún yín tí mo ti rí tí Olúwa yín àti Olùràpadà yín yíò ṣe; nítorí, fún ìdí èyí ni a ṣe fi wọ́n hàn sí mi, kí ẹ̀yin lè mọ́ ẹnu ọ̀nà nípasẹ̀ èyí tí ẹ̀yin yíò bá wọlé. Nítorí ẹnu ọ̀nà nípasẹ̀ èyí tí ẹ̀yin yíò bá wọlé ni ìrònúpìwàdà àti ìrìbọmi nípasẹ̀ omi; nígbànã sì ni ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín nípasẹ̀ iná àti nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ nbọ̀wá.

18 Nígbànã sì ni ẹ̀yin wà ní ọ̀nà híhá àti tõró yí èyí tí ó ṣe amọ̀nà sí ìyè àìnípẹ̀kun; bẹ̃ni, ẹ̀yin ti wọlé nípasẹ̀ ẹnu ọ̀nà, ẹ̀yin ti ṣe gẹ́gẹ́bí àwọn òfin ti Baba àti Ọmọ; ẹ̀yin sì ti gba Ẹ̀mí Mímọ́, èyí tí o jẹ́rĩ Baba àti Ọmọ, sí mímú ìlérí èyí tí ó ti ṣe ṣẹ, pé bí ẹ̀yin bá wọlé nípasẹ̀ ọ̀nà nã ẹ̀yin yíò rí gbà.

19 Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, lẹ́hìn ti ẹ̀yin bá ti bọ́ sí ọ̀nà híhá àti tõró yí, ẹ̀mi yíò bèrè bóyá a ti ṣe gbogbo nkan? Kíyèsĩ, mo wí fún yin, Rárá; nítorí ẹ̀yin kò ti wá jìnà tó èyí bíkòṣe nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Krístì pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tí kò mì nínú rẹ̀, tí ẹ ngbẹ́kẹ̀lé gbogbo àṣepé rẹ̀ pátápátá, ẹni tí ó jẹ́ alágbára láti gbàlà.

20 Nítorí-èyi, ẹ̀yin kò lè sai tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìdúróṣinṣin nínú Krístì, kí ẹ ní ìrètí dídán, àti ìfẹ́ ti Ọlọ́run àti ti gbogbo àwọn ènìyàn. Nítorí-èyi, bí ẹ̀yin yíò bá tẹ̀síwájú, tí ẹ̀ nṣe àpéjẹ lórí ọ̀rọ̀ Krístì, tí ẹ sì forítì í dé òpin, kíyèsĩ i, báyĩ í ni Baba wí: Ẹ̀yin yíò ní ìyè àìnípẹ̀kun.

21 Àti nísisìyí, kíyèsĩ i, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, èyí ni ọ̀nà nã; kò sì sí ọ̀nà míràn tàbí orúkọ tí a fi fún ni lábẹ́ ọ̀run nípa èyí tí a lè fi gba ènìyàn là ní ìjọba Ọlọ́run. Àti nísisìyí, kíyèsĩ i, èyí ni ẹ̀kọ́ ti Krístì, àti ẹ̀kọ́ ọ̀kanṣoṣo àti òtítọ́ ti Baba, àti ti Ọmọ, àti ti Ẹ̀mí Mímọ́, èyí tí ó jẹ́ Ọlọ́run kan, àìnípẹ̀kun òpin. Àmín.